Rutu ara Moabu.

<< išaaju

itele >>

  Ngbe ọrọ jara.

Ìbátan Olùràpadà Náà.


William Branham.

Ka iroyin ni kikun ni...
Ìbátan Olùràpadà Náà.

Mo fẹ fun iwaasu kekere ti a o wa ni owurọ yii ni akọle kan bi mo ṣe nkọ ọ, ti mo si n gbiyanju lati mu igbagbọ nipa irapada kan wa fun un yin, niti ohun ti o jẹ ati bi a ti n gba a, mo fẹ mu akori yi wa fun un yin ti i ṣe; “Ibatan Olurapada Naa.”

Bayi, lati ra ohun kan pada ni lati mu un pada. Ohun kan ti o ti sọnu bii ki a fi nnkan sinu ile itaja ipasipaarọ kan. Iwọ si lọ lati ra a pada. O ra a pada pẹlu owo. O jẹ ohun ini rẹ, lẹhin ti o ti ra a pada. Ṣugbọn ofin ti Israeli ni pe o ni lati jẹ ibatan lati gba ohun ini kan ti o ti sọnu pada.

Itan wa bẹrẹ ni igba awọn alakoso Israẹli ti wọn jẹ adájọ́, lẹhin iku Joṣua. Lati le ri aworan ti o dara yi, iwọ ka ori marun tabi mẹfa akọkọ ti Iwe Samuẹli kinni; iwọ yoo si ri okodoro itan naa.

-----
Ṣugbọn a o fo awọn nnkan kan bayi lati le e de ibi pataki iwaasu na a gan an, ti o sii jẹ wipe nigba kan, mo bẹrẹ pẹlu Iwe Rutu yii, mo si wa ni ori rẹ fun bii ọsẹ mẹta tabi mẹrin ki n to pari rẹ. Nigba kan mo bẹrẹ pẹlu Iwe Ifihan, mo si lo bi i odidi ọdun kan lati pari ẹkọ lori rẹ. A si n so Iwe Mimọ kekere kọọkan mọ Iwe mimọ miran titi ti a fi lọ ninu gbogbo Bibeli. Eyi si rẹwa pupọ. Nitori naa awa mọ wipe a mi si Bibeli. Nitori pe nipa ẹkọ iṣiro ati ni gbogbo ọna gbogbo.... Ko si iwe àròkọ kan ti a kọ ti ko ni tako ara rẹ ni ibi kan.

A kọ iwe yii fun bi ẹgbẹrun ọdun mẹrin si ara wọn, iyẹn awọn iwe inu Bibeli. A si kọ awọn iwe yii lati ọwọ.... Mo ti gbagbe iye awọn ọkunrin ti wọn kọ Bibeli. Mo si ranti nigba kan ṣugbọn, mo tọrọ aforiji. Mo fẹ sọ wipe ọkunrin ọgọta tabi ju bẹẹ lọ. Ṣugbọn mo lee kuna lori eleyi [Ẹni kan sọrọ lati inu ijọ] Ogoji. Awọn ogoji ọkunrin ni wọn kọ Bibeli, laarin ọpọlọpọ ẹgbẹrun ọdun si ara wọn, ti awọn ọkunrin wọnyii ko mọ ara wọn, ti wọn ko si ri awa wọn ri, tabi ki ẹnikan ka ohun ti ẹnikeji ti kọ ki oun to kọ tirẹ ni ọpọlọpọ igba, ko si wa si ẹyọ ọrọ kan ti o tako ekeji. A mi si Ọrọ Ọlọrun naa.

Wayi ọpọlọpọ awọn eniyan n wo Iwe Rutu yii, gẹgẹ bi wọn ṣe n sọ, wọn ni, “Itan Ifẹ Bibeli ni.” Bibeli jẹ itan ifẹ. Gbogbo Bibeli jẹ itan Ifẹ. Ki i ṣe wipe o jẹ itan ifẹ nikan, o jẹ woliii. Ki i ṣe wipe Bibeli jẹ woliii nikan, o tun jẹ itan. Kii ṣe wipe o jẹ itan ifẹ, itan kan, woliii kan, ṣugbọn Ọlọrun funra Ara Rẹ ni o jẹ. Nitori pe, “Ni atetekọṣe ni Ọrọ wa, Ọrọ yii wa pẹlu Ọlọrun, Ọlọrun si ni Ọrọ naa.” Nitori naa Ọrọ yii jẹ Ọlọrun ti a tẹ sinu iwe. Ẹyin ara, eyi yẹ ki o yanju ọrọ naa. Ọlọrun ti a tẹ sinu iwe. Jeofa ti a tẹ sinu iwe kan. Ko si si ikan kan ninu rẹ ti o jẹ itan arosọ, ṣugbọn o jẹ otitọ pọnbele, so ọkan rẹ rọ lori gbogbo àpólà gbolohun kọọkan rẹ. O wa nibẹ, otitọ si ni. Ọlọrun yoo si ti Ọrọ Rẹ lẹyin.

