Adaparọ ninu Bibeli.


  Iwe ti Ifihan jara.

Jẹnẹsisi.

Ọrọ naa “Jẹnẹsisi” tumọ si “Awọn ibẹrẹ”. Ohun gbogbo le ti wa ni itopase pada si awọn Iwe ti Jẹnẹsisi. Ni akọkọ aye ní kan wọpọ (monotheistic) esin. Polytheism bẹrẹ ni Jẹnẹsisi 11, lakoko ikole Babiloni.


  Adaparọ.

Awọn orisun - Babeli.


William Branham.

Ka iroyin ni kikun ni...
Igba Ijọ Pagamu.

Babẹli ni orukọ Babiloni ni atetekọṣẹ. Itumọ rẹ ni idarudapọ. Kuuṣi ọmọ Hamu gan an ni o bẹrẹ rẹ, ṣugbọn ni akoko Nimrọdu ọmọ rẹ ogboju-ọdẹ, ni a sọ ọ di ilẹ-ọba-nla ti o ni agbara, ti o si tobi. Nimrọdu, gẹgẹ bi akọsilẹ Jẹnẹsisi 11 ati awọn iwe-itan aye ti ṣo, pinnu lati ṣe awọn aṣeyọri mẹta. O fẹ lati gbe orilẹ-ede ti o ni agbara kan dide, o si ṣe bẹẹ. O fẹ tan ẹsin oun tikalararẹ kalẹ, o si ṣe bẹẹ. O fẹ orukọ ma-ni-gbagbe kan fun ara rẹ. O si ṣe aṣeyọri ninu eyi naa pẹlu. Awọn aṣeyọri wọnyi jẹ ohun ma-nigbagbe to bẹẹ gẹẹ ti a fi i pe ijọba Babiloni ni ori wura láàárín gbogbo ijọba aye. Lati wi pe ẹsin rẹ naa gborí, ni a lee fi idi rẹ mulẹ nipa bi Iwe Mimọ ti fi i han pẹlu Satani patapata ni Aisaya 14 ati Ifihan 17 ati 18. Lati inu iwe-itan, a lee fi idi rẹ mulẹ wi pe ẹsin naa fi ipa gbilẹ ni gbogbo agbanla aye, oun si ni ipilẹ fun gbogbo ilana ibọriṣa ati koko pataki gbogbo ilana itan-asan, bi o tilẹ jẹ wi pe orukọ awọn oriṣa naa yatọ si ara wọn kaakiri agbanla aye ni ibamu pẹlu ede awọn eniyan rẹ. Lati wi pe o gba orukọ ma-nigbagbe fun ara rẹ ati awọn ọmọ-lẹyin rẹ kọja sisọ, nitori ni iwọn igba ti aye isisinyi ba n tẹsiwaju (titi ti Jesu yoo fi fi ara Rẹ han fun awọn arakunrin Rẹ) ni wọn yoo maa jọsin, ti wọn yoo ma bu ọla fun Nimurọdu, bi o tilẹ jẹ wi pe orukọ miiran ti o yatọ diẹ si Nimurọdu ni wọn o maa pe, ati ninu ile oriṣa ti o yatọ kiun si eyi ti a ti kọkọ n juba rẹ.

Niwọn igba ti Bibeli ki i sọ ọrọ nipa itan awọn orilẹ-ede miiran lẹkunrẹrẹ, o ṣe pataki fun wa lati ṣe ayẹwo akọsilẹ-itan ti igba laelae ti ko ni imisi Ẹmi Ọlọrun, lati lee ri idahun si ibeere wa bi Pagamu ṣe di ibujoko ẹsin Satani ti Babiloni. Awọn ibi pataki ti a ti lee ri ohun ti a n wa ni awọn akọsilẹ nipa igbe-aye ọlàju awọn ara Ijipiti ati ti awọn Giriki. Idi ni wi pe ọwọ awọn ara Kaldia ni Ijipiti ti gba imọ sayẹnsi ati iṣiro, awọn Giriki si gba a lati Ijipiti.

