Ìrora Ìbímọ.
<< išaaju
itele >>
Ọrun tuntun kan ati aye tuntun kan.
William Branham.Ka iroyin kikun ni... Ìrora Ìbímọ.
Ni bayi, mo fẹ lati sọrọ ni ọsan yi lori àkòrí kan ti mo ti kede: “Ìrora Ìbímọ.” Bayi o dabi pe ko dun un gbọ létí, ṣugbọn o wa ninu Bibeli. Mo gbagbọ pe Jesu n sọrọ nipa rẹ nibiyi, bi O ti sọ, “Iwọ yoo ni ibanujẹ, ṣugbọn ibanujẹ rẹ yoo di ayọ” - O n sọrọ nipa awọn ọmọ-ẹhin Rẹ nibi, bi O ti ṣe mọ pe a o bí ẹsin Kristiẹni laipẹ.
Bayi, ògbólógbò naa ni lati ku ki ànfàní le wa lati bi tuntun. Lati ni.... Ohunkohun ti o ba n bi ọmọ ni lati ni irora ti ìnira, ati pe dajudaju wọn ni lati la irora ti ìnira ati ipọnju kọja ki wọn le rekọja lati inu òfin sinu ore-ọfẹ. Ìbí ti o jẹ pípé ati ti o si jẹ lai ṣe iṣẹ abẹ n ṣe apẹẹrẹ iru ìbí ti ẹ̀mí. Gbogbo ohun ti o jẹ ti ẹ̀dá - ti ara n ṣe apẹẹrẹ ti ẹmi. Ati pe ti a ba ṣe akiyesi ti a ba wo ilẹ ti a si ri igi kan ti o n dagba lori ilẹ, o n tiraka lati ni iye. Eyi lo fi han fun wa pe igi kan wa nibikan ti ko ni ku, nitoripe o n kérora fun ohun kan. A ri awọn eniyan, bi o ti wu ki wọn dagba to, bi wọn ti le ṣe aisan to, ipo-ki-po ti wọn wa wọn n kerora lati wa laaye nitori èyí fi han fun wa pe ìyè kan wa nibikan nibiti a o gbé — gbé laelae. Ṣe akiyesi bi o ṣe jẹ pipe.
Ni bayi, ninu iwe Johanu kinni ori karun un ẹsẹ keje 1 Johanu 5:7 (Mo gbagbọ pe ohun ni, ti n ko ba ṣe aṣiṣe), o sọ pe, “Awọn mẹta ni o njẹri ni ọrun: Baba, Ọrọ, ati Ẹmi Mimọ: awọn mẹtẹta yi si jẹ ọkan. Awọn mẹta ni o njẹri ni ayé; eyi ni omi, ẹ̀jẹ̀, ati Ẹmi, ati pe awọn mẹtẹta si fi ohun sọkan.” Bayi, awọn mẹtẹta àkọ́kọ́ jẹ ọ̀kan; awọn mẹtẹta keji jẹ ti ayé wọn si fi ohun sọkan. O ko le ni Baba laisi Ọmọ; o ko le ni Ọmọ lai ni Ẹmi Mimọ. Ṣugbọn o le ni omi laisi ẹjẹ ati ẹjẹ laisi Ẹmi.
Mo ro pe nipasẹ awọn igba ijọ wa a ti fi ìdí eyi mulẹ pe o jẹ otitọ. Omi, ẹjẹ, Ẹmi; idalare, isọdimimọ, Iribọmi ti Ẹmi Mimọ. Eyi n ṣe àfiwé tabi imusẹ rẹ eyiti a mu jade lati inu ìbí ti ẹda. Wo nigbati obinrin kan tabi ohunkohun ba wa ninu ìrora ti ibimọ, ohun àkọkọ yoo sẹlẹ̀: omi a tú jade (ibimọ ti ko ni isẹ́ abẹ ninu); ohun keji ni ẹjẹ; ati lẹhinna ni ìyè; omi, ẹjẹ, ẹ̀mi. Ati pe eyi jẹ àpapọ̀ ibimọ pípé, ibimọ ti ko ni iṣẹ́ abẹ nínú.
