Ìgbàsókè Naa.
<< išaaju
itele >>
Ìgbàsókè Naa.
William Branham.Lati... Ìgbàsókè Naa.
Orin Dafidi 27:4-5,
4 Ohun kan ni emi ntọrọ lọdọ OLUWA, oun naa ni emi yoo maa wa kiri; ki emi ki o lee maa gbe inu ile OLUWA ni ọjọ aye mi gbogbo, ki emi ki o le maa wo ẹwà OLUWA, ki emi ki o si le maa beere ni tempili Rẹ.
5 Nitori ni igba ipọnju, Oun yoo pa mi mọ ninu àgọ́: ati ni ibi ìkọ̀ọ̀kọ̀ àgọ́ Rẹ ni Oun yoo pa mi mọ; yoo si gbe mi ka ori àpáta.Bayi, Ọlọrun ní ọna ti O maa n gba se nkan, kii sii yi ilana Rẹ pada. Ko yi nkan Rẹ pada ri.... Ọlọrun ti kii yipada ni. Ni Amosi 3:7 O sọ pe Oun ki yoo se ohunkohun lori ilẹ aye ayafi ti O ba kọkọ fi han fun awọn iransẹ Rẹ̀, awọn wolii. Bi o si se daju pe O se ileri Rẹ, yoo se e.
Bayi, a ti la awọn igba ijọ kọja, sugbọn a se ileri fun wa pe ni ikẹyin ọjọ, ni ibamu pẹlu Malaki 4, wipe wolii kan yoo tun pada wa si aye. Bẹẹni! Ẹ kiyesi iwa isẹda rẹ̀ ati ohun ti yoo jẹ. Ọlọrun lo ẹmi yẹn ni igba marun: akọkọ ninu Elijah, ninu Elisa, ati Johannu Onitẹbọmi, o pe ijọ jade, ati iyoku awọn Juu; igba marun, oore-ofẹ, J - e - s - u, i - g - b - a - g - b - ọ, o si jẹ nọmba oore-ofẹ. Se ẹ rii? O dara.
Ẹ ranti bayi, a se ileri isẹ-ohun-Ọlọrun naa. Nigbati awọn ijọ si ti da gbogbo awọn ijinlẹ wọnyi ru mo ara wọn loju lati ọwọ awọn oniwaasu, yoo gba wolii kan taara lati ọdọ Ọlọrun wa lati fi i han. Ohun ti O si se ileri lati se gan-an niyẹn. Se ẹ rii?
Ẹ ranti bayi, Ọrọ Oluwa maa n tọ wolii wa, ki i se ẹlẹkọ ẹsin, sugbọn wolii. O jẹ olufihan Ọrọ Ọlọrun. Ko lee sọ ohunkohun; ko lee sọ ero ti ara rẹ; kiki ohun ti Ọlọrun ba fihan nikan ni o lee sọ. Ti o fi kan wolii Balaamu paapaa, nigbati o gbiyanju lati ta ẹ̀tọ́ rẹ; o ni, “Bawo ni wolii kan se le sọ ohunkohun bikose ohun ti Ọlọrun fi si ẹnu rẹ̀? Ohun ti Ọlọrun n se ni, o kò si lee sọ ohun miiran. A bi ọ bẹẹ ni. Ko ju pe ẹ lee....Ti o ba le sọ pe, “N ko le la oju mi,” nigbati o si n wò. Se ẹ rii? O le se e. O ko lee maa nọ̀gà nigbati o lee riran. Se ẹ rii? O ko lee jẹ́ aja nigbati o jẹ́ eniyan. Se ẹ rii? A kan da ọ bẹẹ ni, Ọlọrun si nilati, nigbagbogbo... ni awọn iran nipasẹ Isaiah, Jeremiah, ati gbogbo... Elijah, ati awọn iran ti o ti kọja lọ, nigbati awọn ẹgbẹ oniwaasu ti da gbogbo nkan ru, Oun yoo ran wolii, yoo si gbée dide lati ibiti ẹnikẹni ko fojú si. Ko ni darapọ mọ ẹgbẹ wọn kankan, yoo si sọ Ọrọ Rẹ̀, a o si pee kuro loju agbo, awọn ẹni otitọ Ọlọrun ti o yigbi. Ati nigbagbogbo o maa n jẹ.... Bi ẹ se lee mọ̀ ọ́, O sọ pe, “Ti ẹnikan ba wà laarin yin ti o jẹ ẹni ẹmi tabi wolii....”
