Kristi ti ode Ijo Re.
Kristi ti ode Ijo Re.
William Branham.Ka iroyin ni kikun ni...
Igba Ijọ Laodikea.Ifihan 3:20-22,
20 Kiyesi Mo duro ni ẹnu ilẹkun, Mo si n kan-an-kun, bi ẹnikẹni ba gbọ Ohun Mi, ti o si ṣi ilẹkun, Emi o si wọle tọ ọ wa, Emi o si maa ba a jẹun, ati oun pẹlu Mi.
21 Ẹni ti o ba ṣẹgun ni Emi o fifun lati joko pẹlu Mi ninu Itẹ Mi, bi Emi pẹlu ti ṣẹgun, ti Mo si joko pẹlu Baba Mi ninu Itẹ Rẹ.
22 Ẹni ti o ba ni eti, ki o gbọ ohun ti Ẹmi n sọ fun awọn ijọ.“Ọpọlọpọ aigbọra-ẹni-ye ni o wa lori ẹsẹ yii nitori ọpọlọpọ aladori ẹnikọọkan ti n ṣiṣẹ ipolongo Ihinrere maa n lo O ninu iṣẹ naa bi ẹni wi pe Jesu n duro ni ẹnu ilẹkun ọkan ẹlẹṣẹ kọọkan ti O n kan ilẹkun lati wọle. Wọn yoo si wi pe bi ẹlẹṣẹ naa ba si ilẹkun ọkan rẹ Oluwa yoo wọle. Ṣugbọn ki i ṣe aladori ẹlẹṣẹ kọọkan ni ẹsẹ yii n bawi. Gbogbo iṣẹ ti Ọlọrun ran si igba ijọ yii kasẹ-n-lẹ pẹlu awọn ọrọ kan naa ti Ọlọrun fi kasẹ awọn igba ijọ yooku nilẹ. Ninu ẹsẹ22, Ọrọ Ọlọrun wi pe, “Ẹni ti o ba ni eti ki o gbọ ohun ti Ẹmi n sọ fun AWỌN IJỌ.” Nitori naa, eyi ni iṣẹ ti a ran si igba ijọ ikẹyin yii. Ipo ti ijọ Laodekia wa ni yii bi opin rẹ ti n sunmọle. Ki i ṣẹ iṣẹ ti o jẹmọ ẹnikan ṣoṣo, ti a ran si ẹni naa; Ẹmi Ọlorun ni, Ti n sọ ibi ti Jesu wa fun wa. KRISTI TI FI IJỌ SILẸ.
Lai ṣe aniani, njẹ eyi kọ ni ibi ti ọrọ yoo pari si, tabi igbẹyin ọrọ naa, nigba ti a ba ṣá Ọrọ-Ọlọrun tì fun ẹkọ-kẹkọ, ti a fi awọn poopu, bisọbu, aarẹ oludamọran ati bẹẹ bẹẹ lọdipo Ẹmi Mimọ, ti a si fi iṣẹ ọwọ eniyan, didi ọmọ ijọ, tabi didi ẹru ilana ijọ rọpo Olugbala? Kin ni o kù ti a lee ṣe lodi si I ti a ko i ti i ṣe? Eyi ni ìkọ-Ọ̀rọ-Ọlọrun-silẹ naa! Eyi ni isubu-kuro-ninu-igbagbọ naa. Eyi ni o ṣilẹkun silẹ gbagada fun aṣodi-si- Kristi. Nitori bi Ẹni kan ba wá ni Ọrukọ Baba Rẹ (Jesu) ti wọn ko si gba A, ṣugbọn ti a si kọ Ọ silẹ, nigba naa ni ẹlomiiran yoo wa ni orukọ ara rẹ, (opurọ, adibọn) oun ni wọn yoo si gba. Johanu 5:43. Ọkunrin ẹṣe ni, ọmọ egbe nì, yoo wa gba iṣakoso.
