Irú Ẹranko-tó-Padà-Dejò.

<< išaaju

itele >>

  Ngbe ọrọ jara.

Je o ẹya apulu?
Otitọ nipa ẹṣẹ atilẹba.


William Branham.

Ka iroyin kikun ni...
Irú Ẹranko-tó-Padà-Dejò.

Jẹnẹsisi 3:1-7,
1 Ejo saa se aláàrékérekè ju ẹranko igbẹ iyoku lọ ti Oluwa Ọlọrun ti da. O si wi fun obinrin naa pe, ootọ ni Ọlọrun wi pe, Ẹyin ko gbọdọ jẹ gbogbo eso igi ọgba?
2 Obinrin naa si wi fun ejo pe, Awa a maa jẹ ninu eso igi ọgba.
3 Sugbọn ninu igi ni, ti o wa laarin ọgba Ọlọrun ti wipe, ẹyin ko gbọdọ jẹ ninu rẹ, bẹẹni ẹyin ko gbọdọ fọwọkan an. Ki ẹyin ki o ma ba a ku.
4 Ejo naa si wi fun obinrin naa pe, ẹyin ki yoo ku ikukiku kan
5 Nitori Ọlọrun mọn pe, ni ọjọ ti ẹyin ba jẹ ninu rẹ, nigba naa ni oju yin yoo la, ẹyin yoo si dabi Ọlọrun, ẹ oo mọn rere ati buburu.
6 Nigba ti obinrin naa si rii pe, igi naa dara ni jijẹ ati pe, o si dara fun oju, ati igi ti a i fẹ lati mu ni gbọn, o mu ninu eso rẹ̀, o si jẹ́, o si fi fun ọkọ rẹ pẹlu rẹ, oun si jẹ.
7 Oju awọn mejeji si la, wọn si mọn pe awọn wa ni ihoho; wọn si gán ewe ọpọtọ pọ, wọn si dá ìbà-ǹ-tẹ́ fun ara wọn.

Kiyesii bayi, ohun to sẹlẹ ni yi. Mo gbagbọ, mo si lee fi idi rẹ mulẹ pẹlu Bibeli pe, ẹranko to-pada-dejo yẹn ni o see. Ẹranko-to-pada-dejo naa ni alafo-to-sọnu yẹn, láàárín ìnàkí ati eniyan. Fetisilẹ, Kiyesi bayii, ẹranko-to-pada-dejo, kii se ẹda afàyàfà tẹlẹ. O jẹ alarekereke julọ ninu gbogbo ẹranko igbẹ.
Bayii, mo lọ wa awọn iwe atumọ ede loni lati ibi gbogbo, lati wadi ohun ti arekereke tumọ si. O tumọ si “lati jafara, kun fun ọgbọn àlùmọ̀kọ́rọ́yí” Itumọ ti o si dara julọ jẹ ti ọrọ Heberu “Mahah”! Itumọ rẹ si ni: “Nini ìmọ̀ tootọ nipa awọn ilana iye”.

Bayi ẹjẹ ki a kiyesi eleyi fun isẹju diẹ. O jafafa, o ni ọgbọn alumọkọrọyi, sibẹ a pee ni “ejo” Sugbọn ranti pe oun ni o jafafa julọ ninu ohun gbogbo ti o wa, oun ni o si sunmọ eniyan julọ ninu gbogbo ẹranko aye: O sunmọ eniyan pẹkipẹki, kii se ẹda ti o n fàyàfà. Ẹ̀gún naa lo sọ ọ di afaya-wọ-nilẹ-kiri. Bibeli wi pe, oun ni o lẹwa julọ.
Ègún naa papa ko tilẹ gba gbogbo ẹwa rẹ kuro tan. Sibẹ, gbogbo awọn awọ ejo si lẹwa, ati irin ọla rẹ, ati ọgbọn arekereke rẹ. Ègún naa gan aa ko gba gbogbo rẹ kuro tan. Sugbọn ranti, Ọlọrun sọ fun un pe, awọn ẹsẹ̀ ẹ rẹ̀ yoo parẹ, yoo si maa fi aya fa kiri. O ko si lee ri egungun kankan ninu ejo ti o farajọ ti eniyan. Idi si niyi ti imọ ijinlẹ fi wáa tì, sugbọn oun ni yii.

