Obinrin Jẹsebẹẹli nì.


  Iwe ti Ifihan jara.

Jẹsebẹẹli awọn obìnrin wolĩ.


William Branham.

Ka iroyin ni kikun ni...
Igba Ijọ Tiatira.

Ifihan 2:20-23,
Ṣugbọn eyi ni Mo ri wi si ọ, nitori ti iwọ fi aaye silẹ fun obinrin ni, Jẹsebẹli ti o pe ara rẹ ni wolii, o si n kọ awọn iranṣẹ Mi, o si n tan wọn lati maa ṣe agbere, ati lati maa jẹ ohun ti a pa rubọ si oriṣa. Emi si fi saa fun un lati ronupiwada; ko si fẹ ronupiwada agbere rẹ. Kiyesi i Emi o gbe e sọ si ori akete, ati awọn ti n ba a ṣe panṣaga ni Emi o fi sinu ipọnju nla, bikoṣe bi wọn ba ronupiwada iṣẹ wọn. Emi o si fi iku pa awọn ọmọ rẹ; gbogbo ijọ ni yoo si mọ pe, Emi ni Ẹni Ti n wadi inu ati ọkan: Emi o si fifun olukuluku yin gẹgẹ bi iṣẹ yin.

Ohun akọkọ ti o ṣe pataki gidigidi ti a kọ nipa Jẹsebẹẹli ni wi pe KI I ṢE ọmọbinrin Abrahamu, bẹẹ ni dídi ara ẹya Israẹli rẹ ki i ṣe ni ibamu pẹlu ilana Ọrọ Ọlọrun fun gbigba ajeji si inu Israẹli, gẹgẹ bi o ti ri pẹlu Ruutu ara Moabu. Ko ri bẹ rara. Obinrin yii jẹ ọmọ Ẹtibaali, ọba Sidoni (Iwe Awọn Ọba Kin-in-ni 16:31) ẹni ti i ṣe aworo Asitaate. O gun ori itẹ nigba ti o pa Fẹliisi, ọba ti o jẹ ṣaaju rẹ. Lẹsẹkẹsẹ, a ri i wi pe ọmọ apaniyan ni. (Lai si aniani, eyi ran wa leti Kaini). Ọna ti o gba di ara Israẹli ki i ṣe nipa ọna ti Ọlọrun ti la silẹ fun awọn ẹya alaikọla lati di ara Israẹli; ṣugbọn o di ara Israẹli nipa IGBEYAWO pẹlu Ahabu, ọba awọn ẹya mẹwa Israẹli. Wayi o, idapọ yii gẹgẹ bi a ti ri i ko tẹle ilana Ọlọrun; ti iṣelu ni. Bayi ni a ri i wi pe obinrin yii ti o ti jin-in-giri ninu ibọriṣa ko ni ifẹ kankan bi o ti wu ki o kere to lati di olufọkansin Ọlọrun Otitọ Kanṣoṣo. Ṣugbọn o ti bá ara rẹ jẹ́ ẹ̀jẹ́ wi pe oun yoo yí Israẹli lọkan pada kuro lẹyin Oluwa.

Israẹli (awọn ẹya mẹwa naa) ti mọ ohun ti o jẹ lati fi ori balẹ fun ẹgbọọrọ maalu wura, ṣugbọn wọn ko i ti i di abọriṣa paraku, nitori wi pe wọn n jọsin fun Ọlọrun, wọn si gba ofin Mose gbo. Ṣugbọn lati igba ti Ahabu ti gbe Jẹsebẹẹli ni iyawo ni ibọriṣa ti bẹrẹ si i peléke lemọ́lemọ́ ni ọna bubuku ni Israẹli. O jẹ igba ti obinrin yii di àwòrò ninu awọn ile oriṣa ti o kọ fun Asitaate (Fẹnusi) ati Baali (oriṣa oorun) ni ọ̀rọ̀ orilẹ- ede Israẹli ti polúkúrúmuṣu de ibi ti idarudapọ ti bẹ́ silẹ.

