Ọrọ Iṣaaju Nipa Awọn Igba Ijọ.


  Iwe ti Ifihan jara.

Awọn ijọ mejee ti Asia.


William Branham.

Ka iroyin kikun ni...
Igba Ijọ Efesu.

Lati lee jẹ ki o ni ẹkunrẹrẹ oye Ohùn-Ọlọrun si awọn Igba Ijọ, mo fẹ ṣe alaye awọn oriiṣiriiṣi ilana ti mo fi mọn orukọ awọn ojiṣẹ-Ohùn Ọlọrun, bi Igba Ijọ kọọkan ti gùn to, ati awọn nnkan íyoku ti o jẹmọ awọn Igba Ijọ.

Ni iwọn igba ti o jẹ wi pe ẹkọ yii ni eyi ti o ṣe pataki julọ ti mo ti i dawọle titi o fi di asiko yii, mo gbadura si Ọlọrun fun ọpọlọpọ ọjọ fun imisi Ẹmi Mimọ. Lẹyin eyi nikan ni mo to ka ipa Iwe Mimọ Ti o sọrọ nipa awọn Igba Ijọ, mo si kà, mo si ṣe agbeyẹwo awọn iwe-itan ijọ ti o wa ni arọwọto mi, eyi ti awọn onpitan ti ko ṣègbè rara kọ. Ọlọrun ko ṣai gbọ adura mi, nitori nigba ti mo ka Ọrọ Ọlọrun ati awọn iwe-itan, Ẹmi-Mimọ jẹ ki n ri ilana kan ti o farahan ninu gbogbo ìgbà ti o ti kọja lọ, titi o fi di ìgbà ode oni ti a n gbe inu rẹ yii, eyi ti n ṣe opin ọjọ.

Kọkọrọ naa ti Oluwa fi fun mi lati lee mọn ojiṣẹ-Ohun-Ọlọrun fun Igba Ijọ kọọkan jẹ eyi ti o wa ni ibamu rẹgirẹgi julọ pẹlu Iwe Mimọ. Lootọ, a tilẹ lee pe e ni Ilana Bibeli ti o ṣe pataki julọ lori eyi ti ohun gbogbo sinmi le. Ifihan naa ni wi pe, Ọlọrun ki i yipada, ati wi pe ọna Rẹ jẹ alaileyipada gẹgẹ bi Oun naa Ti jẹ. Ninu Heberu 13:8, O wi pe,

“Jesu Kristi ọkan naa ni lana, ati loni, ati titi lae.”

Oniwaasu 3:14-15,
“Emi mọ̀n wi pe ohun kohun ti Ọlọrun ṣe yoo wà laelae: a kò lee fi ohun kan kun un, bẹẹni a ko lee mu ohun kan kuro ninu rẹ; Ọlọrun si ṣe eyi ki eniyan ki o lee maa bẹru Rẹ. Ohun ti o ti wà ri, n bẹ nisisinyi; eyi ti yoo si wà, o ti wà ná; Ọlọrun si beere eyi ti o ti kọja lọ.”

Ohun ti a n sọ naa ni yii: Ọlọrun Ti ki i yipada, Ti ọna Rẹ ki i si i yipada. Ohun ti O ṣe NI IGBA AKỌKỌ ni Yoomaa ṣe titi ti Yoo fi ṣe e ni IGBA IKẸYIN. Iyipada kankan ki yoo si rara. Fi ilana yii wo awọn Igba Ijọ, iru ọkunrin ti Ọlọrun yan fun Igba Ijọ akọkọ ati ọna ti O gba fi ara Rẹ han ninu iṣẹ-iriju-iwaasu ọkunrin naa yoo jẹ apẹẹrẹ fun awọn Igba Ijọ ti o kù. Ohun ti Ọlọrun ṣe ni Igba Ijọ akọkọ ni O fẹ ṣe ni awọn Igba Ijọ ti o kù.

