Kikan Jesu Kristi mọ agbelebu lẹẹkeji!

<< išaaju

itele >>

  Opin akoko jara.

Ìfẹ̀sùnkanni Na.


William Branham.

Ka iroyin ni kikun ni...
Ìfẹ̀sùnkanni Na.

Loni, mo fẹ ka awọn ẹsẹ Iwe Mimọ kan, ni iṣẹju kan, lati inu Ọrọ Ọlọrun mimọ, eyiti a ri ninu iwe Luuku Mimọ, ori kẹtalelogun, iwe Luuku Mimọ fun ipilẹ - lati fi ipilẹ lelẹ fun ohun ti mo fẹ sọ, ero kan pato nipa ohun ti mo fẹ sọ. Ẹ jẹ ki a ṣi Luuku Mimọ ori kẹtalelogun. Mo fẹ ka ẹsẹ kan; ohun ti mo nilo niyẹn fun ipilẹ owurọ yii, lati gbe ọrọ yii le. Ni bayi, a o ka ẹsẹ ogun - ori ikẹtalelogun, ẹsẹ ikẹtalelọgbọn ni ori ikẹtalelogun.

Nigbati wọn si de ibi ti a n pe ni Agbari, nibẹ ni wọn gbe kan-an mọ agbelebu, ati awọn arufin naa, ọkan ni ọwọ ọtun, ati ọkan ni ọwọ osi.

Ni bayi, mo fẹ mu ọrọ mẹrin lati ibẹyẹn, lati ibi ti a ka, lati fi ṣe ipilẹ ohun ti mo fẹ sọ: nibẹ ni wọn kan-an mọ agbelebu - ọrọ mẹrin. Koko ọrọ mi ni mo pe ni... Mo n fi ẹ̀sùn kan awọn ijọ ẹlẹkọ-adamọ ọjọ oni, ati ọpọlọpọ awọn ijọ ti o da duro, wipe wọn kan Jesu Kristi mọ agbelebu ni ọtun loni - mo n fi ẹ̀sùn kan wọn. Akori iwaasu mi ni owurọ yii ni mo pe ni Ìfẹ̀sùnkanni Na.

Mo si fẹ ṣe e ki o dabi iyara kan, ile-ẹjọ kan, nibiti o wa... Ju gbogbo rẹ lọ, pẹpẹ iwaasu ati ile-ijọsin jẹ ile- ẹjọ. Bibeli sọ wipe itẹ idajọ ni... wipe idajọ yoo bẹrẹ lati ile Oluwa lọ. Eyi si dabi itẹ-idajọ ati awọn adajọ, ati awọn ẹlẹri, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ẹniti o jẹ ẹlẹri mi loni ni Ọrọ Ọlọrun, mo si fi ẹ̀sùn kan awọn ijọ ọjọ oni. Emi ko mu ẹlẹṣẹ wa sinu eyi; ijọ nikan ni mo n sọ eyi si. Yoo wa ninu fanran, emi yoo si gbiyanju lati tete ṣetan.

Mo fi ẹ̀sùn kan iran yii fun kikan Jesu Kristi mọ agbelebu lẹẹkeji!

Ni bayi, lati ṣe eyi ni iran ti a n gbe inu rẹ yii, lati ṣe eyi, mo nilati fi ẹri han. Ti mo ba nilati mu ẹ̀sùn wá, a nilati fi ẹri iwa ọdaran naa han, eyiti a ti hu. Lati fi ẹ̀sùn kan wọn, mo nilati mu ẹri wa lati fi idi rẹ mulẹ, wipe o ri bẹẹ - wipe ohun ti mo n sọ yoo lee duro niwaju adajọ agba, eyiti... Mo si fi ara mi ṣe agbẹjọro fun - lori ẹ̀sùn yii.
Nitoripe Ọrọ Ọlọrun ni ẹlẹri mi, mo fi ẹ̀sùn kan iran yii fun kikan mọ agbelebu.

Mo gbọdọ fihan, n o si fihan, wipe ẹmi kannaa ti o wa lara awọn eniyan loni, ni ẹmi kannaa ti o mu kikan mọ agbelebu akọkọ wa, o si n ṣe nkan kannaa bayi. Mo nilati ṣe bẹẹ, ti yoo ba jẹ kikan mọ agbelebu, eyiti wọn kan-an mọ agbelebu. Mo gbọdọ fi han awọn eniyan wipe iṣesi kannaa ninu awọn eniyan loni ni o n ṣe nkan kannaa, nipa ti ẹmi, eyiti wọn ṣe nipa ti ara nigbanaa: wọn kan Jesu Kristi nipa ti ara mọ agbelebu, ani Ọmọ Ọlọrun.