Pẹlu eyi lọkan wa, a lee bẹrẹ sii ri ohun ti Ẹmi Ọlọrun n gbe kalẹ ni Igba Ijọ Tiatira yii. Ohun ni yii.
Ahabu gbe Jẹsebẹẹli ni iyawo, o ṣe eleyi gẹgẹ bi arekereke iṣelu lati fun ijọba rẹ ni okun ati lati dena ogun. Bayi gẹlẹ ni ijọ ṣe ni igba ti o ṣe igbeyawo labẹ Constantine. Awọn mejeeji darapọ nitori iṣelu, bi o tilẹ jẹ wi pe ohun Ẹmi ni wọn fi ṣe bojúbojú. Ko si ẹni ti o lee mu un da mi loju wi pe Kristiani ni Constantine. Abọriṣa ti o n lo awọn ohun ti a mọ̀n mọ́ awọn Kristiani ni. O ya agbelebu funfun si ara asà awọn ọmọ-ogun rẹ. Oun ni o da ẹgbẹ Akọni Columbus silẹ. O gbe agbelebu kan si ténté ile agogo ile Ọlọrun Sofia Mimọ, eyi ti o bẹrẹ aṣa atọwọdọwọ kan.

Ero Constantine ni lati ko gbogbo awọn abọriṣa, awọn Kristaini alafẹnujẹ ati awọn Kristiani tootọ papọ di ọkan. Fun igba diẹ o dabi ẹni wi pe yoo ṣe aṣeyọri, nitori awọn ojulowo onigbagbọ ba wọn rin diẹ lati lee ri i boya awọn a lee mu awọn ti o ti ṣako lọ pada wa sinu Ọrọ Ọlọrun. Nigba ti wọn ri i wi pe wọn ko lee mu awọn ti o ti ṣako lọ pada wa sinu Otitọ, o di dandangbọn fun wọn lati yọwọ-yọsẹ kuro ninu ẹgbẹ oṣelu yii. Nigba ti wọn ṣe bẹẹ, a pe wọn ni aladamọ, a si ṣe inunibini si wọn.

Jẹ ki n sọ nihin pe ohun kan naa ni o n ṣẹlẹ lọwọlọwọ loni. Gbogbo awọn eniyan n gbarijọ di ọkan. Wọn n kọ Bibeli kan ti yoo tẹ́ gbogbo eniyan lọrun, i baa jẹJuu, Aguda tabi Alatako-ijọ Aguda. Loni wọn ni Igbimọ Nikia tiwọn ṣugbọn wọn n pe e ni Igbimọ Agbarijọ Ẹsin Agbaye. Njẹ o mọ ẹni ti agbarijọ yii n ba ja? Awọn ti o ni Ẹmi Ọlọrun ni inu ọkan wọn ni. Ki i ṣe awọn ti wọn fi-idari-eniyan-dipo-Ẹmi Mimọ ti wọn n pe ni ẹni ti o ni Ẹmi Ọlọrun ni mo n sọ. Awọn ti wọn jẹ Pentikọsita nitori a kun ọkan wọn pẹlu Ẹmi Mimọ, ti wọn si ni awọn iṣẹ ami ati ẹbun Emi Mimọ ni aarin wọn nitori pe wọn n rin ninu Otitọ ni mo n sọ ni pa rẹ.

Nigba ti Ahabu gbe Jẹsebẹẹli ni iyawo nitori èrè iṣelu, o ta ogun ibi rẹ. Arakunrin, nigba ti o ba darapọ mọ awọn ti wọn n fi-eniyan-ṣe-adari-dipo-Ẹmi Mimọ o ta ogun ibi rẹ ni yẹn, o gba a gbọ o, tabi o ko gba a gbọ. Olukuluku ẹgbẹ ti o tako IjọAguda ti o ti jade ri kuro ninu rẹ ti o si tun pada sinu rẹ ti ta ogun ibi wọn, nigba ti o ba ta ogun ibi rẹ, o dabi Esau lasan-ni—o lee sọkun, ki o sun ẹjẹ, ki o ronupiwada bi o ti lee ṣe to, ṣugbọn ki yoo ṣe o ni ire kan. Ohun kan pere ni o lee ṣe, ohun naa si ni ki o,“Jade kuro láàárín rẹ, ẹyin eniyan Mi ki o si dẹkun nini ipin ninu ẹṣẹ rẹ!” Wayi o, bi o ba ro wi pe ohun ti mo sọ yii ki i ṣe otitọ, ṣaa dahun ibeere kanṣoṣo yii. Njẹ ẹnikẹni ti o wa laaye lee darukọ ìjọ tabi agbekalẹ Ọlọrun kan ti o ni isọji ri, ti o si ṣubu si inu gbigba idari-eniyan-dipo-ti-Ẹmi Mimọ, ti o si di ẹgbẹ ti n fi ẹkọ-adamọ-rọpo- Ọrọ-Ọlọrun, ti o tun wa pada bọ si ọdọ Ọlọrun lẹyin iṣubu yii? Ka awọn iwe itan-akọsilẹ. O ko lee ri ọkan— ani ọkan ṣoṣo.

