Iran Patimọsi.


  Iwe ti Ifihan jara.

Johanu ni Patimọsi.


William Branham.

Ka iroyin ni kikun ni...
Iran Patimọsi.

Iwe Ifihan 1:9,10
9 Emi Johanu, arakunrin yin ati alabapin pẹlu yin ninu wahala ati ijọba ati suuru ti n bẹ ninu Jesu, wa ninu erẹkuṣu ti a n pe ni Patimọsi, nitori Ọrọ Ọlọrun, ati nitori ẹri Jesu Kristi.
10 Mo wa ninu Ẹmi ni ọjọ Oluwa, mo si gbọ Ohun nla kan lẹyin mi, bi iro ipe,

A fun Johanu ni awọn iran ti o tẹlera wọn lẹsẹẹsẹ wọnyi ti ìsípayá Ẹni Ti Jesu Kristi i ṣe nigba ti a le e danu kuro ni ilu si erekuṣu Patimọsi. Erekuṣu kekere yii jẹ ọgbọn ibusọ si eti bebe Asia Minor, ninu Okun Aegean. Nitori wi pe erekuṣu yii jẹ kikida apata, ti ejo, alangba ati àkeekèé si gba ibẹ kan, ko wulo pupọ fun ìṣòwò. Nitori naa Ijọba-nla Roomu lo o gẹgẹ bi ibi ti a ti n fi ìyà-jẹni, ani ibi ti a n ko awọn ọdaran ti o buru jai, awọn ẹlẹwọn nitori ọrọ oṣelu, abb., pamọ si.

Iwọ yoo ṣe akiyesi wi pe Johanu pe ara rẹ fun awọn Kristiani ni, arakunrin wọn ninu ipọnju. Igba naa ni àkókó ti ijọ àkókó n dojukọ inunibini nla. Ki i ṣe wi pe, “a n sọ ọrọ-odi si ẹsin wọn ni ibi gbogbo” nikan, ṣugbọn a sọ awọn eniyan naa paapaa si ọgba ẹwọn, a si n pa wọn. Johanu, gẹgẹ bi ogunlọgọ miiran, n jiya bayi ninu túbú fun Ọrọ Ọlọrun ati ẹri Jesu Kristi. Nigba ti a mu un, wọn gbiyanju lati pa a nipa sise e ninu epo fun wakati mẹrinlelogun, ṣugbọn pabo ni eyi jasi. Nigba naa ni awọn agbèfọ́ba onínúfùfù ti ko ri ohunkohun ti wọn lee tun fi Johanu ṣe mọ́ da a lẹbi wi pe ajẹ ni, wọn si sọ ọ si erekuṣu Patimọsi. Ṣugbọn Ọlọrun wà pẹlu rẹ, a si da ẹmi rẹ si lati fi erekuṣu naa silẹ pada lọ si Efesu ni ibi ti o ti tẹsiwaju gẹgẹ bi oluṣọ-agutan titi di ọjọ iku rẹ.

Ipele meje ogo ti Ẹni ti i Ṣe.

Iwe Ifihan 1:14-16,
“Ori Rẹ ati irun Rẹ funfun bi ẹ̀gbọ̀n owu, o funfun bi sno, oju Rẹ si dabi ọwọ ina: Ẹsẹ Rẹ si dabi idẹ daradara, bi ẹni pe a da a ninu ìléru; Ohùn Rẹ si dabi iro omi pupọ. O si ni irawọ meje ni ọwọ ọtun Rẹ; ati lati ẹnu Rẹ wa ni Ida oloju Meji mímú ti jade; oju Rẹ si dabi oorun ti o n fi agbara rẹ ran.“

Ifarahan Jesu si Johanu ẹni ti a le jade kuro ni ilu nitori Ọrọ Ọlọrun wu u lori, o si fun un ni imisi jọjọ. Si wo o, ỌRỌ Aaye naa wá duro niwaju rẹ̀. Oye ati imọlẹ iran ti Johanu ri yii tobi pupọ, nitori gbogbo apejuwe Ẹni Ti o jẹ ati ohun ti O ṣe ni o ni ohun ti o duro fun. Iṣipaya agbayanu nla-nla Ẹni Ologo Ti I ṣe ni iran naa jẹ.

