Ọjọ-ori wa, Laodikea.


  Iwe ti Ifihan jara.

Ọjọ-ori wa, Laodikea.


William Branham.

Ka akọọlẹ naa ni...
Igba Ijọ Laodikea.

Ifihan 3:15-19,
15 Emi mọn iṣe rẹ, pe iwọ ko gbona bẹẹ ni iwọ ko tutu: Emi i ba fẹ pe ki iwọ kúkú tutù, tabi ki iwọ kuku gbona.
16 Njẹ nitori ti iwọ ṣe ilọwọọwọ, ti o ko gbona, bẹẹ ni o ko tutu, Emio pọ ọ jade kuro ni ẹnu Mi.
17 Nitori ti iwọ wi pe, Emi ni ọrọ, Emi si n pọ si i ni ọrọ, Emi ko si ṣe alaini ohunkohun; ti iwọ ko si mọnpe, oṣi ni iwọ, ati àre, ati talaka, ati afoju, ati ẹni-ihoho.
18 Emi fun ọ ni imọran pe ki o ra wura lọwọ Mi ti a ti dà ninu ina, ki iwọ ki o lee di ọlọrọ; ati aṣọ funfun, ki iwọ ki o lee fi wọ ara rẹ, ati ki itiju ihoho rẹ ki o maa ba han, ki o si fi òògùn kun oju rẹ, ki iwọ ki o lee riran.
19 Gbogbo awọn tiEmi ba fẹ ni Mo n bawi, ti Mo si n nà: Nitori naa ni itara, ki o si ronupiwada.

Bi a ṣe jumọ ka gbolohun yii papọ o damiloju wi pe o ti ṣe akiyesi wi pe Ẹmi ko sọ ohunkohun ti o dara nipa igba ijọ yii. O fi ẹ̀sùn meji kan wọn, o si kede idajọ Rẹ le wọn lori.

(1) Ifihan 3:15-16,
“Emi mọn iṣẹ rẹ, pe iwo ko gbona bẹẹ ni iwọ ko tutu:
Emi i ba fẹ pe ki iwọ kuku tutu, tabi ki iwọ kuku gbọna. Njẹ nitori ti iwọ ṣe ilọwọọwọ, ti o ko sì gbona, bẹẹ ni o ko tutu, Emi o pọ ọ jade kuro ni ẹnu Mi.“

A o wo eleyi finni-finni. Ọrọ Ọlọrun sọ wi pe awọn ara Igba Ijọ Laodekia yii ko-gbona-ko-tutu. Ilọwọọwọ yii jẹ ohun ti o yẹ kiỌlọrun fi iya jẹ wọn fun. Ijiya naa ni wi pe Ọlọrun yoo tu wọn danu kuro ni ẹnu Rẹ. A ko fẹ ṣe aṣiṣe ninu ohun ti a n sọ ni ihin yii gẹgẹ bi ẹgbẹlẹgbẹ eniyan ti nṣe. Gẹgẹ bi alaimọkan-mọkan, wọn n wi pe Ọlọrun lee tu ọ danu kuro lẹnu Rẹ, ati wi pe eleyi fi ẹsẹ rẹ mulẹ wi pe ko si otitọ kan, bo tilẹ ti wu ki o mọ, ninuẹkọ igbagbọ aabo ainipẹkun fun awọn ẹni-mimọ. Mo fẹ to ọ sọna lori ero yiilẹṣẹkẹsẹ. A ko kọ ẹsẹ Bibeli yii si aladori ẹnikọọkan. Ijọ ni a kọ Ọ si. Ijọ ni O n ba wi. Ṣiwaju si i, bi o ba fi Ọrọ Ọlọrun sọkan, iwọ yoo ranti wi pe ko si ibikibi ti O ti sọ wi pe a wà ni ẸNU Ọlọrun. A fín wa si atẹlẹwọ Rẹ. Ookan aya Rẹ ni O gbe wa si. Ki alaye to da aye, ki ọlọjọ to bẹrẹ si kajọ ni igba ìwáṣẹ̀, ni a ti wa ninu ọkàn Rẹ. Ninu agbo agutan Rẹ, ati ninu pápá Rẹ ni a wà. Ṣugbọn a ko fi igba kan ri wà ni ẹnu Rẹ. Ṣugbọn kin ni n bẹ ninu ẹnu Oluwa? Ọrọ Ọlọrun ni n bẹ ni ẹnu Rẹ.

