Ẹṣẹ Atilẹba. Igi Iye.
Ẹṣẹ Atilẹba. Je o ẹya apulu?
(Otitọ nipa ẹṣẹ atilẹba.)
William Branham.Ka iroyin ni kikun ni...
Igba Ijọ EfesuIwe Ifihan 2:7,
“... Ẹni ti o ba ṣẹgun ni Emi o fi eso Igi Iye ni fun jẹ, Ti n bẹ láàárín Paradise Ọlọrun.”Eyi ni ere ti ọjọ iwaju fun gbogbo awọn ajagun-ṣẹgun ninu gbogbo awọn Igba Ijọ kọọkan. Nigba ti ìró ipe ikẹyin si ogun ba ti dún, ti a ti bọ́ ihamọra-ogun wa silẹ, nigba naa ni a o sinmi ni Paradise Ọlọrun, ipin wa yoo si jẹ Igi Iye titi Aye Ainipẹkun.
“Igi Iye.” Njẹ akawe ọrọ ti o dara kọ ni eyi bi? Igba mẹta ni a sọ nipa rẹ ninu Jẹnẹsisi, ati ni igba mẹta ninu Ifihan. Ni ibi mẹfẹẹfa Igi kan naa ni. O si duro fun ohun kan naa.
Ṣugbọn kin ni Igi Iye? Lakọkọ naa, a ni lati mọn ohun ti igi gan an duro fun. Ni Numeri 24:6, gẹgẹ bi Balaamu ṣe ṣe apejuwe Israẹli, o ni wọn jẹ “Igi Aloi ti Oluwa ti gbin ni.” Ninu gbogbo Iwe-Mimọ, eniyan ni igi duro fun, gẹgẹ bi o ti wa ninu Orin Dafidi Kin-in-ni. Nitori naa, Igi Iye Nì gbọdọ jẹ Ẹni Iye Naa, Eyi si ni Jesu.
Wayi o, Igi meji ni o duro láàárín Ọgba Idẹni. EKin-in-ni jẹ Igi Iye, ekeji si jẹ Igi imọ rere ati buburu. O yẹ ki eniyan gbe igbe aye rẹ nipa jíjẹ ninu Igi Iye; ṣugbọn kọ̀ yẹ ki o fi ọwọ kan Igi keji, bi bẹẹ kọ kiku ni yoo ku. Ṣugbọn eniyan kò yẹ ki o fi ọwọ kan igi keji, nigba ti o si ṣe e, iku wọle tọ ọ wa nipaṣẹ ẹṣẹ rẹ, a si ya a nipa kuro lọdọ Ọlọrun.
Igi Naa Ti o wa ni Idẹni nì, Ti i ṣe Orisun Iye, jẹ Jesu. Ni Johanu ori Kẹfa de Ikẹjọ, Jesu ṣe alaye ara Rẹ gẹgẹ bi Orisun Iye Ainipẹkun. O pe ara Rẹ ni Burẹdi Ti o ti Ọrun wa. O sọ nipa fifi ara Rẹ funni, ati wi pe bi eniyan ba jẹ ninu Oun, ẹni naa ki yoo kù laelae. O wi pe Oun mọn Abrahamu, ati pẹlu wi pe ki Abrahamu to wà, Oun TI WÀ. O sọ tẹlẹ wi pe Oun Funrara Oun yoo fun wọn ni Omi Iye, ti ongbẹ ki yoo gbẹ ẹni ti o ba mu Un mọ laelae, ṣugbọn ẹni naa yoo wa laaye titi Aye Ainipẹkun. O fi ara Rẹ han gẹgẹ bi, EMI NI NLA nì. Oun ni Burẹdi Iye, Ẹni Ainipẹkun, IGI IYE. O wa nibẹ ni Idẹni láàárín Ọgba naa, ani bi Oun yoo ṣe wa ni aarin Paradise Ọlọrun.
