Paripari.
<< išaaju
itele >>
A Fi Krístì Hàn Nínú Ọ̀rọ̀ Òun Fúnrarẹ̀.
William Branham.Ka iroyin kikun ni...
A Fi Krístì Hàn Nínú Ọ̀rọ̀ Òun Fúnrarẹ̀.Bayi n ó sọrọ lori akori: A Fi Krístì Hàn Nínú Ọ̀rọ̀ Òun Funra Rẹ - bi o se jẹ wipe ninu Awọn Ibukun Ori Oke, aworan Kristi duro sibẹ, o tayọ síta. Ibiti mo ti gbero akori yii niyẹn.
Bayi, Kristi ati Ọrọ naa, ọ̀kan ni wọ́n, se ẹ rii.
Wọn sọ pe, “Bawo ni Bibeli...?” Awọn eniyan n sọ.... Mo wà ninu ọ̀kọ̀ pẹlu ọkunrin kan laipẹ yii. Ó ni, “Ronu nipa rẹ̀. Awa ti a wà ni aye yii, bi a se ri, a kàn mọ̀, tabi a kàn lè sọ pe a gba wa la nipa awọn ìtàn asán Júù kan ti wọn pe ni Bibeli.”
Mo ni, “Alagba, emi ko mọ bi ẹ se so iyẹn, sugbọn emi kò gbagbọ wipe itan asan ti awọn Júù ni.” Mo ni....
Ó sọ pe, “O dara, ẹ ngbadura.... Kini ẹ ngbadura si? Mo beere fun nkan bayi-bayi ati awọn nkan kan, n ko ri i gba.”Mo sọ pe, “O si adura gba. A ko gbọdọ gbadura lati yi ọkàn Ọlọrun pada; a gbọdọ gbadura lati yi ọkan tiwa padà. Ọkàn Ọlọrun ko nilo a nyii pada, ẹ ò rii bi. Otitọ ni.” Mo ni, “Kii se ohun ti o gbadura fun....”
Mo mọ ọdọmọkunrin Katoliiki kan nigba kan ti o ni iwe adura, ti o n sọ adura fun iya rẹ lati wa laaye. O sì kú, o sì ju iwe adura naa sinu iná. Kò buru, se ẹ rii.... Emi ko gba ti iwe adura naa, sugbọn lọnakọna.... Se ẹ rii, ẹ hu ìwà òdì. Ẹ ngbiyanju lati sọ fun Ọlọrun ohun ti Ó yẹ ki Ó se. Adura gbọdọ jẹ, “Oluwa, yi mi pada ki n le ba Ọrọ Rẹ mu,” ki i se yipada.... Ki i se, “Jẹ ki n yi ọkan Rẹ pada; Iwọ yi ọkan mi pada. (Se ẹ rii?) Iwọ yi ọkan mi padà si ifẹ Rẹ, ifẹ Rẹ ni a si kọ sile ninu Iwe naa. Oluwa, mase jẹ ki n lọ ayafi ti O ba tó yi ọkan mi pada ki ó dabi Tirẹ. Lẹyin ti ọkan mi ba ti yipada ti o dabi Tirẹ, nigbanaa n o gba gbogbo ọrọ ti O kọ silẹ gbọ. O si sọ nibẹ wipe Iwọ yoo mu ki ohun gbogbo sisẹ papọ si rere fun awọn ti o fẹ Ọ, mo si fé Ọ, Oluwa. Gbogbo rẹ n sisẹ pọ si rere.”-----
Kiyesii. Bayi, a pada wa, a nilati ni ohun kan tabi omiran ti a di mu. Ohun kan nilati jẹ òpómúléró; iyẹn ni wipe, ó jẹ paripari. Olukuluku si nilati ni paripari tabi opin kan. Mo waasu lori rẹ nigba kan ni ọdun diẹ sẹyin, lori opin, ibi ti ọrọ pin si. Gẹgẹbi oludari ni ibi eré bọọlù, ti ó ba sọ wipe gbígbá ni, ohun ti o jẹ gan-an niyẹn. Ko si bi o se rii, oludari ti sọ wipe gbígbá ni.Iwọ sọ pe, “Ki i se gbigba. ̣Ohun yoowu to jẹ, nigbati o ba ti sọ pe, ”Gba a,“ bẹẹ ni, o pari niyẹn, ohun ti.... Òun ni ipari ọrọ.
