Awọn Ọlọhun, Jesu Kristi.


  Iwe ti Ifihan jara.

Mẹtalọkan aṣiṣe.


William Branham.

Ka iroyin ni kikun ni...
Ifihan ti Jesu Kristi.

Iwe Ifihan 1:5,
Ati lati ọdọ Jesu Kristi, Ẹlẹri Olootọ, Akọbi ninu awọn oku, ati Alaṣẹ awọn ọba aye. Ẹni Ti o fẹ wa, Ti o si wẹ wa ninu ẹjẹ Rẹ kuro ninu ẹṣẹ wa,

Iwe Ifihan 1:8,
Emi ni Alfa ati Omega, Ipilẹṣẹ ati Opin, ni Oluwa wi, Ẹni Ti o n bẹ, Ti o ti wa, Ti o si n bọ wa, Olodumare.

Wayi o. Gbogbo awọn gbolohun wọnyi, “Ẹni Ti n bẹ”, ati “Ti o si ti wa,” ati “Ti o si n bọwa”, ati, “Ẹlẹri Olootọ”, ati, “Akọbi Ninu awọn Oku”, ati, “Alaṣẹ awọn ọba aye”, ati, “Alfa ati Omega”, ati, “Olodumare” jẹ́ apele ati apejuwe ẸNIKAN, ANI ẸNIKAN ṢOṢO NAA, Ẹni Ti I ṣe Jesu Kristi Oluwa, Ẹni Ti o wẹ̀ wa nu kuro ninu ẹṣẹ wa ninu ẹjẹ Oun Tikalararẹ.

Ẹmi Ọlọrun ninu Johanu sọrọ bayi lati lee gbe Jesu ka iwaju wa gẹgẹ bi Ọlọrun Ti o ga julọ ati lati fi Ẹni Ti Ọlọrunn ṣe han wa gẹgẹ bi Ọlọrun KANṢOṢO. Ẹkọ-àdámọ̀ nlanla kan wa loni wi pe Ọlọrun mẹta ni n bẹ dipo ọkan. Ṣugbọn iṣipaya ti a fifun Johanu lati ọwọ Jesu, Funrararẹ ṣe atunṣe ẹkọ-adamọ yii. Ki i ṣe wi pe Ọlọrun mẹta ni o wa, bikoṣe Ọlọrun kan Ti n ṣiṣẹ ni ipo-iṣẹ mẹta. Ọlọrun KAN Ti o ni àpèlé mẹta, Baba, Ọmọ, Ẹmi Mimọ, ni n bẹ. Iṣipaya nla yii ni ijọ akọkọ ni, o si di dandan ki a da a pada si inu ijọ ni ọjọ ikẹyin yii pẹlu ilana ìtẹ̀bọmi pipe.

Awọn-ẹlẹkọ ijinlẹ-awọn-ẹsin-aye ti igbalode ko ni gba ohun ti mo sọ yii nitori ohun ti a kọ a sinu iweiroyin Onigbagbọ nla kan ni yii.“Ẹkọ naa (lori mẹtalokan) jẹ kókó pataki ninu ohun ti Majẹmu Laelae n sọ. Ni gbogbo ọna oun pẹlu ni koko pataki ninu ohun ti Majẹmu Titun n sọ. Gẹgẹ bi Majẹmu Laelae ti lodi gbaa si i wipe Ọlọrun ju ọkan lọ, bẹẹ naa ni Majẹmu Titun lodi si i. Sibẹ, Majẹmu Titun n kọni yekeyeke wi pe Baba jẹ Ọlọrun, Ọmọ naa si jẹ Ọlọrun, ati wi pe Ẹmi Mimọ pẹlu jẹ Ọlọrun, ati wi pe awọn mẹtẹẹta wọnyi KI IṢE ipa mẹta Ẹni kan ṣoṣo, bikoṣe awọn Ẹni Mẹta ti Wọn wa ni ibaṣepọ tootọ láàárín ara wọn. Nihin ni a ri ẹkọ nla ti Ẹni Mẹta Ti I ṣe Ọlọrun kan”.

Bẹẹ ni wọn tun wi pe, “Ọlọrun, ni ibamu pẹlu Bibeli, ki I kan I ṣe Ẹnikan, bikoṣe ẹni mẹta ninu Ọlọrun kan. Eyi ni ijinlẹ nla ti Mẹtalọkan”.

Akiika. Bawo ni ẹni mẹta ṣe lee wà ninu Ọlọrun kan? Ki i se wi pe Bibeli ko wi bẹ ẹ nikan, ṣugbọn o fi han wi pe ironu wọn yi paapaa ko tilẹ mu ọgbọn lọwọ rara rara. Awọn ẹni mẹta ọtọọtọ bi a tilẹ fi eroja kan naa ṣẹ iṣẹda wọn jẹ orisa mẹta, lai jẹ bẹẹ, ede ko ni itumọ mọ rara.