Bayi, wolii.... Nkankan wa ti a n pe ni ẹbun isọtẹlẹ ninu ijọ, sugbọn a maa n yan wolii tẹlẹ ni, a si maa n mọ̀ ọ́ tẹlẹ fun wakati yẹn. Se ẹ rii? Bẹẹni, sa.
Bayi, ti isọtẹlẹ ba jade lọ, ẹni meji tabi mẹta nilati joko ki wọn si yẹ̀ ẹ́ wò boya o tọnà tabi bẹẹkọ ki ijọ to lee gba a. Sugbọn kò si ẹnikan ti a gbe siwaju wolii, nitori oun ni Ọrọ Ọlọrun dajudaju. Oun ni Ọrọ yẹn ni ìgbà tirẹ. O rii ti Olorun n fi han....
Bayi, ti Ọlọrun ba ti se ileri lati fi iyẹn ransẹ si wa ni ikẹyin ọjọ, lati mu iyawo jade kuro ninu rẹ́dẹrẹ̀dẹ ẹ̀sìn, ọna kansoso ti a le gba se e.Ko lee see sese laelae.... ijọ ko lee gba Kristi. Awọn ijọ Afede-ajeji-sẹri-Ẹmi-Mimọ, a ko lee mu ki isẹ-ohun-Ọlọrun yii tẹsiwaju ni ipo ti ijọ wa loni. Bawo ni a se fẹ mu igba ikẹyin jade ni ipo ti wọn wa loni, nigbati gbogbo wọn lodi si ara wọn, ati ohun gbogbo miiran, ninu isẹ́ ìsìn? Oluwa saanu. Rẹ́dẹrẹ̀dẹ ni. O ti di ijọ ẹlẹkọ adamọ. Ati nigbakuugba, mo beere lọwọ oǹkọ̀tàn yoowu lati sọ ti ko ba ri bẹẹ. Ni gbogbo igba ti isẹ-ohun Ọlọrun kan ba jade lọ lori ilẹ aye, ti wọn ba si ti fi ọgbọn eniyan gbee kalẹ, yoo kú sibẹ ni. Ijọ Afede-ajejisẹri-Ẹmi-Mimọ si ti se nkan kanna bi gbogbo wọn ti se - ijọ Afede-ajeji-sẹri-Ẹmi-Mimọ ti o jade.
Ẹyin ijọ Ipejọpọ ti Ọlọrun, nigbati awọn baba nla yin ati awọn iya yin jade kuro ninu awọn ijọ ti a fi ọgbọn eniyan gbẹ kalẹ nibi Igbimọ Gbogboogbò atijọ nni, ti wọn pariwo, ti wọn si yin Ọlọrun, ti wọn si sọrọ tako awọn nkan; ẹ si pada bii aja sinu èébì rẹ̀, ati bii ẹlẹdẹ sinu ẹrọ̀fọ̀ rẹ̀, ẹ si se nkan kannaa ti wọn se; ati ni bayi, ẹ kun fun ẹsin lasan debi wipe ẹ sé ọkàn aanu yin pa, ẹnikan si nilati ni iwe idapọ ki o to lee ni idapọ pẹlu yin.
