Ẹkọ awọn Nikolaitani.
Ẹkọ awọn Nikolaitani.
William Branham.Ka iroyin ni kikun ni...
Igba Ijọ Pagamu.Iwe Ifihan 2:15,
“Bẹẹ naa pẹlụ ni iwọ ni awọn ti o gba ẹkọ awọn Niko-laitaini gbọ, eyi ti Mo korira.”Iwọ yoo ranti wi pe ni Igba Ijọ Efesu mo fi ye ọ pe ọrọ Niko-laitaini yii, wá lati inu ọrọ Giriki meji: Nikao, ti o tumọ si lati ṣẹgun, ati Lao, ti o tumọ si ọmọ-ijọ. Niko-laitaini wa tumọ si lati ṣẹgun (tẹgaba lori) ọmọ-ijọ. Wayi o, eeṣe ti eyi fi jẹ ohun ti o buru jai? O buru nitori wi pe Ọlọrun ko fi igba kan ri fi ijọ Rẹ le ọwọ awọn adari ti a ti ọwọ eniyan yan, ti n fi ọna iṣelu ṣe ohun gbogbo. O ti fi ijọ Rẹ si abẹ itọju awọn olori ti Ọlọrun yan, ti a kun pẹlu Ẹmi Mimọ, tin gbe nipa Ọrọ Ọlọrun, awọn ti n ṣe idari awọn eniyan Rẹ nipa fifi Ọrọ Ọlọrun bọ wọn. Ko ya awọn eniyan si ọtọ si ẹlẹgbẹ-jẹgbẹ ki awọn ẹgbẹ alufaa mimọ lee maa dari awọn ọmọ-ijọ. Otitọ ni wi pe awọn oludari ni lati jẹ mimọ, ṣugbọn bẹẹ naa ni o ni lati ri pẹlu awọn ọmọ-ijọ. Ni afikun, ko si ibi ikan ninu Ọrọ Ọlọrun ti awọn alufaa tabi awọn oniwaasu tabi awọn eniyan bi i bẹẹ ti n laja láàárín Ọlọrun ati awọn eniyan, bẹẹ ni a ko ri ibikibi ti a ti ya wọn si ọtọọtọ ninu ijọsin wọn si Oluwa. Ọlọrun fẹ ki gbogbo eniyan fẹran Oun, ki wọn si maa jumọ sin Oun. Ẹkọ-itẹgabaalufaa- lori-awọn-ọmọ-ijọ n pa awọn ilana wọnyi run, kaka bẹ o ya awọn alufaa si ọtọ o si sọ wọn di oluwa dipo iranṣẹ.
Ẹkọ yii bẹrẹ ni tootọ gẹgẹ bi ìṣe ni igba ijọ akọkọ. O dabi ẹni wi pe ede-ai-yede naa wà pẹlu awọn ọrọ meji kan: alagba (awọn prẹsibita) ati alabojuto (awọn biṣọọbu). Bi o tilẹ jẹ wi pe Iwe Mimọ fihan ni wi pe ọpọlọpọ alagba ni o wa ni ijọ kọọkan, awọn kan (Ignatius wa ni ara wọn) bẹẹrẹ si i kọni wi pe biṣọọbu jẹ ẹni ti ipo rẹ ga julọ tabi ti o ni aṣẹ ati idari lori awọn alagba. Otitọ ọrọ naa ni wi pe, ọrọ ti a n pe ni “alagba” duro fun iru ẹni ti ẹni naa jẹ, nigba ti “biṣọọbu” duro fun ipo-iṣẹ ọkunrin kan naa. Alagba ni ẹni ti ẹni naa jẹ. Biṣọọbu si ni ipo-iṣẹ rẹ. Ọrọ yii, “Alagba” ko fi igba kan ri ni itumọ miiran, ko si ni ni itumọ miiran ju ọjọ ori eniyan ninu Oluwa nikan lọ. O jẹ alagba, ki i ṣe nitori wi pe wọn yan an tabi wọn fi jẹ oye naa, ati bẹẹ bẹẹ lọ, ṣugbọn nitori wi pe O NI ỌJỌ LORI NINU OLUWA. Ọ jẹ ẹni ti o fi ẹsẹ mulẹ gbọingbọin, ti a kọ jiná, ti ki i ṣe ope, ṣugbọn ti o ṣe e gbarale nitori iriri ati igbe-aye onigbagbọ ti o daniloju ti o ti ni fun ọpọlọpọ ọdun.
