Ọlọ́run Ìran Búburú yìí.

<< išaaju

itele >>

  Opin akoko jara.

Ọlọrun n pe awọn eniyan kan fun Orukọ Rẹ.


William Branham.

Ka iroyin kikun ni...
Ọlọ́run Ìran Búburú yìí.

Bayii, akori iwaasu mi lowurọ yi ni Ọlọrun Akoko Buburu yii. Bi a ti se ka ninu Ọrọ naa, ọlọrun aye yi, akoko buburu yii. Bayii, iwaasu yii n tọka si awọn ibi ti akoko buburu yii. O si jẹ igbagbọ mi pe gbogbo... pe Bibeli ni idahun gbogbo fun akoko kọọkan, a si ti kọọ sinu Bibeli fun onigbagbọ akoko naa. Mo gbagbọ pe ohun gbogbo ti a nilo ni a ti kọ sinu Bibeli yii. O kan nilo ki Ẹmi Mimọ sipaya Rẹ fun wa. Emi ko gbagbọ pe, ẹnikẹni ni ayé yi ni ẹtọ lati se itumọ si Ọrọ Ọlọrun. Ọlọrun ko nilo ẹnikẹni lati tumọ Ọrọ Rẹ. Oun ni olutumọ Ara rẹ. O sọ wipe, ohun yoo see, O si n see.

Gẹgẹ bi mo ti sọ lọpọlọpọ igba. O wipe “wundia kan yoo loyun” O sọ eyii nipasẹ woli kan, o si se bẹẹ. Ẹnikan ko nilo lati sọ itumọ iyẹn. O sọ wipe ni ọjọ ikẹhin, “Oun yoo tu Ẹmi Rẹ jade sori gbogbo eniyan,” O si se bẹẹ. Ko nilo ki ẹnikan tumọ rẹ. O wipe “ni igbẹyin ọjọ, awọn nkan wọnyii ti a ri to n sẹlẹ bayi yoo sẹlẹ. Ko nilo itumọ a ti tumọ rẹ. Se o rii?

Bayi, kiyesi gidigidi bi a se n kẹkọ Ọrọ naa. Ọlọrun Akoko Buburu yii, ti a n gbe inu rẹ yii. O lee sajeji, o sajeji pupọ, ninu akoko Ore-ọfẹ yii, nigbati “Ọlọrun n mu awọn eniyan kan, fun Orukọ Rẹ, Eyi ni Iyawo Rẹ, lati inu iran buburu ti a pe ni akoko buburu yii. Akoko gan an ti ”Ọlọrun n pe awọn eniyan kan fun Orukọ Rẹ, jade nipa ore-ọfẹ, a si pe e ni iran buburu. Bayi, a o o fi idi rẹ mulẹ pẹlu Bibeli, pe eyi ni akoko ti O n sọrọ nipa rẹ.

O sajeji pupọ lati ro eyi, pe ni iran ti o buru bi eleyii ni Ọlọrun yoo ma a pe Iyawo Rẹ. Kiyesi, o wipe awọn eniyan kan, kii se ijọ kan. Tori kin ni? Sibẹ, a pe e ni ijọ naa. Sugbọn Oun yoo pe awọn eniyan kan. Bayii, Ijọ jẹ akojọpọ awọn eniyan to jẹ onirun-u-ru. Sugbọn Ọlọrun n pe ọkan nihin. Ko sọ wi pe “Emi yoo pe Mẹtọdisti, Pẹntikọsiti” o wipe, Oun yoo pe awọn eniyan kan. Fun kin-ni? Fun Orukọ Rẹ. Se o rii, awọn eniyan kan. Ọkan lati Metọdisti, ọkan lati Baptisti, ọkan lati Ijọ Luther. Ọkan lati Katoliiki. Se o rii? Sugbọn O n pe awọn eniyan kan fun Orukọ Rẹ, ti o gba Orukọ Rẹ, ti a fẹ sọna ni Orukọ Rẹ ti wọn si n lọ si igbeyawo kan pẹlu Rẹ, lati di ara Ara Rẹ, nipa iyantẹlẹ. Gẹgẹ bi okunrin kan ti maa n yan iyawo ti o tọ kan laye, ti a yantẹlẹ lati jẹ ara rẹ. Gẹgẹ bẹẹ ni a se n yan iyawo Kristi bayii. Lati saaju ipilẹsẹ aye, Ọlọrun ti yan an tẹlẹ lati jẹ Ara naa. Ah!, Iwe Mimọ lọrọ pupọ, o kun fun oyin.