Loni, nipa Ọrọ kannaa, nipa Ẹmi Mimọ kannaa, ati Ọrọ kannaa, mo fẹ fihan fun awọn ijọ, ibi ti wọn duro si: wipe wọn n ṣe nkan kannaa loni; Bibeli si wipe wọn yoo ṣe e; a o si fihan wipe ọjọ naa ni a n gbe inu rẹ bayi. Wọn ko lee ṣe e ni ọdun melo kan ṣẹyin. Mo lee sọ wipe aadọta ọdun ṣẹyin, wọn ko lee ṣe e. Ṣugbọn oni gan-an ni akoko naa. Wọn ko si lee ṣe e ni bii ọdun mẹwa ṣẹyin, ṣugbọn wọn lee ṣe e loni, nitori ọjọ ti lọ. A ti wa ni igba ikẹyin. Mo si gbagbọ, gẹgẹbi iranṣẹ Rẹ, wipe a ti fẹ kuro ni ilẹ yii lo si ilẹ miiran.

Nitorinaa, akoko ironupiwada fun orilẹ-ede ti lọ, mo gbagbọ wipe orilẹ-ede yii ko lee ronupiwada. Mo gbagbọ wipe o ti re aala aanu kọja si idajọ. Mo gbagbọ wipe o n fi dirodiro bayi.

“Arakunrin Branham, ki o to bẹrẹ ẹjọ rẹ, bawo ni o ṣe fẹ fidi rẹ mulẹ?” Bayi ni: wipe a jẹbi ẹṣẹ kannaa, eyiti o mu ki Ọlọrun pa aye run ni igba ẹkun omi. A jẹbi awọn ẹṣẹ kannaa ti O mu ki O pa aye run ni igba Sodomu ati Gomora. Njẹ ni bayi... A ni gbogbo ẹri ti ẹmi niwaju wa bayi, gbogbo ẹri ti ẹmi, ti gbogbo aye mọ, eyiti o mu aanu Ọlọrun sọkalẹ wa sori awọn iran wọnyẹn, eyiti o jẹ wipe nigbati wọn kọ ọ, o mu idajọ wa. Njẹ ti iran yii ba ti kọ aanu kannaa ti wọn kọ ni igba yẹn, Ọlọrun yoo jẹ alaiṣododo lati jẹ ki wọn lọ bẹẹ lai si idajọ.

A mọ wipe nipa ti ẹmi, wọn n ṣe nkan kannaa loni, nitoriti wọn n ṣe e fun idi kannaa, ati ni ọna kannaa ti wọn fi ṣe e nigbati wọn kan Oluwa mọ agbelebu nipa ti ara. Wọn n ṣe e nitori owu jijẹ, nitori ifọju ti ẹmi, wipe wọn ko fẹ ri i; wọn ko fẹ feti si i. Jesu, ninu irin-ajo Rẹ lori ilẹ aye, O wipe, “Otitọ ni Isaiah sọ nipa tiyin wipe; ẹ ni oju, ẹ ko riran, ẹ ni eti, ẹ ko gbọran.”

Idi kannaa, ipinnu kannaa, ati awọn ero kannaa, wọn tun n mu kikan Kristi mọ agbelebu wa lọtun, ni ọtun (a o de ibẹ laipẹ), fun idi kannaa ti wọn fi ṣe e ni igba yẹn. Wọn ko ri nkankan lodi si i; wọn ko jẹ pe e nija. Wọn si mọ wipe ẹri naa wa nibẹ; wọn si mọ wipe Bibeli sọ bẹẹ; ohun kanṣoṣo ti wọn lee ṣe ni ki wọn sọrọ odi si i. Bẹẹ gan-an ni. Nitorinaa... Gbogbo nkan wọnyi, idi kannaa ni....

Ni bayi, nitori idi yii, mo fi ẹ̀sùn kan iran yii nitoriti wọn kan Jesu Kristi mọ agbelebu, fun kikan mọ agbelebu, wọn jẹbi. Pẹlu ọwọ ijọ ẹlẹkọ-adamọ ti o dọti, ọwọ buburu, ọwọ imọ-tara-ẹni-nikan ni wọn fi kan Ọmọ Alade Iye mọ agbelebu, ti O fẹ fi ara Rẹ han fun awọn eniyan.
O lee wipe, “Ẹni kannaa kẹ?”
“Ni atetekọṣe ni Ọrọ wa... Ọlọrun si ni Ọrọ naa. Ọrọ naa si di ara,” o fi ara rẹ han. Ọrọ naa farahan ninu ara, wọn si da ara naa lẹbi, wọn pa a; nitoriti Ọrọ naa farahan. Heberu 13:8 wipe, “Jesu Kristi, ọkannaa lana, loni, ati titi lae.” Ọrọ kannaa ni. Ṣe ẹ ri i? Fun idi kannaa, wọn n gbiyanju lati kan Ọrọ naa mọ agbelebu.