Ati ẹyin ti o gbagbọ wipe ẹni kan ni o wa ninu ọlọrun, Ọlọrun fun yin ni isẹ-ohun-Ọlọrun bi iyẹn, dipo ki ẹ rẹ ara yin silẹ, ki ẹ si tẹsiwaju, nse ni ẹ sọ ẹgbẹ yin di ijọ ẹlẹkọ adamọ. Nibo ni gbogbo yin wa bayi? Ninu òsùnwọ̀n kannaa. Bẹẹ gan ni! Ẹmi Ọlọrun si ntẹsiwaju. “Emi Oluwa yoo gbin; Emi yoo si bomirin tọsan toru, ki ẹnikẹni ma baa...” O yan awọn nkan wọnyi lati wa, O si nilati fi eyi ransẹ.Ohun àkọ́kọ́ ti yoo sẹlẹ nigbati Ó ba nsọkalẹ lati ọrun wa ni wipe, ariwo kan yoo wà! Ki ni? Isẹ-ohun-Ọlọrun lati kó awọn eniyan jọ ni. Isẹ-ohun-Ọlọrun kan yoo kọ́kọ́ jade lọ na. Bayi, “Akoko lati tun atupa se. Ẹ dide ki ẹ tun atupa yin se.” Ìsọ́ wo niyẹn? Ikeje, kii se ikẹfa, ikeje ni. “Woo, ọkọ iyawo n bọ. Ẹ dide ki ẹ tun atupa yin se.” Wọn si se bẹẹ. Awọn kan ninu wọn si rii wipe awọn kò tilẹ ni ororo kankan ninu atupa wọn. Se ẹ rii? Sugbọn o jẹ àkókò lati tun atupa se. O jẹ akoko Malaki 4, ohun ti O... O jẹ Luku 17. O jẹ Isaiah... Gbogbo awọn asọtẹlẹ yẹn ti o lee duro daradara ninu Iwe Mimọ loni, a rii ti o wa laaye nibẹyẹn. Ko si....
Se ẹ ri awọn nkan wọnyi ti o nsẹlẹ, arakunrin mi ọwọn, arabinrin, ti Ọlọrun ọrun si mọ̀ wipe mo lee ku ni ori pẹpẹ yii bayi, o kàn nilati rìn kaakiri fun igba diẹ. O kan jẹ... O lagbara, nigbati ẹ ri Ọlọrun sọkalẹ wa lati ọrun, ti O si duro niwaju awọn eniyan, ti O si duro sibẹ, ti O fi ara Rẹ han bi O se maa n se. Otitọ si niyẹ̣n, pẹlu Bibeli yii ni sisi. Se ẹ rii? A ti wa nihin!
Ilana ijọ ẹlẹkọ adamọ ti kú. Ó ti lọ. Ko lee ji dide mọ laelae. A o fi ina sun-un. Ohun ti a maa n se si eepo ni oko niyẹn. Ẹ sa kuro ninu rẹ. Ẹ wọ inu Kristi. Mase sọ pe, “Mo je ọmọ ijọ Eleto!”; “Mo jẹ ọmọ ijọ Onitẹbọmi”; “Mo jẹ ọmọ ijọ Afede-ajeji-sẹri-Ẹmi-Mimọ!” Iwọ wọ inu Kristi. Ti o ba si wà ninu Kristi, kò si ọrọ kan ti a kọ sihin ti o kò ni gbagbọ. N ko bikita ohun ti ẹnikẹni sọ. Ọlọrun yoo si jẹ ki nkan yẹn farahan, nitori o.... Nigbati o tu Ẹmi dà si ori Ọrọ, ki lo sẹlẹ? O dabi igba ti eniyan da omi sori irugbin kan ni. Yoo yè, yoo si mu eso iru ara rẹ jade.O sọ pe, “Mo ni baptisimu Ẹmi Mimọ.” Iyẹn ko sọ pe a ti gba ọ la, ko tilẹ jọọ ́ rara. Wo ibi, o jẹ ẹda alara mẹta. O jẹ.... Ninu ẹni kekere yii ni ọkàn wà; ekeji ni ẹ̀mí, ẹkẹta ni ara. Bayi, o ní awọn ònmọ̀ marun ninu ara yii lati le se pẹlu ilé rẹ ninu aye. Wọn kò ni nkankan se pẹlu awọn ti o kù. O ni ònmọ̀ marun ti ẹ̀mí naa nibi, ìfẹ́ ati ẹ̀rí ọkan ati bẹẹ bẹẹ lọ bẹyẹn. Sugbọn ninu ibi yii ni o n gbe. Ohun ti o jẹ niyẹn.