-----
Bayi itan yii beere ni ọna yii; bi obinrin ti o ṣee fẹran, ti o si dụn, ọrukọ rẹ ni Naomi. Itumọ Naomi ni “adun” Ẹlimẹlẹki jẹ ọkọ rẹ, oun tumọ si isin'. Isin aladun ni ẹbi wọn. Wọn ni ọmọkunrin kan, Mahlon, orukọ rẹ eyi tumọ si “Aisan,” ati Kiloni eyi ọmọkeji tumọ si “aarẹ, irẹwẹsi, ibanujẹ.” Eyi ni ẹbi naa.

O si ̣ṣe.... Iyàn kan bẹ silẹ̀ Israẹli. Asiṣe akọkọ ti ọmọ Juu kan lee ṣe ni ki o fi ilẹ naa silẹ. Ọlọrun ni o fun wọn ni ilẹ naa. Nigbati a fun Abrahamu ni ilẹ naa, Ọlọrun sọ fun wipe ki o ma ṣe fi ilẹ naa silẹ. O si ̣ṣe asiṣe nigbati o lọ si Gẹra, o wọ inu iṣoro. Ko yẹ ki Juu kan fi Palẹstini silẹ. Ati mu wọn jade lati inu ibi gbogbo aye, ati bayi wọn n pada bọ ọ.

-----
Wayi, mo fẹ ṣe afiwe, ni owurọ yii, Naomi alagba obinrin, gẹgẹ bii ijọ ti ilu gba wọ ile, eyi i ni ni ijọ Juu ti ilu gba. Rutu ara Moabu, jẹ ijọ awọn ẹya Alaikọla, eyi ti o jẹ ijọ Kristẹni, ijọ tuntun naa. Mo si fẹ lọ ninu eyi ni abala mẹrin ọtọọtọ: Rutu (mo ti kọ ọ silẹ nihin), Rutu ti o n pinnu, o n ṣe ipinnu rẹ; Rutu ti o n sin; Rutu ti o n simi; Rutu ti o gba ere ipinnu rẹ. Bi a ṣe n pada bayi, Rutu ti o n ṣe ipinnu naa; Rutu, lẹyin ti o ṣe ipinnu rẹ, lẹyin naa Rutu n sin; lẹyin naa Rutu simi; lẹyin naa Rutu gba èrè.

-----
Rutu ti o n ṣe ipinnu kan. Wayi, Rutu n sin ni abẹ́ ipinnu rẹ. [Wayi, kiyesi ni iṣẹju kan]. Wayi, Rutu lọ si oko lati sa ipeṣẹ́-ọka.
Wayi iya rẹ sọ fun un (eyi ti o jẹ Majẹmu laelae n sọ fun Majẹmu Titun, njẹ ẹ mọ), iya rẹ sọ fun un, wipe, “A wa si ni ibatan kan, orukọ rẹ si ni Boasi. Ọlọrọ ni, O si jẹ ibatan ti o sun mọ wa. Iwọ lọ, si oko rẹ boya.... ma ṣe lọ si oko ẹlomiran o, lọ si oko rẹ.”
Iyẹn jẹ bi Ẹmi Mimọ ṣe ma a n sọ fun wa pe lati ma ya lọ si inu awọn iwe ijọ kan, bii awọn katikisimu kan, ṣugbọn ki a lọ si oko Ọlọrun, iyẹn majemu laelae naa, ti iṣe Bibeli. Maṣe sọ wipe,' o ti daa, awa yoo sọ eleyi. Awa yoo si sọ eleyi fun adura kan, awa yoo ni eleyi,' Duro laara pẹlu oko na a. Lọ taara si inu rẹ nitori pe ibatan ti o sunmọ wa ni O jẹ.