Ṣaa fi ẹti si awọn ọrọ wọnyi lẹẹkan si i, “Emi ni Alfa ati Omega, Ẹni isaaju ati Ẹni ikẹyin, bẹẹ ni Oluwa wi, ẸniTi o Wa, Ti o si Ti Wa, Ti o si n Bọ Wa, Olodumare”. Ọlọrun ni Yii. Eyi ki I ṣe wolii, eniyan lasan. Ọlọrun Ni. Eyi ki I ṣe iṣipaya Ọlọrun mẹta bikoṣe Ọlọrun KAN, Olodumare.

Nigba ti ijọ bẹrẹ, wọn ko gba Ọlọrun mẹta gbọ. Iwọ ko lee ri iru igbagbo bayi láàárín awọn aposteli. Lẹyin igba aye awọn aposteli ni ẹkọ yii wọ inu ijọ ti o di oun nla ati ẹkọ opomulero pataki ni akoko igbimọ Nikia. Ẹkọ Ẹni Ti Ọlọrun I ṣe mu ki ijọ ya si mẹji ni Nikia. Lati inu iyapa yii ni awọn ẹgbẹ alasẹ-kọja-ala meji ti jade. Ọkan ninu wọn gbagbọ wi pe Ọlọrun pupọ ni n bẹ, wọn si gba Ọlọrun mẹta gbọ, awọn keji gbagbọ wipe Ọlọrun ẹyọkan ti ko ni ipo-iṣẹ mẹta ni n bẹẹ. Bi o ti lẹ jẹ wi pe ilẹ fẹ si i diẹ ki ẹkọ keji to gbilẹ, o ṣaa gbilẹ dandan, o si wa pẹlu wa loni. Ṣugbọn Iṣipaya ti Ẹmi fun Johanu si awọn ijọ ni wi pe, “Emi ni Jesu Kristi Oluwa, Emi ni Ohun GBOGBO ti Ọlọrun jẹ. Ko si Ọlọrun miiran mọ.” O si fi ontẹ Rẹ tẹ Iṣipaya yii.

Gba eyi yẹ wo: Tani i ṣe Baba Jesu? Matiu 1:8 wi pe, “O loyun lati ọwọ Ẹmi Mimọ.” Ṣugbọn Jesu,Funrararẹ, wi pe Ọlọrun ni Baba Oun. Ọlọrun Baba ati Ọlọrun Ẹmi Mimọ gẹgẹ bi a ti maa n saba lo awọn ọrọ wọnyi jasi wi pe ỌKAN ni Baba ati Ẹmi Mimọ. Ni tootọ ọkan ni Wọn, bi bẹẹ kọ Baba meji ni Jesu ni. Ṣugbọn kiyeṣi i, Jesu wi pe Ọkan ni Oun ati Baba Oun - ki i ṣe meji. Itumọ eyi ni wi pe ỌKAN ni Ọlọrun.

Niwọn igba ti eyi jẹ otitọ ni ibamu pẹlu akọsilẹ-itan ati Ọrọ Ọlọrun, o jẹ kayefin fun awọn eniyan ibi ti ẹkọ mẹtalokan ti wa. Ẹkọ yii di ẹkọ ipilẹ opomulero ni ibi ipade Igbimọ Nikia ti a ṣe ni ọdun 325 L.I.A.O. Mẹtalọkan yii (ọrọ ti o lodi si Bibeli ni gbogbo ọna yii) jẹ jade lati inu ọpọlọpọ oriṣa ti awọn ara Roomu n bọ. Awọn ara Roomu ni ọpọlọpọ orisa ti wọn n gba adura si. Bẹẹ ni wọn n ma gbadura si awọn Baba nla wọn gẹgẹ bi alagbawi. Ẹkọ mẹtalọkan yi i jẹ igbẹsẹ lati fun awọn orisa atijọ wọnni ni orukọ tuntun. Nitori naa, a n fi orukọ awọn ẹniyan mimọ pe wọn ki o ba lee fi ara jọ Ọrọ Ọlọrun. Bayi, dipo Jupiter, Venus, Mars, abb., a n pe wọn ni Pọọlu, Peteru, Fatima, Christopher, abb., abb., Ẹsin ibọriṣa wọn ko Iee ṣe e ṣe pẹlu igbagbọ ninu Ọlọrun kanṣoṣo, nitori naa wọn pin Ọlọrun si mẹta, wọn si sọ awọn ẹni mimọ di alagbawi gẹgẹ bi wọn ṣe sọ awọn baba nla wọn di alagbawi wọn.