Niwọn igba ti o jẹ wi pe awọn abọrẹ̀ ni o wa ni iṣakoso fifi ẹkọ awọn sayẹnsi wọnyi kọni, ati niwọn igba ti wọn lo awọn sayẹnsi wọnyi gẹgẹ bi ara ẹsin ibọrisa, eyi ti fun wa ni ọna lati loye bi ẹṣin Babiloni ṣe gbilẹ ninu awọn orilẹ-ede mejeeji wọnyi. Otitọ tun ni wi pe, ni igbakugba ti orilẹ-ede kan ba ṣẹgun omiran, lai pẹ ẹsin orilẹ-ede ti o ṣẹgun maa n di ẹsin awọn ti a ṣẹgun. Bẹẹ naa ni o jẹ ohun ti a mọn daradara wi pe awọn Giriki ní awọn apẹẹrẹ ilana mejeejila kan naa ti o pin ipa ọna oorun ati awọn ẹda ọrun iyoku si ọna mejila ọgbọọgba (Zodiac) bi i ti awọn ara Babiloni, ati wi pe a si ti ri i ninu awọn akọsilẹ itan atijọ ti Ijipiti wi pe awọn ni wọn fun awọn Giriki ni imọ bibọ oniru-un-ru oriṣa. Bayi ni awọn ijinlẹ Babiloni tan kalẹ lati orilẹ-ede de orilẹ-ede titi ti o fi farahan ni Roomu, China, India, ati ni Ariwa ati Gusu Amẹrika paapaa ni a ti ri ipilẹ ijọsin kan naa.

Dajudaju awọn itan igba ijimiji fi ẹnu kò pẹlu Bibeli wi pe ẹsin Babiloni yii kọ́ ni ẹsin àkọ́kọ́ tí awọn eniyan igba ìwáṣẹ sin. O jẹ ẹsin akọkọ ti o yẹsẹ kuro ninu igbagbọ atetekọṣe naa; ṣugbọn ẹsin yii funrararẹ kọ ni ẹsin atetekọṣe akọkọ. Awọn opitan gẹgẹ bi Wilkson ati Mallett ti fi idi rẹ mulẹ gbangba lati inu awọn akọsilẹ ti igba ijimiji wi pe ni igba kan ri gbogbo awọn eniyan aye gbagbọ ninu ỌLỌRUN KANṢOṢO, Ti o ga julọ, Ti o jẹ Ainipẹkun, Ẹni Airi, Ẹni Ti o fi Ọrọ ẹnu Rẹ da ohun gbogbo, Ti iwa Rẹ kun fun ifẹ, Ẹni Ti o jẹ Rere ati Olododo. Ṣugbọn bi o ti jẹ wi pe ohunkohun ti Satani baa lee dibajẹ ni o maa n dibajẹ, a ri i ti o yi awọn eniyan lọkan pada ki wọn lee kọ Otito silẹ. Bi Satani ti maa n gbiyanju ni igba gbogbo lati gba ijọsin bi ẹni wi pe oun ni Ọlọrun, ani bi i wi pe ki i ṣe iranṣe ati ẹda ọwọ Ọlọrun, o gba ijọsin kuro lọdọ Ọlọrun ki awọn eniyan lee maa sin oun, ati nipa ṣiṣe bẹẹ, ki oun lee di ẹni ti a gbe ga. Dajudaju, o mu ifẹ ọkan rẹ lati tan ẹsin rẹ jakejado agbanla-aye ṣẹ. Ọlọrun jẹri si eyi ni Iwe Roomu bayi wi pe: “Nigba ti wọn mọn Ọlọrun wọn ko yin In logo bi Ọlọrun titi ti wọn fi di asan ni ironu wọn, ati nipa iṣududu ọkan wọn, wọn gba ẹsin idibajẹ, wọn si sin awọn ẹda dipo Ẹlẹda.”

Ranti wi pe ẹda ọwọ Ọlọrun ni Satani (Ọmọ Owurọ). Bayi ni a wa ri i wi pe bi o ti jẹ wi pe nigba kan ri a tan Otitọ kalẹ láàárín awọn eniyan, ti gbogbo wọn si gba Otitọ kan yii gbọ, ọjọ kan de lẹyin igba yii ti ogunlọgọ awọn eniyan yipada kuro lọdọ Ọlọrun ti wọn si n tan iru ẹsin eṣu kan kalẹ ni gbogbo agbanla aye. Itan jẹri si i wi pe awọn ọmọ ẹya Ṣẹmu ti o mu iduro wọn pẹlu Otitọ Ti ki i yipada tako iran Hamu gidigidi, awọn wọnyi ti wọn ti yipada kuro ninu Otitọ si eke Satani. Ko si akoko lati maa fi ọrọ we ọrọ lori eleyi, a kan ṣaa yán an ṣo ni ki o lee ri wi pe ẹsin meji, ani ẹsin meji pere ni o wa, eyi ti o si jẹ buburu ninu wọn ni o di eyi ti a tan kaakiri agbanla-aye.

