Ọjọ naa ni Kalfári.

<< išaaju

itele >>

  Ajinde jara.

A san gbese ẹ̀ṣẹ̀.


William Branham.
 

Ka iroyin ni kikun ni...
Ọjọ naa ni Kalfári.

Luku 23:33,
Nígbà tí wọ́n dé ibi tí wọn ń pè ní, “Ibi Agbárí”, wọ́n kàn án mọ́ agbelebu níbẹ̀ pẹlu àwọn arúfin meji náà, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, ekeji ní ọwọ́ òsì.

O jẹ ọkan ninu awọn ọjọ ti o ṣe pataki julọ ninu gbogbo awọn ọjọ ti Ọlọrun ti da si orilẹ-aye. Ti o ba si jẹ wipe o ṣe pataki fun iran eniyan - Kalfari, mo rò pé o dara fun wa lati pada ki a si ṣe ayẹwo ki a si wo ohun ti ọjọ yi tumọ si fun wa. Nitori o dami loju pe ni akoko ti o ti fẹrẹ pari ti a n gbe inu rẹ yi, a n wa gbogbo ohun ti o ṣe pataki ninu Ọlọrun ki awa ki o le mọ̀, ati ohun gbogbo ti a le ṣe iwadi rẹ, a wà nibiyi lati kọ ọ. Ki a le ri ohun ti o wa fun wa, ati ohun ti Ọlọrun ti ̣se fun wa, ki a si ri ohun ti o ti ṣeleri pe ohun yoo ṣe fun wa. Idi ti a fi wa si ile-ijọsin niyi.

Idi ti oniwaasu fi n waasu niyi. Idi ti o fi n kẹkọ ti o si n ṣe àṣàrò ninu Iwe-Mimọ ti o si n bẹbẹ fun ìmísí, o jẹ nitoripe o jẹ ojiṣẹ-ilu fun awọn eniyan Ọlọrun, o si n gbiyanju lati wa ohun kan ti yoo ṣe.... ti Ọlọrun yoo sọ fun awọn eniyan Rẹ̀, ohun kan ti yoo ràn wọn lọwọ. Boya yoo dá wọn lẹjọ ninu ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ṣugbọn yoo jẹ iranlọwọ lati gbe wọn dide, ki wọn ki o le kọ ẹ̀ṣẹ̀ wọn silẹ, ki wọn si dide lati sin Oluwa. Ojiṣẹ Ọlọrun gbọdọ wa awọn nkan wọnyi.

Ti ọjọ yi ba ̣se pataki to bẹẹ gẹ, ọkan lara awọn ọjọ ti o lógo, ẹ jẹ ki a wo awọn ohun mẹta pataki ti ọjọ yi tumọ si fún wa. A le mu bi i ọgọrun púpọ̀. Ṣugbọn ni owurọ yi mo kan mú awọn ohun mẹta pataki ti a fẹ́ wò fun awọn akoko diẹ ti o kàn, ohun ti Kalfari tumọ si fún wa. Mo si gbadura pe yoo da gbogbo awọn ẹlẹsẹ ti o wa nibiyi lẹ́bi, yoo jẹ ki gbogbo awọn eniyan mimọ lọ si ori eekun wọn, yoo jẹ ki gbogbo awọn ti o n ṣe aisan gbe igbagbọ rẹ soke si Ọlọrun ki wọn si rin jade pẹlu ìwósán, gbogbo ẹlẹ́sẹ̀ ni yoo ri ìgbàlà, gbogbo apadasẹyin ki wọn pada wa ki oju ara rẹ si ti i, ki gbogbo awọn eniyan mimọ si kún fún ayọ ki wọn si gba ireti tuntutn - ireti tuntun.