Ọrọ Ọlọrun, iyẹn Majẹmu laelae, jẹ ibatan ti o sunmọ ni fun Majẹmu Titun. Ijọ atijọ naa jẹ iya ijọ titun (ẹ rii) iyẹn, Kristẹni, iyẹn onigbagbọ,' “Maṣe lọ si oko ẹlomiran. Duro taara ni oko rẹ. Boya ni ọjọ kan, o le ri ojurere gba lọdọ rẹ”. Ati ni ọjọ kan nigba ti Rutu wa ninu oko, ọdọ ọmọkunrin ọlọrọ naa ti orukọ rẹ n jẹ Boasi, ti o jẹ ijoye, bọrọkini kan, n kọja lọ o si ri i. Oo! nigba ti o ri i, o ni ifẹ rẹ. O ro wipe obinrin ti o dara pupọ ni eyi. O ni ifẹ rẹ, o ni ifẹ iwa rẹ. Njẹ o ranti pe o sọ pe, “Emi mọ, awọn eniyan mi si mọ, pe ọmọbinrin oniwarere ni iwọ jẹ.”
O ṣe ipinnu taara, ipinnu san an. O pada wa si ihin o si gbe gẹgẹ bi o ṣe sọ wipe oun yoo ṣe.

Ni ọna miran ẹwẹ loni wọn wipe, “Awa mọ wipe Kristẹni ni iwọ jẹ. Awa mọ wipe eniyan Ọlọrun ni iwọ, nitori pe ko si ọkunrin ti o le ṣe awọn iṣẹ iyanu wọnyi ayaafi bi Ọlọrun ba wa pẹlu rẹ.” Ohun ti Nikodemu sọ fun Jesu, niyẹn, o wipe, olukọni, awa mọ wipe olukọni kan ti o ti ọdọ Ọlọrun wa ni iwọ I ṣe; Ko si ọkunrin ti o le ṣe awọn nnkan ti iwọ n ṣe wonyii, ayaafi bi Ọlọrun ba wa pẹlu rẹ; nigba ti Nikodemu le e ri ti o joko nibẹ, ti o si mọ awọn ero ọkan wọn gan an yatọ.
Obinrin kan fi ọwọ kan aṣọ rẹ, O yipada o si sọ wipe, “Tani o fi ọwọ kan mi?” Gbogbo wọn ṣẹ́. O si wo ẹyin wo laarin awọn ero naa, O si wipe, “iwọ pẹlu isun ẹjẹ nibẹ, Igbagbọ rẹ ti mu ọ larada”.

O wipe, “Ko si ẹni ti o le e ṣe iyẹn ayaafi bi Ọlọrun ba wa pẹlu rẹ! Awa mọ wipe lati ọdọ Ọlọrun ni iwọ ti wa. Awa ko le e gba Ọ, nitori pe wọn yoo le wa jade lati inu ijọ.” Ẹ ri i, ẹka ajara ti o lọ naa, arakunrin West, gẹgẹ bi a ṣe n sọrọ nipa rẹ ni asalẹ ana. Wọn yoo gba ọ jade. “Ṣugbọn ni isalẹ ọkan wa awa mọ wipe, iwọ wa lati ibi ajara ojulowo naa.” Kristi ni igi ajara naa, ẹ̀ka ni awa jẹ. “Awa mọ, nitori pe a rii iye kan naa ti o wa ninu Ọlọrun, pe o wa ninu Rẹ.”
Ohun ti Boasi ri ni inu Rutu ni eyi. Ipinnu san an naa, obinrin oniwa rere kan ti o duro ni iwaju rẹ. O si ni ifẹ rẹ.

Bayi, mo fẹ ki ẹ ṣe akiyesi, Naomi, iyẹn Ijọ atijọ, bẹrẹ si ṣalaye gbogbo awọn ofin ẹsin rẹ fun Rutu: gẹgẹ bi Majẹmu laelae ṣe jẹ ojiji fun Majẹmu Titun. Wayi, mo fẹ ki itan yi ye yin gidigidi ti majemu titun. Bayi, mo fẹ fi awọn ojiji rẹ han. Majẹmu ti laelae ṣe alaye ti titun. Ti o ba le ka. Nitori o jẹ ojiji ti Majẹmu Titun. Bayi ti mo ba nlọ si ibi ogiri yẹn, ti emi ko si ti ri ara mi, mo si ri ojiji mi, ma wa ma ri ero inu oun ti mo jẹ. Ti o ba fẹ mọ ohun ti Majẹmu Titun jẹ, nigba naa ka Majẹmu laelae iwọ yoo si ri ojiji rẹ, ẹ ri i. Nigba yi ni Majẹmu Titun bẹrẹ, iwọ yoo wa, wipe, “Eeṣe, dajudaju, ohun naa niyi.” Iwe Heberu, Paulu pada sẹhin o si ṣe alaye rẹ.