Igbagbọ ninu Ọlọrun Kanṣoṣo yipada si ẹsin ọpọlọpọ oriṣa ni Babiloni. Irọ eṣu ati awọn ijinlẹ rẹ doju ija kọ Otitọ Ọlọrun ati awọn Ijinlẹ Rẹ ni ilu naa. Satani wa di ọlọrun aye yii ni tootọ, o si bẹrẹ si i fi agbara gba ijọsin lọwọ awọn ti o ti tan jẹ ti o si n mu ki o gbagbọ wi pe ni tootọ oun ni Oluwa.

Ẹsin ọta ti i ṣe bibọ ogunlọgọ oriṣa bẹrẹ pẹlu ẹkọ mẹtalọkan. “Èrò ti ẹni mẹta ninu Ọlọrun kan” yii ti bẹrẹ lati ibẹrẹ ìwáṣẹ wa. O ya ni lẹnu wi pe awọn ẹlẹkọ ijinlẹ awọn ẹsin aye ti ode-oni ko i ti ṣe awari eyi ninu itan, ṣugbọn dajudaju, nitori eṣu ti tan wọn jẹ gẹgẹ bi o ti tan awọn baba-nla wọn jẹ, wọn ṣì gbagbọ sibẹ ninu ẹni mẹta ninu Ọlọrun kan. Jẹki wọn fi ibi kan pere han wa ninu Iwe Mimọ ni ibi ti Ọlọrun ti fi aṣẹ si ẹkọ naa. Njẹ ko ha ya ni lẹnu wi pe ni igba ti awọn ọmọ-ọmọ Hamu n ba ibọriṣa Satani tí ẹkọ ipilẹ rẹ jẹ ti oriṣa mẹta lọ, ko si ami kan rara ti o fi han wi pe awọn ọmọ-ọmọ Ṣẹmu gba ohun ti o jọ bẹẹ gbọ tabi ki wọn ni aṣeyẹ isin ti o tilẹ ni ohun ti o fi ara pẹ ohun ti a lee fi we e? Njẹ ko ha ni ya ni lẹnu wi pe awọn Heberu gbagbọ wi pe, “Gbọ ile Israẹli, Oluwa Ọlọrun rẹ Ọlọrun KANṢOṢO ni”, ti o ba jẹ wi pe ẹni mẹta ni Ọlọrun I ṣe? Abrahamu ọmọ-ọmọ Ṣẹmu ri Ọlọrun KANṢOṢỌ pẹlu angẹli meji ni Jẹnẹsisi 18.

Nisisinyi, ọna wo ni wọn gba lati ṣe apejuwe mẹtalọkan yii fun awọn eniyan? A ṣe apejuwe rẹ nipa nnkan onigun mẹta kan ti awọn ẹ̀gbẹ́ rẹ jẹ́ iwọn kan naa, gẹgẹ bi o ti wa ni Roomu loni. Haba! awọn Heberu ko ni iru agbekalẹ yii. Nisisinyi tani o tọna? Ṣe awọn Heberu ni tabi awọn ara Babiloni? Ni Eṣia, igbagbọ ninu oriṣa pupọ ti oriṣa mẹta ninu ọkan yii ni a gbe kalẹ gẹgẹ bi oriṣa olori mẹta kan. A gbe oriṣa yii kalẹ gẹgẹ bi agbara imọ mẹta. Ni India, o ba ifẹ ọkan wọn mu lati gbe e kalẹ gẹgẹ bi oriṣa kan ni irisi mẹta. Bayi ni ẹkọ awọn ẹlẹkọ ijinlẹ awọn ẹsin aye ṣe ri loni. Ni Japan, ni Buuda Nla pẹlu ori mẹta gẹgẹ bi eyi ti a ṣe apejuwe rẹ ṣaaju wa.