Ohun nla pataki ti Kalfari tumọ si fún wa, ati gbogbo agbaye jẹ́, o ni ìdáhùn fun ibeere ẹ̀ṣẹ̀ lẹẹkan ṣoṣo. A ri wipe eniyan jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀ si jẹ gbèsè ti ẹnikẹni kò lee san. Gbèsè, naa pọ to bẹẹ gẹ titi o fi jẹ wipe ko si ẹnikan ti o le san gbese naa. Mo gbagbọ daju pe Ọlọrun ti pinu rẹ pe yoo ri bẹ́ẹ̀ - pe gbese naa yoo pọ to bẹẹ gẹ ti ko ni fi si eniyan kankan ti o maa lee sanwo rẹ - ki Oun ba le ṣe eleyi funrara Rẹ̀! Bayi, iku ni ere ẹ̀ṣẹ̀. Gbogbo wa ni a bi ninu ẹ̀ṣẹ̀ ti a dá ninu aiṣedede, a wá sinu aye yi a si n parọ́. Nitorina, gbogbo wa jẹ aláìyẹ, tabi wọn kò ri ẹnikankan ni aye yi ti o yẹ.

Ẹṣẹ ko si bẹrẹ ni ayé yi. Ẹ̀ṣẹ̀ bẹrẹ ni ọrun, Lusiferi, eṣu naa, jẹ ẹda Ọlọrun ti a ti da lẹbi nitori aigbọran rẹ̀ ṣaaju ki o to wá si aye. Ẹṣẹ bẹrẹ lọrun, nibiti Ọlọrun fi awọn angẹli si ati bẹẹbẹẹ lọ o gbe wọn lori oṣuwọn kannaa ti O gbé eniyan si. Lori imọ. Igi ìmọ̀ rere.... igi iye ati igi imọ rere, nibiti eniyan ti le ṣe iyan. Ati nigbati a fun Lusiferi ni anfani lati ṣe ìyàn rẹ́, o fẹ ohun miran ti o dara ju ohun ti Ọlọrun ni lọ. Ibiti wahala ti bẹrẹ niyi.

A si bèrè ìtanràn fun ẹ̀ṣẹ̀. Gbese rẹ si ni ikú. Iku ni èrè rẹ̀. Ati eyi jẹ.... a le lọ sinu ijinlẹ rẹ̀, nitoripe emi ko gbagbọ wipe sụgbọn iku kan ṣoṣo ni o wa. Iye kan ṣoṣo ni o wà. Mo gbagbọ wipe eniyan ti o ni Iye ainipẹkun ko le ku mọ laelae, mo si gbagbọ wipe iyapa ayeraye wa fun ọkan naa ti o dẹṣẹ. Nitori Bibeli sọ wipe, “Ọkan ti o ba dẹṣẹ, yoo kú dandan - ko ki n ṣe eniyan naa, ọkàn naa ti o dẹṣẹ. Nitorina Satani gbọdọ kú dandan, lati le pa a run patapata. Bi mo ti sẹ lodi si awọn ti o gbagbọ wipe gbogbo ẹda ni a o gbala ti wọn si sọ wipe a o gba Satani là! O dẹṣẹ, oun si ni oludasilẹ ẹ̀ṣẹ̀. Ọkan rẹ dẹṣẹ, o si jẹ ẹ̀mi. A o pa ẹmi yi run patapata ko si ni ku ohunkohun ninu rẹ̀.

Ati nigbati ẹ̀ṣẹ̀ wa sinu aye ni ibẹrẹ gẹgẹ bi i ìkuùkú dudu ti o sọkalẹ lati ọrun, o sọ aye di rudurudu. O sọ gbogbo ẹda aye, ati gbogbo ẹda Ọlọrun, sinu ìgbèkùn. Eniyan wa ninu ìgbèkùn ikú, àisàn, wahala, ibanujẹ. Gbogbo ẹ̀dá ni o ṣubu pẹlu rẹ. Ẹ̀ṣẹ̀ jẹ ogun akunilórun ti o sọ gbogbo aye di rudurudu! Ati lẹhinnaa a si gbé wa sibiyi, ni aláìnírètí, nitoripe gbogbo ẹ̀dá ni aye ni o wa ni ìgbèkùn fún u, gbogbo ẹni ti a bi ni aye ni o wa ni igbekun rẹ. Nitorina o nira lati wa lati ibikan nibiti ko si ẹ̀ṣẹ̀. Ko le jẹ wipe yoo wa lati àyé.