Sori akori ọrọ mi bayi, lati fọ koko ọrọ ti mo fẹ sọ si wẹwẹ: Nibẹ... awọn ọrọ mẹrin naa. Ẹ jẹ ki a ṣalaye rẹ. Nibẹ, ilu ti o mọ julọ ni agbaye, Jerusalẹmu; nibẹ, ilu ti o kun fun ẹsin julọ ni gbogbo aye. Nibẹ, awọn, awọn eniyan ti o kun fun ẹsin julọ ni gbogbo aye, nibi àsè ẹsin, àsè Irekọja. Nibẹ, ibi ti o kun fun ẹsin julọ, ilu ti o kun fun ẹsin julọ, olu gbogbo awọn ijọ ti a fi ọgbọn eniyan gbe kalẹ, ori gbogbo wọn, nibẹ, awọn, awọn ẹlẹsin julọ ni gbogbo aye, wọn pejọpọ lati gbogbo aye. Wọn kan mọ agbelebu, iku itiju julọ ti o lee - ti a fi lee pa ẹnikẹni - nihooho, wọn bọ aṣọ kuro lara Rẹ. O farada ẹgan naa. Aworan agbelebu ní aṣọ kan ti a fi yi ara Rẹ, ṣugbọn wọn bọ aṣọ Rẹ kuro lara Rẹ. Ohun ti o ti ni loju julọ...

Nibẹ (ilu ẹlẹsin julọ), awọn (awọn eniyan ẹlẹsin julọ), kan mọ agbelebu (iku ti o ti ni loju julọ), Oun (ẹniti o ṣe iyebiye julọ).

Ṣe iyẹn ko ha to lati da iran yii lẹbi! Nibẹ, awọn ijọ ẹlẹsin julọ, awọn ijọ ti o tobi julọ, wọn pejọ pọ si ọna kan; awọn, awọn ẹlẹsin julọ ninu gbogbo ẹya, awọn eniyan ti o yẹ ki wọn jẹ olufọkansin Ọlọrun... Wọn pejọ pọ nibi àsè mimọ julọ ti wọn ni, iwẹnumọ Irekọja, nigbati a mu wọn jade kuro ninu ide sinu ominira. Nibẹ, ni akoko yẹn, awọn, ni igba yẹn, awọn ẹlẹsin julọ, nibi àsè ẹsin ti o tobi julọ, ni ilu ẹsin julọ, wọn mu ohun ti o ti ni loju julọ ba Ọmọ-alade iye: lati bọ eniyan si ihooho, ki wọn si gbe e kọ sori igi; nitori “Egbe ni fun ẹni naa...” ni ofin ti wọn fi n jọsin sọ, “Egbe ni fun ẹni naa ti a gbe kọ sori igi.” A sọ ọ di ẹgun fun wa. Wọn bọ aṣọ rẹ, wọn na a, wọn fi i ṣe ẹlẹya, Ọlọrun ọrun funra Rẹ, wọn bọ aṣọ Rẹ kuro lara Rẹ, wọn si kan-an mọ agbelebu... Oun, nibẹ ni wọn ti kan-an mọ agbelebu labẹ ijiya Roomu ti o ga julọ.

Iku ti o ti ni loju julọ loni ki yoo jẹ wipe a yan ibọn pa eniyan. Iku ti o ti ni loju julọ loni ki yoo jẹ - wipe a fi ọkọ ayọkẹlẹ pa eniyan, tabi ki a tẹ ẹ ri sinu omi, tabi ki a fi ina sun-un; ṣugbọn iku ti o ti ni loju julọ loni ni ijiya ti o ga julọ ni gbangba, nibiti gbogbo aye yoo ti fi ẹ̀sùn kan ọ wipe o jẹbi. Gbogbo aye si gbe ọwọ wọn le ọkunrin yii, wọn sọ wipe O jẹbi, nigbati O jẹ alailẹṣẹ. O kú labẹ ọta, kii ṣe ti awọn ọrẹ Rẹ, kii ṣe awọn ofin Rẹ, ṣugbọn labẹ kikan mọ agbelebu ọta, Ọmọ-alade iye, ẹni ti o ṣe iyebiye julọ ti o tii wa si aye ri, tabi ti yoo wa si aye ri, Jesu Kristi - Oun, ẹniti o ṣe iyebiye julọ. Ẹ fi iyẹn si ọkan bi a ṣe n mu ipilẹ ọrọ naa wa loni.

