Eyi ha ni ami opin bi, alagba?

<< išaaju

itele >>

  Opin akoko jara.

Ni ọjọ ohun angẹli keje...


William Branham.

Ka iroyin ni kikun ni...
Eyi ha ni ami opin bi, alagba?

Ifihan 10:7,
7 Ṣugbọn ni ọjọ ohun angẹli keje, nigbati yoo ba fun ipe, nigbana ni ohun ijinlẹ Ọlọrun pari, gẹgẹ bi ihinrere ti O sọ fun awọn iranṣẹ Rẹ; awọn wolii.

Bayi, ninu irinajo naa, awọn iṣẹlẹ kan ti ṣẹlẹ ti nko lee loye. Ọ̀kan ninu awọn ohun ti nko lee loye ni igbati mo jẹ ọmọde, ti awọn iran yẹn yoo tọ mi wa. Ti n o si ri wọn, ti n o sọ fun awọn obi mi, nipa awọn nkan ti yoo ṣẹlẹ. Wọn ro pe ẹgbọn riri lo n ṣe mi. Ṣugbọn ohun to sajeji nipe, o maa n ṣẹlẹ bi mo ti maa n sọ ọ gẹlẹ.

Ẹyin wipe, “Ṣe iyẹn ṣẹlẹ siwaju iyipada rẹ kuro ninu ẹ̀ṣẹ̀ ni?”
Bẹẹ ni. “Ẹbun ati ipe wa laisi ironupiwada,” Bibeli sọ bẹẹ. A bi ọ si inu aye yi fun awọn idi kan.... Ironupiwada rẹ kọ lo n mu ẹbun wa. A yan ọ tẹlẹ si i ni. Bayi, ni oju ọna.... Nigbati mo jẹ ọmọde.... Ilu ti mo n gbe ninu rẹ ko tẹ mi lọrun. Mo fẹ lati lọ si iwọ oorun ni ọna kan.

-----
O gbọdọ ti to agogo mẹwa ni ọjọ naa, nigbati iyawo mi n wọ inu iyara wa, o si ṣẹlẹ pe, mo wọ inu iran kan lọ, ni owurọ ọjọ naa.... Bayi, ẹ ranti pe ki i ṣe ala! Iyatọ wa laarin àlá ati iran. Ala n ṣẹlẹ nigbati eniyan n sun; iran n waye, nigbati eniyan ko sun. A bi wa ni ọna yẹn. Eniyan ẹlẹran ara, nigbati ó ba la ala, o n ṣẹlẹ ni oju orun. Ko si mọ ohunkohun ni oju orun. Awọn ònmọ̀ rẹ̀ ni agbara, nigbati ko ti i sun. Ni ipo aisun, iwọ jẹ eniyan pipe. O n ri, o n mọ ìtọ́wò, o n ni imọlara, o n gbọ òórùn, o si n gbọran. Ṣugbọn nigbati o ba wa ni oju orun, ti o sun, iwọ ko lee riran, mọ ìtọ́wò, ni imọlara, gbọ òórùn, tabi ki o gbọ́ran. Ṣugbọn ohun kan n ṣẹlẹ nigbati o ba n la àlá pe.... Iwọ n pada si ipo aisun yi. Iranti kan wa, ti iwọ fi n ranti ohun kan ti o la ala nipa rẹ ni ọpọlọpọ ọdun sẹyin. Bi eniyan ṣe ri niyi. Ṣugbọn Ọlọrun ṣe iyantẹlẹ ohun kan, ipo ala yi ko jina si a-riran, ipo orun ati aisun wa papọ fun a-riran. Fun ariran lati ri iran kan, ko nilo lati sùn - o n wa ni inu awọn oǹmọ̀ ara rẹ̀, o n la àlá nigbati ko sun.

