Itan ijọ.
<< išaaju
itele >>
William Branham.Lati lee jẹ ki o ni ẹkunrẹrẹ oye Ohùn-Ọlọrun si awọn Igba Ijọ, mo fẹ ṣe alaye awọn oriiṣiriiṣi ilana ti mo fi mọn orukọ awọn ojiṣẹ-Ohùn Ọlọrun, bi Igba Ijọ kọọkan ti gùn to, ati awọn nnkan íyoku ti o jẹmọ awọn Igba Ijọ.
Kọkọrọ naa ti Oluwa fi fun mi lati lee mọn ojiṣẹ-Ohun-Ọlọrun fun Igba Ijọ kọọkan jẹ eyi ti o wa ni ibamu rẹgirẹgi julọ pẹlu Iwe Mimọ. Lootọ, a tilẹ lee pe e ni Ilana Bibeli ti o ṣe pataki julọ lori eyi ti ohun gbogbo sinmi le. Ifihan naa ni wi pe, Ọlọrun ki i yipada, ati wi pe ọna Rẹ jẹ alaileyipada gẹgẹ bi Oun naa Ti jẹ. Ninu Heberu 13:8, O wi pe, “Jesu Kristi ọkan naa ni lana, ati loni, ati titi lae.”
Ohun ti a n sọ naa ni yii: Ọlọrun Ti ki i yipada, Ti ọna Rẹ ki i si i yipada. Ohun ti O ṣe NI IGBA AKỌKỌ ni Yoomaa ṣe titi ti Yoo fi ṣe e ni IGBA IKẸYIN. Iyipada kankan ki yoo si rara.
Nipasẹ Ọrọ Ọlọrun ti a kọ silẹ lati ọwọ Ẹmi Mimọ, a mọn bi ijọ akọkọ tabi ojulowo ijọ nì ṣe bẹrẹ gẹlẹ, ati bi Ọlọrun ṣe fi ara Rẹ han ninu rẹ.
Ọrọ Ọlọrun ko lee yipada, a ko si lee yi I pada, nitori Ọrọ Ọlọrun ni Ọlọrun. Johanu 1:1, “Ni atetekọṣe ni Ọrọ wa, Ọrọ si wa pẹlu Ọlọrun, Ọlọrun si ni Ọrọ naa.”
Nitori naa, ohun ti ijọ jẹ ni akoko Pẹntikọsti ni idiwọn. Eyi ni awokọse. Ko si awokọṣe miiran. Ohun iyoowu ti awọn ọjọgbọn lee sọ, Ọlọrun KO I TI yi awokọṣe naa pada. Ohun ti Ọlọrun ṣe ni ọjọ Pẹntikọsti ni O nilati maa ṣe lọ titi awọn Igba Ijọ yoo fi pari.
Ayokuro lati... Igba Ijọ Efesu.
Awọn ijọ mejee ti Asia.
Efesu.
Ilu Efesu jẹ ọkan ninu awọn ilu mẹta ti o ṣe pataki julọ ni Eṣia. Ni ọpọlọpọ igba, a maa a n pe ni ilu kẹta ti Ẹsin Igbagbọ Kristi, Jerusalẹmu ni eKin-in-ni, Antioku ni ekeji. O jẹ ilu ti o lọrọ pupọ. Ijọba Roomu ni o ṣe akoso ilu naa, bi o tilẹ jẹ wi pe ede Griki ni wọn sọ.
Ayokuro lati... Igba Ijọ Efesu.
Simaina.
Ilu Simaina yii wa ni iha ariwa Efesu ni ẹnu ẹsẹ-odo ibi ti okun ti ya wọ Simaina. Nitori ebute-kọ rẹ ti o dara, o jẹ ilu kátà-kárà ti o lokiki nitori awọn ọja rẹ ti a n fi ranṣẹ si oke-okun. Ilu ti o ta awọn iyooku yọ ni nitori awọn ile-iwe ọrọ-ariyanjiyan, ti ọgbọn eniyan, ti ẹkọ-eto-ilera, ti awọn ẹkọ-sayẹnsi ati awọn ile meremere.