Matiu 4:4,
“Ṣugbọn O dahun wi pe, A ti kọwe rẹ pe, Eniyan ki yoo wa laaye nipa akara nikan, bikoṣe nipa gbogbo Ọrọ Ti o ti ẹnu Ọlọrun jade wa.” O yẹ ki Ọrọ Ọlọrun wa lẹnu awa naa pẹlu. Wayi o, a mọn wi o pe, Eniyan ki yoo wa laaye nipa akara nikan, bikoṣe nipa gbogbo Ọrọ Ti o ti enu Ọlọrun jade wa“. O yẹ ki Ọrọ Ọlọrun wa ni ẹnu awa naa pẹlu. Wayi o, a mọn wi pe Ijọ ni ara Rẹ. O wa nihin, o n gba ipo Rẹ, Kin ni o yẹ ki o wa lẹnu Ijọ? ỌRỌ ỌLỌRUN.

Peteru Kin-in-ni 4:11,
“Bi ẹnikẹni ba n sọrọ, ki o maa sọ ọ bi Ọrọ Ọlọrun.” Peteru Keji 1:21, “Nitori asọtẹlẹ kan ko ti ipa ifẹ eniyan wa ri; ṣugbọn awọn eniyan n sọrọ lati ọdọ Ọlọrun bi a ti dari wọn lati ọwọ Ẹmi Mimọ wá.” Nigba naa kin ni o kunna pẹlu awọn eniyan ọjọ ikẹyin yii? WỌN TI FI ỌRỌ ỌLỌRUN SILẸ, WỌN KO NI IFẸ ỌKAN TI O GBONA NIPA RẸ MỌ́. WỌN WÀ NI ILOWỌỌWỌ NIPA RẸ. N o wa fi idi eleyi mulẹ bayi.

Awọn ọmọ ijọ Onitẹbọmi ni ẹkọkẹkọ atiadamọ wọn ti wọnti wọn fi Ọrọ Ọlọrun kan so lẹṣẹ, o ko si lee yi wọn ni ọkan pada kuro ninu rẹ. Wọn wi pe igba ọjọ awọn aposteli, ninu eyi ti iṣẹ iyanu n ṣẹlẹ ti de opin, ati wi pe ko si Ibaptisi pẹlu Ẹmi Mimọ lẹyin ti a ba gbagbọ. Awọn Mẹtọdisti sọ (wọn si fi Ọrọ Ọlọrun kan gbe e lẹṣẹ) wi pe ko si itẹbọmi (wiwọ́n omi le eniyan lori ki i ṣe itẹbọmi) ati wi pe isọ-ni-di-mimọ ni Ibaptisi Ẹmi Mimọ. Koko igbagbọ Ijọ Kristi ni itẹbọmi ti n sọ ni di atunbi, o si fẹrẹ jẹ wi pe gbogbo wọn ni n wọ inu odo gẹgẹ bi ẹlẹṣẹ ti ara rẹ gbẹ, ti wọn si n jade gẹgẹ bi ẹlẹṣẹti ara rẹ tutu. Sibẹsibẹ wọn si tẹnumọ ọn wi pe ẹkọ igbagbọ wọn wà ni ibamu pẹlu Ọrọ Ọlọrun. Ẹ mu wọn ni ọkọọkan titi de ori awọn ijọ a-fi-ede-ajeji-ṣẹri-Ẹmi Mimọ. Njẹ wọn gba Ọrọ Ọlọrun gbọ bi? Fi Ọrọ Ọlọrun dan wọn wo, ki o si wo nnkan ti wọn yoo ṣe pẹlu Rẹ. O fẹrẹ jẹ wi pe gbogbo igba ni wọn yoo gba isọyigi-ara dipo Ọrọ Ọlọrun. Bi o ba lee ṣe iṣẹ ami bi i ki ororo tabi ẹjẹ jade ni ara eniyan, tabi ki o fi ede oniru-un-ru, ati awọn ifarahan-ami, boya o ba Ọrọ Ọlọrun mun tabi ko ba A mun, tabi boya a fi itumọ Ọrọ Ọlọrun tio tọ si i ninu Bibeli tabi bẹe kọ, ọgọọrọeniyan ni yoo gba a tọwotẹsẹ. Ṣugbọn kin ni o ti ṣẹlẹ si Ọrọ Ọlọrun. A ti pa Ọrọ Ọlọrun ti si ẹgbẹ kan, nitori naa, Ọlọrun ni, “N o kọ oju ija si gbogbo yin, N o tu yin jade kuro ni ẹnu Mi. Opin ni yii. Nitori wi pe fun igba meje ni igba ijọ meje ni N ko ti ri ohun miiran bikoṣe awọn eniyan ti n gbé ọrọ tiwọn ga ju Ọrọ Mi lọ. Nitori naa, níopin igba ijọ yii N o tu yin kuro ni ẹnu Mi. Gbogbo rẹ ti pari. Lootọ N o sọrọ. Bẹẹ ni, Mo wa nihin láàárín ijọ. Amin Ọlọrun, Ti o jẹ Olootọ ati Olododo yoo ṣi ara Rẹ paya, yoo si JẸ NIPASẸ WOLII MI.” Bẹẹ ni, bẹẹ gẹlẹ ni o ri.