Matiu 24 sọrọ nipa awọn ami ni oju sanmọ ni ọjọ ikẹyin nigba ti o ba ku fẹẹrẹẹ ki Jesu de. N ko mọn boya o ṣe akiyesi imuṣẹ iru ami bẹẹ ti o ṣelẹ ni lọọlọ yii, eyi ti o fi otitọ ti a ti n sọrọ nipa rẹ yii han. Otitọ naa ni wi pe, diẹ diẹ ni a ti n ti Jesu si ẹgbẹ titi di igba ijọ ikẹyin ti a kuku ti I si ode ijọ. Ranti wi pe, ni igba ijọ akọkọ, Ijọ jẹ òbíríkítí ti o fẹrẹ kún fun Otitọ Ọrọ Ọlọrun. Sibẹsibẹ, ẹkọ-adamọ kan ti a n pe ni ìṣe awọn Niko-laitani wà ti ko jẹ́ ki obirikiti yii kun fun Otitọ. Lẹyin naa, ni igba ijọ ti o tẹle e, okunkun yọ kelẹkẹlẹ wọ inu ijọ sii titi di igba ti obirikiti imọlẹ yii ko mọlẹ to ti atẹyinwa mọ, ti okunkun si gba ipa ti o pọ si i ninu rẹ. Ni igba ijọ kẹta, okunkun bo o siwaju sii, ni igba ijọ kẹrin ti i ṣe igba Okunkun Aye, imọlẹ naa ti fẹrẹ poora tan.
Nisisinyi, gba ohun ti mo wi yii yẹwo. Imọlẹ Kristi ni ijo n gba a tan. Kristi ni OORUN. Ijọ ni oṣupa. Obirikiti imọlẹ naa ni oṣupa. O dinku lati oṣupa àràmọ́jú ti o jẹ igba ijọ kin-in-ni di oṣupa àrànlọ ni igba ijọ kẹrin. Ṣugbọn ni igba ijọ karun-un imọlẹ rẹ bẹrẹ si i pọ sii. Ni igba ijọ lkẹfa, o gbe igbesẹ nla ninu idagbasoke rẹ. Ni apakan ijọ keje, idagbasoke rẹ yii tẹsiwaju si i, ṣugbọn lojiji o dawọ idagbasoke duro, o si bẹrẹ si i pajude titi o fi fẹrẹ parẹ patapata, ti o fi wa di wi pe dipo imọlẹ, okunkun ti kikọ-Ọrọ Ọlọrun silẹ ni o gbilẹ, ni igba ti o si di opin igba ijọ yii, ko tilẹ ran mọ rara nitori okunkun biribiri ti bo o mọlẹ. Ni igba yii, Kristi ti wá wà ni ode ijọ.
Ami naa ti o ṣẹlẹ ni awọọsanmọ ni yii. Isiji-bo-oṣupa eyi ti o ṣẹlẹ kẹyin jẹ eyi ti ojiji aye fi okunkun bọ oṣupa patapata. Isiji-bo-oṣupa yii ṣẹlẹ diẹdiẹ ni ipele meje titi o fi di okunkun biribiri. Ni ipele keje ni okunkun biribiri ti ṣiji bo oṣupa bi poopu Roomu (Pọọlu kẹfa) ti lọ si Palẹstini lati ṣe abẹwo mimo si Jerusalẹmu. Oun ni poopu kin-in-ni ti o kọkọ lọ si Jerusalẹmu ri. Orukọ poopu yii ni Pọọlu kẹfa.
Pọọlu ni ojiṣe-Ohun-Ọlọrun fun igba ijọ akọkọ, ọkunrin yii si n jẹ orukọ yii. Kiyesi wi pe ikẹfa ni, tabi nọmba eniyan. Eleyi ki i kan an ṣe eeṣi lasan. Nigba ti o lọ si Jerusalẹmuu, oṣupa tabi ijọ lọ si inu okunkun patapata. Oun ni yii. Opin ni yii. Iran yii ko ni rekọja titi ohun gbogbo yoo fi ṣẹ. Bẹẹ ni. Jesu Oluwa, maa bọ kaankan!