Ọlọrun ti paámọ́ kuro loju awọn ọlọgbọn ati amoye, o si seleri lati fihan fun awọn ọmọ Ọlọrun. Ni opin aye, nigba ti a oo fi awọn ọmọ Ọlọrun han fayeri. Nigba ti, “awọn ọmọ Ọlọrun yọ̀, ani saaju ipilẹsẹ aye”. Nigba ti ifihan nla nipa 'Ẹniti-Ọlọrun-I-se', ati awọn nkan bẹẹ yoo di mimọn ni igbẹhin aye. Oun yoo fi nkan wọnyi han fayeri nipasẹ awọn ọmọ Ọlọrun. Ẹ mọn wi pe, Iwe Mimọ ni eyi. Awa si ni yii.
Idi niyii ti Ọlọrun fi nsi nkan wọnyi paya fun wa. Ọlọrun n mu awọn Ọmọ Rẹ wa si ifihan-fayeri. Ọlọrun n kọja gbogbo imọ ati oye eniyan, O n kọja si inu awọn isipaya ti Ẹmi, o si n mu wọn sọkalẹ wa. A ko ha ti ka a ninu Bibeli yii, “Eyi yi ni fun ẹni ti o ni Ọgbọn?” Kii se ohun kan ti o kọ́, ninu ile ẹkọ Bibeli, sugbọn ohun ti o wu Ọlọrun lati fifun un. Awọn ọmọ Ọlọrun ti a fihan faye ri.

Eyi ni ẹranko-to-pada-dejo naa, eyi ni ohun ti o jẹ tẹlẹ, mo fẹẹ se apejuwe rẹ fun ọ. A ti bẹrẹ lati légbélègbé, de ọ̀pọ̀lọ́, siwaju ati siwaju titi ti a oo fi kan ọ̀bọ, titi de ìnàkí. Ati lati ìnàkí, lẹẹkan naa, a ti ìnàkí bọ si eniyan, a si beere wi pe, bawo lo se jẹ? 'O dara,' Imọ ijinlẹ wi pe, “ẹ duro na! a ko lee pa eniyan ati ọbọ papọ mọn ìnàkí, ko lee seese lati mu eniyan ati ẹranko bimọ. Ẹjẹ wọn ko ni papọ. Ẹjẹ tirẹ gẹgẹbi eniyan yatọ patapata si ẹjẹ ẹranko gbogbo. Ẹjẹ kan wa ni alafo yẹn, wọn ko si lee ri ẹranko naa. Ah! Halleluya: Mo kunfun ayọ nisisiyi.

Kiyesii. Kin ni? Ọlọrun fi pamọ fun wọn. Ko si egungun kan ninu ejo to farajọ egungun eniyan. Ọlọrun mu ki o jinna réré sii to bẹẹ ti awọn ọlọgbọn aye ko lee wa a ri. Emi yoo fi han ọ, ibi ti ọlọgbọn aye yẹn ti wa, ati ibi ti o wa. Se o ri i, ko lee wa eleyi ri. O ni lati wa nipa ifihan. “Iwọ ni Kristi naa Ọmọ Ọlọrun. Lori apata yii, Emi yoo kọ Ijọ Mi; ẹnu ọna isa oku ki yoo bori Rẹ”, Ifihan Ẹmi.
Bawo ni Abẹli se mọn lati fi ọdọ-aguntan rubọ, dipo Kaini ti o fi awọn eso igi rubọ. Nipa isipaya Ẹmi ni a fi han fun un. O ko lee rii gba ni ile ẹkọ Bibeli. Oko lee gba nipasẹ Ijọ-ẹlẹkọ-adamọ. Iwọ yoo gba lati Ọrun.

