Ẹkọ Balaamu.


  Iwe ti Ifihan jara.

Ẹkọ Balaamu.


William Branham.

Ka akọọlẹ naa ni... Igba Ijọ Pagamu.

Ifihan 2:14,
“Ṣugbọn Mo ni nnkan diẹ, i wi si ọ, nitori ti iwọ ni awọn ti o di ẹkọ ti Balaamu mu nibẹ, ẹni ti o kọ́ Balaku lati mu ohun ikọsẹ wa siwaju awọn ọmọ Israẹli, lati maa jẹ ohun ti a pa rubọ si oriṣa, ati lati maa ṣe agbere.”

Ko si bi o ṣe lee ni igbekalẹ Niko-laitani ninu ijọ lai jẹ wi pe ẹkọ keji yii wa nibẹ pẹlu. Sẹ o ri i, bi o ba mu Ọrọ Ọlọrun ati idari Ẹmi Mimọ kuro gẹgẹ bi ọna ijọsin (awọn ti o n sin Mi ni lati sin Mi ninu Ẹmi ati Otitọ) nigba naa o ni lati fun awọn eniyan naa ni ọna ijọsin miiran gẹgẹ bi arọ́pò, ifirọpo yii ni o jasi ẹkọ Balaamu.

Bi a o ba ni oye ohun ti ẹkọ Balaamu i ṣe ninu Ijọ Majẹmu Titun, o yẹ ki a pada lọ si ohun ti o jẹ ninu ijọ Majẹmu laelae, ki a si fi ṣe ayẹwo Igba Ijọ kẹta ni, ki a si tọ pinpin rẹ wa si igba ijọ ti a wà ninu rẹ lọwọlọwọ bayi.

Itan yii wa ninu Iwe Numeri ori-keji-le-logun de ori karun-un-din-lọgbọn. Wayi o, a mọn wi pe awọn ọmọ Israẹli ni awọn ẹni ti Ọlọrun yan. Awọn ni ijọ Pẹntikọsti tootọ ti ọjọ tiwọn. Wọn ti gba aabo labẹ ẹjẹ naa, a ti baptisi gbogbo wọn ninu Okun Pupa, wọn jade wa lati inu odo naa wọn n kọrin ninu Ẹmi, wọn si n jo labẹ okun Ẹmi Mimọ, ti Mariamu, wolii-obinrin si n lu ilu-oniṣaworo rẹ. Lẹyin irin-ajo fun igba diẹ, awọn ọmọ-Israẹli de ilẹ Moabu. Iwọ yoo ranti ẹni ti Moabu jẹ. Ọmọ ọkunrin Lọọti ti o bi nipaṣẹ ọkan ninu awọn ọmọ obinrin rẹ ni. Lọọti ẹwẹ, si jẹ ọmọ aburo Abrahamu ọkunrin, nitori naa Israẹli ati Moabu jẹ ibatan. Mo fẹ ki eyi ye ọ. Awọn ara Moabu mọ Otitọ, yala wọn gbe nipa rẹ tabi wọn ko ṣe bẹẹ.

Bayi ni Israẹli de aala Moabu, o si ran awọn oniṣẹ si ọba wi pe, “Arakunrin ni wa. Jẹ ki a la orilẹ-ede rẹ kọja. Bi awọn eniyan tabi ohun ọsin wa ba jẹ, tabi mu ohunkohun, ao fi tayọtayọ san owo rẹ.” Ṣugbọn ojojo-ra mu ọba Balaki olori ẹgbẹ Niko-laitani nì, ko fẹ gba ki ijọ kọja láàárín ilu rẹ pẹlu awọn awọn iṣẹ - ami, awọn iṣẹ-ara ati oniru-un-ru awọn ifarahan Ẹmi Mimọ, awọn ti oju wọn n tan pẹlu ogo Ọlọrun. Eyi lewu pupọ, nitori wi pe o lee padanu ọpọ ninu awọn eniyan rẹ. Nitori naa Balaku kọ jalẹ lati jẹ ki lsraẹli gba aarin ilu rẹ kọja. Ni tootọ ẹru ti o ni fun wọn yii pọ to bẹẹ ti o fi lọ ba wolii àyálò kan ti a n pe ni Balaamu, o si sọ wi pe ki o ṣe alagata láàárín oun ati Ọlọrun, ki o si be Olodumare lati fi Israẹli gẹgun, lati lee sọ wọn di alailagbara. Balaamu, ẹni ti o wa ni ifoju-sọna lati ko ipa ninu eto iṣelu ki o si di ẹni nla dunnu, gidigidi lati ṣe bẹẹ. Ṣugbọn nigba ti o ri i wi pe oun ni lati tọ Ọlọrun lọ, ki oun si ri oju rere Rẹ gbà lati fi awọn eniyan naa bú, ni iwọn igba ti oun ko lee da a ṣe, o lọi beere bọya Ọlọrun lee fun oun ni aṣẹ Rẹ lati lọ.Njẹ eyi ko ha dabi awọn ẹlẹkọ Niko-laitani ti a ni pẹlu wa loni bi? Wọn a maa gẹgun fun ẹnikẹni ti kò bá ní gba tiwọn.

