Ta ni Mèlkísédékì yìí?
<< išaaju
Ta ni Mèlkísédékì yìí?
William Branham.Ka iroyin kikun ni...
Ta ni Mèlkísédékì yìí?Heberu 7:1-3,
1 Nitori Melkisedeki yii, ọba Salẹmu, alufaa Ọlọrun Oga Ogo, ẹniti o pade Abraham bi o ti n pada bọ lati ibi pipa awọn ọba, o si sure fun-un;
2 Ẹniti Abrahamu pin idamẹwa ohun gbogbo fun; ni ọna ekini ni itumọ rẹ, Ọba ododo, ati lẹyinnaa pẹlu, Ọba Salẹmu, tii se Ọba alaafia;
3 Laini baba, laini iya, laini itan iran, bẹẹni ko ni ibẹrẹ ọjọ, tabi opin aye; sugbọn a se e bii Ọmọ Ọlọrun, o wa ni alufaa titi.Ẹ ronu nipa ẹni nla yii, bi ẹni yii se nilati jẹ ẹni nla to! Ni bayi, ibeere naa ni wipe, “Ta ni ọkunrin yii?” Awọn ẹlẹkọ ẹsin ti ni èrò ti o yatọ si ara wọn. Sugbọn lati igba ti a ti si awọn edidi mejeeje, iwe ijinlẹ naa ti o ti jẹ adiitu si wa. Gẹgẹbi Ifihan 10:1-7, gbogbo awọn ijinlẹ ti a ti kọ sinu iwe yii, ti a ti fi pamọ ni gbogbo igba awọn alatunse, ni o yẹ ki a mu wa si gbangba nipasẹ angẹli igba ijọ ti o kẹyin. Ẹni melo ni o mọ wipe eyi ri bẹẹ? Bẹẹ ni, a nilati mu u wa. Gbogbo ijinlẹ iwe ijinlẹ naa ni a nilati fi han fun ojisẹ igba ijọ Laodikea.
Gẹgẹbi a ti rii wipe ariyanjiyan pupọ wa nipa ẹni yii ati kókó ọrọ yii, mo ro wipe o yẹ fun wa lati wọ inu rẹ, lati wadi tani ẹni yii jẹ. Bayi, ọpọlọpọ ẹkọ ni o wà nipa Rẹ̀.
Ọkan ninu awọn ẹkọ naa sọ wipe, “Itan asan kan ni. Kii se ẹniyan gidi gan-an.” Awọn miiran sọ wipe, “Ilana ipo awọn alufaa ni, wipe ilana alufaa ti Melkisedeki niyẹn.” Eleyi ti o sunmọ ọn ju niyẹn, ti o sunmọ iyẹn ju ekeji lọ, nitori wọn sọ wipe ilana ipo awọn alufaa ni. Ko le jẹ bẹẹ, nitori ni ẹsẹ kẹrin, o sọ wipe ẹnikan ni - ọkunrin kan. Nitorinaa, lati le jẹ ẹnikan, Ó nilati jẹ eniyan kan - ọkunrin kan. Kii se ilana; sugbọn ẹnikan ni! Nitorinaa, kii kan se ilana ipo awọn alufaa, bẹẹni kii se itan lasan. Eniyan kan ni.Ẹni naa si jẹ ainipẹkun. Ti ẹ ba kiyesii, “Ko ni baba, ko ni iya. Ko ni igba kankan ti O bẹrẹ. Ko si ni igba kankan ti Ó de opin.” Ẹni yoowu ti O jẹ, O si n bẹ láàyè ni asalẹ yii, nitori Bibeli sọ nibi yii, wipe, “Ko ni baba, tabi iya, ibẹrẹ ọjọ, tabi opin aye. Nitorinaa o nilati jẹ ẹni ainipẹkun. Se bẹẹ ni? Ẹni ainipẹkun! Nitorinaa ẹnikan soso ni o lee jẹ, Ọlọrun niyẹn, nitori Oun nikan ni o jẹ ainipẹkun - Ọlọrun!
Bayi, ni I Timotiu 6:15 ati 16, ti ẹ ba fẹ ka iyẹn ni igba miiran, maa fẹ ki ẹ ka a. Bayi, ohun ti emi n sọ ni wipe, Ọlọrun ni, nitori Oun nikan ni o lee jẹ aiku. Ni bayi, Ọlọrun pa ara Rẹ da di eniyan; ohun ti Ó jẹ niyẹn, “Ko ni baba, ko ni iya, ko ni ibẹrẹ ọjọ aye, ko ni opin aye.”