1.Irun Rẹ funfun Bi Sno.

Ohun ti Johanu kọkọ ri ti o si sọ ni fi-funfun irun ori Rẹ. O funfun o si n dan bi yinyin. Eyi ki i ṣe nitori ọjọ ori Rẹ. O ti o. Irun ori Rẹ ti o funfun gboo ti o si n dan ko duro fun ogbó, ṣugbọn ìrírí, iwa-agba ati ọgbọn. Ẹni Ainipẹkun ni ki i gbó. Kin ni asiko jẹ si Ọlọrun? Ohun kekere ni asiko jẹ si Ọlọrun, ṣugbọn ọgbọn jẹ ohun nla si I. O dabi igba ti Solomọni beere ọgbọn lọdọ Ọlọrun lati ṣe idajọ awọn eniyan Israẹli. Nisisinyi, O n bọ, Onidajọ gbogbo agbaye. A o de E ni ade ọgbọn. Ohun ti irun funfun ti n dan naa duro fun ni eyi.

Oun ni Onidajọ Ti o n ṣi awọn iwe naa, Ti o si n ṣe idajọ lati inu wọn. Daniẹli ri I Ti o n bọ ninu awọsanmọ. Ohun ti Johanu ri gẹlẹ ni yii. Wọn ri I lọna kan naa. Wọn ri Onidajọ naa pẹlu amure idajọ Rẹ lori awọn ejika Rẹ, Ti o duro ni mímọ́, lai ni abawọn, Ti o kun fun ọgbọn, Ti o kun-oju-oṣuwọn patapata lati dá aye lẹjọ ninu ododo. Alleluya.

2. Oju Rẹ bi Ina.

Ro eyi wo. Awọn oju ti o fi igba kan le ròrò pẹlu omije ibanujẹ ati aanu. Awọn oju ti o sọkun pẹlu ikaaanu ni ibi iboji Lasaru. Awọn oju ti ko ri ibi awọn apaniyan ti o kan An mọ agbelebu, ṣugbọn ni ibanujẹ O kigbe wi pe, “Baba dariji wọn”. Nisisinyi awọn oju wọnyi di ẹla ahọn ina, oju Onidajọ ti yoo san ẹsan fun awọn ti o kọ Ọ silẹ. Eyi ti O fihan julọ ninu gbogbo ifarahan ipo-ọkan eniyan nigba ti O farahan gẹgẹ bi Ọmọ Eniyan ni wi pe O sọkun lọpọlọpọ igba. Bi o tilẹ jẹ wi pe O sọkun O si banujẹ lọpọlọpọ, Ọlọrun ṣi ni sibẹsibẹ Awọn oju kan naa wọnyi ri iran. Wọn wo ọkan eniyan jinlẹ, wọn si ni imọ ero ti o wa ninu rẹ gan an, wọn si mọn gbogbo ọna ati iṣe wọn. Ọlọrun arinu-rode Ti n foju eniyan riran, Ẹni Ti n kigbe si awọn ti ko mọn Ọn gẹgẹ bi Ẹni Ti o jẹ wi pe, “...Bikoṣe pe ẹ ba gbagbọ pe Emi Ni, ẹ o ku ninu ẹṣẹ yin”. Johanu 8:24. “Bi Emi ko ba ṣe awọn iṣẹ Baba Mi, ẹ maṣe gba Mi gbọ. Ṣugbọn bi Emi ba ṣe wọn (awọn iṣẹ Baba Mi), bi ẹyin ko tilẹ gba Mi gbọ, ẹ gba Iṣẹ naa gbọ”. Johanu 10:37-38. Bii Jeremaya atijọ, Jesu ni Wolii ẹlẹkun naa, nitori awọn eniyan ko gba Ọrọ Ọlọrun, wọn si pa iṣipaya Ọrọ naa ti si ẹgbẹ kan.