Nipasẹ Ọrọ Ọlọrun ti a kọ silẹ lati ọwọ Ẹmi Mimọ, a mọn bi ijọ akọkọ tabi ojulowo ijọ nì ṣe bẹrẹ gẹlẹ, ati bi Ọlọrun ṣe fi ara Rẹ han ninu rẹ. Ọrọ Ọlọrun ko lee yipada, a ko si lee yi I pada, nitori Ọrọ Ọlọrun ni Ọlọrun. Johanu 1:1,

“Ni atetekọṣe ni Ọrọ wa, Ọrọ si wa pẹlu Ọlọrun, Ọlọrun si ni Ọrọ naa.”

Lati yí ẹyọ ọrọ kan pada ninu Ọrọ Ọlọrun gẹgẹ bi Eefa ti ṣe, yoo mu ẹṣẹ ati iku wa, gẹge bi Ifihan 22:18-19 paapaa ti sọ,

“...Bi ẹnikẹni ba fi kun Wọn, Ọlọrun yoo fi awọn ìyọnu ti a kọ si inu Iwe yii kún un. Bi ẹnikẹni ba si mu kuro ninu ọrọ Iwe Isọtẹle yii, Ọlọrun yoo si mu ipa tirẹ kuro ninu Iwe Iye, ati kuro ninu Ilu Mimọ ni, ati kuro ninu awọn ohun ti a kọ sinu Iwe yii.”

Nitori naa, ohun ti ijọ jẹ ni akoko Pẹntikọsti ni idiwọn. Eyi ni awokọse. Ko si awokọṣe miiran. Ohun iyoowu ti awọn ọjọgbọn lee sọ, Ọlọrun KO I TI yi awokọṣe naa pada. Ohun ti Ọlọrun ṣe ni ọjọ Pẹntikọsti ni O nilati maa ṣe lọ titi awọn Igba Ijọ yoo fi pari.

Bi o tilẹ jẹ wi pe awọn ọ̀jọ̀gbọ́n lee sọ fun ọ wi pe akoko awọn Apọsteli ti kọja lọ, iwọ maṣe gba a gbọ. Iru gbolohun bẹẹ kuna ni ọna meji. Ni akọkọ, o kuna lati ro wi pe ko si awọn Apọsteli mọ nitori pe awọn mejila akọkọ ti kú. Itumọn apọsteli ni, “Ẹni ti a ran jade”; ọpọlọpọ ni o wà ti a ran jade loni, ṣugbọn ti a n pe wọn ni akiri-waasu-Ọrọ-Ọlọrun. Ni iwọn igba ti a ba ṣi n pe awọn eniyan, ti a si n ran wọn jade lọ pẹlu Ọrọ Iye, àkókò awọn Apọsteli ṣi n tẹsiwaju. Ni ọna keji, wọn n tọka si i pe, “Igba-ifihan agbara Ẹmi Mimọ” ti kọja nitori wi pe a ti pari kikọ Bibeli. Eyi ki i ṣe otitọ. Ko tilẹ si ẹsẹ Bibeli kan ti o mu ero yii wa, ṣugbọn ọpọlọpọ ẹsẹ Iwe Mimọ sọ gbangba wi pe ko ri bẹẹ. Ẹri wa wi pe awọn ẹ̀sún mejeeji wọnyi jẹ irọ funfun balau ni yii: Iṣe Apọsteli 2:38-39,

“Peteru si wi fun wọn pe, Ẹ ronupiwada, ki a si baptisi olukuluku yin ni Orukọ Jesu Kristi fun idariji ẹṣẹ yin, ẹyin o si gba ẹbun Ẹmi Mimọ.
Nitori fun yin ni ileri naa, ati fun awọn ọmọ yin, ati fun gbogbo awọn ti o jina rere, ani gbogbo awọn ti Oluwa Ọlọrun wa yoo pè.”

Ileri agbara ti a gbe wọ awọn Apọsteli ni ọjọ Pẹntikọsti wa fun “yin (awọn Juu), ati fun awọn ọmọ yin (awọn Juu), ati fun awọn ti wọn wa lokeere (awọn Ẹya Alaikọla), ati gbogbo awọn ti Oluwa Ọlọrun wa yoo pè (awọn Juu ati awọn Ẹya Alaikọla)”. Titi ti Ọlọrun yoo fi dẹkun pípè, Ohun-Ọlọrun ati agbara Pẹntikọsti ki YOO DOPIN.