Awọn eniyan kan lero wi pe awọn Igi mẹji wọnyi jẹ igi meji miiran lasan gẹge bi awọn igi iyoku ti Ọlọrun gbin si inu Ọgba naa. Ṣugbọn awọn akẹkọ Bibeli ti o jafafa mọn wi pe eyi ko ri bẹẹ. Nigba ti Johanu Onitẹbọmi kigbe wi pe a ti gbe aake le gbongbo gbogbo igi, ko ṣo nipa awọn igi lasan, ṣugbọn o n sọrọ nipa awọn ohun Ẹmi. Ni Johanu Kin-in-ni 5:11, O wi pe, “ẸRI naa si ni eyi pe, Ọlọrun fun wa ni Iye Ainipẹkun, Iye yii si n bẹ ninu Ọmọ Rẹ.” Jesu ṣo ni Johanu 5:40 wi pe, “Ẹyin ko si fẹ lati wa sọdọ Mi, ki ẹyin ki o lee ni Iye.” Nitori naa, Akọsilẹ Naa, Ọrọ Ọlọrun, sọ ni pato ati ni kedere wi pe, IYE AINIPẸKUN n bẹ ninu Ọmọ Naa. Ki i ṣe ni ibomiran. Johanu Kin-in-ni 5:12, “Ẹni ti o ba ni Ọmọ, o ni Iye; ẹni ti ko ba si ni Ọmọ Ọlọrun, KO NI Iye.” Nisisinyi, niwọn igba ti Akọsilẹ Naa ko lee yipada, ti a ko si lee yọ kuro ninu Rẹ tabi ki a fi kun Un, nigba naa Akọsilẹ Naa wa sibẹ wi pe IYE NAA WA NINU ỌMỌ....Niwọn igba ti eyi ri bẹẹ, IGI TI O WA NINU ỌGBA NAA NÌ LATI JẸ JESU.
O dara bẹẹ.Bi igi Iye ba jẹ eniyan kan, nigba naa Igi Imọ Rere ati Buburu ni lati jẹ ẹnikan PẸLU. Ko lee yatọ si bi a ti ṣe sọ ọ yii. Bayi, Ẹni Ododo naa ati Ẹni Buburu nì duro ni ẹgbẹ ara wọn láàárín Ọgba Idẹni. Isikiẹli 28:13a, “Iwọ (Satani) ti wa ni Idẹni, Ọgba Ọlọrun...”
Nihin ni a gba ojulowo iṣipaya tootọ ti “IruẸranko-ti-a-palarada-di-ejo (Sapẹnti)”. Ohun ti o ṣelẹ gan an ní Ọgba Idẹni ni eyi. Ọrọ Ọlọrun sọ wi pe ẹranko-ti-a-palarada-di-ejo tan Eefa jẹ ni. Ohun ti o ṣẹlẹ ni wi pe okuku tan Eefa jẹ ni lati ní ibalopọ láàárín ọkunrin ati obinrin pẹlu rẹ ni. Iwe-Mimọ sọ ni Jẹnẹsisi 3:1 wi pe, “Sapẹnti ṣaa ṣe arekereke ju ẹranko igbẹ iyoku lọ ti Oluwa Ọlọrun ti da”. Ẹranko yii sunmọ eniyan to bẹẹ gẹẹ ti o fi lee ronu, ti o si lee sọrọ (sibẹ-sibẹ ẹranko patapata si ni) O jẹ́ ẹ̀dá ti n nàró rìn, ti iṣẹda rẹ si wa láàárín inaki ati eniyan, ṣugbọn o jọ eniyan ju inaki lọ. O jọ eniyan to bẹẹ gẹẹ ti o fi fẹrẹ ẹ dabi eniyan, ti irú àtọ̀ rẹ lee dapọ mọ, o si dapọ pẹlu ti obinrin naa, ti eyi si mu obinrin naa ti ipa bẹẹ loyun. Nigba ti eyi ṣẹlẹ, Ọlọrun gegun fun ẹranko-ti-a-palarada-di-ejo naa. O yi egungun kọọkan ninu ara ẹranko-ti-a-palarada-di-ejo naa pada ti o fi ní lati maa fi àyà wọ́ bi ejo. Bi o ti wu ki sayẹnsi ṣe iwadi to, wọn ko lee ri ẹranko ti iru-iye rẹ lee dapọ mọ ti eniyan. Ọlọrun ri si i wi pe wọn ki yoo ri i. Eniyan jafafa o si lee ri ijọra ti o wa láàárín eniyan ati ẹranko, o si n gbiyanju lati fi idi eyi mulẹ nipa ẹkọ wi pe gbogbo ẹda alaaye ti inu bulọọku-ti-a-fi-pilẹ-ẹya-ara kanṣoṣo pere jade. Ko si ohun ti o jọ eyi rara. Ṣugbọn otitọ ni wi pe iru-iye eniyan ati ẹranko dapọ. Eyi jẹ ọkan ninu awọn Ijinle Ọlọrun Ti o ti farasin, ṣugbọn ti a ṣipaya nihin. Eyi ṣẹlẹ nibẹ nigba naa láàárín Ọgba Idẹni nigba ti Eefa kọ Iye silẹ lati gba iku.