Wayi, ṣe akiyesi rẹ daradara bayi, nigba ti Rutu sọ wipe.... tabi nigba ti Naomi sọ fun Rutu, pe, ti o wipe “ọkunrin naa jẹ ibatan wa. Ti o ba le ri ore-ọfẹ gba lọdọ rẹ, iwọ yoo ni isimi.” (Oo, akiika!) “Bayi ti o ba ri ore- ọfẹ gba ni ọdọ rẹ iwọ yoo ni isimi.” Boasi duro fun Kristi, ọkunrin Ọlọrọ naa ẹni ti o jẹ arole ohun gbogbo, ti Oluwa ikore. Oo akiika! Eeṣe, ani gẹgẹ bi, Boasi si wa ti o gun kẹkẹ ẹsin wa si bẹ o n wo gbogbo ayika ọgba, oju rẹ si ri Rutu. Oun ni ọ̀gá. Oun ni Oluwa Ikore naa. Rutu wa ri ojurere gba ni iwaju rẹ (Boasi).

Ohun ti ijọ n ṣe gẹlẹ niyi loni. Nigbati Oluwa Ikore n kọja lọ, Oluwa ri awọn ile nlanla awọn ile olori ṣonṣo tempili, awọn ẹgbẹ akọrin ti a kọ daradara. Oun n wa awọn aladori ẹnikọọkan! Awọn Ọkunrin ati obinrin ti wọn ti fi ara won ji Kristi, ti wọn yaa ara wọn sọtọ fun iṣẹ Ọlọrun. Ti wọn ṣe awọn ipinnu taara, ipinnu san an fun Kristi, ti wọn ya ara wọn sọtọ fun isin Rẹ “Ọlọrun emi gba a gbọ! Mo gba gbogbo Ọrọ rẹ Kọọkan gbọ.” Nigba ti Ọrọ Rẹ ba sọ ohunkohun, emi yoo duro taara pẹlu rẹ. Ọrọ rẹ niyẹn. Mo gba gbogbo Ọrọ rẹ gbọ. Ọrọ rẹ kọọkan gbọ'. Ohun ti Kristi n wa niyẹn, Oluwa Ikore. Awọn ẹni ti o fẹ fun ni Ẹmi mimọ naa ni awọn ti ebi n pa. Awọn ti o pongbẹ ni. “Alabukunfun ni ẹyin nigba ti ebi ba n pa yin, ti oungbe si ngbẹ yin: nitori a o kun yin. Oun n gbiyanju lati ri ijọ naa ni oni.

Bayi, nigba naa, a sọ fun Rutu ki o ṣe ohun itiju kan, oun si ti ṣetan lati ṣe bẹẹ nitori pe o ti ṣe ipinnu rẹ. Iru apẹẹrẹ onigbagbọ wo ni Rutu jẹ. Iru apẹẹrẹ pipe wo ni eyi! Naomi, ti I ṣe ijọ atijọ naa, wipe, 'Lọ ni asalẹ yi, akoko ikore baali ni! Oo, ero ti o rẹwa ti a lee so ara wa taara mọ nibẹ ni eyi.

Naomi ati Rutu de ni akoko ikore ọka baali gẹlẹ. Akoko ọka baali jẹ akoko ounjẹ-akoko ti a n I bọ ni, ounjẹ ti a ṣẹṣẹ pese. Ijọ ni opin ọjọ wọnyi, ti o ti lọ ninu ẹgbẹwa ọdun ti ikoni iboriṣa ati ohun gbogbo bẹẹ ti wa de ni akoko ikore ọka-baali, ti I ṣe igbe-aye titun, ounjẹ tuntun, oyin lati ọrun wa. (Russell sọrọ nipa akara ti ao fi oyin din!) Ohun gan an niyi! Akara iye. Awọn baba yin jẹ mana wọn si ku. Sugbọn Emi ni akara iye ti o ti ọdọ Ọlọrun wa lati ọrun. Bi eniyan kan ba jẹ ninu akara yi, oun ki yoo ku mọ laelae.' Ni opin ọjọ yi, a si mu ijọ wọle wa bayi ni akoko ikore ọka-baali.