Awọn oju Onidajọ naa ti o mun bi ina ti o si n ṣáná, tilẹ n kọ ìṣe igba-aye gbogbo eniyan silẹ bayi. Bayi O ti n lọ soke-sodo jake-jado aye, ko si ohun ti Jesu ko mọn. O mọn awọn ifẹ ọkan ati ohun ti ẹni kọọkan n gbero lati ṣe. Ko si ohun ti o farasin ti a ko ni fihan, nitori ohun gbogbo ni o han kedere niwaju Rẹ, Ẹni Ti awa ni i ba lo. Njẹ o mọn wi pe, lọwọlọwọ bayi paapaa O mọn ohun ti o n ro.

Bẹ ẹ ni, bayi ni O duro gẹgẹ bi Onidajọ pẹlu oju ti o n ṣana lati ṣe idajọ. Ọjọ aanu ti dopin. Aaa, awọn eniyan i ba ronupiwada ki wọn si wa oju Rẹ ni ododo nigba ti akoko ṣi wa. Ki wọn ki o fi ookan aya Rẹ ṣe irọri wọn ki ina to sọ aye di eeru.

3. Ẹsẹ̀ Idẹ.

“Ẹsẹ̀ Rẹ dabi idẹ didan, bi eyi ti a dà ninu ina ileeru”. A mọn idẹ fun lile kokooko rẹ ti ko lẹgbẹ. Ko si ohunkohun ti a lee da mọ ọn lati dẹ̀ ẹ́. Ṣugbọn idẹ ti o ṣe apejuwe ẹsẹ Rẹ jẹ eyi ti ko lẹ́gbẹ́ rara nitori o ti la idanwo ti o gbona bi ina ileeru kọja, idanwo ti ẹnikẹni ko i tii la kọja ri. Bẹẹ gẹlẹ ni o ri. Nitori idẹ duro fun Idajọ Ọlọrun: idajọ ti Ọlọrun pa laṣẹ ti O si mu ṣẹ.

Numeri 21:8-9,
“Oluwa si wi fun Mose pe, Rọ ejo amubina kan, ki o si fi i sori ọpa gigun kan: yoo si ṣe, olukuluku ẹni ti ejo ba buṣan, nigba ti o ba wo o, yoo ye. Mose si rọ ejo idẹ kan, o si fi i sori ọpa gigun naa: o si ṣe, pe bi ejo kan ba bu eniyan kan ṣan, nigba ti o ba wo ejo idẹ naa, oun a ye“. Awọn ọmọ Israẹli ti dẹ́ṣẹ̀. A si gbọdọ dá ẹṣẹ lẹjọ. Nitori naa Ọlọrun paṣẹ fun Mose lati gbe ejo idẹ kọ igi, gbogbo ẹni ti o wo o ni a si gbala kuro ninu ijiya ẹṣẹ wọn.

Ṣugbọn ni ọjọ kan awọn ẹsẹ idẹ naa yoo duro lori ilẹ aye. Oludajọ gbogbo aye ni Yoo si jẹ, idajọ ti o tọ́ si olukuluku ti ko si ni ojuṣaaju, ti o si pe ni Yoo fi da gbogbo eniyan lẹjọ. Ko si ẹni ti idajọ naa yoo yọ silẹ. A ko ni yí idajọ naa pada, bẹẹni ko ni si aanu. Ẹni ti o jẹ alaiṣododo yoo jẹ alaiṣododo sibẹ, ẹni ti o jẹ eleeri yoo jẹ eleeri sibẹ. Ẹni Ti ki i yipada naa Ko ni yipada nigba naa, nitori Ko yipada ri, Ko si ni yipada laelae. Awọn ẹsẹ idẹ naa yoo wó ọta tuutu. Wọn yoo pa aṣodi-si-Kristi, ẹranko naa, ere rẹ ati ohun gbogbo ti o jẹ alaimọ niwaju Rẹ run. Aṣodi-si-Kristi ati awọn ijọ ti n fi Orukọ Rẹ pe ara wọn ti wọn si n dibajẹ ẹwa ati ogo Rẹ ni Yoo run. Gbogbo awọn eniyan buburu, awọn alaigba-Ọlọrun-gbọ, awọn alaigbagbọ ninu aye-airi ati agbara rẹ, awọn ti o fi kun tabi ti o yọ kuro ninu Ọrọ Ọlọrun lati mun Un ni ibamu pẹlu aye ode-oni ati awọn ti n ṣe bi awọn eniyan aye ode-oni ti n ṣe, yoo wa nibẹ. Iku, ọrunapaadi, ati isa-oku yoo wa nibẹ. Bẹẹ ni, wọn yoo wa nibẹ. Nitori nigba ti O ba de, a o ṣi awọn Iwe naa. Nigba yii ni awọn ijọ ko-gbona-ko-tutu paapa ati awọn wundia alaigbọn marun-un nì yoo farahan. Jesu yoo si ya awọn agutan ati ewurẹ sọtọ. Nigba ti O ba de ni Yoo gba iṣakoso ijọba aye, nitori Tirẹ ni, awọn ẹgbẹlẹgbẹ ẹgbẹẹgbẹrun, ti i ṣe Iyawo Rẹ, ti ó wá lati ṣe iṣẹ isin fun Un yoo si wà pẹlu Rẹ. Ogo! Tuuba nisisinyi, tabi o di gbere ni yẹn. Ronu-piwada ki o to pẹ ju. Taji kuro láàárín awọn oku ki o si bẹ Ọlọrun ki O kun ọ pẹlu Ẹmi Rẹ, lai jẹ bẹẹ iwọ yoo padanu Iye Ainipẹkun. Ṣe bẹẹ bayi nigba ti akoko ṣi wa.