Ina ti o ndari ọkọ naa jẹ paripari. Ti o ba sọ pe, “Maa lọ,” o le sọ pe, “O dara, mo nkanju, mo nilati....” Rara, rara, ó sọ pe, “Iwọ duro jẹẹ nigbati ẹnikeji yoo maa lọ,” se ẹ rii. Òun ni paripari.Bayi, paripari kan nilati wa fun ohun gbogbo ti a ba n se. Paripari kan nilati wa nigbati o ba n yan iyawo rẹ. Obinrin kan gbọdọ wa ti o nilati yan. Bayi, igba kan nilati wa ti iwọ yoo lọ ra ọkọ̀, iru paripari wo ni iwọ yo wo. Se yoo jẹ Ford, Chevy, Plymouth, ọkọ òkèèrè? Ohun yoowu to jẹ, o nilati ni paripari kan.
-----
O dara, olukuluku ijọ-adamọ ni o jẹ paripari fun awọn onigbagbọ rẹ. Sugbọn ni temi, ati awọn ti mo ni ireti pe mo ndari lọ si ọdọ Kristi - ati nipa Kristi - Bibeli ni paripari wa. Ko si.... Nitori Ọlọrun sọ pe, “Jẹ ki ọrọ gbogbo eniyan jẹ irọ, ki Temi jẹ otitọ.” Mo si gbagbọ wipe Bibeli ni paripari Ọlọrun. Ko si ohun ti ẹlomiran lee sọ, oun ni paripari.Bibeli ki i se iwe awọn ilana kan. Rara, sa! Ki i se iwe awọn ilana, tabi ìgbékalẹ̀ kan fun iwa omolúàbí. Bibeli ki i se iwe awọn ilana kan, ọpọlọpọ awọn ilana lo wà ati bẹẹ bẹẹ lọ. Rara, sa! Ki i se iwe awọn iwa omoluabi. Rara, sà, ko ri bẹẹ. Bẹẹni ki i kan se iwe itan lasan, tabi iwe ẹkọ nipa ẹ̀sìn, nitori o jẹ ifihan Jesu Kristi. Bayi, ti ẹ ba fẹ ka iyẹn - ẹyin ti ẹ ni iwe yin, ẹ se ami si i - iyẹn ni Ifihan 1:1-3. Bibeli jẹ ifihan Jesu Kristi.
-----
Bayi, kiyesi Bibeli yii. Awọn kan ninu wọn sọ wipe, “Ah, ko buru, o ti se eleyi, o ti se tọhun.” Sugbọn jẹ ki n sọ nkankan fun yin.... Ẹ jẹ ki a lọ sinu itan Bibeli fun isẹju kan ki a wo ibi ti o ti wa. Ogoji awọn onkọwe otootọ ni o kọ Ọ́. Ogoji awọn eniyan ni o kọ Bibeli laarin ẹgbàá ọdun o din irínwó ati ni ìgbà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ti wọn sọ àsọtẹ́lẹ̀ awọn isẹlẹ ti o se pataki julọ ti o tii sẹlẹ ri ninu itan agbaye, ati ni ọpọlọpo ìgbà, ni ọpọlọpọ ọdun ki o to sẹlẹ. Ko si si asise kan ninu gbogbo iwe mẹ́rìndínláàdọ́rin naa. Àkíìkà! Kò si ònkọ̀wé kan yatọ si Ọlọrun ti o lee pe bi èyínnì. Kò si ọrọ kan ti o tako omiran. Ẹ ranti, ẹgbàá ọdun o din irinwo si ara wọn, ni a fi kọ Bibeli - lati igba Mose titi di igba ikú Johannu ni erékùsù Pátmò, ẹgbàá ọdun o din irínwó - a si kọ lati ọwọ awọn akọwe mẹ́rìndínláàdọ́rin. Ọkan kò si mọ ekeji, wọn kò si ni I gẹgẹbi Ọrọ. Awọn miiran ninu wọn kò tilẹ fi igba kan ri Ọrọ naa rara. Sugbọn nigba ti wọn kọ Ọ́, ti a si loye wipe wọn je wolii, nigbati wọn wa ko awọn asọtẹlẹ wọn papọ, ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu wọn ba ekeji mu de oju àmì.-----
Bayi, ki a sọ pe fun apẹẹrẹ, lati.... Ti a ba lọ bayi ti a mu iwe ìsẹ̀gùn oyinbo mẹ́rìndínláàdọ́rin ti o nii se pẹlu ẹran ara, ti a kọ lati ọwọ ile-ẹ̀kọ́sẹ́ isegun oyinbo mẹ́rìndínláàdọ́rin ọtọọtọ, ọgọrun o le mẹ́rìndínlógún... tabi ẹgbàá ọdun o din irínwó si ara wọn? N ko mọ iru itẹsiwaju ti a o ba jade?Rara, ko si itẹsiwaju ninu iyẹn; sugbọn ko si ọrọ kan ninu Bibeli ti o tako ekeji. Ko si wolii kan ti o tako ekeji. Olukuluku wọn lo pe. Nigbati ọkan ba si wá ti o sọtẹlẹ, ti wolii tootọ nni si dide ti o pè é joko, nigbanaa a fi i han, se ẹ rii. Nitorinaa, Bibeli jẹ Ọrọ Ọlọrun si gbogbo onigbagbọ tootọ.