-----
Bayi, ninu iran yi, tabi bi mo ṣe n sọ, mo wo, mo si ri ohun ajeji kan. Bayi, o da bi ẹnipe ọmọ mi ọkunrin kekere, Josẹfu, wa ni ẹgbẹ mi. Mo n ba a sọrọ. Bayi, ti iwọ yoo ba kiyesi iran yẹn daradara, iwọ yoo ri idi ti Joseph fi n duro sibẹ.
Mo si wo o, igbo nla kan si wa. Ninu igbo yi, ninu asopọ awọn ẹyẹ - awọn ẹyẹ kekeke, wọn ga, wọn si gun ni iwọn aabọ inṣi.... Wọn jẹ alagba kekere. Awọn iyẹ wọn dori kodo. Iyẹ meji si mẹta lo wa ni apa oke, mẹfa si mẹjọ ni apa to tẹlee, awọn mẹdogun tabi ogun lo tẹ lee, wọn sọkalẹ ni irisi piramidi, ile olori ṣonṣo. Awọn ẹda kekere naa .... Awọn iranṣẹ kekeke yi, o ti rẹ̀ wọn. Wọn si n wo iha ila oorun. Mo si wa ni Tucson, ni Arizona, ninu iran naa. Nitori .... Ọlọrun ṣe e ni ọna ti ko fẹ ki n kuna lati ri ibiti iran naa ti n waye. Mo n gbọn èèmọ́ kuro lara mi ninu aginju naa. Mo wipe, “Bayi, mo mọ pe eyi jẹ iran, mo si mọ pe mo wa ni Ilu Tucson. Mo si mọ pe awọn ẹyẹ kekeke nibẹ n duro fun ohun kan.” Wọn si n wo iha ila oorun. Lojiji, wọn mura lati fo, wọn si lọ si iha ila oorun.

Ni kete ti wọn fo lọ, asopọ awọn ẹyẹ ti o gun ju ti wọn lọ wa. Wọn da bi adaba, iyẹ wọn mú ṣonṣo, o si jẹ alawọ ewú-ori, awọn iyẹ ti o mọ́ra ju ti awọn ẹyẹ akọkọ ti ̣se iranṣẹ lọ. Wọn si n bọ wa si iha ila oorun kiakia. Bi wọn ṣe kuro ni oju mi, mo yi oju mi si iha iwọ oorun, o si ṣẹlẹ nibẹ. Iro nla kan wá, ti o mi gbogbo aye ti-ti! Bayi maṣe padanu eyi! Ẹyin ti ẹ n feti si ohun yi, ẹ ri i daju pe ẹ loye eyi daradara!
Lakọkọ, ìró bi àrá! Mo si ro pe o dun bi iro to n jade, tabi ohunkohun ti a lee pe iru iro to maa n dún nigbati ọkọ-ofurufu ba n fo kọja, ti iro naa si pada wa si ori ilẹ aye. O mi tì-tì.... O dún bi àrá, ohun gbogbo bẹẹ. Nigbana, o lee jẹ iro ara ati ohun bi mọnamọna. Nko ri mọnamọna. Mo kan gbọ iro nla yẹn ti o jade lọ, ti o dún bi igba ti o ti gusu wa lati ọdọ mi, si iha orilẹ ede Mexico.

Ṣugbọn o mi ilẹ ti-ti. Nigbati o si ̣se bẹẹ, mo ṣi n wo ila iwọ oorun, ati lọ si ainipẹkun, mo ri akojọ-pọ ohun kan to n bọ wa. O da bi ẹnipe àmì tó-tò-tó ni. Iye awọn ti o wa nibẹ ko lee din-ni-marun, ko si lee ju meje lọ. Ṣugbọn wọn ni irisi Piramidi, eyitiṣe ile olori ṣonṣo, to maa n fẹ̀ nisalẹ ṣugbọn to n tin-rin lọ soke, bẹẹ ni awọn ojiṣẹ to n bọ wa yi ri.
Nigbati eyi si ṣẹlẹ, agbara Ọlọrun Olodumare gbe mi lọ soke lati lọ pade wọn. Mo si lee ri i.... Ko fi mi silẹ. Ọjọ mẹjọ ti kọja, nko si lee gbagbe rẹ sibẹ. Ko si ohun to yọ mi lẹnu to bẹẹ ri. Awọn ẹbi mi yoo sọ eyi fun yin.