Rutu, ọmọ ẹya Alaikọla kan, ni a le jade, ti a ti I danu, a si ti mu un wọle bayi gẹgẹ bi (a ni lati tẹwo gba a gẹgẹ bi iyawo Kristi) o wọle wa ni akoko ọka baali.
O wipe, “Wayi i, wọ aṣọ rẹ si ọrun rẹ.” Ko wipe, “Bọ aṣọ rẹ kuro ni ọrun rẹ.” Bawo ni eyi ṣe yatọ to si ti oni. “Wọ aṣọ rẹ si ọrun rẹ nigba ti iwọ ba lọ pade rẹ. Oun yoo lọ fẹ ọka barle ni alẹ oni. Sọkalẹ lọ ki o si wọ aṣọ rẹ si ọrun rẹ. Bo ara rẹ daadaa, lati lọ pade rẹ.

Loni, wọn ko fẹ wọ aṣọ. “Wọ aṣọ si ọrun rẹ daadaa. Sọkalẹ lọ si ọdọ rẹ nitori pe o yoo fẹ ọka-barle. Lẹyinnaa iwọ ṣe ami si ibi ti yoo sun si.” Njẹ iwọ ṣe iyẹn? Ni Gọlgọta! Ni ọpọlọpọ ọdun sẹyin, mo ṣe ami ni ọkan mi nipa ibi ti O ti fi Ẹmi Rẹ le lẹ ki O lee gba mi. “Kiyesi ibi naa ti o sun si. Ṣe akiyesi ibi ti o sun si.” Ohun ti onigbagbọ kọọkan yẹ ki o ṣe niyẹn. Ṣe akiyesi Ohun ti O ti ṣe fun ọ. Iwaasu Ọjọ Aiku ti o kọja lori, “Ibẹwo si Kalfari.” Ṣe akiyesi ohun ti Kristi ṣe fun ọ.

Naomi sọ wipe, “Sàmì si ibi ti Boasi sun si. Nigba ti o ba ti fi ara le ilẹ lati sun (lati simi) iwọ lọ ki o si sun si ibi ẹsẹ rẹ.” Ki i ṣe ni ibi ori rẹ; ẹsẹ rẹ! - alaiyẹ. “Lẹyinnaa, mu aṣọ ibora rẹ, ki o faa le ori ara rẹ.” Njẹ iyẹn ye yin? Kaaṣa, mo mọ pe iwọ le e ro wipe emi jẹ alakata-kiti ẹsin, ṣugbọn iyẹn tẹ mi lọrun gẹlẹ, iyẹn Ẹmi Ọlọrun. Ṣe akiyesi ibi ti O sun si.... ni Kalfari; ni ibi ti O ti sun si inu iboji naa; ni Gẹtisimani. Ṣe akiyesi rẹ, fa lọ si ibi ẹsẹ Rẹ, ki o si sun si ibẹ, ki o si ku si ara rẹ, ẹ ri i. Bi ọrọ naa ṣe ri ni iyẹn. Fi aṣọ rẹ bo ara rẹ. O wipe, “Aṣọ rẹ naa,” oun ti obinrin naa pe e niyẹn.

Rutu si sọ pe, “Ohun ti iwọ ba sọ fun mi ni emi yoo ṣe.”
Oo, ipinnu sàn án kan fun onigbagbọ kan kọ ni eyi! “Ohun ti Bibeli ba sọ, iyẹn ni emi yoo ṣe. O sọ wipe, 'Ẹ ronupiwada, ki a si baptisi yin ni orukọ Jesu Kristi,' Emi yoo ṣe bẹẹ. Bi o ba sọ pe, 'Ẹ lọ si inu gbogbo aye ki ẹ si lọ waasu ihinrere, emi yoo ṣe bẹẹ. Bi o ba sọ pe.... ohun yoowu ti o ba sọ, 'Jesu Kristi ọkan ni àná, ọkan ni oni ati ọkan titi ayeraye.' Ohunkohun ti o ba sọ fun mi pe ki n ṣe, emi yoo ṣe e.” Ẹ ri i, eyi jẹ ijọ ti o n gba aṣẹ lati inu Ọrọ Ọlọrun. O n sun silẹ.