Lati igba yii naa ni awọn eniyan ti kùnà lati ni oye wi pe Ọlọrun kan Ti o ni ipo-iṣẹ mẹta tabi ìfarahànfáráyérí mẹta ni n bẹ. Wọn mọ wi pe Ọlọrun kan ni n bẹ ni ibamu pẹlu Ọrọ Ọlọrun, ṣugbọn wọn gbiyanju lati sọỌ di ẹkọ agbayanu kan eyi ti o wi pe Ọlọrun dabi idi ọsan ṣikiti kan, ani wi pe Ọlọrun jẹ eniyan mẹta ọtọọtọ ti o ni Ẹda Ọlọrun dọgba-n-dọgba. Ṣugbọn Ọrọ Ọlọrun sọ ni kedere ninu Iwe Ifihan wi pe, Jesu naa ni “Ẹni Ti n Bẹ”, “Ẹni Ti o ti Wa” ati “Ẹni Ti n Bọ Wa.”“Oun ni Alfa ati Omega,” eyi ti o tumọsi wi pe, “Oun ni lati ”A deY“ tabi OUN NI GBOGBO RẸ. Oun ni ohun gbogbo-Olodumare. Oun ni Òdòdò Ṣaroni, Liliti Afonifoji, Irawọ Owurọ Ti o Mọlẹ, Ẹka Ododo, Baba, Ọmọ ati Ẹmi Mimọ. Oun ni Ọlọrun, Ọlọrun Olodumare. ỌLỌRUN KANṢOṢO.

Timoti kin-in-ni 4;16 sọ wi pe, “Lai si iyemeji, titobi ni ohun ijinlẹ iwa-bi-Ọlọrun, Ẹni Ti a fihan ninu ara, Ti a dalare ninu Ẹmi, Ti awọn angeli ri, Ti a waasu Rẹ láàárín awọn orile-ede, Ti a gbagbọ ninu aye, Ti a gba soke sinu Ogo”. Ohun ti Bibeli sọ ni yii. Ko sọ ohunkohun nipa ẹni kin-in-ni tabi ẹni keji tabi ẹni kẹta nihin. O ṣo wi peỌlọrun fi ara han gẹgẹ bi eniyan. Ọlọrun kan ṣoṣo. ỌLỌRUN KANṢOṢO yii farahan ninu ara. O yẹ ki eleyi to lati fi ẹnu ọrọ naa jona. Ọlọrun wá ni aworan eniyan. Iyẹn ko sọ Ọ diỌLỌRUN MIIRAN. ỌLỌRUN NI, ỌLỌRUN KAN NAA. Iṣipaya ni o jẹ ni igba naa, iṣipaya naa ni loni. Ọlọrun Kanṣoṣo.

Ẹ jẹ ki a pada lọ si inu Bibeli ki a si ri ohun ti O jẹ ni ibẹrẹ ni ibamu pẹlu iṣipaya Ara Rẹ ti O fi fun ni. Jehofa Nla naa fi ara han Israẹli ninu Ọwọn Ina. Gẹgẹ bi Angẹli Majẹmu naa O gbe ninu Ọwọn Ina, O si dari Israẹli lojoojumọ. Ni tẹmpili O kede bibọ Ara Rẹ pẹlu Ikuku Nla kan. Lẹyin eyi ni ọjọ kan, O fi ara han ninu ara kan Ti a bi nipasẹ wundia; ani eyi ti a pese silẹ fun Un. Ọlọrun Ti o rababa lori agọ awọn Israeli ti wá gbe agọ ẹran ara wọ, O si n gbe gẹgẹ bi eniyan láàárín awọn eniyan. Ṣugbọn ỌLỌRUN KAN NAA ni. Bibeli kọ ni wi pe ỌLỌRUN N GBE INU KRISTI. ARA naa ni Jesu. Ni inu Rẹ ni gbogbo ẹkunrẹrẹ Ẹni Ti Ọlọrun I ṣe n gbe NINU ARA. Ko si ohun ti o tun lee ye ni yekeyeke ju eyi lọ. Ijinlẹ, bẹẹ ni. Ṣugbọn otitọ gidi ponbele ni-ko si lee han kedere ju eyi lọ. Nitori naa ti Ọlọrun ko ba jẹ ẹni mẹta ni igba naa, Ko lee jẹ ẹni mẹta loni. ỌLỌRUN KAN: Ọlọrun yii kan naa ni o di eniyan ẹlẹran ara.