Mo lee ri awọn angẹli naa, ti irisi wọn ni ìyẹ́-ẹ̀yìn, wọn yára ju bi iro ṣe lee yara lọ. Wọn wa lati ainipẹkun laarin iṣẹju aaya. Ki o to ṣẹju, ni iṣẹju kan, wọn ti de ibẹ. Nko ni akoko lati ka wọn. Ko si akoko, ju ki n wo wọn lasan lọ. Awọn ti wọn lagbara, awọn angẹli alagbara nla, ti iyẹ wọn funfun! Iyẹ wọn wa lori wọn, won n lọ “Wiu-wiu,” nigbati eyi si ṣẹlẹ, a gbe mi lọ si inu Piramidi yi, ti asopọ awọn angẹli naa mu wa.
Mo ro o, Pe, “Bayi, ohun niyi.” Nko lee sọrọ, mo wipe, “Ah, akiika! Eyi tumọsi pe iro kan n bẹ ti yoo pa mi. Mo ti de opin irinajo mi ni aye bayi. Nko gbọdọ sọ fun awọn eniyan mi nigbati iran yi ba lọ. Nko fẹ ki wọn o mọ nipa rẹ. Ṣugbọn Baba ọrun ti jẹ ki n mọ pe akoko mi ti pari. Nko ni sọ fun ẹbi mi, ki wọn o ma ba a ṣe iyọnu nipa mi, nitoripe mo ti fẹ kuro lori ilẹ aye. Awọn angẹli wọnyi si ti wa fun mi, n o si ku laipẹ, ninu iro kan.”

Nigbana, ero kan tọ mi wa, nigbati mo wa ninu awọn asopọ naa, o wipe “Rara, iyẹn ki i ṣe bẹẹ. Ti yoo ba pa ọ, ko ba ti pa Joseph pẹlu,” mo si n gbọ ti Joseph n pe mi. Koburu, nigbana, mo yipada, mo si ro pe, “Oluwa Ọlọrun ki ni iran yi tumọsi?”
Mo n ro o, o si tọ mi wa. Ki i ṣe ohùn, o kan tọ mi wa ni.“ Ah! Awọn angẹli Ọlọrun lo n tọ mi wa yi, lati fun mi ni aṣẹ isẹ iranṣẹ mi ti o kan!” Nigbati mo si ro iyẹn, mo gbe ọwọ mi soke mo si wipe, “Ah, Jesu Oluwa, ki ni ohun ti Iwọ yoo fẹ ki n ṣe? Iran naa si pari. Fun bi wakati kan, nko ni imọlara kankan.

Bayi, ẹyin eniyan wọnyi mọ ohun ti ibukun Ọlọrun jẹ. Ṣugbọn agbara Ọlọrun yatọ patapata, agbara Oluwa ni iru ipo bẹẹ. Mo ti ni imọlara rẹ ni ọpọlọpọ igba tẹlẹ ri, ninu iran, ṣugbọn ko to bẹẹ. O dabi ẹru to wa tọwọtọwọ. Ẹru ba mi, to bẹẹ gẹẹ ti ara mi rọ niwaju awọn ẹda yi. Otitọ ni mo n sọ. Bi Paulu ti sọ, “Emi ko parọ.” Ẹ ko ti i ri ki n maa sọ ohun ti ko tọna nipa iru nkan bẹẹ ri. Ohun kan fẹẹ ṣẹlẹ!