Bayi, kiyesi ẹranko-to-pada-dejo nigba naa, ni ibẹrẹ. Jẹ ki a ya aworan-an rẹ. Ẹni to tobi, to si sigbọnlẹ ni. O wa laaarin ìnàkí ati eniyan. Esu, Lusiferi si mọn pe ẹjẹ ẹranko-to-pada-dejo nikan ni o lee dapọ mọn ẹjẹ eniyan lati dọmọ, oun nikan ni oun lee lo. Ko lee sisẹ pẹlu ìnàkí, ẹjẹ ìnàkí ko ni sisẹ naa. Ko lee sisẹ pẹlu awọn miiran. Ko lee sisẹ pẹlu agutan. Ko lee sise pẹlu ẹsin, ko lee mu awọn ẹranko to ku lo. Ẹranko topada-dejo yii nikan lo lee lo.
Jẹ ki a woo bayi, ki a wo o bi o se ri loju. O jẹ ẹda kan to tobi to si sigbọnle. Omiiran isẹnbaye ni. Nibẹ ni wọn ti ri awọn egungun nla wọnyi, emi yoo si fi eyi han fun ọ ninu Bibeli. Bayi, kiyesii finifini, O dara. Ẹda nla yii. Ẹ jẹ ki a sọ pe, o ga bi ẹsẹ bata mẹwa, awọn ejika to tobi. O ri bi eniyan gẹlẹ.

O lee mu ki awọn ẹranko gun ẹranko miiran, ki o si bi awọn ẹranko. Bi awọn ẹranko ti ndapọ, wọn n ga si, titi ti o fi de ipele ti eniyan. Sugbọn, alafo to wa laaarin eniyan ati awọn ẹranko iyoku, a ti ge e kuro. Awa melo la mọn pe imọ ijinlẹ ko lee ri alafo to sọnu naa? Gbogbo yin lo mọn iyẹn. Kin ni idi i rẹ? Ẹranko-to-pada-dejo yẹn niyii.
Ẹda giga titobi ni. Esu wa sọkalẹ wa si ibẹ, o wipe, mo lee fun un ni imisi“, Nigba ti o ba n wo obinrin ati ise obinrin, ranti pe, esu ni o misi ọ (ti obirin naa kii sii se iyawo rẹ.) Kiyesii bayi, esu wa o si bọsi inu ẹranko-to-pada-dejo. O si wa ba Eefa ninu ọgba Edẹni, ti o wa ni ihoho, o si baa sọrọ nipa eso ti o wa laarin. Aarin jasi agbedemeji ati bẹẹbẹẹ lọ, oye ọ; ni apejọpọ onirun-un-ru eniyan. O si wi pe, “O dun gan an. O dara lati woo”.

Kin ni o se? O bẹrẹ lati ma ba eefa sere ifẹ, o si baa sepọ gẹgẹbi ọkọ. Obinrin naa si ri I wi pe o dun, nitori naa o lọ sọ fun ọkọ rẹ, sugbọn o ti loyun lati ọwọ esu. O si bi ọmọkunrin rẹ, akọbi, ti orukọ rẹ njẹ Kaini, tii se ọmọ satani.
Bayii, iwọ sọ wi pe, “Ko ri bẹẹ” O dara, a o se awari rẹ bi o ba ri bẹẹ, tabi ko ri bẹẹ “Emi yoo si fi ọta saarin iru rẹ, ati iru ẹranko-to-pada-dejo” Kinla? 'Iru ẹranko-to-pada-dejo!' O ni irú kan, Obirin naa si ni irú kan. Iru Obinrin naa, yoo fọ ori rẹ, iwọ yoo si pá ni gìgísẹ̀ rẹ̀“ Ipalara yi tumọ si 'ki a se Etutu'. Eyi yi ni irú ẹranko-to-pada-dejo. Si kiyesi, awọn ọkunrin meji yi jade wa. Bayi, ẹranko-to-pada-dejo yii, bi o se duro nibẹ, ẹda to tobi bi omiiran yii. O wa ni inaduro, O si jẹbi pe o se pansaga pẹlu iyawo Adamu. Nibo ni ẹsẹ pọ si loni? Kin ni o sọ nkan da bi o ti ri loni? Bayi, dajudaju, ohun ti mo nsọ ti ye ọ.

Nibẹ ni a si rii. Nigba ti eyi sẹlẹ, Ọlọrun bẹrẹ sii pe Adamu ati Eefa. Ọkunrin na si dahun pe, “Emi wa ni ihoho”. Ọlọrun wi pe, “Ta lo sọ fun ọ pe o wa ni ihoho?” Nigba naa wọn bẹrẹ sii ti ẹbi si ara wọn bi awọn ologun ti maa nse. O wipe, “Obinrin ti o fifun mi, Oun lo see. Oun lo fi lọ mi.” Se obinrin wi pe “Ẹranko-to-pada-dejo lo fun mi ni apulu jẹ?” Hówù! Oniwaasu! ki i se bẹẹ lo se wi. Obinrin na wi pe “Ẹranko-to-pada-dejo lo tan mi” Njẹ o mọn ohun ti titanjẹ ti Eefa sọ yii tumọn si? O tumọn si, “Lati famọra titi ti o fi sere ifẹ”. O jasi, “o dibajẹ rẹ” Esu ko fun un ni apulu jẹ. “Ẹranko-to-pada-dejo ti dibajẹ ẹ mi”. Nigba naa ni ègún ni de.