Se Jesu ko sọ wipe òjò n rọ sori olododo ati alaisododo. Fi èpò si ibẹyẹn, ati alikama si ibẹyẹn, ki o si da omi le wọn lori, ki o si fi wọn si ibi ajílẹ̀ ati awọn nkan bẹyẹn, njẹ awọn mejeeji ki yoo yè nipa omi kannaa bi? Dajudaju! O dara, ki ni? Ọ̀kan ninu wọn yoo so èpò, nitori gbogbo ohun ti ó jẹ niyẹn. Epo yoo gbe ọwọ rẹ̀ soke yoo si pariwo gẹgẹbi alikama naa se se.Njẹ Bibeli ko ha sọ wipe ni ikẹyin ọjọ, awọn èké Kristi yoo wà, kii se awọn eke Jesu bayi, awọn eke Kristi ni, awọn ẹni-ami-ororo, ti a ta ami ororo eke si ni ti Ọrọ naa. Ami-ororo ijọ ẹlẹkọ adamọ, sugbọn kii se si Ọrọ naa, nitori Ọrọ naa yoo jẹri ara Rẹ. Kò nilo ohun miiran; yoo jẹri ara Rẹ. Awọn ẹni-ami-ororo eke yoo si wa. Ẹ nì ohùn-ti-a-gbasilẹ mi lori iyẹn. Iyẹn si ni ami-ororo.... Ah, ti o bá pe ọ̀kan ti o si wipe, “A, se Jesu kan ni ọ?”, “Ah, dajudaju bẹẹkọ!” Wọn ko ni gba iyẹn. Sugbọn nigbati o ba di, “Ah, ogo, mo ni ami-ororo....” Ami-ororo tootọ si ni.
Ẹ ranti, Kaiafa naa ni i, o si sọtẹlẹ. Bẹẹ naa ni Balamu ni i, o si sọtẹlẹ, sugbọn iyẹn ko ni nkankan se pẹlu inu yii. Bikose wipe iyẹn bá jẹ́ iru Ọlọrun, iru Rẹ lati ibẹrẹ, ti a yan tẹlẹ, o ti tan niyẹn. N ko bikita bi o se pariwo to, bi o se fede fọ to, sare, pariwo; iyẹn ko ni nkankan se pẹlu rẹ̀. Èpò lee pariwo gẹgẹbi awọn to kù. Mo ti ri awọn keferi ti wọn dide, pariwo, fedefọ, ti wọn si n fi agbari eniyan mu ẹjẹ, ti wọn si n pe esu. Se ẹ rii? Nitorinaa, ẹ kò fẹ ọkankan ninu awọn ìjìlára ati awọn nkan yẹn; ẹ gbagbe rẹ. Ọkàn rẹ ninu Ọrọ yẹn ni, Kristi si niyẹn. Ẹ mu u wa sibẹ, ki ẹ si wo bi yoo se fi ara rẹ han, gẹgẹbi yoo se si ara rẹ̀ bi awọn iru miiran, ti yoo si sọ ara rẹ di mimọ fun iran ti o n gbe inu rẹ.
Luther ko lee mu ohun kan wa bikose isẹpẹ igi. Awọn ti o kù wọnyi lee mu awọn nkan ti o kù wá. A ti wà ni igba alikama bayi. Awọn atẹle Luther, ojulowo ọmọ ijọ Luther nilati bi ojulowo ọmọ ijọ Luther. Ojulowo ọmọ ijọ Afede-ajeji-sẹri-Ẹmi-Mimọ nilati bi ojulowo ọmọ-ijọ Afede-ajeji-sẹri-Ẹmi-Mimọ. Ko ju bẹẹ lọ. Sugbọn a ti kọja àkókò yẹn bayi, a si n tẹsiwaju.
Njẹ ẹ mọ wipe ijọ Katoliiki bẹrẹ gẹgẹbi ijọ Afede-ajeji-sẹri-Ẹmi-Mimọ? Ti ijọ Afede-ajeji-sẹri-Ẹmi-Mimọ ba si wà fun ẹgbàá ọdun, yoo bajẹ ju bi ijọ Katoliiki se ri bayi lọ. Otitọ niyẹn! Mo n sọ iyẹn fun awọn arakunrin mi ati awọn arabinrin mi ti mo fẹran, Ọlọrun si mọ iyẹn. Sugbọn ẹ ranti, ẹyin ọ̀rẹ́, mo nilati pade yin nibi idajọ. Iyẹn si lee ma pẹ mọ. Mo nilati jẹri si ohun ti i se otitọ.