Ifihan 10:7,
“Ṣugbọn ni ọjọ ohun iranṣẹ keje, nigba ti yoo ba fun ipe, nigba naa ni ohun Ijinlẹ Ọlọrun pari, gẹgẹ bi Ihinrere Ti O sọ fun awọn iranṣẹ Rẹ, awọn wolii.”

Ohun niyẹn. Yoo ran wolii ti Ọlọrun jẹrigbe wi pe o jẹ wolii. Ọlọrun yoo ran wolii Rẹ kan lẹyin nnkan bi ẹgbaa ọdun. Ọlọrun yoo ran ẹnikan ti o jinna réré si ifi-idari-eniyan-rọpo-Ẹmi Mimọ, ẹkọ-iwe, ati ẹgbẹ awọn ẹlẹsin, ti yoo fi jẹ bi i Johanu Onitẹbọmi ati Elija atijọ, yoo gbọ lati ọdọ Ọlọrun nikan, yoo si ni. “Bayi ni Oluwa wi”, yoo si jẹ agbenusọ fun Ọlọrun. Yoo jẹ abenuganỌlọrun, OUN NAA NI YOO SI YI ỌKAN AWỌN ỌMỌ PADA SI TI AWỌN BABA, GẸGẸ BI A TI SỌ Ọ NI MALAKI 4:6. Yoo mu awọn ayanfẹ ọjọ ikẹyin pada wa, wọn yoo si gbọ Otitọ kan naa gẹlẹ gẹgẹ bi Pọọlu ti ṣe kọni, lati ẹnu wolii yii kan naa, ẹni ti Ọlọrun jẹrigbe wi pe wolii ni. Yoo mu Otitọ ti wọn ní ní igba Pọọlu wa padabọ sipo. Awọn ayanfẹ ti o wa pẹlu rẹ ni ọjọ naa ni yoo jẹ́ awọn gan an ti yoo fi Ọlọrun han faraye ri nitootọ, wọn yoo jẹ ara Rẹ, wọn yoo si jẹ Ohùn Rẹ, wọn yoo si ṣe awọn iṣẹ Rẹ. Halleluya! Njẹ o ri ohun ti mo n sọ bi?.