-----
Ni bayi, awọn ọrọ mẹrin wọnyẹn: Nibẹ wọn kan-an mọ agbelebu. A si n fi Bibeli han bayi. Ṣe ẹ ri i, ọrọ mẹrin pere ni, ṣugbọn Bibeli ko awọn otitọ rẹ pọ. Ni temi, mo nilati lọ kaakiri lati ṣalaye ohun ti mo n sọ, ṣugbọn Bibeli ko nilo lati ṣalaye ohunkohun. Otitọ ni gbogbo rẹ. Nitorinaa, Bibeli ko nilati ṣalaye ohunkohun. Ko nilo lati ṣalaye rẹ, nitori otitọ ni gbogbo rẹ.

Ọrọ mẹrin niwọnyi ninu awọn otitọ nla rẹ. Emi yoo gbiyanju lati ṣalaye rẹ. Lati ṣalaye rẹ yoo gba ọpọlọpọ iwe. Ko si ọna fun mi lati ṣalaye awọn ọrọ mẹrin wọnyẹn. Ṣugbọn ni bayi, ẹ jẹ ki awa, nipa iranlọwọ ẹniti o mu ki a kọ iwe naa, ẹ jẹ ki a gbiyanju lati ṣalaye awọn ọrọ mẹrin wọnyẹn, lati mu u wa ni ọna ti o jẹ wipe awọn eniyan yoo lee loye rẹ.
Kini a ni niwaju wa bayi? A ni kikan mọ agbelebu akọkọ niwaju wa, ni ibi mimọ julọ, awọn ẹlẹsin julọ, iku ti o ti ni loju julọ, si ẹniti o ṣe iyebiye julọ. Ah, ohun ti o tako ara wọn ni! Kai, ohun itiju ni!

-----
Ẹ kiyesi i, awọn, awọn olujọsin, awọn eniyan ti wọn ti n foju sọna fun ileri naa, awọn ti wọn ti n foju sọna fun-un ni gbogbo ọdun ati ni gbogbo iran, lai ṣe iṣẹ miiran bikoṣe ki wọn wa ni ilẹ-ẹkọ ẹsin yẹn nigbagbogbo; ṣugbọn wọn ti pin Ọrọ naa gẹgẹbi ẹkọ ilẹ-ẹkọ ẹsin wọn, wọn si ti padanu otitọ rẹ. Awọn, awọn alufaa, iṣẹ-iriju ọjọ yẹn; nibẹ, ni olu-ilu ẹsin wọn, awọn, iṣẹ-iriju ọjọ yẹn n pa Ọlọrun naa, Ọdọ-aguntan naa. Ẹni naa ti wọn sọ wipe awọn n sin, wọn n pa a.

Loni ẹwẹ, mo fi ẹ̀sùn kan awọn oniwaasu ti a ti yan wọnyi! Ninu ẹkọkẹkọ wọn, ati ninu ijọ ẹlẹkọ-adamọ wọn, wọn n kan Ọlọrun kannaa mọ agbelebu niwaju awọn eniyan, Ọlọrun ti wọn sọ wipe awọn fẹran ti awọn si n sin. Mo fi ẹ̀sùn kan awọn oniwaasu wọnyi ni orukọ Jesu Oluwa, nitori ẹkọ wọn, awọn ti wọn n sọ wipe ọjọ iṣẹ-iyanu ti kọja, ati wipe baptisiimu omi ni orukọ Jesu Kristi ko to, ko si tọ́. Nitori eyikeyi ninu ọrọ wọnyi ti wọn ti fi ẹkọ-adamọ rọpo rẹ, mo fi ẹ̀sùn kan wọn wipe wọn jẹbi, ati wipe ẹjẹ Jesu Kristi n bẹ lọwọ wọn, fun wipe wọn kan Jesu Oluwa mọ agbelebu lọtun lẹẹkeji! Wọn n kan Kristi mọ agbelebu fun awọn eniyan, wọn n gba ohun ti o yẹ ki wọn fun wọn kuro lọwọ wọn, wọn si fi ohun miiran rọpo rẹ, ani ẹkọ-adamọ ijọ nitori okiki.