Wayi, ranti, ohun itiju ni iyẹn jẹ fun ọdọbinrin opó naa lati lọ sun si ẹgbẹ ọkunrin yii, ni ibi ẹsẹ rẹ. Ohun itiju loju awọn eniyan ti aye! Oo, njẹ iwọ le e fi ara da a? Ohun ni yi.
Wo o! Wo o, bi o ṣe jẹ niyi! Ijọ naa, awọn ọdọbinrin naa, awọn ọdọkunrin, awọn arugbo tabi awọn ọdọ, ni a sọ fun wipe ki wọn ya ara wọn sọtọ kuro ninu aye, ki wọn si wa si ibi kan, ijọba ti Ẹmi Mimọ kan, eyi ti o jẹ ohun itiju si aye. Ni inu ọkan wọn, wọn mọ ohun ti ohun yii tumọ si. Ṣugbọn ni oju awọn eniyan aye wọn jẹ awọn alakata-kiti ẹsin, wọn jẹ awọn agbarayilẹ mimọ tabi iru ohun kan bẹẹ, orukọ itiju kan. Ṣugbọn a sọ fun ijọ ki o ṣe bẹẹ. Njẹ iwọ n fẹ lati sami si ibi naa, ki o si sun si ibẹ? Jẹ ki aye pe ọ ni ohunkohun ti wọn ba fẹ pe ọ.

Orin atijọ kan lọ bayi pe:

Emi ti bẹrẹ irinajo naa pẹlu Jesu nikan (Njẹ iwọ ri i?),
Ki emi ni irọri okuta bi i ti Jesu
Emi yoo mu ọna mi pọn pẹlu awọn Eniyan Oluwa diẹ ti a ti kẹgan,
Emi ti bẹrẹ pẹlu Jesu, emi yoo rin Irin ajo naa de opin.

-----
Sami si ibi na ti O sun si. Ki o si sun sibẹ pẹlu Rẹ. Njẹ iwọ ṣetan lati lọ si Kalfari ni owurọ yii, gẹgẹ bi mo ṣe sọ ni Ọjọ Aiku ti o kọja? Njẹ iwọ ti mu ara rẹ wa si ibi naa, nibi ti a ti kan Jesu mọ agbelebu?

Ka iroyin ni kikun ni...
Ìbátan Olùràpadà Náà.


Ohun ijinlẹ Kristi.

Wẹẹbu iwe iroyin Gẹẹsi.

Iwe Ifihan jara.

 

Ọlọrun ati Imọ Atọka.
- Archaeology.

Igbasoke n bọ.

 

Awọn ẹkọ akọkọ
ti ifiranṣẹ naa.

Awọn ti o dara iroyin.
Jesu ku fun ese re.

Iribomi Omi.

 

Awọsanma eleri nla.

Ọwọn ti ina.

Ogo Shekinah ti Ọlọrun.

Ibojì ti ṣofo.
O ti jinde.

Ọlọrun salaye.

Awọn ìgbà ijọ meje.

Awọn edidi meje.

Ọlọrun ati Itan.
jara Atọka - Dáníẹ́lì.

Kristiẹni ije jara.
Ìgbéyàwó Àti Ìkọ̀sílẹ̀.
Akojọ Ifiranṣẹ.

Opin akoko jara.

Ngbe ọrọ jara.

Keresimesi jara.

Iku. Ohun ti nigbana?

Orúkọ Ọlọrun.

Ọkọ Noa.

 

Ẹṣẹ Atilẹba.
Je o ẹya apulu?

Adaparọ.
Awọn orisun - Babeli.

Ọlọrun ati Imọ.
Dainoso Adaparọ.

Archaeology.
Sodomu ati Gomorra.

  Iwe-mimọ sọ...

Sùn títí di òwúrọ̀, nígbà tí ó bá di òwúrọ̀ bí ó bá tẹ́ ẹ lọ́rùn láti ṣú ọ lópó gẹ́gẹ́ bí ẹ̀tọ́ rẹ̀, ó dára, jẹ́ kí ó ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣugbọn bí kò bá fẹ́ ṣe ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìbátan, bí OLUWA ti wà láàyè, n óo ṣe ẹ̀tọ́, gẹ́gẹ́ bí ìbátan tí ó súnmọ́ ọn. Sùn títí di òwúrọ̀.

Rutu 3:13


Tẹ aworan kan lati ṣe igbasilẹ aworan iwọn ni kikun tabi PDF.


Acts of the Prophet.

(PDFs Gẹẹsi)

Ìgbéyàwó Àti Ìkọ̀sílẹ̀.

(PDF)

William Branham
Life Story.

(PDF Gẹẹsi)

How the Angel came
to me.

(PDF Gẹẹsi)


Ifiranṣẹ ibudo...Yan ede rẹ ki o gba awọn ifiranṣẹ ọfẹ lati ọdọ Arákùnrin Branham.