4. Ohùn Rẹ Dabi Iro Omi Pupọ.

Wayi o, Kin ni awọn ọpọ omi duro fun? Gbọ bi a ti kọ Ọ ni Iwe Ifihan 17:15, “...awọn omi ti iwọ ri ni, ... eniyan ati ẹya ati orilẹ ati oniru-un-ru ede ni wọn.” Ohùn Rẹ dabi ti ogunlọgọ awọn eniyan ti n sọrọ. Kin ni o n ṣẹlẹ? Ibi Idajọ naa ni. Nitori awọn wọnyi ni ohùn awọn ogunlọgọ ẹlẹri ti o ti n jẹri nipa Kristi, ti n waasu Ihinrere Rẹ nipasẹ Ẹmi Mimọ. Yoo jẹ ohùn olukuluku eniyan ti o n da ẹlẹṣẹ ti ko fetisi ikilọ lẹjọ. Gaara ni a o gbọ ohùn awọn ojiṣẹ-Ohun-Ọlọrun mejeeje naa bi wọn ṣe kigbe fatafata. Awọn oniwaasu ododo ti wọn waasu agbara Jesu ti n gba ni la, ti wọn waasu itẹbọmi ni Orukọ Jesu, ti wọn waasu ifikunni ati agbara Ẹmi Mimọ, awọn ti Ọrọ Ọlọrun ṣe pataki si wọn ju aye wọn lọ; gbogbo wọn ni Ohùn Jesu Kristi nipasẹ Ẹmi Mimọ ni iran kọọkan lati ibẹrẹ de opin. Johanu 17:20, “Ki i si i ṣe kiki awọn wọnyi ni Mo n gbadura fun, ṣugbọn fun awọn pẹlu ti yoo gba Mi gbọ nipa ọrọ wọn.”

Aaa, i ba ti dara to bi o ba loye eyi. Omi ni o pa gbogbo aye rẹ́, ṣugbọn omi kan naa ni o gba Noa la, ti o si da gbogbo ilẹ aye si fun Noa. Feti si Ohun Rẹ, ohun awọn iranṣẹ Rẹ bi O ṣe n pe ọ si ironupiwada ati Iye.