Nigba ti Balaamu beere aaye ni ọdọ Ọlọrun lati lọ, Ọlọrun kọ jálẹ̀ fun un. Eyi dun un pupọpupọ, ṣugbọn Balaku fi aake kọri, o si ṣe ileri wi pe oun yoo fun un ni ọpọlọpọ ọrọ ati ọla sii. Nitori eyi Balaamu pada tọ Ọlọrun lọ. Wayi o, idahun akọkọ ti Ọlọrun fun un yẹ ki o tẹ ẹ lọrun. Ṣugbọn eyi ko tó fun Balaamu ti o fẹ ṣe ifẹ inu ti ara rẹ. Nigba ti Ọlọrun ri i wi pe o ti pinnu lati ṣe ohun ti o lodi yii, Ọlọrun ní ki o dide ki o maa lọ. Ni-ẹyẹ-o-sọ-ka o di kẹtẹkẹtẹ rẹ ni gaari o si mu ọna rẹ pọn. O yẹ ki o mọn wi pe ifẹ Ọlọrun ti a gba laaye lasan ni eyi, ati wi pe oun ko ni lee fi awọn eniyan naa bu bi oun tilẹlọ ni ogun igba, ti oun si gbiyanju ni ogun igba pẹlu. Bi i Balaamu ni awọn eniyan ri loni! Wọn gbagbọ ninu Ọlọrun mẹta, wọn si n ṣe ibaptisi ni apele mẹta dipo ORUKỌ naa, sibẹ Ọlọrun yoo ran Ẹmi Rẹ sori wọn gẹgẹ bi O ti ṣe fun Balaamu, wọn a si maa tẹsiwaju, wọn a si maa gbagbọ wi pe awọn tọ́ gan an, eyi ni o fi wọn han wi pe wọn jẹ oniwa Balaamu gẹlẹ. Ṣe o ri ẹkọ Balaamu bayi. Tẹsiwaju, laibikita. Ṣe e ni ọna ti o wu ọ. Wọn n sọ wi pe, “Ṣebi Ọlọrun ti bukun wa. O ni lati jẹ wi pe ohun ti a n ṣe tọ́ ní.” Mo mọn wi pe O ti bukun fun yin, n ko sẹ eyi. Ṣugbọn ọna ifi-idari-eniyan-rọpo-Ẹmi Mimọ kan naa ti Balaamu tọ ni o jẹ. Eyi jẹ ìṣe orikunkun si Ọrọ Ọlọrun. Ẹkọ eke ni.

