Iribomi Omi.
Ifihan ti Jesu Kristi.
William Branham.Ka iroyin kikun ni...
Ifihan ti Jesu Kristi.Láàárín idibajẹ ọpọlọpọ ipa Ọrọ Ọlọrun ni ode oni, mo gba wi pe yoo gba iṣipaya tootọ lati ọdọ Ẹmi Mimọ lati ri Otitọ nipa Ẹni Ti Ọlọrun I ṣe. Ṣugbọn ni iwọn igba ti a kọ́ Ijọ Ọlọrun ti n ṣẹgun, ti o si n bori lori Iṣipaya, a lee maa reti ki Ọlọrun ki o ṣi Otitọ Rẹ paya fun wa.
Ṣugbọn ni tootọ o ko nilo iṣipaya lati ri otitọ itẹbọmi. Kedere ni o farahan ni inu Ọrọ Ọlọrun, Ti a kọ kòrókòró silẹ ninu Bibeli. Njẹ o ṣeeṣe fun iṣẹju kan, ki a ṣi awọn apọsteli lọna kuro ninu aṣẹ ti Oluwa pa fun wọn lati ṣe itẹbọmi ni Orukọ Baba, ati ti Ọmọ, ati ti Ẹmi Mimọ, ki wọn si wa mọọn mọ ṣe aigbọran si aṣẹ yii bi? Wọn mọ ohun ti Orukọ Yii jẹ, ko si si ibikibi ninu Ọrọ Ọlọrun ti ati ṣe itẹbọmi ni ọna miiran yatọ si ni Orukọ Jesu Kristi Oluwa.
Ọgbọn ori lasan yoo sọ fun sọ wi pe Iwe Iṣẹ Awọn Aposteli jẹ igbesi aye, eto, ati ẹkọ Igbagbọ Ijọ, ti wọn ba si ṣe itẹbọmi ni ọna yii,eyi ni o ni lati jẹ ọna ti a gbọdọ fi ṣe itẹbọmi. Ti o ba rò wi pe Ọrọ yii nipọn ju, kin ni ero rẹ nipa eyi? Ẹnikẹni ti ko ṣe itẹbọmi ni Orukọ Jesu Oluwa ni lati tun itẹbọmi wọn se.
Iṣe Apọsteli 19-1-6,
“O si ṣe, nigba ti Apollo wa ni Kọrinti, ti Pọọlu ti kọja lọ niha ẹkun oke, o wa si Efesu: o si ri awọn ọmọ-ẹyin kan; O si wi fun wọn pe, Ẹyin ha ti gba Ẹmi Mimọ lati igba ti ẹyin ti gbagbọ? Wọn si wi fun un pe, Awa ko gbọ rara bi Ẹmi Mimọ kan wà. O si wi pe, njẹ baptimu wo ni a ha baptisi yin si? Wọn si wi pe, si baptismu ti Johanu. Pọọlu si wi pe, Nitotọ ni Johanu fi baptismu ti ironupiwada baptisi, o n wi fun awọn eniyan pe, ki wọn ki o gba Ẹni Ti n bọ lẹyin oun gbọ, èyiinì ni Kristi Jesu. Nigba ti wọn si gbọ, a baptisi wọn ni Orukọ Jesu Oluwa. Nigba ti Pọọlu si gbe ọwọ le wọn, Ẹmi Mimọ si ba lee wọn; wọn si n fọ ede miiran, wọn si n sọ asọtẹlẹ.”Bi o ti ṣe ri ni yii. Awọn eniyan rere ti ilu Efesu ti gbọ nipa Mesaya Ti n bọ ti Johanu waasu Rẹ. Wọn ti ṣe itẹbọmi fun ironupiwada awọn ẹṣẹ wọn, wọn n FI OJU SI ỌNA lati gba Jesu gbọ. Ṣugbọn nisisinyi asiko ti to lati boju wo ẸYIN wo Jesu, ki a si tẹ wọn bọmi fun IMUKURO awọn ẹṣẹ wọn. Asiko ti to lati gba Ẹmi Mimọ. Nigba ti a si ṣẹ itẹbọmi fun wọn ni Orukọ Jesu Kristi Oluwa, Pọọlu gbe ọwọ le wọn, Ẹmi Mimọ si ba le wọn.