5. Ni Ọwọ Ọtun Rẹ Ni Awọn Irawọ Meje Wa.

“O ní irawọ meje ni ọwọ ọtun Rẹ”. Ko si aniani wi pe a ti mọn ṣaaju ninu ẹsẹ ogun ohun ti awọn irawọ meje wọnyi jẹ. “Ijinlẹ awọn irawọ meje yii ni awọn angẹli naa, (awọn ojiṣe-Ohun-Ọlọrun), ti igba ijọ mejeeje”. Ko si bi a ṣe lee ṣe aṣiṣe nipa eleyi lọnakọna nitori wi pe Oun Funrararẹ ni o tumọ Rẹ fun wa. Awọn irawọ meje wọnyi ni awọn ojiṣẹ-Ohun-Ọlọrun si igba ijọ meje ọtọọtọ. A kò darukọ wọn. A kan sọ fun wa wi pe meje ni wọn ni, ọkọọkan si igba ijọ kọọkan. Lati Igba Ijọ Efesu titi di Igba Ijọ Laodekia yii, olukuluku ojiṣẹ-Ohun-Ọlọrun ni o mun Otitọ wa fun awọn eniyan lai fi igba kankan kuna lati ri i wi pe O jẹ Ọrọ Ọlọrun si Igba Ijọ naa pato. Olukuluku wọn di I mu. Wọn duro ṣinṣin ninu otitọ wọn si Imọlẹ ipilẹṣẹ naa. Bi igba ijọ kọọkan ṣe n fa sẹyin kuro lọdọ Ọlọrun ni ojiṣẹ-Ohun Rẹ olododo naa n pe igba Ijọ naa pada sinu Ọrọ Ọlọrun. Ọdọ Oluwa ni okun wọn ti wa, lai jẹ bẹẹ wọn ki ba ti lee bori iji naa laelae. Wọn wa ni ipamọ labẹ aabo Rẹ, nitori ko si ohunkohun ti o lee ja wọn gba kuro ni ọwọ Rẹ, bẹẹ ni ko si ohunkohun ti o lee yà wọn nipa kuro ninu Ifẹ Rẹ, i baa jẹ aisan, ewu, ihoho, ìyàn, ida, iye tabi iku.Wọn jọwọ ara wọn fun Un ni tootọ. Agbara-Rẹ-ti-ko-lopin si pa wọn mọ. Wọn ko bikita fun inunibini ti o ṣẹlẹ si wọn. Irora ati ifini-rẹẹrin-ẹlẹya jẹ ohun ti wọn fi fi ogo fun Ọlọrun wi pe O ka wọn yẹ lati jiya fun Un. Ni idupẹ fun igbala Rẹ, ina igbesi-aye wọn n jò pẹlu Iye Rẹ, o si n fi ifẹ, suuru, iwa-tutu, ikora-ẹni-ni-ijanu, iwa-pẹlẹ, ati jijẹ olootọ Rẹ han. Ọlọrun si ṣe alatilẹyin wọn pẹlu iṣẹ-ara, ami, ati iṣẹ-iyanu. Wọn pe wọn ni a-gba-weremẹsin ati alakatakiti. Awọn ẹgbẹ ẹlẹsin-ti-o-fi-eniyan-rọpo-Ẹmi Mimọ bu ẹnu-àtẹ́ lu wọn, wọn si fiwọn ṣe ẹlẹya, ṣugbọn awọn ṣe olootọ si Ọrọ naa.

Itunu yii ko wà fun awọn ojiṣẹ-Ohun-Ọlọrun igba ijọ mejeeje nikan. Gbogbo onigbagbọ otitọ kọọkan ni o n bẹ ni ọwọ Ọlọrun ti o si lee jẹ anfaani ifẹ ati agbara Rẹ, kí o si gba ẹkunrẹrẹ anfaani ohun gbogbo ti Ọlọrun jẹ́ si onigbagbọ. Ohun ti Ọlọrun fi fun ojiṣẹ-Ohun-Ọlọrun naa, ati ọna ti O fi n bukun un, ti O si fi n lo o, jẹ apẹẹrẹ inu-rere Rẹ si gbogbo onigbagbọ ati ikẹ Rẹ si GBOGBO ẹya ara Rẹ. Amin.

6. Idà Oloju Meji.

“Lati ẹnu Rẹ ni Ida Oloju Meji ti jade”. Ni Iwe Heberu 4:12, “Nitori Ọrọ Ọlọrun yè, O si ni agbara, O si mun ju idakida oloju meji lọ, O si n gún ni ani titi de pinpin ọkan ati ẹmi niya, ati orike ati inu egungun, Oun si ni Olumọ ero inu ati ete ọkan”. Lati ẹnu Rẹ ni Ida Oloju Meji Ti o mun ṣanṣan Eyi Ti i ṣe ỌRỌ ỌLỌRUN ti jade.