Kiyesi ohun ti Ọlọrun sọ fun wọn ninu Ọgba. Jẹn. 3:15, “Emi o si fi ọta saaarin iwọ ati obinrin naa, ati saaarin iru ọmọ rẹ ati Iru-ọmọ rẹ, Oun o fọ ọ ni ori, iwọ o si pa A ni gigiisẹ”. Bi a ba gbà wi pe otitọ ni ohun ti Ọrọ Ọlọrun sọ wi pe obinrin naa ni Iru-ọmọ, o di dandan gbọn nigba naa ki ẹranko-ti-a-pa-lara-da-di-ejo ni iru-ọmọ pẹlu. Bi Iru obinrin naa ba jẹ ọmọkunrin ti a bí lai jẹ wi pe obinrin naa ni ibalopọ pẹlu ọkunrin, nigba naa iru ẹranko-ti-a-pa-lara-da-di-ejo naa ni lati wá ni ọna kan naa, ani, o ni lati jẹ ọmọkunrin miiran ti a bi lai si ibalopọ láàárín ọkunrin ati obinrin ti o la ohun elo ibimọ ti akọ eniyan lọ. Ko si akẹkọ Bibeli ti ko mọn wi pe Iru Obinrin naa ni Kristi, Ẹni Ti o wá lati ọwọ Ọlọrun lai si ibalopọ láàárín ọkunrin ati obinrin nibẹ. Bẹẹ naa ni o jẹ ohun ti a mọn dajudaju wi pe asọtẹlẹ nipa fífọ́ ori eṣu jẹ asọtẹlẹ gan an nipa ohun ti Kristi yoo ṣe si Satani ni ori Agbelebu. Ni ori Agbelebu ni Kristi yoo ti fọ́ ori Satani tiSatani yoo si pa gigirisẹ Oluwa lára.
Ipa Ọrọ Ọlọrun yii jẹ iṣipaya bi iru-ọmọ ẹranko-ti-a-palarada-di-ejo ninu ẹran-ara-eniyan ṣe wọ inu aye, ani gẹgẹ bi Akọsilẹ Luku 1:26-35, ṣe jẹ Akọsilẹ perepere nipa bi Iru Obinrin naa ṣe di arigbamu ninu ẹran-ara-eniyan lai lọwọ akọ-ẹda eniyan ninu: Igba Ijọ Efesu 19 “Ni oṣu Kẹfa a si ran angẹli Geburẹli lati ọdọ Ọlọrunlọ si ilu kan ni Galili ti a n pe ni Nasarẹti, si wundia kan ti a fẹ fun ọkunrin kan ti a n pe ni Josẹfu, ti idile Dafidi; orukọ wundia naa a si maa jẹ Maria. Angẹli naa si tọ ọ wa, o ni Alaafia, iwọ ẹni ti a kọju si ṣe ni oore, Oluwa wa pẹlu rẹ: alabukun-fun ni iwọ ninu awọn obinrin Ṣugbọn ọkan rẹ ko lelẹ nitori Ọrọ naa, o si rò ninu ara rẹ pe, iru kíkíkin ni eyi? Angẹli naa si wi fun un pe, Ma bẹru Maria: nitori iwọ ti ri ojurere lọdọ Ọlọrun. Ṣaa si kiyesi i, iwọ o loyun ninu rẹ, iwọ o si bi Ọmọkunrin kan, iwọ o si pe Orukọ Rẹ ni JESU, Oun o pọ, Ọmọ Ọga-ogo julọ ni a o si maa pe E: Oluwa Ọlọrun yoo si fi Itẹ Dafidi Baba Rẹ fun Un: Yoo si jọba ni ile Jakọbu titi aye; Ijọba Rẹ ki yoo si ni ipẹkun. Nigba naa ni Maria wi fun angẹli naa pe, Eyi yoo ha se ri bẹẹ nigba ti emi ko ti i mọ ọkunrin? Angẹli naa si dahun o si wi fun un pe, Ẹmi Mimọ yoo tọ ọ wa, ati Agbara Ọlọrun Ọga Ogo yoo ṣiji bo ọ: nitori naa Ohun Mimọ Ti a o ti inu rẹ bi, Ọmọ Ọlọrun ni a o ma pe E.“
Gẹgẹ bi Iru Obinrin naa ṣe jẹ Ọlọrun gangan Funrararẹ Ti o mu Ara Rẹ jade ninu ẹran-ara-eniyan ni afojuri,bẹẹ naa ni iru ẹranko-ti-a-palarada-di-ejo jẹ́ ọna ti Satani ri ti o ṣi silẹ fun oun lati wọ inu iran ẹda eniyan gegẹ bi eniyan ẹlẹran-ara. O jẹ aiṣeeṣe fun Satani lati sọ ara rẹ di eniyan ni ọna ti Ọlọrun lo lati so ara Rẹ di eniyan (nitori wi pe ẹda ti A DÁ ti o jẹ ẹda ẹmi lasan ni), nitori naa, Akọsilẹ ti Jẹnẹsisi n sọ ọna ti o fi mu iru-ọmọ rẹ wọ inu ẹda eniyan. Ẹwẹ, ranti wi pe Satani ni a n pe ni “Sapẹnti” nì. Iru-ọmọ rẹ tabi ọna ti o fi mu irú rẹ wọ inu ẹda eniyan ni a sọ nipa rẹ.