Ah awọn ara ọ̀wọn ti wọn wa ni Efesu ni jẹ eniyan daradara; bi ẹnikẹni ba wa ti o yẹ ki ọkan rẹ balẹ, awọn ni. Kiyesi ibi ti wọn ti rin irin-ajo igbagbọ wọn de. Wọn ti de ibi ti wọn ti gba Mesaya Ti n bọ gbọ. Wọn mura silẹ de E. Njẹ iwọ ri i wi pe lẹyin gbogbo nnkan wọnyi wọn ko mọ wi pe O wa? O ti wa, O si ti lọ, O yẹ ki wọn ṣe itẹbọmi ni Orukọ Jesu Kristi Oluwa. Wọn nilo ki a kun wọn pẹlu Ẹmi Mimọ. Ti a ba ti ri ọ bọmi ni Orukọ Jesu Kristi Oluwa, Ọlọrun yoo kun ọ pẹlu Ẹmi Rẹ. Bẹẹ ni Ọrọ Ọlọrun wi.
Ohun ti a ka ni Iṣe Apọsteli 19:6 ni imuṣẹ Iṣe Apọsteli 2:38,
“Ẹ ronupiwada, ki a si baptisi olukuluku yin ni Orukọ Jesu Kristi fun idariji ẹṣẹ yin, ẹyin o si gba ẹbun Ẹmi Mimọ.”Ṣe o ri i, Pọọlu nipasẹ Ẹmi Mimọ sọ ohun kan naa gẹlẹ ti Peteru sọ nipasẹ Ẹmi Mimọ. Ohun ti a sọ, a ko SI LEE yipada. O ni lati jẹ bakan naa lati ọjọ Pẹntikọsti titi di ọjọ ti ayanfẹ naa ti yoo wọ Ijọba Ọlọrun kẹyin yoo ṣe itẹbọmi.
Galatia 1:8,
“Ṣugbọn bi o ṣe awa ni, tabi angẹli kan lati Ọrun wa, ni o ba waasu Ihinrere miiran fun yin ju eyi ti a ti waasu fun yin lọ, jẹ ki o di ẹni ifibu.”Wayi o, ọpọlọpọ ẹyin ti ẹ gba ẹkọ wi pe Ipo-iṣẹ kan-pere-ni-Ọlọrun ni n ṣe itẹbọmi ni ọna ti o kuna. Ẹ n ṣe itẹbọmi fun atunbi bi ẹni wi pe itẹbọmi ni n gba ni la. Atunbi ki i wa nipa omi: iṣẹ́ Ẹmi ni. Ọkunrin ti o ti ipasẹ Ẹmi Mimọ paṣẹ wi pe, “Ẹ ronupowada ki a si ṣe itẹbọmi fun olukuluku yin ni Orukọ Jesu Oluwa”, ko sọ wi pe itẹbọmi n sọ ni di atunbi. O sọ wi pe itẹbọmi jẹ ẹri “ọkan ti o dara si Ọlọrun” lasan ni. Ko ju bẹẹ lọ.
Peteru kin-in-ni 3:21,
“Apẹẹrẹ eyi ti n gba yin la nisisinyi pẹlu, ani baptisi, (ki i ṣe ìwẹ eeri ti ara nu, bikoṣe idahun ẹri-ọkan rere sipa Ọlọrun), nipa ajinde Jesu Kristi.”
Mo gba eyi gbọ.Bi ẹnikẹni ba ni ero ti o kunna wi pe akọsile itan lee fi ẹsẹ rẹ mulẹ wi pe a ṣẹ iribọmi ni ọna miiran ti o yatọ si ni Orukọ Jesu Kristi Oluwa, un o rọ ọ ki o ka akọsilẹ-itan, ki o si fi oju ara rẹ ri i. Akọsilẹ tootọ ti iribọmi kan ti wọn ṣe ni ilu Roomu ni ọgọrun ọdun lẹyin iku ati ajinde Oluwa wa (L.I.A.O) ti a si tẹ jade ninu iweiroyin- a-ti-gba-de-gba “TIME”, ti ọjọ karun-un oṣu Kejila, 1955 ni yii,
“Diakoni naa gbe ọwọ rẹ soke, nigba naa ni Publius Decius gba ẹnu ọna yara itẹbọmi naa wọle. Marcus Vasca, aṣẹgita, wa ni iduro ninu omi ti o mu un de ibadi, o si n rẹrin bi Pubilius ti wọ́ inu omi naa wa si egbe rẹ. Marus Vasca beere lọwọ Publius wi pe, “Njẹ o gbagbọ?” Publius si dahun wi pe Mo gbagbọ wi pe igbala mi wa lati ọwọ Jesu Kristi Ẹni Ti a kan mo agbelebu labẹ Pọntu Pilatu. Mo ku pẹlu Rẹ ki n lee ni Iye Ainipẹkun pẹlu Rẹ̀. Nigba naa ni Publius wa ni imọlara ọwọ Marcus Vasca ti o lagbara, ti o di mu bi o ṣe n rọra n jọwọ ara re si ẹyin si inu omi ti o si gbọ ohun Marcus ni eti rẹ wi pe, “Mo ri ọ bọmi ni Orukọ Jesu Oluwa”- bi omi tutu naa ṣe bo o mọlẹ.”