Kiyesi, kii se ohun ti ẹnikan ti sọ, ti ẹnikan ti pe, sugbọn ohun ti Ọlọrun yan saaju ipilẹsẹ aye, O si n pe awọn eniyan yii, ni ọjọ ikẹhin yii, kii se ẹgbẹ-to-fi-idari-eniyan-rọpo-idari-Ẹmi Mimọ. Awọn eniyan kan fun Orukọ Rẹ. Ni akoko buburu yii, ni Oun si n see, akoko ẹtan yii gan an.

Lọsẹ to lọ, ninu Matiu 24, ohun ni ìran to kún fun ẹ̀tàn julọ ninu gbogbo akoko. Gbogbo akoko ẹtan lati inu ọgba Edẹni lati ibẹrẹ dopin, ko tii si akoko kan to kun fun ẹtan bii ti akoko yii. Awọn woli eke yoo dide, wọn yoo si fi isẹ amin ati isẹ àrà han, to ba seese lati tan Ayanfẹ papa jẹ. Se o rii?̀ Bayii, ijọ to tutu, to gan, to kun fun ẹkọ ẹsin lasan ko ni tilẹ mi Ayanfẹ, Ayanfẹ ko ni kọ bi-ara-si-iyẹn. Sugbọn, eyi to sunmọ otitọ pẹkipẹki yẹn. Fifi kiki Ọrọ Ọlọrun kan silẹ ni o nilo lati se. A seleri yi fun akoko yii, akoko to lagbara. Ẹyin Kristẹni ni ibi gbogbo, ẹ fiyesi wakati ti a n gbe inu rẹ yii! Ẹ sami si, ẹ kaa, ẹ fẹtisilẹ gidigidi.

Kinni idi ti Ọlọrun fi n pe awọn eniyan lati inu akoko buburu yi fun Orukọ Rẹ. Idi nipe, ki a le dan Obinrin yii wo, Iyawo Rẹ. Nigba ti o ba farahan faye ri, ti a fi da satani loju. Gẹgẹ bi o ti ri ni ibẹrẹ bẹẹ ni yoo ri ni igbẹhin.

Irugbin kan maa n bẹrẹ ninu ilẹ, yoo dagba nipasẹ awọn alaaru-iye, sugbọn ni opin rẹ yoo pada di eso ti o jẹ nigba ti a kọkọ gbin-in. Bi iru ẹtan se bẹrẹ ni Edẹni bẹ gẹlẹ ni yoo jẹ ni igbẹhin aye. Gẹgẹ bi Ihinrere se ri, nigbati o subu si ijọ-ẹlẹkọ-adamọ ni Nikia, Romu, yo pari si ẹgbẹ-to-feniyan-sadari-dipo-Ẹmi Mimọ to tayọ. Gẹgẹ bi Iru Ijọ tooto se subu nigba naa, pẹlu isẹ amin ati isẹ ara pẹlu Kristi ti o wa laaye laarin wọn, o n pari ni igbẹyin ọjọ yii labẹ Isẹ-Iriju-Iwaasu Malaki, ori kẹrin, o si dapada wa, Igbagbọ atetekọse ti wọn gba nigba akọkọ.

A rii bayi pe, iran buburu yi wá lati fi Iyawo Kristi han fun satani pe, Oun kii se bi Eefa, pe kii se iru Obinrin bẹẹ. A o o si dan-an-wo, nipa Ọrọ Ọlọrun. Iyawo naa, bi a se dan iyawo Adamu wo nipa Ọrọ naa, Iyawo Adamu si gba gbogbo ọrọ naa gbọ, sugbọn a da a loju ru, lori ileri kan, wi pe, “O jẹ ọkan naa, lana, loni ati titi lae” sugbọn o kuna lori ileri kan, labẹ idanwo ọta lojukoroju. Bayii, awọn eniyan ti a n pe mọn Orukọ Rẹ ni Iyawo Rẹ. Yoo wa sinu ohun kan naa ti o sẹlẹ tẹlẹ, kii se nipa otitọ ẹgbẹ-ẹlẹkọ-adamọ tabi ohun miiran bikose Ọrọ Ọlọrun.