Ọlọrun wi pe “Nitori pe iwọ feti si Ẹranko-to-pada-dejo dipo ọkọ ọ rẹ, iwọ mu iye kuro laye. Iwọ yoo sọ ibanujẹ rẹ di pupọ ati iloyun rẹ yoo wa fun ọkọ ọ rẹ,” ati bẹẹ bẹẹ lọ. “Nitoriti iwọ fetisi aya a rẹ, dipo Mi, inu ilẹ ni Mo ti mu ọ jade (Ẹda Ọlọrun to ga julọ), iwọ yoo pada di erupẹ.” “Ati iwọ ẹranko-to-pada-dejo, nitori iwọ se eyi, a ge awọn ẹsẹ̀ rẹ kuro. Aya rẹ ni iwọ yoo maa fi wọ́, ni gbogbo ọjọ aye e rẹ. A o si korira a rẹ, Erupẹ ilẹ ni yoo si jẹ onjẹ ẹ rẹ”. Ẹ rii bayi, Alafo to sọnu yẹn niyẹn.

Bayi, a ri Kaini. Ẹ jẹ ki a kiyesi awọn iwa ẹda a rẹ. Wo Kaini. Kin ni o jẹ? O jẹ olókòwò to jafafa. O n dako, o jafafa, o gbọn pupọ, o kun fun ẹ̀sìn pupọ. Kiyesi awọn akayẹ ẹ rẹ bayi. Sa a ba mi kalọ fun isẹju diẹ si. Kaini niyi. O mọn nipa iwa rere. O fẹran ile isin. O kọ ile Ijọsin fun rara rẹ̀, o si mu ọrẹ wa. O se pẹpẹ ijọsin. Ó kó òdòdó sorii pẹpẹ rẹ. O si wi pe, “Se O rii Oluwa, emi mọn pe a jẹ eso apulu, ohun to fa a niyẹn” Ara awọn iru u rẹ si ni ero kan naa sibẹ. O fihan ibi ti o ti wa.

O ko apulu rẹ wa lati oko, o ko si ori pẹpẹ. O si wi pe, “eyi yoo se etutu”.
Ọlọrun wi pe, “kii se apulu”
Sugbọn, nipa ifihan tẹ̀mí, Abeli mọn wi pe, ẹjẹ ni. Nitorina, O mu ọdọ-aguntan wa, o ge ọrun rẹ titi o fi ku. Ọlọrun si wi pe, “Bẹẹ ni, ohun to fa isubu ni yẹn. Ẹjẹ ni”. Iwọ mọn ẹjẹ ti mo nsọrọ nipa rẹ. O dara Ẹjẹ lo fa isubu. Kiyesi bayi.

Nigba ti Kaini rii wi pe Ọlọrun ti tẹwọ gba 'gbara yilẹ mimọ', arakunrin rẹ ati pe isẹ amin ati isẹ iyanu n sẹlẹ pẹlu rẹ, o se ilara rẹ. O wi pe, “A oo fopin si ohun yii” bayii wo awọn arakunrin rẹ, wo awọn ọmọ rẹ titi di oni. 'Mo jafafa julọ' Nitori naa, inu bii. Nibo ni ibinu ti wa? Se o le sọ pe ibinu.... O pa arakunrin rẹ. Apaniyan ni. Se iwọ lee pe Ọlọrun ni apaniyan?
Adamu si jẹ ọmọ Ọlọrun. Bibeli wipe “Adamu si jẹ ọmọ Ọlọrun” Ìbẹ̀rẹ̀ tí ó mọ́n yẹn. Adamu jẹ ọmọ Ọlọrun. Owu yẹn, ilara, ibinu, gbogbo rẹ ko lee jade lati orisun Mimọ ni. O ni lati wa lati ibomiran. O si wa nipasẹ satani ti i se apaniyan lati ibẹrẹ. Bibeli wi pe o jẹ opurọ ati apaniyan lati ibẹrẹ“ Oun si ni yẹn. O pa arakunrin rẹ.
Eyi si jẹ apẹẹrẹ iku Kristi. Lati inu iyẹn, O gbe Sẹẹti dide lati gba ipo rẹ. Iku, isinku ati ajinde Kristi.