Wayi o, a lee ri idi rẹ ti o fi jẹ wi pe igi ajara meji ni n bẹ, ọkan jẹ ti Otitọ, ekeji jẹ ti eke. Bakan naa ni a ri idi ti Abrahamu fi bi ọmọkunrin meji, ọkan nipa ti ara (ti o ṣe inunibini si Isaaki) ati ekeji nipa ileri. A wa ri idi ti o fi jẹ wi pe a bi awọn ọmọkunrin meji gẹgẹ bi ibeji lati ọdọ obi kan naa, ọkan ninu awọn ọmọ meji naa mọn awọn nnkan Ọlọrun, o si fẹran wọn, nigba ti ọmọkunrin keji mọn pupọ ninu Otitọ kan naa, ṣugbọn ni iwọn nigba ti ko ṣe alabapin Ẹmi kan naa, o ṣe inunibini si ọmọ ti o jẹ ayanfẹ. Ọlọrun ko ṣe awọn kan ni ẹni-itanu lati ta wọn nu lasan. O yan awọn kan ni ẹni-itanu nitori awọn ayanfẹ Rẹ ni. AYANFẸ KO LEE ṣe inunibini si ayanfẹ.
AYANFẸ KO LEE pa ayanfẹ lara. Awọn ẹni-itanu ni i ṣe inubini si awọn ayanfẹ, ti wọn si n pa wọn. Aaa, awọn ẹni-itanu wọnyi jẹ olufẹ ẹsin. Ọlọgbọn bi ejo ni wọn. Iran Kaini ni wọn, iru ẹranko-ti-a-palarada-di-ejo ni wọn. Bi wọn ṣe n kọ awọn Babeli wọn, awọn ilu nla nla wọn. Awọn ilẹ-ijọba-nla wọn, bẹẹ ni wọn ko dẹkun kike pe Ọlọrun. Wọn korira awọn iru Otitọ, wọn yoo si sa gbogbo ipa wọn (ni orukọ Oluwa paapaa) lati pa awọn ayanfẹ Ọlọrun run. Ṣugbọn a nilo wọn. “Kin ni anfaani ìpẹ́-alikama si alikama?” Lai si ipẹ ko si alikama. Ṣugbọn ni igbẹyin kin ni yoo ṣẹlẹ si ipẹ? Jijo ni a o fi ina ajooku jo o. Alikama n kọ? Nibo ni a o ti ri i? Ninu aka rẹ ni a ko o jọ si. O n bẹ nibi ti Oun naa wa. Iṣiji-aye-bo-oṣupa ti o mu oṣupa ṣookun patapata nigba ti Poopu bẹ Jerusalẹmu wo. Jọwọ dabu iwe yii lati wo aworan naa. Aaa, ayanfẹ Ọlọrun, ṣọra. Fi oju ṣọ ori bii alákàn. Kiyesara. Ṣiṣe igbala rẹ yọri pẹlu ẹru ati iwariri. Sinmi le Oluwa, ki o si di alagbara ninu ipa Rẹ. Ọta rẹ, ani eṣu n lọ kaakiri lọwọlọwọ bayi bii kin-ni-un ti n bu ramuramu, o n wa ẹni ti yoo pajẹ kiri. Maa fi adura ṣọna, ki o si duro ṣinṣin. Opin igba ni yii. Epo ati alikama n gbó bayi. Ṣugbọn ki allikama to gbó, a o di awọn epo ti o ti pọn fun jijo. Wo o, gbogbo wọn ni wọn n darapọ mọ Igbimọ Ijọ Agbaye. Eyi ni dídì naa. Laipẹ kiko alikama si inu aka yoo waye. Ṣugbọn lọwọlọwọ bayi awọn ẹmi mejeeji naa n ṣiṣẹ ninu awọn ajara mejeeji. Jade kuro láàárín awọn epo. Bẹẹrẹ si i ṣẹgun, ki Oluwa lee ka ọ yẹ si ẹni ti iyin tọ si, ti o si yẹ lati jọba ati lati ṣe akoso pẹlu Rẹ.
Ka iroyin ni kikun ni... Igba Ijọ Laodikea.
Ẹ gbọ́ Israẹli: OLUWA Ọlọrun yín, OLUWA kan ṣoṣo ni.
Diutaronomi 6:4
Iwe ti Ifihan jara.
Tẹsiwaju lori oju-iwe atẹle.
(Awọn edidi meje.)
A mọn wi
pe igba ijọ
ikẹyin ni yii
nitori Israeli
ti pada si
Palẹstini.
Ifiranṣẹ ibudo...Yan ede rẹ ki o gba awọn ifiranṣẹ ọfẹ lati ọdọ Arákùnrin Branham.