Bayi, a rii ninu Iwe Mimọ wipe ọpọlọpọ n kọni wipe - ẹni mẹta ni o wà ninu Ọlọrun. Ko see se lati jẹ eniyan lai jẹ ẹda kan. Ẹda kan ni a fi n jẹ eniyan.
Alufaa ijọ Onitẹbọmi kan, ni ọ̀sẹ̀ diẹ sẹyin, wa si ile mi, o si sọ pe, “Mo fẹ lati tọ ọ sọna lori ẹkọ nipa ẹniti Ọlọrun jẹ nigbati o ba ri aaye” - o pe mi ni.
Mo ni, “Mo ri aaye bayi.” Nitori mo fẹ ki a tọ mi sọna, a si gbọdọ fi ohun gbogbo silẹ lati se e.
O si wa, o wipe, “Arakunrin Branham, o n kọni wipe Ọlọrun kansoso lo wa.”
Mo ni, “Bẹẹ ni, sa.”
O ni, “Ko buru,” o ni, “Mo gbagbọ wipe Ọlọrun kan ni o wa, sugbọn Ọlọrun kan ninu ẹni mẹta.”
Mo ni, “Alagba, ẹ tun sọ ọ lẹẹkan sii.”
O ni, “Ọlọrun kan ninu ẹni mẹta.”
Mo ni, “Ile-iwe wo ni o ti kawe?” Se ẹ rii? O si sọ ile-ẹkọ Bibeli kan fun mi. Mo ni, “Mo le gba iyẹn gbọ. O ko lee jẹ ẹni kan laijẹ eniyan kan. Ti o ba si jẹ eniyan kan, o jẹ eniyan kan fun ara rẹ. O da duro, ẹda kan soso.”
O si wipe, “Ko buru, awọn ẹlẹkọ ẹsin paapaa ko lee salaye iyẹn.”
Mo ni, “Nipa ifihan ni.”
O si sọ wipe, “Emi ko lee gba ifihan.”
Mo sọ pe, “A jẹ wipe ko si ọna ti Ọlọrun fi le tọ ọ wa, nitori 'A fi pamọ kuro loju awọn ọlọgbọn ati amoye, a si fihan fun awọn ọmọ ọwọ [fihan, ifihan], fihan fun awọn ọmọ ọwọ, awọn ti o fẹ [lati gba a] lati kẹkọ.” Mo si sọ wipe, “Ko si ọna fun Ọlọrun lati tọ ọ wa, o ti tilẹkun mọ ara rẹ kuro lọdọ Rẹ̀.”Gbogbo Bibeli jẹ ifihan Ọlọrun. Gbogbo ijọ ni a kọ́ lori ifihan Ọlọrun. Ko si ọna miiran lati mọ Ọlọrun, nipa ifihan nikan ni. “Ẹni ti Ọmọ ba fi I han fun.” Ifihan; ohun gbogbo jẹ ifihan. Nitorinaa, lati mase gba ifihan naa, o kan jẹ ẹlẹkọ ẹsin ti o tutu, ko si si ireti fun ọ.
Bayi, a rii wipe ẹni yii ko ni baba, ko ni iya, ko ni ibẹrẹ ọjọ, bẹẹni ko ni opin aye. Ọlọrun ni, ti o parada [em morphe].