Ọrọ yii, Simaina, tumọ si ikooro. Itumọ yii ni a mu jade lati inu ọrọ ti a n pe ni òjíá. Òjíá ni a fi maa n kun oku lati ma jẹ ki o lee tètè rà. Nitori idi eyi, itumọ ti o pin si meji ni a lee ri ninu orukọ igba ijọ yii. Igba ti o koro, ti o kun fun iku ni.
Ayokuro lati... Igba Ijọ Simaina.
Pagamu.
Pagamọmu (orukọ re atijọ) wà ni Mysia ni agbegbe kan ti odo mẹta la kọja, ọkan ninu eyi ti awọn eniyan ilu naa n gba de okun. A ṣe apejuwe ilu yii gẹgẹ bi ilu ti o ni ọla julọ ni Esia. O jẹ ilu àṣà ti ile-ikawe rẹ pọwọle ti ilu Alexandria ni titobi. Ṣugbọn ilu yii kun fun ẹṣẹ pupọ, wọn fi ara wọn fun bibọ Aseclapius, pẹlu ilana ẹsin rẹ ti o kun fun iwa ibajẹ, paapaa ibalopọ tọkọtaya ti ko ni ijanu. Aseclapius yii ni wọn n bọ gẹgẹ bi ejo ti o wa laaye ninu tempili rẹ.
Itẹ Satani ati Ibi Ibugbe Rẹ. Pagamu ki i ṣe ibi ti Satani kọkọ gbe (nipa ohun gbogbo ti o jẹmọ ìran-eniyan). Babiloni ni o ti maa n jẹ olu-ilu rẹ, yala a ṣo nipa bi o ti ri gan an ninu ohun ara tabi ni afiwe. Ilu Babiloni ni orisun ẹsin Satani.
Ayokuro lati... Igba Ijọ Pagamu.
Tiatira.
Itan jẹ ki o ye wa pe ilu Tiatira ni o jẹ ilu ti okiki rẹ kere julọ ninu gbogbo awọn ilu mejeeje Iwe Ifihan. Ni aarin Mysia ati Ionian ni o wa. Ọpọlọpọ odo ti o kun fun aran mujẹ-mujẹ ni o yi i ka. Ohun ti o dara julọ nipa ilu naa ni wi pe o ni ọrọ̀ pupọ nitori agbarijọ ẹgbẹ awọn amọkoko, oniṣẹ awọ, ahunṣọ, apaṣọ-laro, aranṣọ abb., ni o wa nibẹ. Ni ilu yii ni Lidia, ẹni ti o n ta aṣọ elese aluko ti wa. Oun ni oyinbo alawọ funfun akọkọ ti Pọọlu jere ọkan rẹ fun Kristi.
Idi ti Ẹmi fi yan ilu yii gẹgẹ bi eyi ti o ni awọn ohun ti o jẹmọ́ ẹsin ti igba ijọ kẹrin ni nitori ẹ̀sìn rẹ. Ẹsin ti o ṣe pataki julọ ni ilu Tiatira jẹ ti ibọ-oriṣa Apollo Tyrimnaios, ti wọn n ṣe ni aṣepọ pẹlu isin ẹgbẹ awo ọba-nla. Apollo ni oriṣa oorun ati igba keji baba rẹ, Zeus.
Ohun ti o yẹ fun akiyesi pataki ni wi pe orukọ Tiatira yii gan an tumọsi, “Obinrin ti n Tẹgaba.”
Ayokuro lati... Igba Ijọ Tiatira.
Saadi.