Bẹẹ si ni o ṣe wa ninu ìpele ti ẹmi. Omi ni; idalare nipa igbagbọ, gbigbagbọ ninu Ọlọrun, gbigba A gbọ gẹgẹ bi Olugbala rẹ kan ṣoṣo, ati ki o ṣe iribọmi. Ikeji jẹ isọdimimọ ti Ẹmi, pe Ọlọrun ti wẹ ẹ̀mí mọ kuro ninu gbogbo awọn ohun ti aye ati ifẹ ti aye. Lẹhinna, Ẹmi Mimọ wa wọle O si fun ọ ni ìbí tuntun ati pe o si kun ohun èlò naa ti a sọ di mimọ.
Fun apẹẹrẹ bi eyi; bayi pe... Ti mo ba sọ ohun ti iwọ ko gbagbọ fun ọ yọ ọ kuro ati lẹhinna jẹ akara oniyẹfun naa. Ṣe akiyesi. Bayi, ìgò kan wa nilẹ lori ààtàn lágbàlá. Iwọ ko kan ni gbe eyi ki o fi si ori tabili rẹ ki o si rọ omi si tabi wara. Rara. Nipa mimu un kuro nilẹ jẹ idalare. Fífọ̀ ọ́ jẹ isọdimimọ, 'nitori ọrọ Giriki sọ-dimimọ jẹ ọrọ ti a so papọ, o tumọ si sọọ di mimọ ki o si yaasọtọ fun lilo (kii ṣe pe o loo lọwọ; fun lilo). Lẹhinna nigbati o ba kún un, o ti fi sinu isẹ.
Ẹ gba mi laaye fun eyi (kii ṣe lati ṣe ipalara), nibiyi ni ẹyin ijọ atipo mimọ - Pilgrim Holiness, ẹyin ijọ Nasareti - Nazarenes kuna lati rin lọ sinu Pẹntikọsti. A fọ yin mọ nipasẹ isọdimimọ, ṣugbọn nigbati o yẹ ki a yin sinu isẹ nipasẹ awọn ẹbun fifi ede miiran sọrọ ati awọn ohun miiran, ẹ kọ ọ silẹ, ẹ tun pada sinu àbàtà lẹẹkansi, wo. Bayi eyi ni ohun ti o sẹlẹ; nigba gbogbo ni eyi si maa ń ṣẹlẹ. Bayi, ki ṣe lati ṣe àtakò rẹ bayi, ṣugbọn mo kan... mo fẹ lati gbe eyi kuro ni ọkan mi. Ati pe eyi si ti n gbóná ninu mi lati igba ti mo ti wa nibiyi nitorina jẹ ki n ṣe eyi.... Bi oore-ọfẹ arakunrin Carl ati ti arakunrin Demos ati awọn ati gbogbo yin.... maa gbiyanju gbogbo ipa mi lati gba ẹmi mi lọwọ rẹ, wo; lẹhinna o wa ku si ọ lọwọ.
Ti ara n ṣe afiwe ti ẹmi. Bayi, a ri i.... Lẹhinna a bi i ni kikun. Nigbati ọmọ naa.... Bayi bi o ṣe maa n ri nigba gbogbo nigbati omi ba jade, o ko nilo lati ṣe wahala pupọ nipa rẹ. Nigbati ẹjẹ ba jade, o ko nilo lati ṣe wahala pupọ nipa rẹ. Ṣugbọn lati le jẹ ki iye wa sinu ọmọ naa, o ni lati fun ni ìláàdí kan ti yoo jẹ ki o kigbe jade. Ati eyi..... ni bayi lai ka iwe - kika, bi awọn arakunrin mi ti o wa nibiyi ti wọn ti gba eto-ẹkọ daradara nipa rẹ (ti awọn), ṣugbọn mo ni lati lo isẹ́ ti ẹ̀dá lati fi ṣe afiwe rẹ. Ati pe ṣe o rii. Eyi ni ohun ti o sẹlẹ; o gba fifun ni ìláàdí gidigidi lati le jẹ ki wọn rii.
Ni bayi mu diẹ... gbígbọ̀n diẹ kan. Boya o ko nilo lati fun u ni ilaadi, ṣugbọn o le jẹ pe ki o kan fun ni gbón diẹ. Nipa wipe a bii nigba miiran yoo ṣe. Di i mu; gbọn ọn. Ti ko ba ti si èémí ninu rẹ, fun u ni ilaadi diẹ, lẹhinna yoo kigbe jade pẹlu ede aimọ (si ara rẹ mo ro bẹẹ). Lọnakọna ti o jẹ o n kigbe. Mo si ro pe ti a ba bi ọmọ kan nipaṣe oku-ọmọ ti ko si kigbe ti ko sí ohùn, ko si imọlara; iyẹn jẹ pe ọmọ naa ti ku.