Pọọlu wi pe Ọrọ Ọlọrun wá pẹlu agbara ati ohùn. Ọrọ Ọlọrun Ti a waasu fi ara Rẹ han ni tootọ. Gẹgẹ bi ida amubi-ina ti n ge ni, O lọ si inu ẹ̀rí ọkan awọn eniyan, ati bi abẹfẹlẹ dokita-oniṣẹ-abẹ O ge awọn arun danu O si tu awọn onde silẹ. Ni ibi gbogbo ti awọn onigbagbọ akọkọ lọ, “ni wọn ti n tẹsiwaju ti wọn n waasu Ihinrere (Ọrọ Ọlọrun), Ọlọrun si n fi idi Ọrọ naa mulẹ pẹlu awọn ami ti n tẹle E”. A mu awọn olókùnrùn ni ara da, a le awọn ẹmi aimọ jade, wọn si fi ede-titun sọrọ. Ọrọ Ọlọrun ni yii, Ti o di Aaye mi oju ìṣe. Ọrọ yii ko fi igba kan ri ṣákìí ni ẹnu awọn onigbagbọ oniwa-bi-Kristi. Ati ni igba ijọ ikẹyin yii Ọrọ naa ní agbara, O si tobi ninu Aya Ọrọ Ọlọrun tootọ ju ti igbakugba lọ. Aaa, ẹyin agbo agutan kekere, ẹyin ẹgbẹ kekere, ẹ maa di Ọrọ naa mun, ẹ kun ẹnu ati ọkan yin pẹlu Rẹ, ni ọjọ kan Ọlọrun yoo fun yin ni Ijọba naa.

7. Oju Rẹ Dabi Oòrùn.

Ni Ifihan 21:23, “Ilu naa ko si ni i wa oorun, tabi oṣupa, lati maa tan imọlẹ si i. Nitori pe ogo Ọlọrun ni o n tan imọlẹ si i. Ọdọ Agutan si ni fitila rẹ.” Eyi ni Jerusalẹmu Titun naa. Ọdọ Agutan naa yoo wà ni Ilu naa, ati nitori Ifarahan-isọkalẹ Rẹ a ko ni nilo imọlẹ kankan nibẹ, eyi ni wi pe oorun ko ni là, ko si ni ran nibẹ nitori Oun Tikalararẹ ni Oorun ati Imọlẹ ibẹ. Awọn orilẹ-ede ti n wa sinu rẹ yoo rin ninu Imọlẹ Re. Inu rẹ ko ha dun wi pe ọjọ yii ti fẹẹrẹ de bi? Johanu ri ọjọ yii ti n bọ. Bẹẹ ni, Jesu Oluwa tete de!

Malaki 4:1-3, “Ṣaa kiyesi i, ọjọ naa n bọ ti yoo maa jo bi ina ileeru; ati gbogbo awọn agberaga, ati gbogbo awọn oluṣe buburu yoo dabi akeku koriko: ọjọ naa ti n bọ yoo si jo wọn run, ni Oluwa awọn Ọmọ-ogun wi, ti ki yoo fi ku gbongbo, tabi ẹka fun wọn. Ṣugbọn Oorun Ododo yoo la, ti Oun ti imularada ni iyẹ-apa Rẹ, fun ẹyin ti o bẹru Orukọ Mi; ẹyin o si jade lọ, ẹyin o si maa dagba bi awọn ẹgbọrọ maalu inu agbo. Ẹyin o si tẹ awọn eniyan buburu mọlẹ: nitori wọn o jasi eeru labẹ atẹlẹsẹ yin ni ọjọ naa ti Emi o da, ni Oluwa awọn Ọmọ-ogun wi.“ Oun tun niyẹn lẹẹkan sii. OORUN naa n fi gbogbo agbara Rẹ ràn. Aaa, itanṣan agbara Ọmọ Ọlọrun n tan ni aarin ọpa fitila wura meje. Nibẹ ni O duro, Oludajọ naa, Ẹni naa Ti o jiya Ti o si ku fun wa. O gba ibinu idajọ Ọlọrun si ori ara Rẹ. O da nikan tẹ ifunti ti ọti ibinu Ọlọrun kikoro. Gẹgẹ bi a ti sọ ṣaaju, si ẹlẹṣẹ, Ohun Rẹ dabi iro omi ti n sọkalẹ si ori apata tabi iji ti n kọlu bebe alapata, bi i wi pe yoo ya á. Ṣugbọn si ẹni-mimọ, Ohun Rẹ dabi ohun odo ti n kọrin aladun bi o ti n sinmi pẹlu itẹlọrun ninu Kristi. Bi O ṣe n tan Imọlẹ itanṣan ifẹ Rẹ, ti N tu ni lara, si ori wa, O wi pe, “Ma bẹru, Emi ni Ẹni ti O ti wa, Ẹni ti o nbẹ, Ẹni ti o n bọwa; Emi ni Olodumare. Lẹhin Mi ko si ẹlomiran. Emi ni Alfa ati Omega, Emi ni GBOGBO rẹ”. Oun ni Lili Afonifoji, Irawọ Owurọ Ti o mọlẹ. Oun ni Arẹwa Julọ láàárín ẹgbẹrun mẹwa si ọkan mi. Bẹẹ ni, Ọjọ nla nì ti ṣetán lati là, ti Oorun Ododo yoo là pẹlu iwosan ni iyẹ apa Rẹ.