Ṣugbọn eyi ti o fi oye ohun ti a n ṣo yii ye ni julọ ni eyi ti o gbe ero mẹtalọkan Ọlọrun yii jade pẹlu irisi mẹta: 1. Ori baba arugbo kan ti o duro fun Ọlọrun Baba. 2. Obirikiti kan, eyi ti o tọka si “Irú” ninu imọ ijinlẹ, eyi ti o jasi Ọmọ naa. 3. Awọn iyẹ apa ati ti iru ẹyẹ kan (adaba). Nihin ni a ri ẹkọ Baba, Ọmọ, ati Ẹmi Mimọ, awọn eniyan mẹta ninu Ọlọrun kanṣoṣo, mẹtalọkan, orukọ ti wọn pe e yii gan naa ni o n jẹ. O lee ri ohun kan naa ni Roomu. Jẹki n beere lẹẹkan sii, njẹ ko ha jẹ iyalẹnu wi pe eṣu ati awọn ẹlẹsin rẹ ni ifihan Otitọ ju baba igbagbọ (Abrahamu) ati awọn iran rẹ lọ? Njẹ ko tun ṣe ajeji wi pe awọn ẹlẹsin Satani mọn nipa Ọlọrun ju awọn ọmọ Ọlọrun lọ. Nisisinyi ohun ti awọn ẹlẹkọ ijinlẹ awọn ẹsin aye ti aye ode-oni yii n gbiyanju lati ṣo fun wa nigba ti wọn ba n sọ nipa mẹtakọlan ni yẹn. Ṣaa ranti ohun kan yii lati oni lọ: awọn akọsilẹ wọnyii jẹ otitọ, okodoro si ni wọn -opurọ ni Satani ati baba irọ ni,igbakugba ti o ba si wá pẹlu imọlẹ-ki-mọlẹ irọ ṣi ni sibẹ sibẹ. Apaniyan ni. Ẹkọ mẹtalọkan rẹ ti pa aimoye eniyan, yoo si tun pa ọpọlọpọ si i titi Jesu yoo fi de.

Gẹgẹ bi itan ti sọ ko pẹ pupọ ki iyipada to de ba ẹkọ igbagbọ ti Baba, Ọmọ ati Ẹmi Mimọ yii. Satani n mu wọn diẹdiẹ kuro ninu Otitọ ni. Ọna ti wọn wa fi gbe imọ Ọlọrun kalẹ nisisinyi ni yii: 1. Baba Ainipẹkun, 2. Ẹmi Ọlọrun Ti a fi si inu abo ENIYAN KAN. (Njẹ eyi mu ọ ronu?) 3. Ọmọ Ọlọrun kan Ti I ṣe amujade ti iloyun naa, (Iru Obinrin naa).

Ṣugbọn eṣu ko ti i ni itẹlọrun. Ko i ti i gba ijọsin fun ara rẹ loju koroju ayaafi ni ipaṣẹ awọn ami tabi awọn ère wọnyi. Bẹẹ ni o tun mu awọn eniyan naa jina kuro ninu Otitọ siwaju si i. Nipa awọn ijinlẹ rẹ o fun wọn ni iṣipaya wi pe niwọn igba ti Ọlọrun Baba Nla, Ẹni-airi nì ko ṣuja igbe-aye ati ìṣẹ awọn eniyan ṣugbọn ti O dakẹ jẹẹ si ohun ti i ṣe ti wọn, nigba naa, ohun tí o kàn lati ṣe si I ni wi pe ki a maa jọsin fun ni idakẹjẹ. Ohun ti o jasi ni wi pe ki a kuku fi oju fo O da bi a ṣe lee ṣe e to, tabi ki a tilẹ gbagbe Rẹ sẹgbẹ kan patapata. Ẹkọ yii tún tàn ká gbogbo aye pẹlu, ati loni oloni yii ni India a lee ri wi pe awọn ile oriṣa ti a kọ fun Ẹlẹda nla nì, oriṣa-ti-ki-i-fọhun, kéré ni iye pupọ.

Nigba ti ki i ṣe ọran-an-yan lati maa sin baba-aṣẹda yii, ohun ti o tọ loju wọn ni ki ijọsin yí si ọdọ iya ati ọmọ gẹgẹ bi ohun ti a n juba fun. Ni Ijipiti, a ri iru aya ati ọmọ yii ti a pe ni Isisi ati Osiriisi. Ni India, Isi ati Isiwara ni. (Fiyesi bi orukọ wọn ti jọra wọn to paapaa). Ni Eṣia Sibẹli ati Diousi ni. Ni Roomu ati Girisi bakan naa ni. Ati ni China, pẹlu. Ro o bi iyalẹnu awọn tí ijọ Aguda rán jade ti to nigba ti wọn de China ti wọn si ri Iya kan (Madona) ati Ọmọ kan pẹlu itansan imọlẹ ti n jade lati ibi ori ọmọ-ọwọ naa. A fẹrẹ lee ṣe paṣipaarọ ere yii pẹlu eyi ti o wa ni Vatican bikoṣe ti awọn iyatọ diẹdiẹ ni iwo oju wọn.