Eyi ni ohun ti o n sẹlẹ pẹlu ijọ loni, ilana eto wọn — a ti ni ọpọlọpọ awọn oku-ọmọ ti a bi. Eyi jẹ otitọ. Wọn nilo ilaadi ti ihinrere, ṣe o ri, ati bẹbẹ lọ ... lati ji wọn dide, lati jẹ ki wọn ni ìdánimọ̀ ara wọn ki Ọlọrun le mi eemi iye sinu wọn! Bayi a ri pe eyi jẹ otitọ. O jẹ ẹkọ-ijinlẹ ti o múnádóko, ṣugbọn o jẹ otitọ lọnakona.
-----
A sọ fun wa nipasẹ awọn wolii Ọlọrun pe a o ni aye tuntun, ọrun tuntun kan ati aye tuntun kan. Ti o ba fẹ iwe- mimọ fun eyi, iwe Ifihan 21- ori ookan-le-logun ni o jẹ. Mo le sọ ayọka rẹ fun ọ. Mo ni nibiyi. Johanu sọ pe: “Mo ri ọrun tuntun ati aye tuntun: nitori ọrun akọkọ ati... aye akọkọ ti kọja lọ.” (O ti lọ.).Ni bayi, ti a ba fẹ ni aye tuntun, aye atijọ ati aye tuntun ko le jọ wa laaye papọ ni akoko kanna - tabi, aye tuntun ati aye atijọ ko le jọ wa laaye papọ ni akoko kanna. Ko le si awọn ilana eto aye meji papọ ni akoko kanna. Bayi, lati le gba aye tuntun, ti atijọ ni lati ku. Bayi, ti aye ti atijọ ba ni lati ku, lẹhinna o n ni awọn irora ibimọ fun tuntun miiran lọwọlọwọ.
Ati lẹhinna ti dokita kan ba lọ ṣe ayewo fun ẹnikan ti o n rọbí lọwọ, bayi ikan lara awọn ohun ti dokita yoo ṣe — eyiti mo n sọrọ niwaju meji tabi mẹta, eyiti mo mọ, awọn dokita oniṣegun ti o dara nibiyi, awọn dokita Kristiani. Emi yoo beere eyi lọwọ rẹ. Ikan ninu awọn ohun akọkọ ti dokita yoo ṣe lẹhin igba ti o ba ti n wo ẹniti o n rọbi ni lati ṣe ìdíwọ̀n akoko fun awọn irora naa bi wọn ṣe pọ to, awọn irora ibimọ. O fun awọn irora naa ni ìdíwọ̀n-akoko, bawo ni wọn ṣe sunmọ ara wọn si to ati bi ìdíwòn kọọkan ṣe n dunni si to. Ikan maa n nira lati ni ju ekeji lọ; eyi ti o tẹle, si tun nira sii. Wọn n sunmọra si. Eyi ni ọna ti o le fi ṣe ayẹwo ibimọ naa, nipasẹ awọn irora ibimọ. O dara, ti ayé ogbologbo ba lee kuro ki aye tuntun le wá, jẹ ki a kan wo diẹ ninu awọn irora ibimọ ti a n lakọja ni orilẹ aye. Lẹhin eyi, a oo ri ọjọ ti a wa ati pe nibo lode ninu ìrọbí rẹ.
Ogun Agbaye akọkọ fi irora-ibimọ nla han. O fi ọkan ninu awọn irora-ibimọ akọkọ han pe o nlọ sinu irọbi, nitori akoko yẹn to wa fun u a mu awọn àdó-iku jade wa, ati pe a ni awọn ẹ̀rọ ti o ni ìbon ati afẹfẹ gaasi majele. Ati pe ṣe o ranti... boya ọpọlọpọ ninu yin ko le. Mo jẹ ọmọde kekere ti ọjọ ori rẹ to ọdun mẹjọ, ṣugbọn mo ranti bi wọn ti ṣe maa n sọrọ nipa musitadi ati gaasi chlorine ati bẹbẹ lọ — bi o ṣe dabi pe o kan sẹsẹ bẹrẹ ati pe wọn sọ pe yoo sun gbogbo aye. Yoo pa gbogbo eniyan. O dara, o le jẹ pe eyi sẹlẹ — awọn afẹfẹ kan fẹ kọja lori ilẹ-aye, ati bi gbogbo awọn eniyan ṣe n bẹru dé iku fun ohun ija nla ti gaasi majele naa. Ayé la irora-ibimọ akọkọ rẹ kọja.