Bayi ni Balamu mu ọna rẹ pọn ti o si n lọ kánkán titi ti angẹli lati ọdọ Ọlọrun fi dena rẹ. Ṣugbọn wolii naa (ti a lee fi we biṣọọbu, olori alufaa alase-ekeji-oriṣa, alaga, aarẹ ati alakoso-agba ijọ loni) fọ́jú si ohun Ẹmi, nitori èrè ọla ati ogo ati ti owo, to bẹẹ gẹẹ ti ko fi ri angẹli naa ti oun ti ida ti o yọ ti on duro de e. Nibẹ nio duro si lati dena aṣiwere wolii nì. Kẹtẹkẹtẹ naa ri i, o si yẹ si ọtun, o yẹ si osi, ni igbẹyin gbẹyin, o wa rún ẹsẹ Balaamu mọ ogiri olokuta. Kẹtẹkẹtẹ naa duro gbọn-in, o si kọ̀ lati tẹsiwaju, nitori wi pe ko lee tẹsiwaju. Nitori naa Balaamu bẹ́ silẹ, o si bẹrẹ si i na an. Nigba naa ni kẹtẹkẹtẹ yii bẹrẹ si sọrọ si Balaamu. Ọlọrun jẹ ki kẹtẹkẹtẹ naa bẹrẹ si fi ede eniyan sọrọ. Kẹtẹkẹtẹ naa ki i ṣe iru amulumala, iru ogidi ni. O wi fun wolii afọju naa bayi wi pe, “Emi ha kọ ni kẹtẹkẹtẹ rẹ, emi ko ha ti maa n fi tinutinu ati tayọ-tayọ gbe ọ kiri lati ọjọ wọnyi wa bi? Balaamu dahun o ni, ”Bẹẹ ni, Bẹẹ ni, iwọ ni kẹtẹkẹtẹ mi, o si ti n gbe mi kiri daradara titi di isisinyi, bi iwọ ko ba si fẹ lọ mọ,n o pa ọ ni.... kinla! Kin ni eyi, ṣe mo n ba kẹtẹkẹtẹ sọrọ ni? Eyi ma pa ni lẹrin o, mo ro wi pe mo gbọ ti kẹtẹkẹtẹ naa n sọrọ ni, emi naa si n da a lohun.“

Ni igba gbogbo ni Ọlọrun maa n fi ede-ajeji sọrọ. O sọrọ ni ibi ase Belṣassari, ati lẹyin naa ni Ọjọ Pẹntikọsiti. O tun n ṣe bẹẹ naa loni. O jẹ ikilọ wi pe idajọ n kan ilẹkun ni.

Nigba naa ni Balaamu ri angẹli naa ni ojukoroju. O sọ fun Balaamu wi pe ọla kẹtẹkẹtẹ rẹ ni o jẹ, i ba ti di oloogbe nisisinyi fun didan ti o dan Ọlọrun wo. Ṣugbọn nigba ti Balaamu ṣe ileri lati pada si ile, o gba a laaye lati tẹsiwaju, pẹlu ikilọ wi pe ohun ti Ọlọrun ba sọ fun un ni ki o sọ.

Bayi ni Balaamu lọ ti o si kọ́ pẹpẹ meje fun irubọ ẹran mimọ meje. O pa àgbò kan ti o duro fun bíbọ̀ Mesaya naa. O mọn ohun ti o yẹ ni ṣiṣe lati lee ri idahun si ibeere rẹ lọdọ Ọlọrun. O mọn ba-a-ti-ṣe; ṣugbọn ko ri Ìyọ́nú (agbara-ti-i-mu-nnkan-ṣiṣẹ) Ẹmi Ọlọrun gba; bẹẹ naa ni o ri loni. Ṣe ẹ ko ri nnkan ti a n sọ yii ni, ẹyin ẹlẹkọ Ifi-idari-eniyan-dipo-Ẹmi Mimọ? Israẹli wa ni afonifoji, wọn n ṣe irubọ kan naa, wọn n ṣe ohun kan naa ti Balaamu ṣe, ṣugbọn ẹgbẹ kan ṣoṣo ni o ni awọn iṣẹ-ami Ọlọrun láàárín wọn. Awọn nikan ṣoṣo ni Ọlọrun wa láàárín wọn. Eto ẹsin lasan ko lee gbe ọ de ibikibi. Ko lee rọpo ifihan agbara Ẹmi Ọlọrun. Ohun yii kan naa ni o ṣẹlẹ ni Nikia. Wọn gba ẹkọ Balaamu wọle, wọn kọ ẹkọ-opomulero Ọlọrun. Wọn kọsẹ̀, bẹẹ ni, wọn ṣubu. Wọn di oku lasan.

Lẹyin ti wọn ti rubọ tan, Balaamu ṣe tan lati sọ aṣọtẹlẹ. Ṣugbọn Ọlọrun lọ́ ahọn rẹ, ko si lee fi wọn bu. O wúùre fun wọn ni.