Ti a bá fi inu gbe ayẹwo akọsilẹ itan ijọ yii wo ni gúnímọ̀, eyi yoo fi daniloju bi ero yii ti ṣe pe perepere to han. Ni igba Igba Okunkun Aye awọn eniyan fẹrẹ padanu Ọrọ Ọlọrun tan patapata. Ṣugbọn Ọlọrun rán Luther pẹlu ỌRỌ naa. Ijọ Luther nigba naa jẹ agbẹnusọ fun Ọlọrun. Ṣugbọn wọn fi idari eniyan rọpo Ẹmi Mimọ, awọn eniyan si tun padanu Ọrọ Ọlọrun, nitori ẹkọ-adamọ ati ẹkọ-eke, lai ki i ṣe Ọrọ Ọlọrun bi a ti kọ O gẹlẹ, ni ẹgbẹ ti n fi idari-eniyan-rọpo-Ẹmi Mimọ yii maa n duro le lori. Wọn ko lee jẹ agbẹnusọ fun Ọlọrun mọ. Lẹyin eyi ni Ọlọrun ran Wesley, ti Ọrọ Ọlọrun ti ẹnu rẹ jade ni igba aye rẹ. Gbogbo awọn ti o gba iṣipaya ti o mu wa lati ọdọ Ọlọrun wá di ẹpisteli aaye ti a kọ, ti gbogbo eniyan si mọn fun iran ti wọn. Nigba ti awọn Mẹtọdisti kuna, Ọlọrun gbe awọn ominran dide, bẹe ni O si ti tẹsiwaju ninu gbogbo awọn ọdun wọnyi titi di ọjọ ikẹyin yii nigba ti awọn eniyan kan wa lori ilẹ aye lẹẹkan si ti yoo jẹ Ohun ikẹyin si igba ikẹyin labẹ idari ojiṣẹ-Ohun-Ọlọrun wọn.

Bẹẹ ni o ri. Ijọ ki i ṣe “agbẹnusọ” Ọlọrun mọ. Ọrọ ara rẹ ni o n sọ. Nitori naa Ọlọrun kọ ẹyin si i. Ọlọrun yoo fi idaamu ba a nipasẹ wolii ati Iyawo naa, nitori Ohun Ọlọrun yoo wa ninu Iyawo naa. Bẹẹ ni, bi o ṣe ri ni yii, nitori Ọrọ Ọlọrun sọ ninu ẹsẹ kẹtadinlogun ori ti o kẹyin ni Iwe Ifihan wi pe, “Ẹmi ati aya Kristi wi pe, Maa bọ.” Lẹẹkan si, aye yoo gbọ taara lati ọdọ Ọlọrun bi ti Pẹntikọsti, ṣugbọnṣaa, a o gan Iyawo Ọrọ naa bi o ti ṣe ri ni igba ijọ akọkọ.

Wayi o, O ti kigbe si igba ijọ ikẹyin wi pe, “Ọrọ Ọlọrun n bẹ ni ọwọ rẹ. Ko i ti i si igba ijọ ti o ni Bibẹli to ọ ri. Ṣugbọn o ko ṣe ohunkohun nipa Ọrọ Ọlọrun bikoṣe wi pe o n pin In. O n ṣa A si wẹwẹ, o n mu eyi ti o fẹ, o si n fi eyi ti o kò fẹ silẹ. O kò nifẹ si FIFI ṢE IWA HU, bikoṣe wi pe ki o maa jiyan lori Rẹ. I ba wun Mi ki o tilẹ yanọkan, yala ki o tutu tabi ki o gbona. Bi oba tutu ti o si kọ Ọ silẹ N ba lee fara da a. Bi o ba gbona girigiri bi ẹṣẹ ina, ti o si mọn wi pe otitọ ni In, ti o si fi I ṣe iwa hu, Emi yoo yin ọ fun eyi. Ṣugbọn nigba ti o ba ṣaa gba Ọrọ Mi lasan, ti o kò bu ọla fun Un, Emi naa yoo sa ẹsan fun ọ gẹgẹ bi iṣẹ rẹ, N o kọ̀ lati bu ọla fun ọ. N o tu ọ jade kuro ni ẹnuMi nitori wi pe o n jẹ ki eebi gbe Mi.”