A tun rii wipe, a ti ni Ogun Agbaye keji. Ati pe awọn irora rẹ tun pọ si, o banilẹru si ni gbogbo igba, awọn irora-ibi ti aye. O fẹrẹ le pari ni akoko ado-iku nitori pe yoo pa odindi ilu kan run. O lagbara pupọ ju awọn irora Ogun Agbaye akọkọ ti iparun si aye.
Bayi, o mọ pe akoko itusilẹ rẹ ti wa ni ìtòsí. Idi niyi ti ara rẹ ko fi balẹ, bi o ti jẹ aifọkanbalẹ, o jẹ nitori pe ado-iku ti afẹfẹ ihidirogini - hydrogen ati awọn ado-olóró tinu afẹfẹ ti o le pa gbogbo agbaye run. Orilẹ-ede kan n bẹru ti ekeji, laibikita bi o ti kere to. Wọn ti ni awọn ado-olóró wọnyi ti wọn jẹwọ wipe o le ṣe e — ọkan ninu wọn, wọn le ṣe itọsọna wọn nipasẹ awọn irawọ ati ki wọn si ju wọn silẹ nibikibi ti wọn ba fẹ ni agbaye.
Ilu Rusia, bi mo ti gbọ ninu iroyin laipẹ yi, o jẹwọ pe oun le pa orilẹ-ede yi run ki oun si da àbò bo awọn afẹfẹ-atọmu tabi awọn nkan bẹẹ kuro ninu pipa orilẹ-ede rẹ run. A ko mọ ohun ti a le ṣe nipa rẹ. Onikaluku n ṣe ijẹwọ awọn nkan wọnyi, ati pe o ri bẹ. Awọn eniyan ni.... Awọn onimọ-ijinlẹ ti wọ inu yàrá-isẹ ti Ọlọrun ti o tobi titi wọn yoo fi pa ara wọn run. Ọlọrun maa n gba laye nigbagbogbo ki ọgbọn pa ara rẹ run. Ọlọrun ko pa ohunkohun run. Eniyan maa n pa ara rẹ run nipa ọgbọn gẹgẹ bi o ti ṣe ni ibẹrẹ, mu ọgbọn Satani dipo Ọrọ Ọlọrun. Bayi, o mọ pe oun gbọdọ parẹ. Oun ko le duro.
-----
Nitorinaa o mọ pe oun ko le duro mọ. Awọn eniyan mọ pe ko le duro mọ, ati pe gbogbo aye mọ pe yoo sẹlẹ nitori Ọlọrun sọ pe yoo ri bẹ. Gbogbo ọrun ati aye yoo wa ninu ina. Yoo jẹ isọdọtun gbogbo nkan ki a le bi aye tuntun. Ọlọrun ti sọtẹlẹ rẹ.O di ibajẹ ninu gbogbo awọn eto rẹ ati pe o ni lati ṣe bẹ lati le jẹ ki o jẹra kuro. Nitorinaa idi niyi ti mo fi sọ pe o ni aifọkanbalẹ pupọ ati pe o ni pupa ni oju ati iporuru-ọkan ati awọn iwariri-ilẹ nibi gbogbo ni oke ati ni isalẹ eti okun ati awọn ìgbì omi ni Alasika ati mímì si oke ati si isalẹ eti okun pẹlu awọn iwariri-ilẹ ati awọn nkan ti awọn eniyan kọwe, “Sẹ ki a fi silẹ? Ṣe ki a fi silẹ?” Wo, wọn ko mọ kini ohun ti a le ṣe. Ko si ibi aabo ṣugbọn Ọkan, eyi ni Kristi, Ọmọ Ọlọrun alaaye. Ati pe ohun kan soso ni o wa ti o jẹ ibi aabo, ati pe Oun ni; gbogbo awọn ti o wa nita eyi ni yoo parun pẹlu idaniloju gẹgẹ bi Ọlọrun ti sọ bẹ.