Inu bi Balaki gidigidi, ṣugbọn ko si ohunkohun ti Balaamu lee ṣe nipa aṣọtẹlẹ naa. Ẹmi Mimọ ti sọ ọ naa. Nitori naa ni Balaki ṣe sọ fun Balaamu ki o sọkalẹ lọ si afonifoji naa ki o si wo awọn aiṣedede wọn boya o lee ṣe i ṣe lati fi wọn bu. Ọna ọgbọn ẹwẹ ti Balaki lo ni ọna ọgbọn ẹwẹ kan naa ti wọn n lo loni. Awọn ijọ-ti-n-fi-ẹkọ-adamọ-rọpo-Ọrọ Ọlọrun yii n fi oju tẹmbẹlu awọn agbo onigbagbọ kekere, ohunkohun ti wọn ba si lee ri láàárín wọn lati fi sọ ọrọ abuku si wọn, ni wọn yoo mu jade, ti wọn yoo si polongo. Bi onigbagbọ ti ode oni ba gbe igbe-aye ẹṣẹ ko si ẹnikẹni ti n sọ ohunkohun nipa rẹ, ṣugbọn jẹki ọkan ninu awọn ayanfẹ ṣe aṣiṣe kan, gbogbo iwe-iroyin ti n bẹ ni orilẹ-ede ni yoo polonge rẹ. Bẹẹni, Israẹli ní awọn aiṣedede rẹ. Wọn ni ipa igbe-aye ti ko loriyin, ṣugbọn pẹlu gbogbo aiṣedede wọn wọnyi, ipinnu Ọlọrun ti n ṣiṣẹ nipa iyanfẹ, nipa oore-ọfẹ lai ṣe nipa iṣẹ, WỌN NI IKUUKU NAA NI ỌSAN ATI ỌWỌN INA NAA NI ORU, OKUTA TI A LÙ NAA, EJO IDẸ, ATI AWỌN IṢẸ-AMI PẸLU IṢẸ-IYANU. Olọrun fi da awọn eniyan loju wi pe Israẹli ni ti Ohun ni tootọ, ki i ṣe nipa iṣẹ-ọwọ wọn bikoṣe nipa ohun ti Ọlọrun ṣe láàárín wọn.

Ka akọọlẹ naa ni... Igba Ijọ Pagamu.Iwe ti Ifihan jara.
Tẹsiwaju lori oju-iwe atẹle.
(Obinrin Jẹsebẹẹli nì.)


Ọlọrun ni
ọpọlọpọ apele,...
ṣugbọn orukọ
eniyan kan
pere ni O ni,
Orukọ naa si
ni Jesu.


Ohun ijinlẹ Kristi.

Wẹẹbu iwe iroyin Gẹẹsi.

Iwe Ifihan jara.

 

Ọlọrun ati Imọ Atọka.
- Archaeology.

Igbasoke n bọ.

 

Awọn ẹkọ akọkọ
ti ifiranṣẹ naa.

Awọn ti o dara iroyin.
Jesu ku fun ese re.

Iribomi Omi.

 

Awọsanma eleri nla.

Ọwọn ti ina.

Ogo Shekinah ti Ọlọrun.

Ibojì ti ṣofo.
O ti jinde.

Ọlọrun salaye.

Awọn ìgbà ijọ meje.

Awọn edidi meje.

Ọlọrun ati Itan.
jara Atọka - Dáníẹ́lì.

Opin akoko jara.

Ngbe ọrọ jara.

Orúkọ Ọlọrun.

Ọkọ Noa.

 

Ẹṣẹ Atilẹba.
Je o ẹya apulu?

Adaparọ.
Awọn orisun - Babeli.

Ọlọrun ati Imọ.
Dainoso Adaparọ.

Archaeology.
Sodomu ati Gomorra.

  Iwe-mimọ sọ...

Ẹ gbọ́ Israẹli: OLUWA Ọlọrun yín, OLUWA kan ṣoṣo ni.

Diutaronomi 6:4


Tẹ aworan kan lati ṣe igbasilẹ aworan iwọn ni kikun tabi PDF.


Acts of the Prophet.

(PDF Gẹẹsi)

The Two Babylons

by Rev Alexander Hislop.
(PDF Gẹẹsi)

Oke ati dide igbo
ni egbon ni Ṣaina.

Awọn lili ti ina.

Ọwọn ti ina.
- Houston 1950.

Imọlẹ lori apata
jibiti.


Ifiranṣẹ ibudo...Yan ede rẹ ki o gba awọn ifiranṣẹ ọfẹ lati ọdọ Arákùnrin Branham.