Nitori, ni ibẹrẹ Bibeli, a fun eniyan ni Ọrọ Ọlọrun lati maa gbe nipa Rẹ. Ọrọ kansoso ti a si tumọ nipasẹ satani ninu ẹranko-kan-to-pada-dejo. Ẹranko naa lee ba Eefa sọrọ, ó sì si Ọrọ naa tumọn fun Eefa, o si sọnu. Se o rii? O gbọdọ jẹ gbogbo Ọrọ naa.

Ni agbedemeji Bibeli, Jesu wa o si wipe “Eniyan ki yoo wa laaye nipa akara nikan, sugbọn gbogbo Ọrọ naa.” Nigba ti satani dan an wo. Bayi, Ọlọrun n sọ fun wa ni opin ọjọ, pe “Ọlọrun aye buburu yii yoo dide ni igbẹhin aye”. Ọlọrun saanu fun wa! Ẹ mase jẹ ka rìn pẹlu igberaga, to ti àyà sita, to mọ-ọn tan, nitori awa pẹlu wa ninu aigbọran nigba kan ri. Ẹ jẹ ki a wa si ibi Itẹ Ore-Ọfẹ, pẹlu ore ọfẹ, aanu ati imọlara ninu ọkan wa si Ọlọrun.

O ya ni lẹnu bayii, lẹhin iwaasu Ihinrere fun ẹgbẹrun ọdun meji o din ọgọrun ọdun, nisisiyi, awọn ìlànà aye buru pupọ ju igba ti Oluwa wa laye. Awọn ilana aye buru sii. Aye n lọ si asepari nla kan. Ẹ mọn eleyi. Oluwa n mu Ọrọ Rẹ sẹ ni gbogbo ọna.

Ìfihàn 18:4-5,
4 Mo si gbọ ohun miiran lati ọrun wa n wi pe, “Ẹ ti inu rẹ̀ jade ẹyin eniyan mi. ki ẹ ma baa se alabapin ninu ẹsẹ rẹ̀, ki ẹ ma baa si se gba ninu iyọnu rẹ̀.
5 Nitori awọn ẹsẹ rẹ ga, ani de ọrun. Ọlọrun si ti ranti aisedeede rẹ̀.

----
Iru ikilọ wo niyii! Eyi sọ ijọ pada si Ifihan 3:14, si igba Ijọ Laodikia gẹlẹ. Iwa aibikita fun ofin, o kun fun ẹsin, sugbọn ko bikita fun ofin Ọlọrun. “Nitori ti iwọ wipe awa lọrọ, a ko si salaini ohunkohun? Iwo ko si mọn pe, iwọ wa ni ihoho, o jẹ ẹni are, o fọju, o ko si mọn ọn”. O ba Iwe Mimọ ti igba Ijọ yii mu, kii se fun Iwe Mimọ ọjọ ti Danieli, kii se ti ọjọ ti Noa, sugbọn ti iran buburu to gbẹyin yi.

Kiyesi nihin, “Iwọ wa ni ihoho”. Jẹ ki iyẹn ki o wọ ọkan wa lọ daradara. Mo mọn pe, mo lee ni ọpọ atako lori ero yii, sugbọn o ti wa de ibi ti o fẹrẹ ma seese, ki Kristẹni jade ni ile rẹ, lai ba ara rẹ niwaju iran buburu yi nipa awọn obinrin ti ko wọsọ to bo ihoho ara.