-----
Mo da awọn ẹgbẹ kannaa lẹbi loni, mo fi ẹ̀sùn kan wọn wipe wọn jẹbi niwaju Ọlọrun, nipa Ọrọ Ọlọrun, wipe wọn n ṣe nkan kannaa. A fi ẹ̀sùn kan iran yii.
Ẹ ranti Heberu 13:8. Ọkannaa ni lana, loni, ati titi laelae.
Bawo ni wọn ṣe da a lẹbi? Nitoriti ẹkọ-adamọ wọn ko gba a. Ninu ọkan wọn, wọn mọ yatọ. Njẹ Nikodemu, ni ori kẹta iwe Johanu Mimọ, ko ha sọ ọ bi? “Rabbi, awa, awa Farisi, awa oniwaasu, awa olukọ, awa mọ wipe olukọni ti a ran lati ọdọ Ọlọrun wa ni Ọ, nitori ko si ẹniti o lee ṣe awọn ohun ti Iwọ n ṣe bikoṣepe Ọlọrun wa pẹlu rẹ,” ṣe ẹ ri i. Ọkan lara wọn jẹri nipa rẹ ni gbangba. Ṣugbọn nitori ẹkọ-adamọ wọn, wọn kan Kristi mọ agbelebu. Loni ẹwẹ, ko si ẹniti o lee ka iwe, ti ko ni lee ka Iṣe Awọn Aposteli 2:38 gẹgẹbi emi naa ṣe lee ka a, ati awọn ti o ku naa gẹgẹbi mo ṣe lee ka a. Ṣugbọn nitori ẹkọ-adamọ wọn, ati nitori iwe ijọ ẹlẹkọ-adamọ wọn, ni apo wọn. (Ami ẹranko naa, eyiti wọn n gbe kiri gẹgẹbi iwe idapọ). Nipa gbigba awọn nkan wọnni, wọn kan Jesu Kristi mọ agbelebu si ara wọn lọtun, wọn si kan-an mọ agbelebu ni gbangba, wọn si sọ ọrọ-odi si Ọlọrun ti o ṣe ileri lati ṣe nkan yii, wọn si di ẹbi ru iran yii.

Ka iroyin ni kikun ni... Ìfẹ̀sùnkanni Na.


Ohun ijinlẹ Kristi.

Wẹẹbu iwe iroyin Gẹẹsi.

Iwe Ifihan jara.

 

Ọlọrun ati Imọ Atọka.
- Archaeology.

Igbasoke n bọ.

 

Awọn ẹkọ akọkọ
ti ifiranṣẹ naa.

Awọn ti o dara iroyin.
Jesu ku fun ese re.

Iribomi Omi.

 

Awọsanma eleri nla.

Ọwọn ti ina.

Ogo Shekinah ti Ọlọrun.

Ibojì ti ṣofo.
O ti jinde.

Ọlọrun salaye.

Awọn ìgbà ijọ meje.

Awọn edidi meje.

Ọlọrun ati Itan.
jara Atọka - Dáníẹ́lì.

Kristiẹni ije jara.
Ìgbéyàwó Àti Ìkọ̀sílẹ̀.
Akojọ Ifiranṣẹ.

Opin akoko jara.

Ngbe ọrọ jara.

Keresimesi jara.

Iku. Ohun ti nigbana?

Orúkọ Ọlọrun.

Ọkọ Noa.

 

Ẹṣẹ Atilẹba.
Je o ẹya apulu?

Adaparọ.
Awọn orisun - Babeli.

Ọlọrun ati Imọ.
Dainoso Adaparọ.

Archaeology.
Sodomu ati Gomorra.

  Iwe-mimọ sọ...

Nígbà tí wọ́n dé ibi tí wọn ń pè ní, “Ibi Agbárí”, wọ́n kàn án mọ́ agbelebu níbẹ̀ pẹlu àwọn arúfin meji náà, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, ekeji ní ọwọ́ òsì.

Luku 23:33


Tẹ aworan kan lati ṣe igbasilẹ aworan iwọn ni kikun tabi PDF.


Acts of the Prophet.

(PDFs Gẹẹsi)

Chapter 11
- The Cloud

(PDF Gẹẹsi)

Chapter 14
- Sabino Canyon

(PDF Gẹẹsi)
Ibi te idà farahan.

Eyi ha ni ami
opin bi, alagba?

(PDF) Òke Iwọoorun.
Nibiti awọsanma farahan.



 


Ifiranṣẹ ibudo...Yan ede rẹ ki o gba awọn ifiranṣẹ ọfẹ lati ọdọ Arákùnrin Branham.