Si kiyesi, nibi yii ni awọn òmìrán yin ti wa. Kaini si lọ si ilẹ Nodu. Bi baba rẹ ba jẹ ọkunrin omiran giga bawo ni Kaini yoo se ri? Bii baba rẹ. O lọ si ilẹ Nodu, o si fẹ ọkan lara awọn arabinrin rẹ. Ohun kan soso ti o lee se niyẹn. Ko si obinrin miiran ti o lee fẹ bikose, ọmọ Eefa. Itan sọ pe, wọn bi aadọrin ọkunrin ati obinrin. Bi ko ba si obinrin ninu awọn ọmọ Eefa,..... Bibeli kii se akọsilẹ ọmọbinrin nigba ti a ba bi wọn, kiki ọkunrin. Bi ko ba si si obinrin miiran lẹyin Eefa, nigba ti Eefa ku, ẹda eniyan iba ti dopin. Eefa nilati bi awọn ọmọbinrin. Kaini si fẹ ọkan lara awọn arabinrin rẹ.
O lọ si ilẹ Nodu, o si fẹ iyawo rẹ. Nigba ti o si gbe e niyawo nibẹ ni awọn omiran nla yẹn, tii se awọn ọmọkunrin Ọlọrun ti wọn subu; wọn wa ni pase baba wọn, esu, nipasẹ Kaini. Alafo to sọnu naa niyẹn.

Ka iroyin kikun ni...
Irú Ẹranko-tó-Padà-Dejò.



Ifiranṣẹ ibudo...Yan ede rẹ ki o gba awọn ifiranṣẹ ọfẹ lati ọdọ Arákùnrin Branham.


Ohun ijinlẹ Kristi.

Wẹẹbu iwe iroyin Gẹẹsi.

Iwe Ifihan jara.

 

Ọlọrun ati Imọ Atọka.
- Archaeology.

Igbasoke n bọ.

 

Awọn ẹkọ akọkọ
ti ifiranṣẹ naa.

Awọn ti o dara iroyin.
Jesu ku fun ese re.

Iribomi Omi.

 

Awọsanma eleri nla.

Ọwọn ti ina.

Ogo Shekinah ti Ọlọrun.

Ibojì ti ṣofo.
O ti jinde.

Ọlọrun salaye.

Awọn ìgbà ijọ meje.

Awọn edidi meje.

Ọlọrun ati Itan.
jara Atọka - Dáníẹ́lì.

Kristiẹni ije jara.
Ìgbéyàwó Àti Ìkọ̀sílẹ̀.
Akojọ Ifiranṣẹ.

Opin akoko jara.

Ngbe ọrọ jara.

Keresimesi jara.

Iku. Ohun ti nigbana?

Orúkọ Ọlọrun.

Ọkọ Noa.

 

Ẹṣẹ Atilẹba.
Je o ẹya apulu?

Adaparọ.
Awọn orisun - Babeli.

Ọlọrun ati Imọ.
Dainoso Adaparọ.

Archaeology.
Sodomu ati Gomorra.

  Iwe-mimọ sọ...

Ìwà obinrin alágbèrè nìyí: bí ó bá ṣe àgbèrè tán, á ṣojú fúrú, á ní “N kò ṣe àìdára kankan.”

ÌWÉ ÒWE 30:20


Bi jijẹ apulu
ba jẹ ki awọn
obinrin mọn pe
wọn wa ni ihoho,
ẹ jẹ ki a
tun fun wọn
ni apulu lẹẹkansi.


Tẹ aworan kan lati ṣe igbasilẹ aworan iwọn ni kikun tabi PDF.


Acts of the Prophet

(PDF Gẹẹsi)
 

The Pillar of Fire.

(PDF Gẹẹsi)

God, Hidden and
Revealed in simplicity.

(PDF Gẹẹsi)

Ìgbéyàwó Àti Ìkọ̀sílẹ̀.

(PDF)

William Branham
Life Story.

(PDF Gẹẹsi)

How the Angel came
to me.

(PDF Gẹẹsi)