-----
Wọn yoo si rii ni ọjọ kan wipe awọn kò ri àádọjọ miliọnu ọdun imọle paapaa; wọn kan nyi kiri loju kan ni. Bẹẹ gan ni. Ẹ ó rii lọjọ kan nigba ti ẹ ba lọ si Ọrun, ẹ ko ni fo lọ si ibomiran kan; ibi yii gan naa lẹ si wà, ẹ kan wa ni ipele miiran ti o yara ju eleyi lọ ni. Awọn aworan n gba yàrá yii kọja bayi. Gbogbo àwọ̀ ẹ̀wù, asọ, ohunkohun ti ẹ wọ̀ sára jẹ ainipẹkun, o wà ninu akọsilẹ, o ndòòrì yi aye po ni. Gbogbo ìgbà ti o bá sẹ́jú rẹ, ó ti wà ninu akọsile. Kiyesii, tẹlifisan yoo fi idi eleyi mulẹ.-----
Bayi, kiyesii. Ko si si asise ẹyọkan ninu Iwe Mimọ. Jesu, Ọrọ Ọlọrun, n mọ èrò ti o wà ninu ọkàn. Ọrọ Ọlọrun lagbara, o sì mú ju.... Heberu 4:12: “Ọrọ Ọlọrun mu, o si lagbara ju ida oloju meji lọ, ani olùmọ̀ èrò ati ìmọ̀ inu,” se ẹ rii - o lọ taara si inu, o si n fa jade, o si loye. Kini liloye? “Sọ di mimọ, fihan sita.” Ohun ti Ọrọ Ọlọrun si maa nse niyẹn. Loni a sọ wipe, “Ijọ Katoliiki ni Ọrọ Ọlọrun - Onitẹbomi, Eleto, Afedefọ, àgọ́.” Iyẹn kuna. Ọrọ naa jẹ ifihan, Ọlọrun ti a fihan nipa Ọrọ!-----
O pe gan-an ni... Ọrọ Ọlọrun pe gan-an ni, ani Majẹmu Laelae ati Titun jẹ ilaji meji ati odidi kan. Bẹẹ ni. Majẹmu Laelae jẹ ilaji rẹ, Majẹmu Titun si jẹ ilaji rẹ. Mu wọn papọ, iwọ yoo ni gbogbo ifihan Jesu Kristi. Wolii niyẹn ti o n sọrọ, Oun si niyi gẹgẹbi eniyan, se ẹ rii; ilaji meji ati odidi kan.----
Ẹ ranti, Majẹmu Laelae kò pe lai sí Titun. Bẹẹni Titun ko lee pe lai sí ti Laelae. Idi niyẹn ti mo fi sọ pe, ilaji meji - odidi kan. Nitori wolii naa sọ pe, “Oun yoo wà nihin; Oun yoo wà nihin; Oun yoo wà nihin. Wọn ó se eleyi si I, wọn ó se eleyi si i.” Oun sì niyi. “O ti wà nibi; O ti wà nibi, O.... Wọn se eleyi si I, wọn si tun se eleyi si I.” Mo sẹ̀sẹ̀ waasu lori iyẹn ní alẹ ọjọ meloo kan sẹyin ni.Bayi, lati le kọ ẹ̀kọ́ ninu Iwe Mimọ - Pọọlu sọ fun Timoteu, “Se àsàrò ninu rẹ̀, maa fi ọna ẹ̀tọ́ pín Ọrọ Ọlọrun, eyi tii se otitọ.” Awọn “dandan gbọn” mẹta ni o wà ninu Iwe Mimọ. Ni lilo Ọrọ Ọlọrun, awọn nkan mẹta ni o kò gbọdọ se. Bayi, ẹ jẹ ki a yẹ awọn yẹn wò fun isẹju mewaa: Awọn nkan mẹta ti o kò gbọ́dọ̀ se. Ati nibi gbogbo ti ẹ ba wa ni orilẹ-ede yii, ẹ rii daju wipe ẹ fi eleyi si ọkan yin ti ẹ kò ba ni ohun ikọwe. Ẹ kò gbọ́dọ̀ se awọn nkan wọnyi. A maa n sọ fun yin ni gbogbo igba bi ẹ se gbọ́dọ̀ se; bayi, mo fẹ sọ fun yin ohun ti ẹ kò gbọ́dọ̀ se.