Ohun ti ijọ ní ní igba Pẹntikọsti jẹ ẹtọ rẹ ti a ko lee fi du. Ni ibẹrẹ rẹ, o ni ogidi Ọrọ Ọlọrun. O ni agbara Ẹmi ti a n fi han nipa oriiṣiriiṣi iṣẹ-ami ati iṣẹ-àrà ati awọn ẹbun Ẹmi-Mimọ.

Heberu 2:1-4,
“Nitori naa, o yẹ ki awa i ba maa fi iyè gidigidi si ohun wọnni ti awa ti gbọ, ki a ma baa gbá wa lọ kuro ninu wọn nigba kan.
Nitori bi Ọrọ Ti a ti ẹnu awọn angẹli sọ ba duro ṣinṣin, ati ti olukuluku irekọja ati aigbọran (si Ọrọ Ọlọrun) si gba ẹsan bi o ti tọ;
Awa o ti ṣe la a, bi awa ko ba naani iru Igbala nla bi eyi; Ti a tete kọ bẹrẹ si i sọ lati ọdọ Oluwa, Ti a si fi mulẹ fun wa lati ọdọ awọn ẹni ti o gbọ Ọ;
Ọlọrun si n fi iṣẹ-ami, ati iṣẹ-iyanu, ati onirurun-ru iṣẹ-agbara, ati ẹbun Ẹmi Mimọ ba wọn jẹri gẹgẹ bi ifẹ Rẹ?”

Ifi-eniyan-ṣe-adari-ijọ-dipo-Ẹmi Mimọ ko si ni ijọ akọkọ naa. Ẹmi Mimọ ni O dari rẹ̀. Ijọ naa ko tobi pupọ. A korira rẹ, a si ṣaata rẹ. A ni i lara. A ṣe inunibini si i de inu iku. Ṣugbọn o jẹ olootọ si Ọlọrun. O duro ni ibamu pẹlu igbe-aye, eto, ati ẹkọ-igbagbọ-ijọ ti ipilẹṣẹ.

Nisisinyi, maṣe jẹ ki a ṣì ọ lọna nihin. Nigba ti mo sọ wi pe Ọlọrun ati ọna Rẹ ki i yipada, emi ko sọ wi pe ijọ ati awọn ojiṣẹ rẹ ko lee yipada. Ijọ ki i ṣe Ọlọrun. Nitori naa, o lee yipada. Ṣugbọn ohun ti mo sọ ni wi pe nitori Ọlọrunki i yipada ti awọn ọna Rẹ ki i si yipada, a lee pada si atetekọṣẹ ki a si ri iṣẹ akọkọ, ani iṣẹ aṣepe Ọlọrun, ki a si fi eleyi ṣe idiwọn awọn iyoku. Bayi ni a ti n ṣe e. Ni igba gbogbo, IjọOtitọ yoo maa tiraka lati dabi ijọ akọkọ ni Pẹntikọsti. Ijọ Otitọ ti òní yoo maa gbiyanju lati dabi ijọ atijọ akọkọ ni. Awọn ojiṣẹ-Ohun-Ọlọrun si awọn Igba Ijọ, pẹlu ẸmiỌlọrun kan naa ninu wọn bi ti Pọọlu, yoo maa tiraka lati dabi Apọsteli Pọọlu. Wọn ko ni dabi rẹ gẹlẹ; ṣugbọn awọn ojiṣẹ-Ohun-Ọlọrun tootọ ni awọn ti yoo sunmọ Pọọlu julọ; Pọọlu, ẹni ti ko si labẹ idari eniyan kankan, ti o fi gbogbo aye rẹ fun Ọlọrun, ti o mu Ọrọ Ọlọrun nikan ṣoṣo wá fun awọn ẹniyan, ti o si fi Ẹmi Mimọ han fun àráyé rí ninu agbara. Ko si àkàwe miiran ti o lee ṣiṣẹ. Ti àkọ́bẹ̀rẹ̀ ni a ni lati maa fi ṣe awokọṣe. Bi ẹkùn ti n bi ẹkùn, ijọ Ọtitọ yoo jẹ eyi ti yoo maa gbiyanju lati tọ ipasẹ awọn baba iṣaaju ti Pẹntikọsti, ti awọn ojiṣẹ-Ohun-Ọlọrunwọn yoo maa tẹle Apọsteli Pọọlu, ojiṣẹ-Ohun-Ọlọrunsi Igba Ijọ Kin-in-ni. Bi o ṣe rọrun to ni yii, bẹẹ ni o si ṣe yanilẹnu to.