Nigbana, lẹyin igba diẹ, mo sọ pe, “Jesu Oluwa, ti n o ba ku, jẹki n mọ, ki n ma ba sọ fun awọn eniyan mi nipa eyi. Ṣugbọn ti o ba jẹ pe ohun miran ni, jẹki n mọ.” Ko si idahun. Lẹyin ti Ẹmi ti fi mi silẹ fun nkan bi ọgbọn iṣẹju, mo ro bẹẹ, tabi ju bẹẹ lọ, mo wipe, “Oluwa, ti o ba jẹ bẹẹ, nigbana, pe n o ku ni, ti O si ti pari pẹlu mi lori ilẹ aye, ti a o si mu mi lọ si ile bayi.... ti o ba si jẹ bẹẹ, o dara. Gbogbo rẹ dara.” Nitorina, mo wipe, “Ti o ba ri bẹẹ, jẹki n mọ. Ran agbara Rẹ si mi pada. Nigbana, n o mọ, nko si ni sọ fun awọn eniyan mi, tabi ẹnikẹni, nipa rẹ, nitoripe Iwọ n mura lati mu mi lọ.” Ko si si ohun ti o ṣẹlẹ. Mo duro fun igba diẹ.
Nigbana mo sọ pe, Jesu Oluwa, ti ko ba tumọsi iyẹn, ti o si tumọsi pe O ni ohun kan fun mi lati ṣe, ti yoo si fara han mi lẹyinnaa, nigbana, ran agbara Rẹ.“ O si fẹ ẹ lee gbe mi kuro ninu iyara yẹn!

Mo ri ara mi nibikan, nibi igun inu ile naa. Mo lee gbọ bi iyawo mi ṣe n gbiyanju lati mi ilẹkun. Ilẹkun iyara ibusun ti ti-pa. Mo si ni Bibeli kan ti O ṣi silẹ, mo si n ka a.... Nko mọ, ṣugbọn mo gbagbọ pe Iwe Romu ori kẹsan, ẹsẹ ti o gbẹyin ni o wa: “Kiyesii mo gbe okuta ikọsẹ ati apata idigbolu kalẹ si Sioni: ẹnikẹni ti o ba si gba a gbọ, oju ki yoo tii.”

Mo ro o pe, “Iyẹn sajeji n o maa ka iyẹn,” Ẹmi ṣi n gbe mi ninu iyara. Mo pa Bibeli de, mo si n duro sibẹ. Mo lọ si ibi ferese, ni agogo mẹwa owurọ, mo gbe ọwọ mi soke, mo si wipe, “Oluwa Ọlọrun, nko mọ. Eyi jẹ ọjọ to sajeji si mi. Mo si wa ni ẹgbẹ ara mi, o fẹẹ jẹ bẹẹ.”

Mo wipe, “Oluwa, ki ni iyẹn tumọsi? Jẹki n ka a lẹkan si, ti O ba jẹ Iwọ.” (Bayi, eyi jọ ọrọ ọmọde.) Mo si gbe Bibeli naa, mo si ṣii. Ibẹ ni O wa lẹkan si, nibikanaa - Paulu, o n sọ fun awọn Juu pe wọn n gbiyanju lati gba a nipa iṣẹ, ṣugbọn igbagbọ ni a fi n gba a gbọ.

-----
Mo gbagbọ pe angẹli keje ninu Iwe Ifihan ori kẹwa, oun ni iranṣẹ keje ti inu Iwe Ifihan 3:14. Ẹ ranti .... Bayi, ẹ jẹki n ka a, ẹ wo o, nibiti mo ti lee ka a. Nisisiyi, eyi ni angẹli keje.

Ṣugbọn ni ọjọ ohun angẹli keje [ẹsẹ keje], nigbati yoo ba fun ipe, nigbana ni ohun ijinlẹ Ọlọrun pari, gẹgẹ bi ihinrere ti o sọ fun awọn iranṣẹ Rẹ, awọn wolii.

Bayi, ẹ kiyesi, angẹli ni eyi, o si jẹ angẹli igba ijọ keje, nitoripe o sọ nihin pe angẹli igba ijọ keje ni. Njẹ ẹ ri iyẹn? Ti ẹ ba fẹ ri ẹniti.... Tabi ibiti angẹli naa wa - Iwe Ifihan 3:14. Oun ni angẹli si ijọ Laodekia.

-----
Bayi, ẹ feti silẹ daradara. Angẹli keje ti Iwe Ifihan ori kẹwa, ẹsẹ keje ni iranṣẹ igba ijọ keje, ṣe ẹ rii. Bayi, ẹ kiyesi. Bayi, ẹ kiyesii nihin.