Ka iroyin ni kikun ni... Iran Patimọsi.


Ohun ijinlẹ Kristi.

Wẹẹbu iwe iroyin Gẹẹsi.

Iwe Ifihan jara.

 

Ọlọrun ati Imọ Atọka.
- Archaeology.

Igbasoke n bọ.

 

Awọn ẹkọ akọkọ
ti ifiranṣẹ naa.

Awọn ti o dara iroyin.
Jesu ku fun ese re.

Iribomi Omi.

 

Awọsanma eleri nla.

Ọwọn ti ina.

Ogo Shekinah ti Ọlọrun.

Ibojì ti ṣofo.
O ti jinde.

Ọlọrun salaye.

Awọn ìgbà ijọ meje.

Awọn edidi meje.

Ọlọrun ati Itan.
jara Atọka - Dáníẹ́lì.

Kristiẹni ije jara.
Ìgbéyàwó Àti Ìkọ̀sílẹ̀.
Akojọ Ifiranṣẹ.

Opin akoko jara.

Ngbe ọrọ jara.

Keresimesi jara.

Iku. Ohun ti nigbana?

Orúkọ Ọlọrun.

Ọkọ Noa.

 

Ẹṣẹ Atilẹba.
Je o ẹya apulu?

Adaparọ.
Awọn orisun - Babeli.

Ọlọrun ati Imọ.
Dainoso Adaparọ.

Archaeology.
Sodomu ati Gomorra.


Iwe ti Ifihan jara.
Tẹsiwaju lori oju-iwe atẹle.
(Igi Iye. Ẹṣẹ Atilẹba.)



  Iwe-mimọ sọ...

Ẹsẹ Rẹ si dabi ide daradara, bi ẹni pe a da a ninu ileru; Ohun Rẹ si dabi iro omi pupọ.

O si ni irawọ meje ni Ọwọ Ọtun Rẹ; ati lati ẹnu Rẹ wá ni Ida Oloju meji mimu ti jade; oju Rẹ si dabi oorun ti o n fi agbara rẹ ran.

Iwe Ifihan 1:17-18.


Tẹ aworan kan lati ṣe igbasilẹ aworan iwọn ni kikun tabi PDF.


O si jẹ awọn Emi ni.
 

Kristi. Ni awọn
ti nmu fitila.

Acts of the Prophet

(PDFs Gẹẹsi)
 

The Two Babylons

by Rev Alexander Hislop.
(PDF Gẹẹsi)

Oke ati dide igbo
ni egbon ni Ṣaina.

Awọn lili ti ina.

Ọwọn ti ina.
- Houston 1950.

Imọlẹ lori apata
jibiti.


Ifiranṣẹ ibudo...Yan ede rẹ ki o gba awọn ifiranṣẹ ọfẹ lati ọdọ Arákùnrin Branham.