Bayi, ẹ jẹ ki a wo iwe dokita (ti o ba wa ninu iru ipo yi) ati ki a si ri boya eyi yẹ ki o sẹlẹ nigbati a ba fẹ bi aye tuntun. Iwe ti Matteu ori kẹrin-le-logun-24 ninu iwe dokita, eyiti o jẹ Bibeli, ati pe ẹ jẹ ki a wo ohun ti a ti sọ asọtẹlẹ rẹ, kini awọn aami rẹ yoo jẹ. Bayi, ti dokita ba mọ awọn aami ti ibimọ ọmọ kan.... Ati pe nigba ti o ba di akoko ti ọmọ naa yoo wa, o mura ohun gbogbo silẹ nitori o mọ pe akoko naa ni a o bi ọmọ naa nitori gbogbo awọn aami ni o ti fi han. Omi tun jade, ẹjẹ, ati pe o ti to akoko — ọmọ naa n bọ nita, o ti to akoko lati bi ọmọ naa. Ati nitorinaa o mura ohun gbogbo silẹ fun un.
Bayi Jesu sọ fun wa ni pàtó ohun ti yoo ṣẹlẹ ni akoko yi. O sọ fun wa ninu iwe ti Matteu ori kẹrin-lelogun- 24 pe Ijọ (Ijọ otitọ) ati ijọ miiran yoo jẹ — ijọ ti ara, Ijọ ti Ẹmi - yoo jọ sunmọ ara wọn (awọn aláfarawé) titi yoo fi tan awọn ayanfẹ jẹ ti o ba ṣeeṣe. Bi o ti ṣe ri ni awọn ọjọ Noa; bi wọn ti ṣe n jẹ, mimu, ṣe igbeyawo, fifun ni igbeyawo, ati gbogbo awọn iwa-irira ti aye ti a ri loni, Bibeli Iwe naa (iwe dokita) sọ pe yoo sẹlẹ. Nitorinaa nigbati a ba ri pe eyi n sẹlẹ a mọ pe ibimọ wa ni itosi! O ni lati sẹlẹ. Bẹẹni, sa. Bayi, a wo eyi gẹgẹbi orilẹ-ede kan — kii ṣe orilẹ-ede kan, ṣugbọn agbaye kan.
-----
Ijọ yi n la irora ìbímọ kọjá. Ṣe iwọ ko ni ṣe ìyàn rẹ nisinsinyi ni iwaju Rẹ̀? Mo ti fi Ọrọ naa han yin ni gẹlẹ-ohun ti O sọ pe Oun yoo ṣe. La gbogbo gbọngan yi kọ já, beere lọwọ ẹnikẹni ti O ba ti sẹlẹ si, tabi ti O ti ba sọrọ ri tabi ohunkohun to ba jẹ, ki o si wo bọ̀ya mo ti ri wọn ri, mọ wọn ri tabi ohunkohun nipa wọn. O ro pe eniyan le ṣe eyi bi? O jẹ ohun ti ko ṣeéṣe lati sẹlẹ rárá. Sugbọn ki ni? Ọmọ eniyan naa. “Ọrọ Ọlọrun mu ju ìda oloju meji lọ, ìmọ̀ ẹmi yàtọ̀, awọn asiri ọkan.” Gẹlẹ bi o ti rí nigbati O di ẹran ara nibiyi ni ori ilẹ̀ aye ninu Ọmọ Ọlọrun, bayi a ti fi I han lati ọwọ Ọmọ Ọlọrun gẹgẹ bi O ti wa lati pe Iyawo kan jade lati inu awujọ yẹn.“Jade kuro ninu rẹ! Ki a ya ọ sọ́tọ̀!” ni Ọlọrun wi. Maṣe fi ọwọ kan ohun aìmọ́ wọn! Ọlọrun yoo si tẹ́wọ́ gbà ọ́. Ṣe o ṣetán lati fi gbogbo aye rẹ fun Ọlọrun? Ti o ba ṣetan, dide duro lori ẹsẹ rẹ ki o si wipe, “Emi yoo gba A nisinsinyi nipa oore-ọfẹ Ọlọrun pẹlu ohun gbogbo to wa ninu mi.
Ka iroyin kikun ni... Ìrora Ìbímọ.