Gbogbo eniyanmọn wi pe omi ti o lọwọọrọwọ ni o maa n mu eebi gbe ni. Bi o ba nilo oogun kan ti o lee tee mu eniyan bì, o fẹrẹ jẹ omi to lọwọọrọwọ ni o dara ju lati mu, Ijọ ko-gbona-ko -tutu n mu eebi gbe Ọlọrun, O si ti kede rẹ wi pe Oun yoo tu u danu. Eyi ran wa leti bi Ọlọrun ṣe ro nipa igba ti o ku diẹ ki ẹkun omi Noaṣẹlẹ, abi bẹẹ kọ?

Aaa, i ba dara loju Ọlọrun ki ijọ gbona tabi ki o tutu. Ohun ti o dara ju ni wi pe ki ijọ ki o ni itara (gbona girigiri). Ṣugbọn ko ri bẹẹ. A ti ṣe idajọ rẹ naa. Ki i ṣẹ ohun Ọlọrun si aye mọ. Bi o tilẹ jẹ wi pe o n tẹnumọ ọn wi pe Ohùn Ọlọrun si aye ni oun, ṣugbọn Ọlọrun wi pe ki i ṣe bẹẹ.

Aaa, Ọlọrun ṣi ni ohun kan si awọn ara aye sibẹ, ani gẹgẹ bi O ti ṣe fun Iyawo Kristi ni Ohun kan. Gẹgẹ bi a ti sọ ọ tẹlẹ Ohùn yii n bẹ ninu iyawo Rẹ, a o si tun sọ nipa eyi niwaju.

(2) Ifihan 3:17-18,
“Nitori ti iwọwi pe, Emi ni ọrọ̀, emi si n pọ si ni ọrọ̀, emi ko si ṣe alaini ohunkohun , ti iwọ ko si mọn pe, oṣi ni iwọ, ati are, ati talaka, ati afọju, ati ẹni-ihoho: Emi fun ọ ni imọran pe ki o ra wura lọwọ Mi ti a ti dà ninu ina, ki iwọ ki o lee di ọlọrọ; ati aṣọ funfun, ki iwọ ki o lee fi wọ ara rẹ, ati ki itiju ihoho rẹ ki o ma baa han, ki o si fi òògùn kun oju rẹ,ki iwọ ki o lee riran.“

Wo apola gbolohun kin-in-ni ninu ẹsẹ yii, “nitori iwọ wi pe”. Wo o, awọn ni wọn n sọrọ. Wọn n sọrọ bii agbẹnusọ Ọlọrun. Eleyifi idi rẹ mulẹ gẹlẹ wi pe otitọ ni ohun ti mo sọ wi pe ẹsẹ 16-17 tumọ si. Ṣugbọnbi o tilẹ jẹ wi pe wọn wi bẹẹ eyi ko sọ ọ di otitọ. Ijọ Aguda n wi pe oun jẹ agbẹnusọ fun Ọlọrun, wi pe oun ni ohùn Oluwa ti o daju. Bi ẹnikẹni ti lee ṣónù to bayi ninu ohun ti Ẹmi Ọlọrun ni ko ye mi, ṣugbọn wọn n so eso ni ibamu pẹlu iru ti n bẹ ninu wọn ni, awa si mọn ibi ti iru yii ti wa, a bi bẹẹ kọ?

Ijọ Laodekia n wi pe, “Ọlọrọ ni mi, dukia mi si n pọ si i, n ko si ṣe alaini ohunkohun.” Bi o ṣe ri ara rẹ ni yii. O wo ara rẹ ohun ti o si ri ni yii. O sọwi pe, “Ọlọrọ ni mi”, eyi ti o tumọ si wi pe o jẹ ọlọrọ ninu awọn ohun ti aye yii.