Nigbati mo ba lọ si ibi ipade ti mo si ngbadura fun awọn alaisan, iyẹn dara, sugbọn nigbati mo ba wà pẹlu isẹ-ohun-Ọlọrun.... Ti isẹ-ohun-Ọlọrun kan ba jade lọ, ti o bá jẹ́ isẹ-ohun-Ọlọrun tootọ, ti o ba jẹ isẹ-iyanu Ọlọrun nitootọ, ti o ba si duro si aarin ẹgbẹ ti a fi ọgbọn eniyan gbe kalẹ, ẹ mọ wipe ki i se ti Ọlọrun, nitori a ti sọ nkan yẹn na. Jesu jade lọ mu awọn alaisan lara da ki O baa le fa oju awọn eniyan mọra, lẹyinnaa isẹ-iransẹ iwaasu Rẹ̀. Otito niyẹn! Nkankan nilati wà ti Ọlọrun yoo fi saaju. Iwosan lati ọrun wa jẹ... awọn isẹ-iyanu bẹyẹn kan maa n fa oju awọn eniyan mọra ni. Kókó ibẹ gan-an ni isẹ-ohun-Ọlọrun. Iyẹn ni. Ohun ti o ti inu ọkàn wá ni. O ngbiyanju lati ri ojurere awọn eniyan naa, ki wọn baa lee joko feti si I. Se ẹ rii? Nitori awọn kan wà nibẹ ti a ti yan tẹlẹ si ìyè. Diẹ ninu awọn alikama naa bọ silẹ, awọn ẹyẹ si sa a jẹ. Awọn kan bọ si aarin ẹgun, awọn kan bọ si ilẹ ti a ti pèsè, ilẹ ti a ti pèsè silẹ, o si so èso.
Bayi, ohun àkọ́kọ́ ni didun - tabi ohun àkọ́kọ́ ni ìpè tabi ohun kan - ariwo kan, lẹyinna ohùn, lẹyinna ìpè. Ariwo, òjísẹ́ kan ti o n pèsè awọn eniyan silẹ. Ikeji ni ohùn ajinde. Ohùn kanna, oh̀un rara ni Johannu Mimọ 11:38 ati 44 ti o pe Lasaru jade kuro ninu iboji. O n ko iyawo jọ papọ, lẹyinnaa ajinde awọn oku (se ẹ rii?), lati ko wọn lọ soke pẹlu rẹ. Bayi, ẹ kiyesi awọn nkan mẹta ti o nsẹlẹ.
Kini ohun ti o kan? ìpè ni. Ohun kan - ariwo kan, ohùn kan, ìpè kan.Bayi, ohun kẹta ni ipe, eyiti a maa n fi pe awọn eniyan sibi àsẹ̀ ipe; iyẹn si ni yoo jẹ àsè ti iyawo, ase Ọdọ-aguntan pẹlu iyawo ni oju ọrun.
Se ẹ rii, ohun akọkọ ti o jade wa ni isẹ-iransẹ iwaasu Rẹ̀ lati pe iyawo jọ papọ. Ohun ti o tẹle e ni ajinde awọn iyawo ti o sùn, awọn ti o kú ni awọn iran ti o ti kọja. A ko wọn papọ, ati ipe, ase ni ọrun - ni ofuurufu. Eese, ohun ti yoo sẹlẹ niyẹn, ẹyin ọ̀rẹ́.
A ti wà ninu rẹ̀ bayi. Ohun kan ni, ijọ ti o jade nilati wà niwaju òòrùn lati pọn. Ẹ̀rọ ikore nla naa yoo wa laipẹ. Alikama naa ... a o fi ina sun poporo, sugbọn alikama ni a o ko sinu aka rẹ.Lati... Ìgbàsókè Naa.