Ko si ẹnikankan wa ti o le ra ẹnikeji rẹ pada. O gbọdọ jẹ pe yoo wa lati ọ̀dọ̀ ẹlomiran. Nitorina, nigbati eniyan loye pe a ti ya ohun nipa kuro lọdọ Ọlọrun rẹ, o di alárinkiri. Wọn sọkun, wọn kigbe, wọn ṣe làálàá, wọn di alarinkiri laarin awọn oke, ati ninu awọn aṣalẹ, wọn n wa ilu kan ti olupilẹṣẹ rẹ ati ẹniti o kọ ọ jẹ Ọlọrun. Nitori o mọ wipe ti oun ba pada si iwaju Ọlọrun, oun yoo ba A sọrọ nipa gbogbo rẹ. Ṣugbọn ko si ọna lati pada. O sọnu, ko mọ ọna ti oun yoo ya si. Nitorina o kan jade lọ o n rin kiri, o n gbiyanju lati wa ibiti oun yoo ti ri ọna ti o pada lọ si ibẹ! Ohun kan ninu rẹ sọ fun un wipe o wa lati ibikan ti o jẹ pipe.

Ko si ẹnikẹni ninu àpéjọpọ̀ ti a le fi oju-ri ni owurọ yi, tabi ninu àpéjọpọ ti a ti n gbọ ohùn nikan eyiti yoo lọ kaakiri gbogbo orilẹ-aye, ko si ẹnikẹni nibiyi tabi nibo miran, ṣugbọn ti yoo maa wa pipe naa. Nigbati iwọ ba san awọn owo ti o yẹ ki o san, iwọ yoo ro pe gbogbo rẹ ti pari. Nigbati iwọ ba san owo yi, lẹhin naa ẹlomiran yoo tun ṣe aisan ninu ẹbì rẹ. Nigbati aisan yi ba lọ, lẹhin naa owo ti iwọ yoo san yoo tùn pọ̀ si. Ohun akọkọ ti iwọ yoo ri ni wipe, irun ori rẹ ti n di funfun, ati lẹhin naa iwọ yoo nifẹ lati pada di ọ̀dọ́. Ohun kan si maa n wa nigba gbogbo, nigba gbogbo, nitori iji ẹ̀ṣẹ̀ naa. Sụgbọn ninu ọkàn rẹ, nitoripe iwọ n wa eyi, o fi hàn pé pipe kan wa nibikan. Nibikan ohun kan wà.

-----
Nigbẹyin ni ọjọ kan - eyi ni ọjọ naa ni Kalfari - nibẹ ni Ẹnikan ti sọkalẹ wa lati inu ogo, ẹnikan ti orukọ rẹ jẹ Jesu Kristi ọmọ Ọlọrun, ẹniti o wá lati inu ògo, a si da Kalfari silẹ. Eyi ni ọjọ naa ti a san owo naa, a si ̣se idahun fun gbogbo ibeere ẹ̀ṣẹ̀ titi laelae, a si ṣi ọna silẹ fun awọn nkan wọnyi ti ebi rẹ n pa wa ti a si n pongbẹ fún. O mu ibi itẹlọrun wá.

Ko si ọkunrin kankan ti o de Kalfari ti o si ri bi o ti ̣se ri, ti yoo ri bakanna mọ́. Gbogbo ohun ti o le nifẹ lati ni tabi ti o n pongbẹ fún gbogbo rẹ ni a ba pade nigbati o ba de ibiyi. O jẹ ọjọ pataki kan, o si jẹ ohun ti o ṣe pataki, o mi gbogbo aye! O mi gbogbo aye eyiti a kò ti mi aye bi eleyi ri. Nigbati Jesu ku ni Kalfari ti o si san igbese ẹ̀ṣẹ̀.

Aye ẹ̀ṣẹ̀ yi ni okùnkùn biribiri! Oorun lọ silẹ ni ọsan gangan. O ni idamu gidigidi, awọn apata mì tìtìtìtì, awọn okè ya lulẹ̀, ati awọn òkú jade wa lati inu iboji. Kini ohun ti o ṣe? Ọlọrun pari gbogbo rẹ ni Kalfari. O pa ẹranko naa ti a n pe ni Satani lara titi laelae.