Ẹyin obinrin, mo fẹ sọ eyi, mo si fẹ ki ẹ fẹtisilẹ, Ẹyin okunrin ati obinrin, ẹ lee tako eleyi, sugbọn a dari mi lati sọọ. Njẹ o mọn wi pe, obinrin ti o fi ihoho ara rẹ han bayi ko si ninu ọpọlọ pipe? Njẹ o mọn wi pe, asẹwo ni, yala o gba ohun ti mo sọ yii gbọ tabi ko gbagbọ, bi o ro bẹẹ tabi o ko ro bẹẹ? Bi Obinrin yi tilẹ lee duro niwaju Ọlọrun pẹlu ọwọ ti o na soke, ki o si bura wi pe okunrin miiran ko fọwọ kan ohun ri yatọ si ọkọ oun, ohun to sọ yi tilẹ lee jẹ otitọ, sibẹ asẹwo ni. Jesu wi pe, “ẹnikẹni ti o ba wo obinrin lati se ifẹkufẹ si ti baa se pansaga na”, obinrin na si lee....

Woo, o wa ni ihoho. Bibeli wi pe “oun ko si mọn ọn”, Ẹmi ti o n tami ororo lee, lati se ohun bi eleyi jẹ ẹmi ibi, ẹmi asẹwo. Ẹda rẹ ni ode ara, agọ ara rẹ, ẹran ara rẹ le mọn. O le ma se pansaga, o si lee bura si Ọlọrun ki o si jẹ otitọ, pe oun ko se pansaga rị, sugbọn ẹmi rẹ jẹ ẹmi asẹwo. Orisa iwọsọ ati imura ode oni ti fọ ọ loju tobẹẹ ti o fi n wọsọ ifẹkufẹ to si n jade sita bẹẹ.

----
Eniyan ti ita ti a foju rí ní oòmọ̀n ara marun-un. Okunrin ti inu jẹ okunrin ẹmi ti o ni oomọn marun-un tii sẹ ẹri-ọkan, ifẹ ati bẹẹbẹẹ lọ. Ọkunrun ti ode ni, riri, titọwo, ifọwọkan, ìgbọ́-òórùn. Sugbọn ninu ẹmi yẹn ni ọkan kan wa, a si n dari rẹ̀ nipa ohun kan, tii se ifẹ-inu-rẹ, yiyan ohun too fẹ. Iwọ lee gba ohun ti esu sọ, tabi ki o gba ohun ti Ọlọrun sọ. Eyi yoo si fi ẹmi inu rẹ han. Bi o ba jẹ Ẹmi Ọlọrun, yoo maa jẹ ohun tii se ti Ọlọrun, ki yoo si jẹ ohunkohun tii se ti aye. Jesu wi pe, “Bi iwọ ba fẹ aye tabi ohun tii se ti aye, o jẹ nitori pe, ifẹ Ọlọrun ko i tii wọ inu ọkan rẹ rara”. Satani ti tan ọ jẹ. “Eniyan ki yoo si wa laaye nipa akara nikan, bikose nipa gbogbo Ọrọ ti o ti ẹnu Ọlọrun jade”. Kiyesii bayi, a sọ wi pe, o wa ni “ihoho” o kun fun ifẹkufẹ, o wa ni ihoho goloto.

O si da bi ẹni pe, aye wa ni iran to buru julọ ti o tii wa ri. Ko si iran kan ti awọn obinrin tii se bi wọn ti n se yii, ayafi iran ti o wa saaju ikun omi. Jesu si tọka sii. A o de ibẹ laipẹ.

Se Ọlọrun ti sọ agbara lati dari nu ni? Abi O kan n gba agbara miiran laaye lati dari aye? O se mi ni kayeefi. Idahun tootọ si ibeere yii gẹgẹ bi ero temi ni pe, awọn ẹmi meji ti wọn doju ija kọ ara wọn lo n sisẹ ninu aye loni. Ko lee ju awọn meji lọ, ori meji. Ọkan ninu wọn ni Ẹmi Mimọ to n sisẹ. Ekeji si ni ẹmi esu kan ni opin aye yii ti o n sisẹ ẹtan. Emi yoo gbe ero mi le ori koko ọrọ yii fun iyoku iwaasu mi.