Saadi jẹ olu-ilu Lidia atijọ. Ọwọ awọn ọba-nla Lidia ni o ti bọ si ọwọ awọn ara Persia, lati ọwọ awọn ara Persia ni o ti bọ si ọwọ Alexander Nla. Antiochus Nla ni o ṣọ ọ di ahoro. Awọn ọba Pagamu wá gba iṣakoso ijọba naa lẹyin rẹ, titi ti awọn ara Roomu fi gba a ni ọwọ wọn. Ni akoko Tiberius ìṣẹ́lẹ̀ ati ajakalẹ-arun sọ ilu naa di ahoro. Loni, ilu yii ti di òkìtì àwókù ati ahoro.
Ẹ̀sìn ilu yii jẹ ẹsin àìmọ́ bibọ oriṣa obinrin Cybele. A ṣi lee ri àlàpà nla tẹmpili rẹ, titi di òní-oló-òní.
Ayokuro lati... Igba Ijọ Saadi.
Filadẹlfia.
Filadẹlfia wa ni ila-oorun gusu Saadi ni bi ibusọ marun-un-dinlọgọrin si i. Oun ni ilu ti o pọwọle ilu ti o tobi julọ ni Lidia. A tẹ ẹ do sori ọpọlọpọ oke ni agbegbe kan ti a mọ daradara fun gbingbin ajara waini. Owo ẹyọ rẹ ni aworan ori Bacchus ati ti Baccante kan (àwòrò obinrin ti Bacchus).
Ìṣẹ́lẹ̀ pupọ yọ ilu naa lẹnu; sibẹ ilu yii ni o pẹ julọ ninu awọn ilu mejeeje ti Iwe Ifihan. Nitootọ ilu yii ṣi wa titi fi di oni-oloni, ti a n pe ni ede Turkey ni Alasehir tabi ilu Ọlọrun.
Ayokuro lati... Igba Ijọ Filadẹlfia.
Laodekia.
Orukọ naa, Laodekia ti o tumọ si “ẹtọ awọn eniyan” jẹ orukọ ti o wọpọ gidigidi, ti a fi n pe ọpọlọpọ ilu nla fun àyẹ́sí awọn ayaba ti a fi orukọ naa pè. Ilu yii jẹ ọkan ninu awọn ilu ti o ṣe pataki julọ nipa ti ọrọ iṣelu, ati ọkan ninu awọn ti ọrọ-aje rẹ burẹkẹ julọ ni Asia Minor. Ilu naa jogun ọpọlọpọ dukia lati ọwọ awọn ọmọ ilu saraki-saraki.
Ile ẹkọ ìṣègùn nla kan wa nibẹ. Awọn ara ilu yii jẹ alailẹgbẹ ninu iṣẹ-ọna ati imọn sayẹnsi. Ọpọlọpọ igba ni wọn maa n pe e ni 'olu-ilu', nitori o jẹ ibujoko ijọba ibilẹ fun awọn ilu nla nla marun-un-din-lọgbọn miiran. Oriṣa awọn keferi ti wọn n bọ nibẹ ni Zeus. Nitootọ, ni igba kan ri Diopolis (ilu Zeus) ni a n pe ilu yii, ni ibuọla fun oriṣa wọn. Ni ọgọrun ọdun kẹrin lẹyin iku ati ajinde Oluwa wa, wọn ṣe ipade igbimọ ijọ pataki kan nibẹ. Awọn ìṣẹ́lẹ̀ ti o wọpọ ni ilu naa ni o sọ ọ di ahoro patapata lẹyin-ọrẹyin.
Ayokuro lati... Igba Ijọ Laodekia.
Tẹ aworan kan lati ṣe igbasilẹ aworan iwọn ni kikun tabi PDF.
Acts of the Prophet (PDFs Gẹẹsi) |
God, Hidden and Revealed in simplicity. (PDF Gẹẹsi) |
William Branham Life Story. (PDF Gẹẹsi) |
How the Angel came to me. (PDF Gẹẹsi) |
Ifiranṣẹ ibudo...Yan ede rẹ ki o gba awọn ifiranṣẹ ọfẹ lati ọdọ Arákùnrin Branham.