Ki ibalopọ láàárín tọkọtaya to ṣẹlẹ láàárín Adamu ati Eefa ni ẹranko-ti-a-pa-lara-da-di-ejo yii ti ṣaaju Adamu ṣe e. Ẹni ti a si bi nipa ibalopọ yii ni Kaini. Kaini jẹ (a bi i nipasẹ, a loyun rẹ lati ọwọ) “ẹni buburu ni”. Johanu Kin-in-ni 3:12. Ẹmi Mimọ ninu Johanu ko lee pe Adamu ni, “ẹni buburu ni” ni ibi kan (nitori ohun ti yoo jẹ ni yii bi o ba jẹpe oun ni o fun Eefa ni oyun Kaini) ati ni ibomiran ki O pe Adamu ni, “ọmọ Ọlọrun”,eyi ti Adamu jẹ nipa iṣẹda. Luku 3:38. Kaini fi iwa han gẹge bi baba rẹ, a-ṣe-ku-pa-ni ati apaniyan. Ọna ti o fi gbó Ọlọrun lẹnu - nigba ti o duro niwaju Olodumare ni Jẹnẹsisi 4:5,9,13,14, fi iwa rẹ ti ko jọ ti ti eniyan rara-rara han, o tilẹ dabi ẹni wi pe o tayọ akọsilẹ Iwe-Mimọ nipa igbakugba ti Satani doju ija kọ Ọlọrun.
“Ṣugbọn Kaini ati ọọrẹ rẹ ni Ko naani. Kaini si binu gidigidi, oju rẹ si rẹwẹsi Oluwa si wi fun Kaini pe, Nibo ni Abẹli arakunrin rẹ wa? O si wi pe, Emi ko mọn; emi i ṣe olutọju arakunrin mi bi? Kaini si wi fun Oluwa pe, iya ẹṣẹ mi pọ ju eyi ti emi lee ru lọ. Kiyesi i, Iwọ lé mi jade loni kuro lori ilẹ; emi o si di ẹni ti o pamọ kuro loju Rẹ; emi o si maa jẹ isansa ati alarinkiri ni aye; yoo si ṣe ẹnikẹni ti o ba ri mi yoo lu mi pa.“
Kiyesi ọna kan pato ti Akọsilẹ Ọlọrun fi gbe ìbí Kaini, Abẹli ati Sẹẹti kale. Jẹnẹsisi 4:1,2a “Adamu si mọn Eefa aya rẹ; o si loyun, o si bi Kaini, o si wi pe, Mo ri ọkunrin kan gba lọwọ Oluwa, O si bi Abẹli arakunrin rẹ.”
Ọmọkunrin MẸTA ni a bi lati inu ibalopọ tọkọtaya MEJI ti Adamu ni pẹlu iyawo rẹ. Niwọn igba ti Bibeli jẹ Akọsilẹ Ọrọ Ọlọrun Ti o gun rege, Ti o si peye perepere, eyi ki i ṣe aṣiṣe ṣugbọn akọsilẹ lati fun wa ni oye. Ni iwọn igba ti o jẹ ọmọ MẸTA ni a bi lati inu ibalopọ tọkọtaya MEJI ti Adamu ni pẹlu iyawo rẹ, a mọn DAJUDAJU wi pe ỌKAN ninu awọn mẹta naa ki i ṢE ỌMỌ Adamu.Ọlọrun ti kọ eyi silẹ ni ọna yii gẹlẹ lati fi ohun kan han wa. Otitọ ohun ti o ṣẹlẹ ni wi pe Eefa loyun ọmọkunrin MEJI ninu rẹ (ibeji) ti o wá nipa ibaṣepọ tọkọtaya pẹlu akọ ỌTỌỌTỌ. Oyun ibeji ni o ni bi o tilẹ jẹ wi pe iloyun Kaini fi igba diẹ ṣẹlẹ ṣaaju ti Abẹli.
Ka iroyin ni kikun ni... Igba Ijọ Efesu
Wo... Irú Ẹranko-tó-Padà-Dejò. fun diẹ apejuwe awọn.
Iwe ti Ifihan jara.
Tẹsiwaju lori oju-iwe atẹle.
(Ẹkọ awọn Nikolaitani.)
Ti o ba ti
apulu ṣe obinrin
mọ nwọn wà ni
ìhoho, o to akoko
lati kọja ni ayika
awọn apulu lẹẹkansi.
Ifiranṣẹ ibudo...Yan ede rẹ ki o gba awọn ifiranṣẹ ọfẹ lati ọdọ Arákùnrin Branham.