Bayi, ọrọ naa wa lati... ọrọ Giriki yii, ti o tumọ si, “yipada” ni a lo. O pa ara Rẹ da, en morphe, lati ẹnikan si.... Ẹni kansoso; ọrọ Giriki nibẹyẹn, en morphe, tumọ si.... A mu u lati ibi ere ori itage, wipe ẹnikan n yi iboju rẹ pada, lati sọ ọ di osere miiran. Bii ni ile iwe, laipẹ yii, mo gbagbọ wipe, Rebekah, o ku diẹ ki ó jade ile iwe, wọn se ọkan ninu awọn ere Shakespeare. Ọdọmọkunrin kan si nilati yi asọ rẹ pada ni ọpọ igba, nitori o ko ipa bii meji tabi mẹta; sugbọn ẹni kannaa ni. O jade wa nigbakan, o jẹ ọdaran; nigbati o si tun pada jade wa, o tun jẹ ẹda miiran. Ni bayi, ọrọ Giriki, en morphe, tumọ si wipe “o yi iboju rẹ pada.”Ohun ti Ọlọrun si se niyẹn. Ọlọrun kannaa ni, ni gbogbo igba. Ọlọrun ni ìrí Baba, Ẹmi, ati ọ̀wọ̀n ina. Ọlọrun kannaa ni a sọ di ara, ti o si gbe aarin wa, en morphe, a mu u jade wa, ki a lee ri I. Ni bayi, Ọlọrun yẹn kannaa ni Ẹmi Mimọ. Baba, Ọmọ, Mimọ... kii se Ọlọrun mẹta; ipo mẹta ni, ìse mẹta ti Ọlọrun kan naa.
Bibeli wipe, “Ọlọrun kan ni o wa,” kii se mẹta. Sugbọn bi wọn ko se lee... Ẹ ko lee mu eleyi tọ ki ẹ si ni ọlọrun mẹta. Ẹ ko lee sọ iyẹn fun Juu laelae. N o sọ iyẹn fun ọ. Ẹni ti o mọ ohun ti o tọ, ó mọ wipe Ọlọrun kan ni o wa.Ẹ kiyesii, bii agbẹgilere, o fi i pamọ, pẹlu iboju loju rẹ. Ohun ti Ọlọrun se ni iran yii niyẹn. A ti fi pamọ. A ti fi gbogbo awọn nkan wọnyi pamọ, o si yẹ ki a fihan ni iran yii. Bayi, Bibeli sọ wipe a o fi wọn han ni igba ikẹyin. O dabi agbẹgilere ti o fi isẹ rẹ pamọ nipa dída nkan bò ó titi di igba ti yoo fi si iboju naa kuro, yoo si farahan.
Ohun ti Bibeli si ti jẹ niyẹn. O ti jẹ isẹ Ọlọrun ti a ti bo mọlẹ. A si ti fi pamọ lati ipilẹsẹ aye, ati awọn ijinlẹ ẹlẹ́ga meje rẹ̀. Ọlọrun si se ileri ni ọjọ oni, ni igba ijọ Laodikea yii, wipe Oun yoo si iboju naa kuro loju gbogbo rẹ, ki a baa lee rii. Ohun ologo ni!Ọlọrun ti ó parada, [en morphe], ti o fi ọ̀wọ̀n ina boju. Ọlọrun, ti o parada [en morphe], ninu ọkunrin kan ti a n pe ni Jesu. Ọlọrun ti o parada [en morphe], ninu ijọ Rẹ̀. Ọlọrun ni oke wa, Ọlọrun pẹlu wa, Ọlọrun ninu wa; Ọlọrun ti o n din ara Rẹ ku. Ni oke lọhun, Ó mọ́, ko si ẹniti o lee fi ọwọ kan-An, O duro sori oke; ti ẹranko paapaa ba fi ọwọ kan oke naa, o nilati ku.
Ọlọrun si wa sọkalẹ, O yi àgọ́ Rẹ pada, Ó sọkalẹ, O si ba wa gbe, o di ọkan lara wa. “Awa si di I mu,” ni Bibeli sọ. I Timotiu 3:16, “Laisi ariyanjiyan, titobi ni ijinlẹ iwa-bi-ọlọrun; nitori Ọlọrun farahan ninu ara, a fi ọwọ gba A mu.” Ọlọrun jẹ ẹran. Ọlọrun mu omi. Ọlọrun sun. Ọlọrun sọkun. O di ọkan lara wa. Eyi dara, a se afiwe rẹ ninu Bibeli! Ọlọrun niyẹn ni oke wa; Ọlọrun pẹlu wa; ati bayi, Ọlọrun ninu wa, Ẹmi Mimọ. Kii se ẹni kẹta, ẹni kannaa ni!Ọlọrun sọkalẹ, O di ẹran ara, O si ku iku naa, ninu Kristi; ki O baa le fọ ijọ mọ, ki Ó baa lee wọ inu rẹ fun idapọ. Ọlọrun fẹran idapọ. Idi ti o fi dá eniyan lakọkọ niyẹn, fun idapọ ni; Ọlọrun n danikan gbe tẹ́lẹ̀, pẹlu awọn kerubu.