Ṣugbọn rara o, kaka ki awọn biṣọọbu yii duro gbọingbọin laiyẹsẹ ninu ẹkọ ti Pọọlu gbekalẹ ninu awọn Ẹpisteli, wọn tẹle itumọ ikọọkọ ti ara wọn nipa akọsilẹ ti igba ti Pọọlu pe awọn alagba lati Efesu wa si Miletu gẹgẹ bi a ṣe kọ Ọ silẹ ni Iṣe Apọsteli 20. Ni ẹsẹ kẹtadinlogun, Akọsilẹ naa wi pe, a pe “awọn alagba”, ṣugbọnni ẹsẹ kejidinlọgbọn, a pe wọn ni alabojuto (biṣọọbu). Ṣugbọn awọn biṣọọbu wọnyi (lai si aniani ní ifẹ lati dari awọn eniyan Ọlọrun nipa ilana iṣelu, wọn si ni ilara fun agbara) fi aake kọri wi pe ohun ti Pọọlu ṣe yii tumọ si wi pe awọn alabojuto ni agbara ti o ju eyi ti awọn alagba ni láàárín ijọ olukuluku wọn lọ. Loju tiwọn Biṣọọbu jẹ ẹni ti o ni aṣẹ lori ijọ rẹ ati lori ọpọlọpọ oluṣọ-agutan ti awọn ijọ miiran pẹlu. Iru ẹkọ bayi lodi si Iwe Mimọ tabi itan ti a kọsilẹ, sibẹsibẹ eniyan olufọkansin bi Polycarp fi ara mọ iru ifi-eniyan-ṣe-oludari-ijọ-dipo-Ẹmi Mimọ Ọlọrun bayi.
Nitori naa, ohun ti o bẹrẹ gẹgẹ bi ìṣe ni igba ijọ akọkọ di ẹkọ ti o fi ẹsẹ mulẹ, bẹẹ naa ni o ṣe ri ni oni. Titi di oni, awọn biṣọọbu ṣi n wi pe awọn ní agbara lati dari awọn eniyan Ọlọrun, ki wọn si ṣe wọn bi wọn ṣe fẹ́, ki wọn si fi wọn si ipo ti o ba wu wọn ninu iṣẹ-iriju-iwaasu. Eleyi kọ idari Ẹmi Mimọ Ti o wi pe,“Ya Pọọlu ati Banaba sọtọ fun Mi fun iṣẹ eyi ti Mo ti pe wọn si.” Eyi jẹ iṣodi-si-Ọrọ-Ọlọrun, ati iṣodi-si-Kristi.
Matiu 20:25-28,
“Ṣugbọn Jesu pe wọn sọdọ Rẹ, O si wi pe, Ẹyin mọn pe awọn ọba Keferi a maa lo agbara lori wọn, ati awọn ẹni-nla ninu wọn a maa fi ọla teri wọn ba. Ṣugbọn ki yoo ri bẹ láàárín yin: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fẹ pọ ninu yin, ẹ jẹki o ṣe iranṣẹ yin; Ati ẹnikẹni ti o ba fẹ ṣe olori ninu yin, jẹ ki o maa ṣe ọmọ-ọdọ yin: Ani gẹgẹ bi Ọmọ-eniyan ko ti wa ki a ṣe iranṣẹ fun Un, bikoṣe lati ṣe iranṣẹ fun ni, ati lati fi Ẹmi Rẹ ṣe irapada ọpọlọpọ eniyan.“Matiu 23:8-9, “Ṣugbọn ki a maṣe pe ẹyin ni Raabi: nitori pe ẹnikẹni ni Olukọ yin, ani Kristi; ará si ni gbogbo yin. Ẹ ma si ṣe pe ẹnikan ni baba yin ni aye: nitori Ẹnikan ni Baba yin, Ẹni Ti n bẹ ni Ọrun.”