Pẹlu ilana yii ti o rọrun to bẹẹ gẹ, ti o si logo bakan naa, o wa ṣe i ṣe fun mi, pẹlu iranlọwọ Ẹmi Mimọ, lati ka Iwe Ifihan ati awọn iwe-itan, ti mo si ri ninu wọn, Igba Ijọ kọọkan, ojiṣẹ-Ohun-Ọlọrun kọọkan, bi Igba Ijọ kọọkan ṣe gùn to ati ipa ti ọkọọkan wọn kó ninu èròngbàỌlọrun lati Pẹntikọsti titi de opin awọn Igba Ijọ wọnyi.

Ni iwọn igba ti o ti wa loye oṣuwọn ti a fi diwọn ohun ti Ijọ Ọtitọ jẹ bayi (ani ohun ti o jẹ ni Pẹntikọsi ati ni igba awọn apọsteli gẹgẹ bi a ti gbe e kalẹ ninu Ọrọ Ọlọrun ni inu Iwe Iṣẹ Awọn Apọsteli) a wa lee lo ilana kan naa lati fi han wa bi ijọ ṣe kuna. Ẹkọ-ikuna ti ipilẹṣẹ, tabi awọn ẹkọ-ikuna naa, ti o yọ kẹlẹkẹlẹ wọ inu ijọ akọkọ ti a si ifihan ninu Iwe Iṣe Awọn Apọsteli ati Iwe Ifihan ati awọn Ẹpisteli pẹlu, yoo farahan nigbangba sii bi Igba Ijọ kan ṣe n tẹle ekeji, titi yoo fi di okunkun biribiri ti yoo lé Otitọ kuro ninu Igba Ijọ ti o kẹyin, tabi Igba Ijọ Laodekia.

Lati inu kọkọrọ akọkọ ti a gba lati ọwọ Oluwa yii ni otitọ miiran ti ko yanilẹnu to ti iṣaaju ti jẹyọ.Mo sọ wi pe Ijọ Otitọ yoo maa gbiyanju lati dabi eyi ti a ri ninu Iwe Iṣe Awọn Apọsteli. Bi o ti ṣe ri gẹlẹ ni yii. Ṣugbọn a ti wa ṣe awari rẹ̀ wi pe Ọrọ Ọlọrun kọ́ ni pe ẹkọ-ikuna yoo gbogun ja ẹkọ Ọtitọ titi ti ẹkọ Otitọ yoo fi pòórá patapata ni ikẹyin ọjọ nigba ti Oluwa ba fẹrẹẹ de. Ibeere ti n dide ni ọkan wa bayi ni pe; Njẹ Ọlọrun fi awọn Tirẹ silẹ ni, ti O si jẹ ki wọn ṣubu si inu itanjẹ patapata? Aigbẹdọ, ki a ma ri i, nitori Iwe Mimọ sọ gbangba-gbangba ninu Iwe Matiu 24:24 wi pe, A KO LEE tan 'Ayanfẹ' jẹ.

“Nitori awọn eke Kristi, ati eke wolii yoo dide, wọn o si fi ami ati ohun iyanu nla han: to bẹẹ BI O BA LEE ṢEEṢE wọn o tan awọn ayanfẹ paapaa.”