O wa yẹ fun wa lati mọn ẹni ti iya ati ọmọ akọkọ naa i ṣe. Iya-oriṣa akọkọ ti Babiloni ni Semiramis ẹni ti a n pe ni Ria ni awọn-ede ti ila oorun agbaye. Obinrin naa gbe ọmọkunrin kan lọwọ, bi o tilẹ jẹ ọmọ- ọwọ, a ṣe apejuwe rẹ gẹgẹ bi ọkunrin giga,alagbara, arẹwa ati ẹni ti n da awọn obinrin lọrun pupọpupọ. Ni Esikiẹli 8:14, a pe e ni Taamusi. Láàárín awọn opitan Giriki ati Roomu, a pe e ni Bakusi. Si awọn ara Babiloni, Ninusi ni. Idi ti a fi fi i han gẹgẹ bi ọmọ-ọwọ ni ọwọ iya rẹ ati sibẹ sibẹ ti a ṣe apejuwe rẹ gẹgẹ bi alagbara ati akọni ọkunrin ni wi pe a mọn ọn si “Ọkọ ati Ọmọ”. Ọkan ninu awọn apele rẹ ni “Ọkọ Iya rẹ”, ati ni India ni ibi ti a ti mọn iya ati ọmọ naa si Isiwara ati Isi, oun (ọkọ) ni a fi han gẹgẹ bi ọmọ-ọwọ ti n mu ọyan iyawo rẹ.

Ka iroyin ni kikun ni... Igba Ijọ Pagamu.


Ọlọrun ni
ọpọlọpọ apele,...
ṣugbọn orukọ
eniyan kan
pere ni O ni,
Orukọ naa si
ni Jesu.


Ohun ijinlẹ Kristi.

Wẹẹbu iwe iroyin Gẹẹsi.

Iwe Ifihan jara.

 

Ọlọrun ati Imọ Atọka.
- Archaeology.

Igbasoke n bọ.

 

Awọn ẹkọ akọkọ
ti ifiranṣẹ naa.

Awọn ti o dara iroyin.
Jesu ku fun ese re.

Iribomi Omi.

 

Awọsanma eleri nla.

Ọwọn ti ina.

Ogo Shekinah ti Ọlọrun.

Ibojì ti ṣofo.
O ti jinde.

Ọlọrun salaye.

Awọn ìgbà ijọ meje.

Awọn edidi meje.

Ọlọrun ati Itan.
jara Atọka - Dáníẹ́lì.

Kristiẹni ije jara.
Ìgbéyàwó Àti Ìkọ̀sílẹ̀.
Akojọ Ifiranṣẹ.

Opin akoko jara.

Ngbe ọrọ jara.

Keresimesi jara.

Iku. Ohun ti nigbana?

Orúkọ Ọlọrun.

Ọkọ Noa.

 

Ẹṣẹ Atilẹba.
Je o ẹya apulu?

Adaparọ.
Awọn orisun - Babeli.

Ọlọrun ati Imọ.
Dainoso Adaparọ.

Archaeology.
Sodomu ati Gomorra.

  Iwe-mimọ sọ...

Kuṣi ni baba Nimrodu, Nimrodu yìí ni ẹni kinni tí wọ́n mọ̀ ní akọni láyé.

Pẹlu àtìlẹ́yìn OLUWA, Nimrodu di ògbójú ọdẹ, tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n máa ń fi orúkọ rẹ̀ súre fún eniyan pé, “Kí OLUWA sọ ọ́ di ògbójú ọdẹ bíi Nimrodu.”

Ìjọba rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti Babeli, Ereki ati Akadi. Àwọn ìlú mẹtẹẹta yìí wà ní ilẹ̀ Babiloni.

Jẹnẹsisi 10:8-10


Tẹ aworan kan lati ṣe igbasilẹ aworan iwọn ni kikun tabi PDF.


Acts of the Prophet

(PDFs Gẹẹsi)
 

The Two Babylons

by Rev Alexander Hislop.
(PDF Gẹẹsi)

Ṣaaju...

Lẹhin...

William Branham Life Story.

(PDF Gẹẹsi)

How the Angel came
to me.
(PDF Gẹẹsi)


Ifiranṣẹ ibudo...Yan ede rẹ ki o gba awọn ifiranṣẹ ọfẹ lati ọdọ Arákùnrin Branham.