Bayi, lati ìgbà naa ni o ti ni oró ninu, nitoripe O mu imọlẹ wá si iran ọmọ eniyan; gbogbo eniyan ni o si mọ pé ti a ba pa ẹranko kan lara o maa n ni oró si i.... o n fà kaakiri pẹlu egungun ẹyin rẹ ti a ti fọ́. Bayi, A ti ṣẹgun Satani ni Kalfari. Ayé jẹri pe bẹẹni o ri. Owo nla naa ti a ko ti san iru rẹ rí, Ẹni kanṣoṣo naa ti o le san án, sọkalẹ wa o si ṣe eyi ni Kalfari. Ibiyi ni a ti san owo nla naa. Eyi jẹ ọ̀kan ninu awọn nkan wọ̀nyí.

Ọlọrun beere fun eyi. Ko si eniyan kankan ti o yẹ, ko si ẹni kankan ti o ká oju-oṣuwọn, ko si ẹnikankan ti o le e ṣe. Ọlọrun funrara Rẹ sọkalẹ wa a si sọ Ọ di eniyan, O si gbe igbesi-aye eniyan labẹ ifẹ eniyan, a si kan An mọ agbelebu. Ati nibẹ, nigbati Satani ro pe oun ko le e ṣe e, oun ko le la a kọja - Ó la Gesthsemane kọja ati gbogbo idanwo ti ẹnikẹni le e là kọja. O la a kọja bakanna gẹgẹ bi i gbogbo eniyan; ṣugbọn O san gbese naa; ohun ti o sọ aye si okunkun niyi. Gẹgẹ bi òògùn ti a fi maa n kun eniyan lórun ti o ba fẹ ṣiṣẹ abẹ. Nigbati dọkita ba fun eniyan kan ni oogun ti a fi maa kun eniyan lórun.... o ma jẹ ki o kọ́kọ́ sùn patapata ṣaaju ki o to ṣe iṣẹ-abẹ yi. Ati nigbati Ọlọrun ṣe iṣẹ-abẹ fún ìjọ, aye gba òògùn-orun. G̀iri mú ayé. Abájọ, Ọlọrun, ninu ẹran-ara eniyan, n kú lọ. O jẹ akoko ti ayé ti fojusọna fun, síbẹ̀ ọpọlọpọ ninu wọn ko mọ eleyi. Gẹgẹ bi o ti ṣe ri ni oni yi, ọpọlọpọ ni o n wa awọn nkan wọnyi, ati sibẹ wọn ko dá awọn nkan wọnyi mọ̀. Wọn ko loye ọna àbáyọ. Wọn si n gbiyanju lati ṣe ifẹkufẹ ati awọn ohun aye, wọn n gbiyanju lati wa ọna àbáyọ.

Ọpọlọpọ àmì-oju-pátákó ni o wà ti o n tọka si ọjọ́ naa -ọpọlọpọ ojiji. A ti fi òȷ́ijì rẹ hàn lati ara ọdọ-aguntan, lati ara akọmalu, lati ara ẹyẹ àdàbà, ati gbogbo awọn nkan wọnyi, ṣugbọn sibẹ a ko le fọ ọ. Wọn ko le fọ́ ẹ̀wọ̀n ikú naa! Nitori Satani ti gba ayé. Apata naa ti o ti rin kọja lori rẹ rí lori ilẹ ayé, sulfuri (okuta-ina) ti n jó- Lusiferi jẹ ọmọ owurọ o si rin lori ilẹ-ayé nigbati o n ru jade bi i ina - awọn okuta kannaa ti wọn ti tutù, nigbati Jesu kú ni Kalfari, ti o fi agbara jade kuro ninu aye. Owo naa ti a san, a si já ìdè Èṣù naa.