Awọn ẹmi meji naa. Ọkan ninu wọn ni Ẹmi Ọlọrun; ekeji si ni ẹmi esu, to n sisẹ ninu ẹtan. Awọn eniyan aye si nyan eyi ti o wu wọn bayii. Ẹmi Mimọ wa nibi, o n pe Iyawo kan jade fun Kristi. O n se e nipa jijẹri gbe Ọrọ Ileri Rẹ si Iyawo yii, fun iran yii, O n fi I han pe, Kristi ni. Bi o ba yẹ ki ika ọwọ se ohun kan ni iran yii, ika ọwọ yoo se. Bi o ba yẹ ki ẹsẹ tẹsiwaju, yoo see. Bi o ba yẹ ki oju riran ni iran yii, oju yoo riran. Se o rii? Ẹmi Ọlọrun, gẹgẹ bi o ti se dagba de ẹkun rẹrẹ iduro Ọlọrun, ohun ni iran ti a ngbe inu rẹ yii. Ẹmi Mimọ wa nibi, O n jẹri gbe Isẹ Iransẹ wakati yii. Ẹmi Mimọ si n se eyi, ki a lee pe awọn ti o gba Ọlọrun gbọ kuro ninu rudurudu yii. Ẹmi aimọ ti esu si wa laye, o n pe ijọ tirẹ jade nipa ẹkọ isina, bi o ti maa n se, nipa idibajẹ Ọrọ Ọlọrun, gẹgẹ bi o ti se ni ibẹẹrẹ. Ẹ rii ti o n padabọ si akoko irugbin lẹẹkan si lati Edẹni? Ohun tun ni yii lẹẹkan si.

Ka iroyin kikun ni... Ọlọ́run Ìran Búburú yìí.



Ifiranṣẹ ibudo...Yan ede rẹ ki o gba awọn ifiranṣẹ ọfẹ lati ọdọ Arákùnrin Branham.


Ohun ijinlẹ Kristi.

Wẹẹbu iwe iroyin Gẹẹsi.

Iwe Ifihan jara.

 

Ọlọrun ati Imọ Atọka.
- Archaeology.

Igbasoke n bọ.

 

Awọn ẹkọ akọkọ
ti ifiranṣẹ naa.

Awọn ti o dara iroyin.
Jesu ku fun ese re.

Iribomi Omi.

 

Awọsanma eleri nla.

Ọwọn ti ina.

Ogo Shekinah ti Ọlọrun.

Ibojì ti ṣofo.
O ti jinde.

Ọlọrun salaye.

Awọn ìgbà ijọ meje.

Awọn edidi meje.

Ọlọrun ati Itan.
jara Atọka - Dáníẹ́lì.

Kristiẹni ije jara.
Ìgbéyàwó Àti Ìkọ̀sílẹ̀.
Akojọ Ifiranṣẹ.

Opin akoko jara.

Ngbe ọrọ jara.

Keresimesi jara.

Iku. Ohun ti nigbana?

Orúkọ Ọlọrun.

Ọkọ Noa.

 

Ẹṣẹ Atilẹba.
Je o ẹya apulu?

Adaparọ.
Awọn orisun - Babeli.

Ọlọrun ati Imọ.
Dainoso Adaparọ.

Archaeology.
Sodomu ati Gomorra.

  Iwe-mimọ sọ...

Lẹ́yìn èyí mo tún rí angẹli tí ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ bọ̀. Ó ní àṣẹ ńlá. Gbogbo ayé mọ́lẹ̀ nítorí ẹwà ògo rẹ̀.

Ó wá kígbe pé, “Ó tú! Babiloni ìlú ńlá tú! Ó wá di ibi tí àwọn àǹjọ̀nnú ń gbé, tí ẹ̀mí Èṣù oríṣìíríṣìí ń pààrà, tí oríṣìíríṣìí ẹyẹkẹ́yẹ ń kiri.

Ìfihàn 18:1-2



 

Tẹ aworan kan lati ṣe igbasilẹ aworan iwọn ni kikun tabi PDF.


Acts of the Prophet

(PDFs Gẹẹsi)
 

God is Hidden and
Revealed in Simplicity.

(PDF Gẹẹsi)

William Branham
Life Story.

(PDF Gẹẹsi)

How the Angel came
to me.

(PDF Gẹẹsi)