Titi di igba ti a sọ Otitọ yii nu (Otitọ naa ko si pada titi di igba ijọikẹyin yii-eyi ni lati Nikia titi di ibẹẹre ogun ọdun ọgọrun iru rẹ lẹyin iku ati ajinde Oluwa wa ti a wa ninu rẹ yi i) wọn se itẹbọmi ni Orukọ Jesu Kristi. Ṣugbọn Otitọ ti pada wa. Eṣu ko lee joko tẹ iṣipaya naa mọle nigba ti Ẹmi fẹ fi i fun ni.
Ti o ba jẹ wi pe Ọlọrun mẹta ni o n bẹ, nigba naa o lee ṣe itẹbọmi kan fun Baba, ọkan fun Ọmọ, ati ọkan fun Ẹmi Mimọ. Ṣugbọn IṢIPAYA TI A FI FUN Johanu ni wi pe ỌLỌRUN KANṢOṢO ni n bẹ, ati wi pe, Orukọ Rẹ ni OLUWA JESU KRISTI, a si n ṣeitẹbọmi fun Ọlọrun kan ati fun Ọlọrun KANṢOṢO. Idi rẹ ti Peteru fi ṣe itẹbọmi ni ọna ti o fi ṣe e ni ọjọ Pẹntikọsti ni eyi. O gbọdọ jẹ olootọ si iṣipaya naa ti o wi pe, “Jẹki gbogbo ile Israẹli mọ dajudaju, wi pe Ọlọrun ti ṣe JESU KAN NAA, Ti ẹ kan mọ agbelebu NI OLUWA ATI KRISTI.” Oun ni yẹn, “JESU KRISTI OLUWA.”
Ti o ba jẹ wi pe Jesu jẹ Oluwa ati Kristi PAPỌ, nigba naa Oun (Jesu) ko lee jẹ ohunkohun bi ko ṣe “Baba, Ọmọ ati Ẹmi Mimọ” ni inu EYỌ ẸNIKAN Ti o fi ara han ninu ara. KI I SE “Ọlọrun mẹta, mẹtalọkan Olubukun,” ṣugbọn Ọlọrun KAN ẸNIKANṢOṢO Ti o ni apele nla pataki mẹta, pẹlu ipo-iṣẹ mẹta ti O n fi awọn apele wọnyi han. Gbọ Ọ lẹẹkan si i. Jesu Yii kan naa ni, “Oluwa ati Kristi PAPỌ” Oluwa (Baba) ati Kristi (Ẹmi Mimọ) ni Jesu, nitori wi pe Oun (Jesu) ni awọn mejeeji LAPAPỌ (Oluwa ati Kristi).
Bi eyi ko ba fun wa ni iṣipaya ododo nipa Ẹni Ti Ọlọrun I ṣe, ko si ohun miiran ti yoo ṣe e. Oluwa KI I ṣe Ọlọrun miiran; Kristi Ki I ṣe Ọlọrun miiran. Jesu yii ni Oluwa Jesu Kristi-ỌLỌRUN KANṢOṢO. Ni ọjọ kan Filipi wi fun Jesu wi pe, “Oluwa, fi Baba naa han wa, eyi yoo si to fun wa.” Jesu si da a lohun wi pe “Mo haa ti pẹ to bẹ ẹ gẹ pẹlu yin ti ẹyin ko si mọ Mi? Ẹni ti o ba ri Mi ti ri Baba naa, e e ṣe ti iwọ fi wi pe, fi Baba naa han wa? Ọkan ni Emi ati Baba MI.”
----
O ko lee sọ Ọlọrun di Ẹni mẹta tabi ki o pin I si ọna mẹta. O ko lee sọ fun ọmọ Juu wi pe Baba kan, ati Ọmọ kan, ati Ẹmi Mimọ, kan ni n bẹ. Lọgan ni yoo sọ fun ọ ibi ti iru ẹkọ bayi ti wa. Awọn ọmọ Juu mọ wi pe ẹkọ adamọ yii w'aye ni ibi ipade Igbimọ Nikia. Ko yanilẹnu wi pe wọn n kẹgan wa wi pe abọriṣa ni wa.A n sọ nipa Ọlọrun Ti ki i yipada. Awọn Juu naa gba eyi gbọ pẹlu. Ṣugbọn ijọ ti yi Ọlọrun rẹ Ti ki i yipada kuro ni ỌKAN si MẸTA. Ṣugbọn Imọlẹ n pada bọ ni igba aṣaalẹ Iyalẹnu gidigidi ni o jẹ wi pe Otitọ yii n padabọ wa si inu ijọ ni igba ti awọn Juu n pada lọ si Palẹstini. ỌKAN ni Ọlọrun ati Kristi. Jesu yii si ni OLUWA ATI KRISTI PAPỌ. Johanu gba iṣipaya naa, Jesu si ni Iṣipaya naa, O si fi ara Rẹ han ni ọna tootọ nihin ninu Ọrọ Ọlọrun - “Ẹmi NI, Ẹni Ti o ti Wa, Ti o si n bẹ ati Ti yoo si Pada wa, Olodumare. Amin.”