Ọlọrun ti pada fi si ọwọ eniyan, ọna ti yoo fi pada si ohun ti o n wá. Ko nilo lati sọkún mọ. Nigbati o fọ egungun ẹyin Satani ni Kalfari - egungun ẹyin ẹ̀ṣẹ̀, ti aisan - ti o si mu gbogbo ẹda alaaye ni ori-ilẹ ayé pada wa si iwaju Ọlọrun ti a si dari gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ji.
Hallelujah! A ti dari ẹ̀ṣẹ̀ wa ji wa! Eṣu ko le diwa lọna mọ́ kuro lọdọ Ọlọrun! Ọna nla kan wa ti a ṣe, ẹ̀rọ ibanisọrọ kan wa ti a gbe sibẹ, waya kan wa ti o lọ sinu ògo. O mu gbogbo awọn ti o de ibi waya yi wọle. Ti eniyan ba kún fun ẹ̀ṣẹ̀, yoo mu u lọ si ibi waya yi. A le dari gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yi jin in! Ko ki n ṣe eyi nikan, ṣugbọn a ti sanwo ẹ̀ṣẹ̀ yi! O ko nilo lati sọ wipe, “Emi jẹ aláiyẹ.” Dajudaju iwọ jẹ alaiyẹ. Iwọ ko le yẹ laelae. Ṣugbọn Ẹniti o yẹ kan gba ipo rẹ! A ti tú ọ silẹ! O ko nilo lati jẹ alarinkiri mọ́. O ko nilo lati jẹ ọkunrin ti o n wa afẹ́ ayé mọ nita nibiyi lori ilẹ̀ ayé. Nitori,

Ìsun kan wa to kún fun ẹjẹ;
Ti o ṣàn lati ìhà Emmanuẹli;
Ẹlẹṣẹ m'okun ninu rẹ,
O bọ ninu ẹ̀bi.

O ko nilo lati ṣegbe. Opopo kan wa, ati ọna kan, a si n pe ni ọna iwa-mimọ, awọn aláìmọ́ ki yoo kọja lori rẹ.“ Nitori o kọ́kọ́ wa si ìsun naa, lẹhin naa o lọ si opopo naa.

O fọ agbara Satani. O ṣi ile-tubu ti ọrun apadi, ki gbogbo eniyan ti a tìlẹ̀kun mọ́ ni aye yi - ninu túbú - ti wọn n bẹru pe ti oun ba ku, kini ikú yoo jẹ́ sí oun.... Ni Kalfari O ṣi awọn ilẹkun ile-tubu yẹn O si jẹ ki gbogbo awọn ti a mu ni igbèkùn gba ìtúsílẹ̀. Ẹṣẹ ko le fa ọ lulẹ mọ. O ko nilo lati fi ara rẹ silẹ fun ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, o ko nilo lati fi ara rẹ silẹ fun ọti-mimu, siga-mimu, tẹtẹ-tita, irọ-pipa. O le jẹ olootọ, ẹni-mimọ ati olododo; Satani ko si le ṣe ohunkohun nipa rẹ̀, nitoripe o ti di waya naa mú! Waya ìyè naa eyiti o ni ipinlẹ ninu apata ayeraye. Ko si ohunkohun ti o le mi ọ kuro ninu rẹ. Ko si afẹfẹ ti o le mi ọ kuro ninu rẹ̀. Ko si ohunkohun, iku paapa funrararẹ, ko le yà wà nipa kuro ninu ifẹ Ọlọrun ti o wa ninu Kristi Jesu.

Ohun ti Kalfari jẹ niyi. A tu awọn ọkunrin ti o wà ni ìgbèkùn silẹ. Awọn ọkunrin ti wọn wa labẹ ẹ̀ru ikú lẹẹkan ri wọn ko ni bẹru ikú mọ́. Ọkunrin kan ti n pongbẹ fun ìlú kan eyiti Ọlọrun tẹ̀dó ti o si kọ́, o le rin ni opopo naa, ki o si gbe ojú rẹ soke si ọrun, nitoripe o ti gba itusilẹ. Hallelujah, a ti ra a pada! Ko nilo lati jẹ alarinkiri mọ́, nitori ọ̀nà wà ti iwọ yoo fi mọ̀ boya iwọ tọ́ tabi iwọ ko tọ́. Ọlọrun fun wa ni iye. Gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa ti lọ. Ọjọ naa ni Kalfari ni o san gbèsè naa.