Ki wa ni? Idahun naa wà kedere ni iwaju wa. Ijọ Otitọ nbẹ, ati ijọ eke. Ajara Otitọ n bẹ, ajara eke si wa. Ṣugbọn lai si ani-ani, ijọ eke yii, ani ajara eke, yoo maa gbiyanju lati gba ipo Ijọ Otitọ nigba gbogbo, yoo maa jiyan wi pe oun, ani ki i ṣe awọn Ayanfẹ, ni ijọ Otitọ ati ojulowo naa. Ijọ eke yoo gbiyanju lati pa Ijọ Otitọ run. Bi o ti ṣe ri ni yii ninu Iwe Iṣe Awọn Apọsteli, bi a ti ṣe gbe e kalẹ ni yii ninu Igba Ijọ meje, bi a si ti ṣe sọ ọ gbangba ni yii ninu gbogbo awọn Ẹpisteli. Bi o ti ri lati ẹyin wa ni yii, Bi o ti ṣe ri lọwọlọwọ bayi ni yii. Bẹẹ ni yoo si maa ri. Ko lee yipada.

----
Awọn ijọ mejeeje wọnyi ti o wa ni Asia Minor ní awọn iwa idanimọ kan ninu wọn, ni igba atijọ naa lọhun, awọn eyi ti yoo dagba soke di eso gbígbó ninu Igba Ijọ ẹyin-wa-ọla. Awọn ohun ti o jẹ ọjẹlẹ irugbin ni ibẹẹrẹ ni igba naa lọhun jade lẹyin-wa-ọla bi irè-oko ti o ti gbó, ani gẹgẹ bi Jesu ti sọ, “Nitori bi wọn ba n ṣe nnkan wọnyi sara igi tubu, kin ni a o ṣe sara gbigbẹ?” Luuku 23:31.

Ka iroyin kikun ni...
Igba Ijọ Efesu.



Iwe ti Ifihan jara.
Tẹsiwaju lori oju-iwe atẹle.
(Ọjọ-ori wa, Laodikea.)



 

Ohun ijinlẹ Kristi.

Wẹẹbu iwe iroyin Gẹẹsi.

Iwe Ifihan jara.

 

Ọlọrun ati Imọ Atọka.
- Archaeology.

Igbasoke n bọ.

 

Awọn ẹkọ akọkọ
ti ifiranṣẹ naa.

Awọn ti o dara iroyin.
Jesu ku fun ese re.

Iribomi Omi.

 

Awọsanma eleri nla.

Ọwọn ti ina.

Ogo Shekinah ti Ọlọrun.

Ibojì ti ṣofo.
O ti jinde.

Ọlọrun salaye.

Awọn ìgbà ijọ meje.

Awọn edidi meje.

Ọlọrun ati Itan.
jara Atọka - Dáníẹ́lì.

Kristiẹni ije jara.
Ìgbéyàwó Àti Ìkọ̀sílẹ̀.
Akojọ Ifiranṣẹ.

Opin akoko jara.

Ngbe ọrọ jara.

Keresimesi jara.

Iku. Ohun ti nigbana?

Orúkọ Ọlọrun.

Ọkọ Noa.

 

Ẹṣẹ Atilẹba.
Je o ẹya apulu?

Adaparọ.
Awọn orisun - Babeli.

Ọlọrun ati Imọ.
Dainoso Adaparọ.

Archaeology.
Sodomu ati Gomorra.

  Iwe-mimọ sọ...

Tó bá di ìgbà náà, kò ní sí òtútù tabi òjò dídì mọ́,

kò ní sí òkùnkùn, kò ní sí ọ̀sán, kò ní sí òru bíkòṣe ìmọ́lẹ̀ nígbà gbogbo. Ṣugbọn OLUWA nìkan ló mọ ìgbà tí nǹkan wọnyi yóo ṣẹlẹ̀.

Sakaraya 14:6-7


Tẹ aworan kan lati ṣe igbasilẹ aworan iwọn ni kikun tabi PDF.


Acts of the Prophet

(PDFs Gẹẹsi)
 

God, Hidden and
Revealed in simplicity.

(PDF Gẹẹsi)

William Branham
Life Story.

(PDF Gẹẹsi)

How the Angel came
to me.

(PDF Gẹẹsi)


Ifiranṣẹ ibudo...Yan ede rẹ ki o gba awọn ifiranṣẹ ọfẹ lati ọdọ Arákùnrin Branham.