Ti o ko ba ni iṣipaya Ọrọ Ọlọrun, gbe oju rẹ soke ki o si beere iṣipaya lọwọ Ọlọrun. Ọna yii nikan ni o lee fi ni iṣipaya. Iṣipaya ni lati wá lati ọdọ Ọlọrun. Ko fi igba kan ri wá lati ọwọ eniyan, tabi nipa ifi-funni eniyan, bikoṣe nipa ifi-ikun-ni agbara Ẹmi Mimọ. O tilẹ lee kọ Bibeli sori, bi o tilẹ jẹ wi pe eyi dara, sibẹ ko lee ṣe anfaani kankan. Ó nilati jẹ́ iṣipaya lati ọdọ Ọlọrun. O sọ ninu Ọrọ Ọlọrun wi pe ko si ẹnikẹni ti o lee pe Jesu ni Kristi naa, bikoṣe nipaṣẹ Ẹmi Mimọ. Iwọ ni lati gba Ẹmi Mimọ, ni igba naa, ati nigba naa nikan ni Ẹmi Mimọ lee fun ọ ni iṣipaya wi pe, Jesu ni Kristi naa: Ọlọrun, Ẹni Ami-ororo naa.
Ko si ẹni ti o mọ awọn ohun Ọlọrun bikoṣe Ẹmi Ọlọrun ati ẹni ti Ẹmi Ọlọrun ba ṣi wọn paya fun. A ni lati kepe Ọlọrun fun iṣipaya ju ohunkohun miiran ni aye lọ. A ti gba Bibeli, a si ti igba awọn Otitọ nlanla inu Rẹ, ṣugbọn sibẹ Ko i ti i jẹ okodoro si ọgunlọgọ ẹniyan nitori wi pe wọn kò ni iṣipaya nipa Ẹmi Ọlọrun. A ko i ti sọ Ọrọ naa di aaye ninu wọn. Bibeli sọ niKọrinti keji 5:21 wi pe, A ti di ododo Ọlọrun ná nipa idapọ wa pẹlu KRISTI. Njẹ o ye ọ? O sọ wi pe AWA NI ODODO ỌLỌRUN FUNRARARẸ GAN AN nipa wíwà NINU KRISTI. O sọ wi pe Oun (Jesu) di ẸṢẸ fun wa. Ko sọ wi pe O di ẹlẹṣẹ, ṣugbọn O di ẸṢẸ fun wa ki o lee jẹ wi pe nipa idapọ pẹlu Rẹ a lee di ODODO Ọlọrun.
Bi a ba gba Otitọ naa (o si ti di kannpa fun wa lati gba A) wi pe O di ẸṢẸ Funrararẹ gan an fun wa nipa gbígbà ti O gba ipo wa, nigba naa ọran kannpa ni fun wa lati gba Otitọ naa wi pe awa pẹlu, nipa idapọ pẹlu Rẹ ti di ODODO ỌLỌRUN GAN AN. Bi a ba kọ ekin-in-ni a ni lati kọ ekeji pẹlu. Bi a ba gba ekin-in-ni, a ni lati gba ekeji pẹlu. A mọ wi pe Bibeli sọ eyi. A ko lee sẹ ẹ.Ṣugbọn a ti padanu iṣipaya rẹ. Iṣipaya yii ko jẹ arigbamu ati okodoro si ogunlọgọ awọn ọmọ Ọlọrun. Ẹsẹ ti a ka naa jẹ ẹsẹ Bibeli kan ti o dara lasan loju wọn ni. Ṣugbọn a ni lati sọ Ọ di AAYE fun wa. Yoo gba iṣipaya lati lee ri I bẹẹ.
Ka iroyin kikun ni...
Ifihan ti Jesu Kristi.
Iwe ti Ifihan jara.
Tẹsiwaju lori oju-iwe atẹle.
(Iran Patimọsi.)
Ifiranṣẹ ibudo...Yan ede rẹ ki o gba awọn ifiranṣẹ ọfẹ lati ọdọ Arákùnrin Branham.