Ki eyi lee ye ni yekeyeke sii, jẹ ki n ṣe alaye itẹ-gaba-awọn-alufaa-lori-ọmọ-ijọ ni ọna yii. Iwọ yoo ranti wi pe ni Ifihan 13:3, Iwe Mimọ sọ wi pe, “Mo si ri i ọkan ninu awọn ori rẹ bi ẹni pe a ṣa a pa, a si wo ọgbẹ aṣapa rẹ naa san, gbogbo aye si fi iyanu tẹle ẹranko naa.”
A si mọn wi pe ori ti a ṣa pa naa ni ilẹ-ọba nla ti ibọriṣa Roomu, agbara nla ti iṣelu ti agbanla-aye ni. Ori yii ni o tun dìdelẹ̀ lẹẹkan sii gẹgẹ bi, “ilẹ-ijọba-nla ẹlẹsin ijọ Aguda Roomu. Wayi o, ṣe akiyesi eleyi daradara. Kin ni ohun ti ijọba-nla abọriṣa Roomu ṣe ti o ṣe okunfa aṣeyọri rẹ? O ”n kọ ẹ̀yìn awọn eniyan si ara wọn ni, o si ti ipasẹ ṣiṣẹ bẹẹ ṣẹgun wọn“. Iwa ati iṣe Roomu ni yii. Kọ ẹyin wọn si ara wọn, ki o lee ṣẹgun wọn. O fi eyín rẹ ti o dabi irin ya wọn pẹrẹpẹrẹ, o si fi iwọra jẹ wọn run. Ẹnikẹni ti Roomu ba faya, ti o si jẹ-run, ko lee dide mọ laelae, bi igba ti o pa Carthage run to bẹẹ gẹẹ ti ko fi lee dide mọ laelae. Iwa ati ete kan naa ti o ni agbara bi irin, ni o wa ninu rẹ sibẹ nigba ti o dide gẹgẹ bii ijọ eke; ọgbọn ẹwẹ rẹ yii ko i tii yipada rara-kọ ẹyin wọn si ara wọn, ki o si ṣẹgun wọn. Ẹkọ Niko-laitani ni yii, Ọlọrun si korira rẹ.
Otitọ ti a mọn daradara ninu itan ni wi pe nigba ti ẹkọ ikuna yii yọkẹlẹ wọ inu ijọ awọn eniyan bẹrẹ si du ipo biṣọọbu, titi ti o fi jẹ wi pe ni aṣẹyin wa aṣẹyinbọ a n fi ipo naa fun awọn ọmọwe julọ, ti o si ni dukia ju, ti o ni iṣefeefe ti oṣelu julọ. Imọ ati eto eniyan bẹrẹ si i gba ipo ọgbọn Ọlọrun, bẹẹ ni, Ẹmi Mimọ ko si ṣe akoso mọ. Eyi jẹ ohun ti o buru jai, nitori wi pe awọn biṣọọbu bẹrẹ si i sọ wi pe igbe-aye onigbagbọ ti ko ni abawọn ko ṣe pataki fun oniwaasu lati lee waasu Ọrọ Ọlọrun tabi lati ṣe iṣẹ-iriju awọn aṣeyẹ ti o wa ninu ijọ mọ, nitori awọn eroja ilana ẹsin ati awọn aṣeyẹ funrara wọn nikan ni o ṣe pataki. Eleyi fi aaye silẹ fun awọn ẹni ibi (awọn atan-ni-jẹ) lati fọ́ agbo Ọlọrun.
Lẹyin ti ẹkọ atọwọda ti o gbe awọn biṣọọbu si ipo tí Ọrọ Ọlọrun kò fi wọn si ti fi ẹsẹ mulẹ tan, igbesẹ ti o kan ni pinpin awọn oye ẹsin ti a to ni isọri-n-sọri; nitori laipẹ awọn biṣọọbu-agba wá n dari awọn biṣọọbukeekeeke, ti awọn biṣọọbu alaṣẹ-ekeji-oriṣa wá n dari awọn biṣọọbu-agba, nigba ti yoo si di asiko Boniface Kẹta, Poopu kan, ti i ṣe Olori Alufaa Alaṣẹ-ekeji-oriṣa ẹni Ti o ga julọ ni o wa jẹ olori gbogbo wọn.