O n fọnnu lai bikita fun Jakọbu 2:5-7,
“Ẹ fi eti silẹ, ẹyin ara mi olufẹ,Ọlọrun ko ha ti yan awọn talaka aye yii ṣe ọlọrọ ni igbagbọ, ati ajogun Ijọba naa, ti O ti ṣe ileri fun awọn ti o fẹ Ẹ? Ṣugbọn ẹyin ti bu talaka kù. Awọn ọlọrọ ko ha n pọn yin loju, wọn ko ha si n wọ̀ yin lọ si ile ẹjọ? Wọn ko ha n sọ ọrọ-odi si Orukọ rere ni ti a fi pe yin?“ KI I ṢE wi pe mo n gbiyanju latisọ wi pe ọlọrọ eniyan ko lee jẹ ẹni Ẹmi Ọlọrun. Ṣugbọn gbogbo wa ni o mọn wi pe Ọrọ Ọlọrun sọ wi pe awọn iba diẹ ni o o jẹ bẹẹ. Awọn talaka ni o pọ ju ninu ara Ijọ Otitọ. Nigba naa bi o ba si wa ṣe wi pe ijọ kun fun ọrọ, ohunkan wa ti a mọn daju; a ti kọ “Ikabọdu” si ẹnu ọna rẹ. A ko lee sẹ́ eyi nitori Ọrọ Ọlọrun ni.

Ka akọọlẹ naa ni...
Igba Ijọ Laodikea.Iwe ti Ifihan jara.
Tẹsiwaju lori oju-iwe atẹle.
(Kristi ni ita Ijọ naa.)


Ohun ijinlẹ Kristi.

Wẹẹbu iwe iroyin Gẹẹsi.

Iwe Ifihan jara.

 

Ọlọrun ati Imọ Atọka.
- Archaeology.

Igbasoke n bọ.

 

Awọn ẹkọ akọkọ
ti ifiranṣẹ naa.

Awọn ti o dara iroyin.
Jesu ku fun ese re.

Iribomi Omi.

 

Awọsanma eleri nla.

Ọwọn ti ina.

Ogo Shekinah ti Ọlọrun.

Ibojì ti ṣofo.
O ti jinde.

Ọlọrun salaye.

Awọn ìgbà ijọ meje.

Awọn edidi meje.

Ọlọrun ati Itan.
jara Atọka - Dáníẹ́lì.

Opin akoko jara.

Ngbe ọrọ jara.

Orúkọ Ọlọrun.

Ọkọ Noa.

 

Ẹṣẹ Atilẹba.
Je o ẹya apulu?

Adaparọ.
Awọn orisun - Babeli.

Ọlọrun ati Imọ.
Dainoso Adaparọ.

Archaeology.
Sodomu ati Gomorra.

  Iwe-mimọ sọ...

“Kiyesi i, Mo duro ni ẹnu ilẹkun, Mo si n kan-an-kun, bi ẹnikẹni ba gbọ Ohun Mi, ti o si ṣi ilẹkun, Emi o si wọle tọ ọ wa, Emi o si ma ba a jẹun, ati oun pẹlu Mi.

Ẹni ti o ba ṣẹgun ni Emi o fifun lati joko pẹlu Mi lori Itẹ Mi, bi Emi pẹlu ti ṣẹgun, ti Mo si kojo pẹlu Baba mi lori Itẹ Rẹ.

Ẹni ti o ba ni eti, ki o gbọ ohun ti Ẹmi n sọ fun awọn ijọ“.

Ifihan 3:20-22


Tẹ aworan kan lati ṣe igbasilẹ aworan iwọn ni kikun tabi PDF.


Acts of the Prophet.

(PDF Gẹẹsi)

The Two Babylons

by Rev Alexander Hislop.
(PDF Gẹẹsi)

Oke ati dide igbo
ni egbon ni Ṣaina.

Awọn lili ti ina.

Ọwọn ti ina.
- Houston 1950.

Imọlẹ lori apata
jibiti.

A mọn wi
pe igba ijọ
ikẹyin ni yii
nitori Israeli
ti pada si
Palẹstini.Ifiranṣẹ ibudo...Yan ede rẹ ki o gba awọn ifiranṣẹ ọfẹ lati ọdọ Arákùnrin Branham.