Wakati ọganjọ oru ni fun Israẹli nigba ti o darapọ mọ aye, ti o fi awọn ohun Ẹmi silẹ fun ti iṣelu. Wakati ọganjọ oru ni ní Nikia nigba ti ijọ ṣe bakan naa. Wakati ọganjọ oru ni nisisinyi nigba ti awọn ijọ n gbarijọ pọ di ọkan.

Wayi o, nigba ti Ahabu fẹ Jẹsebẹẹli o gba a laaye lati tẹ ọwọ bọ apo owo orilẹ-ede lati kọ ile oriṣa nla meji fun Asitaate ati Baali. Eyi ti a kọ fun Baali tobi to bẹẹ gẹẹ ti o gba gbogbo Israẹli lati jọsin ninu rẹ. Nigba ti Constantine ati ijọ ṣe igbeyawo, Constantine fun ijọ ni awọn ile, o kọ awọn pẹpẹ, o si yá awọn ere oriṣa, o si fi eto si awọn ipo alufaa ti a to ni isọri-n-sọri eyi ti o ti n fi idi mulẹ bọ diẹdiẹ ki o to di igba yẹn.

Ni igba ti agbara ijọba tẹ Jẹsebẹẹli lọwọ tan, o sọ ọ di kannpa fun awọn eniyan lati gba ẹsin rẹ, o si pa awọn wolii ati awọn alufaa Ọlọrun. Ọrọ naa buru to bẹẹ gẹẹ ti Elija, ẹni ti i ṣe ojiṣẹ-Ohun-Ọlọrun fun ọjọ tirẹ fi ro wi pe ohun nikan ni o ṣẹ́kù fun Ọlọrun; ṣugbọn Ọlọrun ni awọn ẹgbẹrun meje imiiran ti ko tẹ eekun wọn ba fun Baali. Bẹẹ naa ni o ṣe ri loni-o-loni yii láàárín awọn ijọ onigbagbọ-adamọ ti Onitẹbọmi, Metọdisti, Ijọ Alagba, abb., wọn ní awọn kan ti yoo jade kuro láàárín wọn ti yoo si pada si ọdọ Ọlọrun. Mo fẹ ki o mọn wi pe n ko fi igba kan ri, tabi nisisinyi, lodi si awọn eniyan. Ifi-ẹkọ-adamọ-rọpo-Ọrọ Ọlọrun —ilana ifi-idari-eniyan-rọpo-Ẹmi Mimọ ni mo lodi si. Mo ni lati lodi si i nitori Ọlọrun korira rẹ.