Jesu sọ wi pe, “Mo ti inu Ọlọrun wa, Mo ti si n lọ (pada) si inu Ọlọrun.” Johanu 16:27-28. Ohun ti o ṣẹlẹ gan an ni yii. O kuro lori ilẹ aye ni ipasẹ iku, isinku, ajinde ati igoke-re-Ọrun Rẹ. Lẹyin naa, Pọọlu ba A pade ni ọna Damasku, O si ba Pọọlu sọrọ, O wi pe, “Sọọlu, Sọọlu, eeṣe ti iwọ fi n ṣe inunibini si Mi?” Pọọlu si wi pe, “Tani Ọ Oluwa? O si wi pe, ”Emi ni Jesu.“ O jẹ Ọwọ Ina, Imọle Ti o lee fọ ni loju. O ti yipada si ipo ti O kọkọ wa gẹgẹ bi O ti sọ wi pe Oun yoo ṣe. O pada si ipo kan naa Ti o wa ki O to gbe Agọ ẹran ara wọ. Bayi gẹlẹ ni Johanu ṣe ri I. Johanu 1:18, ”Ko si ẹni ti o ri Ọlọrun ri; ọmọ kanṣoṣo, Ti n bẹ ni ookan aya Baba, Oun naa ni O sọ Ọ di mímọ̀.“ Ṣe akiyesi ibi ti Johanu sọ wi pe Jesu WA. O n bẹ NI ookan aya Baba.

Luku 2:11 sọ wi pe, “Nitori a bi Olugbala fun yin loni ni ilu Dafidi, Ti i ṣe Kristi Oluwa.” A bi I ni Kristi, ni ijọ kẹjọ a kọ Ọ ni ila, a si sọ Ọ ni Jesu, gẹgẹ bi angẹli naa ti sọ fun wọn ṣaaju. A bi mi ni Branham. Ni igba ti a bi mi, a sọ mi orukọ kan ti i ṣe William. Kristi Ni, ṣugbọn a fi Orukọ kan fun Un nihin láàárín awọn eniyan. Àgọ́ ode ti awọn eniyan lee fi oju ri ni a pe ni Jesu. Oluwa Ogo ni, Olodumare naa ti O fi ara han ninu ẹran ara. Oun ni Ọlọrun Baba, Ọmọ, ati Ẹmi Mimọ. Oun ni gbogbo rẹ.

Ka iroyin ni kikun ni...
Ifihan ti Jesu Kristi.

Ṣe igbasilẹ (Gẹẹsi)   Godhead Explained



Iwe ti Ifihan jara.
Tẹsiwaju lori oju-iwe atẹle.
(Iran Patimọsi.)


Jesu Kristi ni
Ọlọrun.
Jèhófà ti awọn
Majẹmu Lailai,
ni Jesu
ti Titun.



Ifiranṣẹ ibudo...Yan ede rẹ ki o gba awọn ifiranṣẹ ọfẹ lati ọdọ Arákùnrin Branham.


Ohun ijinlẹ Kristi.

Wẹẹbu iwe iroyin Gẹẹsi.

Iwe Ifihan jara.

 

Ọlọrun ati Imọ Atọka.
- Archaeology.

Igbasoke n bọ.

 

Awọn ẹkọ akọkọ
ti ifiranṣẹ naa.

Awọn ti o dara iroyin.
Jesu ku fun ese re.

Iribomi Omi.

 

Awọsanma eleri nla.

Ọwọn ti ina.

Ogo Shekinah ti Ọlọrun.

Ibojì ti ṣofo.
O ti jinde.

Ọlọrun salaye.

Awọn ìgbà ijọ meje.

Awọn edidi meje.

Ọlọrun ati Itan.
jara Atọka - Dáníẹ́lì.

Kristiẹni ije jara.
Ìgbéyàwó Àti Ìkọ̀sílẹ̀.
Akojọ Ifiranṣẹ.

Opin akoko jara.

Ngbe ọrọ jara.

Keresimesi jara.

Iku. Ohun ti nigbana?

Orúkọ Ọlọrun.

Ọkọ Noa.

 

Ẹṣẹ Atilẹba.
Je o ẹya apulu?

Adaparọ.
Awọn orisun - Babeli.

Ọlọrun ati Imọ.
Dainoso Adaparọ.

Archaeology.
Sodomu ati Gomorra.

  Iwe-mimọ sọ...

Ẹ gbọ́ Israẹli: OLUWA Ọlọrun yín, OLUWA kan ṣoṣo ni.

Diutaronomi 6:4


Tẹ aworan kan lati ṣe igbasilẹ aworan iwọn ni kikun tabi PDF.


Acts of the Prophet

(PDFs Gẹẹsi)
 

The Two Babylons

by Rev Alexander Hislop.
(PDF Gẹẹsi)

Oke ati dide igbo
ni egbon ni Ṣaina.

Awọn lili ti ina.

Ọwọn ti ina.
- Houston 1950.

Imọlẹ lori apata
jibiti.