Ṣugbọn ni ọjọ ohun angẹli keje, nigbati yoo ba fun ipe, nigbana ni ohun ijinlẹ Ọlọrun pari....
Bayi, fifun ipe, iranṣẹ yi, angẹli keje nihin, o n fun ipe ohun iṣẹ ti a ran an si ijọ Laodekia. Ẹ kiyesi iru iṣẹ iranṣẹ yi. Bayi, ki i ṣe si angẹli akọkọ (a ko fun un ni iyẹn), angẹli keji, ikẹta, ikẹrin, ikarun, ikẹfa; ṣugbọn angẹli keje ni o ni iru iwaasu yi, ki ni ohun ti o jẹ? Kiyesii, iru iwaasu rẹ; o n pari gbogbo ohun ijinlẹ Ọlọrun ti a kọ sinu Iwe. Angẹli keje n ṣe akojọpọ gbogbo ijinlẹ ti awọn ẹgbẹ ti a fi ọgbọn eniyan gbekalẹ ati awọn ijọ ẹlẹkọ adamọ ti ̣se idibajẹ wọn. Angẹli keje ko wọn jọ, o si pari gbogbo ijinlẹ naa. Ohun ti Bibeli sọ niyi - o n pari ijinlẹ ti a kọ sinu Iwe.

Ka iroyin ni kikun ni...
Eyi ha ni ami opin bi, alagba?

Wo tun... Awọsanma eleri nla.



Ifiranṣẹ ibudo...Yan ede rẹ ki o gba awọn ifiranṣẹ ọfẹ lati ọdọ Arákùnrin Branham.


Ohun ijinlẹ Kristi.

Wẹẹbu iwe iroyin Gẹẹsi.

Iwe Ifihan jara.

 

Ọlọrun ati Imọ Atọka.
- Archaeology.

Igbasoke n bọ.

 

Awọn ẹkọ akọkọ
ti ifiranṣẹ naa.

Awọn ti o dara iroyin.
Jesu ku fun ese re.

Iribomi Omi.

 

Awọsanma eleri nla.

Ọwọn ti ina.

Ogo Shekinah ti Ọlọrun.

Ibojì ti ṣofo.
O ti jinde.

Ọlọrun salaye.

Awọn ìgbà ijọ meje.

Awọn edidi meje.

Ọlọrun ati Itan.
jara Atọka - Dáníẹ́lì.

Kristiẹni ije jara.
Ìgbéyàwó Àti Ìkọ̀sílẹ̀.
Akojọ Ifiranṣẹ.

Opin akoko jara.

Ngbe ọrọ jara.

Keresimesi jara.

Iku. Ohun ti nigbana?

Orúkọ Ọlọrun.

Ọkọ Noa.

 

Ẹṣẹ Atilẹba.
Je o ẹya apulu?

Adaparọ.
Awọn orisun - Babeli.

Ọlọrun ati Imọ.
Dainoso Adaparọ.

Archaeology.
Sodomu ati Gomorra.

  Iwe-mimọ sọ...

Àmì Ọmọ-Eniyan yóo wá yọ ní ọ̀run. Gbogbo àwọn ẹ̀yà ayé yóo figbe ta, wọn yóo rí Ọmọ-Eniyan tí ó ń bọ̀ lórí ìkùukùu ní ọ̀run pẹlu agbára ògo ńlá.

Matiu 24:30


Tẹ aworan kan lati ṣe igbasilẹ aworan iwọn ni kikun tabi PDF.


Acts of the Prophet

(PDFs Gẹẹsi)
 

Eyi ha ni ami
opin bi, alagba?

(PDF) òke Iwọoorun.
Nibiti awọsanma farahan.

Chapter 14
- Sabino Canyon

(PDF Gẹẹsi)

Chapter 11
- The Cloud

(PDF Gẹẹsi)

William Branham
Life Story.

(PDF Gẹẹsi)

How the Angel came
to me.

(PDF Gẹẹsi)