Wayi o, o yẹ ki a danuduro nihin fun iṣẹju kan lati ṣe atunsọ ohun ti a ti sọ tẹlẹ nipa ijọsin ni Tiatira. Gẹgẹ bi mo ti sọ ṣaaju wọn bọ Apollo (ti i ṣe oriṣa oorun) ati ọba-lori-awọn-ọba (emperor) ti i ṣe olori ijọba wọn. Wọn pe Apollo yii ni 'a-yẹ-bi-dànù. O n yẹ ibi danu kuro lori awọn eniyan. O n bukun wọn, o si jẹ oriṣa gidi fun wọn. O yẹ ki o jẹ olukọni fun awọn eniyan naa. O ṣalaye nipa ijọsin, nipa awọn ilana ẹsin ni tẹmpili, nipa awọn iṣẹ-isin fun awọn oriṣa, nipa irubọ ati nipa iku ati iye lẹyin iku. O ṣe eleyi nipa wolii obinrin kan ti ẹmi oriṣa naa ma n gun bi o ba ṣe joko lori aga ẹlẹsẹ mẹta. Haa! Ṣe o ye ọ? Wolii obinrin naa ti a n pe ni Jẹsebẹẹli ni yẹn, o si n kọ awọn eniyan. Ẹkọ rẹ si n tan awọn iranṣẹ Ọlọrun jẹ, o si n mu wọn ṣe agbere. Wayi o, agbere tumọsi, “ẹsin ibọriṣa”. Nipa ti Ẹmi, ohun ti o tumo si ni yii. Idapọ ti ko ba ofin mu ni. Idapọ ti Ahabu ati Constantine jẹ eyi ti ko ba ofin mu. Ẹṣẹ agbere ti ẹmi ni awọn mejeeji da. Gbogbo alagbere ni yoo pari irin-ajo wọn si inu adagun ina. Bẹẹ ni Ọlọrun wi.

Ka iroyin ni kikun ni... Igba Ijọ Tiatira.

Ṣe igbasilẹ (Gẹẹsi)... Jezebel Religion.


  Iwe-mimọ sọ...

Ẹni tí ó bá ṣẹgun, tí ó forí tì í, tí ó ń ṣe iṣẹ́ mi títí dé òpin, òun ni n óo fún ní àṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè, ọ̀pá irin ni yóo fi jọba lórí wọn, bí ìkòkò amọ̀ ni yóo fọ́ wọn túútúú.

Irú àṣẹ tí mo gbà lọ́dọ̀ Baba mi ni n óo fún un.

N óo tún fún un ní ìràwọ̀ òwúrọ̀.

Ifihan 2:26-28



Iwe ti Ifihan jara.
Tẹsiwaju lori oju-iwe atẹle.
(Awọn ìgbà ijọ meje.)





Ifiranṣẹ ibudo...Yan ede rẹ ki o gba awọn ifiranṣẹ ọfẹ lati ọdọ Arákùnrin Branham.


Ohun ijinlẹ Kristi.

Wẹẹbu iwe iroyin Gẹẹsi.

Iwe Ifihan jara.

 

Ọlọrun ati Imọ Atọka.
- Archaeology.

Igbasoke n bọ.

 

Awọn ẹkọ akọkọ
ti ifiranṣẹ naa.

Awọn ti o dara iroyin.
Jesu ku fun ese re.

Iribomi Omi.

 

Awọsanma eleri nla.

Ọwọn ti ina.

Ogo Shekinah ti Ọlọrun.

Ibojì ti ṣofo.
O ti jinde.

Ọlọrun salaye.

Awọn ìgbà ijọ meje.

Awọn edidi meje.

Ọlọrun ati Itan.
jara Atọka - Dáníẹ́lì.

Kristiẹni ije jara.
Ìgbéyàwó Àti Ìkọ̀sílẹ̀.
Akojọ Ifiranṣẹ.

Opin akoko jara.

Ngbe ọrọ jara.

Keresimesi jara.

Iku. Ohun ti nigbana?

Orúkọ Ọlọrun.

Ọkọ Noa.

 

Ẹṣẹ Atilẹba.
Je o ẹya apulu?

Adaparọ.
Awọn orisun - Babeli.

Ọlọrun ati Imọ.
Dainoso Adaparọ.

Archaeology.
Sodomu ati Gomorra.

Tẹ aworan kan lati ṣe igbasilẹ aworan iwọn ni kikun tabi PDF.


Acts of the Prophet

(PDFs Gẹẹsi)
 

The Two Babylons

by Rev Alexander Hislop.
(PDF Gẹẹsi)

Oke ati dide igbo
ni egbon ni Ṣaina.

Awọn lili ti ina.

Ọwọn ti ina.
- Houston 1950.

Imọlẹ lori apata
jibiti.