Pẹlu ẹkọ Niko-laitani ati idapọ ẹsin onigbagbọ pẹlu ẹsin Babiloni yii, ko si abayọri miiran bikoṣe ohun ti Isikẹli ri ninu Iwe Isikẹli 8:10, “Bẹẹni mo wọle, mo si ri; si kiyesi i, gbogbo aworan ohun ti n rako, ati ẹranko irira, ati gbogbo oriṣa ile Israẹli ni a ya ni aworan lara ogiri yika kiri.” Ifihan 18:2,3b, “O si kigbe ni ohun rara, wi pe, Babiloni nla ṣubu, o si di ibujoko awọn ẹmi eṣu, ati iho ẹmi aimọ gbogbo, ati ile ẹyẹ aimọ gbogbo, ati ti ẹyẹ irira,nitori gbogbo orilẹ ede ti mu waini ibinu agbere rẹ.”
Ẹkọ Niko-laitani yii, ijọba eyi ti a fi ẹsẹ rẹ mulẹninu ijọ ko ri oju rere ni ọdọ ọpọlọpọ eniyan nitori wọn lee ka awọn ẹpisteli ti awọn ẹni-mimọ kan kọ lori Ọrọ Ọlọrun. Nitori naa kin ni ijọ ṣe? O yọ awọn olukọni olododo kuro ninu ijọ, o si jo awọn iwe-akọsilẹ naa. Wọn sọ wi pe, “Yoo gba akanṣe ẹkọ lati lee kà, ati lati ni oye Ọrọ Ọlọrun. Nitori Peteru paapaa sọ wi pe, ọpọlọpọ ohun wọọni ti Pọọlu kọ sọro i ye ni”. Niwọn igba ti wọn ti gba Ọrọ Ọlọrun kuro ni ọwọ awọn eniyan naa, ko pẹ ko jina, awọn eniyan naa bẹrẹ si i fi eti si kiki ohun ti alufaa ni lati sọ fun wọn, wọn si n ṣe wọn. Wọn n pe idari yii ni ti Ọlọrun ati Ọrọ Rẹ Mimọ. Wọn gba ọkan ati igbesi-aye awọn eniyan naa, wọn si sọ wọn di ọmọ-ọdọ awọn ẹgbẹ onroro alufaa ti o lagbara.
Bi o ba n fẹ ẹri wi pe Ijọ Aguda n fẹ igbesi-aye ati ọkan awọn eniyan, iwọ ṣaa fi eti silẹ si ofin ti Theodosius kẹwa. Ofin-agbelẹrọ Kin-in-ni ti Theodosius.
O fi ofin yii lelẹ ni kete ti Ijọ Kin-in-ni ti Roomu baptisi rẹ. “Awa ọba-nla mẹta n fẹ ki awọn eniyan wa duro lai yẹsẹ kuro ninu ẹsin ti Peteru kọ́ awọn ara Roomu, ti a ti fi otitọ ọkan daabobo nipa aṣa-ijọ, eyi ti a n kọ ni lati ọwọ Olori Alufaa Alaṣẹ-ekeji-oriṣa ẹni Ti o ga julọ, Damasus ti Roomu, ati Peteru, biṣọọbu Alexandria, ọkunrin oniwa bi ti awọn Apọsteli gẹgẹ bi ilana awọn Apọsteli, ati ẹkọ opomulero Ihinrere; ẹ jẹ ki a gbagbọ ninu Ọlọrun kan ti Baba, Ọmọ ati Ẹmi Mimọ, ti wọn ni ọla ọgọọgba ninu Mẹtalọkan Mimọ. A wa paṣẹ wi pe ki awọn ti o gba igbagbọ yii gbọ maa jẹ kristiani Ijọ Aguda ti Agbaye; a ṣo awọn omugọ ti o n tẹle ẹsin miiran ni orukọ ẹgan nì - aladamọ, a si kọ jalẹ wi pe ki a maa pe ibi ipade wọn ni ile-Ọlọrun. Lai sọ nipa ti idalẹbi ti idajọ Ọlọrun, wọn ni lati maa reti ijẹniya nla ti aṣẹ wa pẹlu amọna lati inu ọgbọn Ọrun yoo ro wi pe o tọ o si yẹ lati fi jẹ wọn...”