Bayi, ẹ kò gbọdọ si Ọrọ naa tumọ. O sọ pe, “O dara, mo gbagbọ wipe ó tumọ si eleyi. Kiki ohun ti o sọ ni ó tumọ si. Kò ni ògbufọ̀ kankan. Ẹ kò si gbọdọ si ọrọ naa gbe si ara wọn. Ẹ ko si gbọdọ yẹ Ọrọ naa kuro ni aaye Rẹ. Ti a ba si se ọkankan ninu awọn wọnyi, yoo da gbogbo Bibeli ru, yoo si sọ ọ di rudurudu.
Kiyesii. Lati si Jesu tumọ ní ìrí Ọlọrun ninu eniyan kan, iwọ yoo sọ Ọ di ọlọrun kan ninu mẹta. Lati si Jesu Kristi tumọ, tii se Ọrọ naa, iwọ yoo sọ Ọ di ọlọrun kan ninu mẹta. Tabi ki o sọ Ọ di ẹnikeji ninu jijẹ Ọlọrun. Ati lati se eleyi, iwọ yoo ba gbogbo Iwe Mimọ jẹ. O kò nii de ibi kankan. Nitorinaa, a kò gbọdọ si I tumọ. Ti o ba si sọ wipe ohun kan pato, o fi itumọ si I, o si sọ wipe ó wà fun akoko miiran tabi a ti lòó fun akoko miiran, o tun se itumọ odi naa niyẹn.
-----
Awọn dadan mẹta yi gbọdọ wa. A kò gbọdọ sii tumọ tabi sii gbe, sii tumọ tabi yẹẹ kuro. A gbọdọ paa mọ gẹgẹbi Ọlọrun ti sọ pe o ri gan-an. Loju awọn aye, Iwe adiitu ni. Awọn eniyan gbagbọ wipe Iwe adiitu kan lasan ni.Nigbakan mo n ba ọkunrin kan ti o gbajumọ gidigidi ni ilu yii sọrọ, ti o ni iduro Kristẹni nla ti o dara, o si sọ pe, “Mo gbiyanju lati ka iwe Ifihan lalẹ ọjọ kan.” O ni, “O nilati jẹ wipe Johannu jẹ obẹ ata ti o ta pupọ, o si bẹrẹ si ni la alakala.” Se ẹ rii, iwe adiitu, sugbọn...
Sugbọn fun onigbagbọ tootọ, o jẹ ifihan Ọlọrun ti a nfihan ninu iran ti a n gbe bayi.
Ó ni, “Awọn ọrọ Mi, ẹmi ati iye ni.” Jesu sọ bẹẹ. Ẹwẹ, “Ọrọ naa jẹ́ irugbin ti afurugbin kan gbin.” A mọ wipe otitọ niyẹn. Ó jẹ́ Ọlọrun ni ìrí Ọrọ, Oun funra Rẹ nikan ni o si lee tumọ rẹ. Òye eniyan ko lagbara to lati tumọ ohun ti o wà ninu ọkan Ọlọrun. Bawo ni inu ti o lopin se le tumọ inu ailọpin, nigbati a ko tilẹ le tumọ inu ara wa gan-an.Ẹ si kiyesii, Òun nikan ni o lee tumọ rẹ, Ó si ntumọ rẹ fun ẹni ti o ba wu U. Kò sọ wipe, “Awọn ẹni kíkú atijọ́ bi wọn se nlọ kaakiri aye ni igba atijọ ati ni orisirisi ọna.” Ọlọrun ni igba atijọ ati ni orisirisi ọna, fi ara Rẹ han fun awọn wolii Rẹ, se ẹ rii.
Ka iroyin kikun ni...
A Fi Krístì Hàn Nínú Ọ̀rọ̀ Òun Fúnrarẹ̀.