-----
Ni akọkọ, a gbọdọ wá ohun ti ọjọ naa tumọ si. Ni ẹẹkeji, a gbọdọ ri ohun ti ọjọ naa ṣe fun wa, ohun ti o ṣe fún wa, Nisisiyi ni ẹ̀kẹta, ẹ jẹ ki a wo ohun ti o yẹki awa naa pẹlu ṣe fun ọjọ naa, ohun ti o yẹ ki a ṣe. Ni àkọ́kọ́, ẹ jẹ ki a wo o, nitori o jẹ ọjọ nla - ọjọ ti o tobi ju gbogbo ọjọ lọ. A san gbese ẹ̀ṣẹ̀. Agbara Satani ni a fọ́. Ati nisisiyi mo fẹ ki ẹ ri ohun ti o yẹ ki awa naa pẹlu ṣe fun ohun ti O ṣe fun wa.

Bayi, fun ohun ti o ṣe, nigbati Jesu kú ni Kalfari, ko ki n ṣe pe o san gbese ẹ̀ṣẹ̀ wa nikan, ṣugbọn o san gbese naa, O si lana silẹ pe ki a le e tẹle E. Nitori àwa, gẹgẹ bi Adamu ti o ṣubu ti a si ti ra pada .... Gẹgẹ bi Ẹmi ṣe dari Adamu - Adamu akọkọ - nipasẹ Ẹmi, ti o ni akoso lori gbogbo ẹ̀dá, lẹhin naa awa Adamu keji, tabi, ọkunrin ti ayé - a ti ra wa pada nipasẹ Kristi lati ọjọ naa ni Kalfari, ki a ba le tẹle E.

Ka iroyin ni kikun ni...
Ọjọ naa ni Kalfári.


Ohun ijinlẹ Kristi.

Wẹẹbu iwe iroyin Gẹẹsi.

Iwe Ifihan jara.

 

Ọlọrun ati Imọ Atọka.
- Archaeology.

Igbasoke n bọ.

 

Awọn ẹkọ akọkọ
ti ifiranṣẹ naa.

Awọn ti o dara iroyin.
Jesu ku fun ese re.

Iribomi Omi.

 

Awọsanma eleri nla.

Ọwọn ti ina.

Ogo Shekinah ti Ọlọrun.

Ibojì ti ṣofo.
O ti jinde.

Ọlọrun salaye.

Awọn ìgbà ijọ meje.

Awọn edidi meje.

Ọlọrun ati Itan.
jara Atọka - Dáníẹ́lì.

Kristiẹni ije jara.
Ìgbéyàwó Àti Ìkọ̀sílẹ̀.
Akojọ Ifiranṣẹ.

Opin akoko jara.

Ngbe ọrọ jara.

Keresimesi jara.

Iku. Ohun ti nigbana?

Orúkọ Ọlọrun.

Ọkọ Noa.

 

Ẹṣẹ Atilẹba.
Je o ẹya apulu?

Adaparọ.
Awọn orisun - Babeli.

Ọlọrun ati Imọ.
Dainoso Adaparọ.

Archaeology.
Sodomu ati Gomorra.

  Iwe-mimọ sọ...

Èyí ni pé nígbà tí ẹnikẹ́ni bá wà ninu Kristi, ó di ẹ̀dá titun. Ohun àtijọ́ ti kọjá lọ. Ìgbé-ayé irú ẹni bẹ́ẹ̀ sì di titun.

Kọrinti Keji 5:17


Tẹ aworan kan lati ṣe igbasilẹ aworan iwọn ni kikun tabi PDF.


Acts of the Prophet

(PDFs Gẹẹsi)
 

Chapter 9
- The Third Pull

(PDF Gẹẹsi)

Ṣaaju...

Lẹhin...

William Branham
Life Story.

(PDF Gẹẹsi)

How the Angel came
to me.
(PDF Gẹẹsi)




Ifiranṣẹ ibudo...Yan ede rẹ ki o gba awọn ifiranṣẹ ọfẹ lati ọdọ Arákùnrin Branham.