Awọn ofin ijiya mẹẹdogun ti ọba-nla yii gbe jade láàárín ọdun mẹẹdogun jẹ ki awọn ajinhinrere padanu awọn ẹtọ lati ṣe ohun ti wọn fẹ nipa ẹsin wọn;ko gba wọn laaye lati ṣe iṣẹ-ijọba, o n fi siṣan owo-itanran, ifi-ipa-gba-ohun-ini ẹni, lile-ni-jade-kuro-ni-ilu, ati ni gba miiran iku, dẹruba wọn.
Njẹ o mọ nnkan kan ṣa? Ohun kan naa ni o wa niwaju wa lati la kọja ni oni.
Ijọ Aguda Roomu n pe ara rẹ ni Iya awọn Ijọ, o n pe ara rẹ ni ijọ ti akọkọ tabi ijọ ipilẹ. Eleyi jẹ otitọ patapata. Oun ni ojulowo ijọ Akọkọ ti Roomu ti o pada ṣẹyin, ti o si lọ si inu ẹṣẹ. Oun ni akọkọ ti o fieniyan- ṣe-olori-ati-idari-ijọ-Ọlọrun-dipo-Ẹmi-Mimọ. Ninu rẹ ni a ti ri awọn ìṣe, ati lẹyin eyi awọn ẹkọ Niko-laitani. Ko si ẹni ti o lee sẹ ẹ wi pe ki i ṣe iya. Iya ni, o si ti bi awọn ọmọ obinrin. Ọmọ obinrin maa n wa lati inu obinrin. Obinrin kan ti a fi aṣọ alawọ pupa wọ ti o joko ni ori oke meje ti Roomu. Aṣẹwo ni obinrin naa jẹ o si ti bi awọn ọmọ obinrin. Awọn ọmọ obinrin naa ni awọn Ijọ-ti-n-tako-Ijọ-Aguda ti o jade kuro ninu rẹ, ti o si pada taara si inu ifi-eniyan-ṣe-adari-ijọ-dipo-Ẹmi Mimọ ati itẹgaba-awọn-alufaalori- ọmọ-ijọ. Iya awọn ijọnaa ni a pe ni agbere. Eyi ni obinrin ti ko jẹ olootọ si ẹ̀jẹ́ igbeyawo rẹ. A gbe e ni iyawo fun Ọlọrun, lẹyin naa o lọ ba eṣu ṣe agbere, ati ninu agbere rẹ ni o ti bi awọn ọmọ obinrin ti wọn dabi rẹ gẹgẹ. Iya yii ati awọn ọmọ obinrin rẹ lapapọ jẹ aṣodi-si-Ọrọ Ọlọrun, aṣodi-si-Ẹmi Mimọ, ati ni titori bẹẹ wọn jẹ aṣodi-si-Kristi. Bẹẹ ni, AṢODI-SI-KRISTI ni wọn.
Nisisinyi ki n to lọ jina mo fẹ fi ẹnu ba a wi pe awọn biṣọọbu ti iṣaaju wọnyi ro wi pe awọn ga ju Ọrọ Ọlọrun lọ. Wọn sọ wi pe awọn lee dárí ẹṣẹ awọn eniyan ji wọn bi wọn ba jẹwọ awọn ẹṣẹ naa. Eyi ko fi igba kan jẹ otitọ ri. Wọn bẹrẹ si i baptisi awọn ọmọ-ọwọ ni igba ọgọrun ọdun keji lẹyin Ajinde. Ibaptisimu fun atunbi gan an ni wọn n ṣe. Ko yanilẹnu wi pe Ọrọ Ọlọrun ko ye awọn eniyan loni. Bi awọn ti o sunmọ Pẹntikọsti pẹkipẹki ko ba ni oye Otitọ ti ipilẹ, melo melo ni awọn eniyan ti o fi ẹgbẹwa ọdun jinna réré si Pẹntikọsiti yoo ṣe wà ni ipo ai-ni-ireti ti o ga julọ ni ti otitọ Ọrọ Ọlọrun to.
Aaa, ijọ Ọlọrun, ireti kan ṣoṣo ni n bẹ. Pada si inu Ọrọ Ọlọrun ki o si duro ninu Rẹ.
Ka iroyin ni kikun ni... Igba Ijọ Pagamu.
Ifiranṣẹ ibudo...Yan ede rẹ ki o gba awọn ifiranṣẹ ọfẹ lati ọdọ Arákùnrin Branham.