Ẹ si kiyesii bayi, Ó dá eniyan, eniyan si subu. Nitorinaa O sọkalẹ wa, O si ra eniyan pada, nitori Ọlọrun fẹ ki a maa sin Oun. Ọrọ ti a n pe ni ọlọrun tumọ si “ohun ti a n sin.” Ẹni ti o si wá si aarin wa yii, gẹgẹbi ọ̀wọ̀n ina, gẹgẹbi ohun kan ti o n yi ọkan wa pada, Ọlọrun yẹn kannaa ni o sọ wipe, “Jẹ ki imọlẹ ki o wa,” imọlẹ si wa. Ọkannaa ni lana, loni, ati titi laelae.Bayi ni atetekọse, Ọlọrun danikan wa pẹlu awọn èrò Rẹ, bi mo se sọ ni owurọ yii. Iyẹn ni awọn èrò ọkan Rẹ. Ko si ohun kan, Ọlọrun nikan ni, sugbọn O ni awọn èrò ọkan. Gẹgẹbi ayaworan nla kan yoo se joko, ninu ọkan rẹ, ki o si ya aworan nkan ti ó rò wipe oun yoo kọ́ - sẹ̀dá. Bayi, ko lee sẹ̀dá, o lee mu ohun kan ti a ti dá ki o si sọ ọ di nkan miiran; nitori Ọlọrun nikan ni o lee sẹ̀dá. Sugbọn yoo ni aworan ohun ti o fẹ se ni ọkan rẹ, iyẹn ni èrò ọkan rẹ, ifẹ ọkan rẹ niyẹn. Bayi, ó jẹ́ èrò, lẹyinnaa yoo sọ ọ jade, nigbanaa ni o to di ọrọ. Ọrọ si jẹ....
Èrò, nigbati a ba sọ ọ jade, o di ọrọ. Èrò ti a sọ jade ni ọrọ, sugbọn o nilati kọ́kọ́ jẹ èrò na. Nitorinaa, o jẹ awọn èrò Ọlọrun; lẹyinnaa o di èrò, lẹyinnaa ọrọ.Ẹ kiyesii. Awọn ti wọn ni ìyè ainipẹkun ni asalẹ yi, ti wà pẹlu Rẹ̀ ati ninu Rẹ tẹlẹ, ninu èrò Rẹ, ki angẹli kankan to wà, irawọ, kerubu, tabi ohunkohun miiran. Ainipẹkun niyẹn. Ti o ba si ni iye ainipẹkun, o ti maa n wa tẹlẹ. Kii se wiwà nibi rẹ, sugbọn ni ìrí ti Ọlọrun ainipẹkun....
Ti kò ba si jẹ́ ainipẹkun, nigbanaa kii se Ọlọrun. Ọlọrun nilati jẹ ainipẹkun. Awa ni opin, Oun kò ni opin. Oun si wà nibi gbogbo, O mọ ohun gbogbo, O si lee se ohun gbogbo. Ti kò bá jẹ́ bẹẹ, a jẹ wipe ko lee jẹ Ọlọrun. Ó mọ ohun gbogbo, nibi gbogbo, nitori ti Ó wà nibi gbogbo. Mímọ ohun gbogbo lo sọ Ọ di Ẹni ti o wà nibi gbogbo. Ó jẹ ẹni kan; ko dabi afẹfẹ. Ẹni kan ni; O n gbe ninu ile kan. Sugbọn nitori ti O mọ ohun gbogbo, mimọ ohun gbogbo, ni Ó fi wà nibi gbogbo, nitori O mọ ohun gbogbo ti o n sẹlẹ.
Esinsin kan ko lee sẹ oju rẹ lai jẹ wipe Ó mọ̀ ọ́. O si ti mọ ọ ki aye to wà, oye igba ti yoo sẹju rẹ, ati oye igba ti yoo ta ẹsẹ rẹ, ki aye to wa. Ainipẹkun niyẹn. A ko lee loye rẹ pẹlu ọkan tiwa, sugbọn Ọlọrun niyẹn. Ọlọrun - ainipẹkun!Ka iroyin kikun ni...
Ta ni Mèlkísédékì yìí?
Ifiranṣẹ ibudo...Yan ede rẹ ki o gba awọn ifiranṣẹ ọfẹ lati ọdọ Arákùnrin Branham.