Òùngbẹ.
<< išaaju
itele >>
Òùngbẹ.
William Branham.Ka iroyin kikun ni...
Òùngbẹ.Ọrọ ti mo fẹ sọrọ le lori lalẹ yii lati inu Bibeli ni a ri ni ẹsẹ keji “Oungbẹ” Mo si wo inu iwe ti a fi ntumọ ede gẹẹsi. Nigbati mo nwo Ọrọ yii, mo nro nipa iwaasu kan ti mo ṣe nigba kan lori. “Oungbẹ si Iye” Mo mu iwaasu naa lati inu Psaamu pẹlu, nibiti Dafidi ti wipe, “Awọn Ilana Rẹ ṣe iyebiye simi ju Iye lọ” Nigbana, mo nyẹ ọrọ yẹn wo tii ṣe “Oungbẹ.” Nitori naa, mo wo o ninu iwe ti a fi ṣe itumọ awọn ọrọ, lati ri ohun ti o tumọ si. Ohun ti Webster si sọ niyii. O jẹ ifẹ ọkan kan ti o ndun ni de inu; nigbati iwọ ba nsafẹri ohun kan to bẹẹ ti o fa irora ọkan fun ọ.
Bayi, kii ṣe ohun ti o sajeji lati ni oungbẹ. Oungbẹ jẹ ohun kan to ba iwa ẹda eniyan mu. O jẹ ohun kan ti Ọlọrun fun wa lati lee safẹri ohun ti a nilo. Ni igba miran, Ọlọrun pẹlu ti fun ọ ni ọwọn idari, ohun kan ti n sakoso awọn ifẹ orisirisi wọnyi. Oungbẹ yii si jẹ ọwọn isakoso kan to wa ninu eniyan, ohun kan ti Ọlọrun fun un lati kilọ fun un lati mọ ohun ti o nilo.
Bayi, orisi oungbẹ meji ni o wa. Oungbẹ ti ara wa, oungbẹ ti ẹmi si wa pẹlu. Mo fẹ ka ohun ti Dafidi sọ yii lẹẹkan si. “Ọkan mi Poungbẹ fun Ọlọrun, ani fun Ọlọrun alaaye.” Kii ṣe ohun itan asan kan, tabi ohun kan to ṣẹlẹ ni ọpọ ọdun sẹyin, tabi itan kan ti ẹnikan sọ - ṣugbọn fun Ọlọrun aaye, Ọlọrun ti o wa nigbogbo igba. Ọkan rẹ si poungbẹ fun Ọlọrun yẹn, kii ṣe ohun itan kan.
A ri i wipe, Ọlọrun fi ọwọn isakoso sinu rẹ, lati fun ọ ni ohun ti o nilo. Agbara Isakoso inu rẹ ni o ndari rẹ. Oungbẹ yii si wa sinu agbara Isakoso yii lati sọ ohun ti o nilo fun ọ. Nipa ti ẹmi, agbara Isakoso wa ninu ọkan rẹ. Agbara Isakoso kan wa ninu ara ti o nsọ ohun ti ara nilo. Eyi si ntọ ọ wa nipa oungbẹ. Bẹẹ gẹgẹ, agbara Isakoso kan wa ninu ọkan, ti o nsọ ohun ti o nilo nipa ti ẹmi, o wa ninu ẹmi rẹ. Iwọ sile sọ iru Iye to nsakoso aye rẹ. Nigbati iwọ ba wo ohun ti awọn ifẹ rẹ jẹ, nigba naa, iwọ lee sọ nipa eleyi, iru iye to wa ninu rẹ, ti o nfẹ awọn ohun ti iwọ nfẹ. Wo o, ohun kan wa ti iwọ ni oungbẹ fun, iyẹn si jẹ ki o mọ ohun ti ọkan rẹ nfẹ, nipa iwa ẹda ti iwọ ni. Mo lero pe iyẹn ye ọ.
Agbara isakoso kan wa ninu ọkàn, agbara isakoso kan si wa ninu ara. Agbara Isakoso kọọkan ni o si nbeere fun ohun ti o nsafẹri. Ọkọọkan ni o nsafẹri ohun ti o nilo, O ma a nran ikilọ jade. Fun apẹẹrẹ, ara ma a npoungbẹ lati tẹ ifẹ inu ara lọrun, bẹẹ ni ẹmi ma a nsafẹri awọn ohun ti ọkàn nilo. Lọpọ Igba ni ifẹ awọn mejeeji si lodi si ara wọn.
A rii wipe, wahala nla ti ọjọ oni ni pe, ọpọ eniyan ni o ngbiyanju lati gbe laarin ifẹ mejeeji. Nitoripe, ọkan ninu wọn nsafẹri awọn ohun aye yii, ekeji si nsafẹri awọn ohun ti ọrun.Gẹgẹbi Paulu ti ṣalaye rẹ ninu Romu 7:21 “Nigbati mo ba fẹ ṣe rere, nigba naa, ibi wa nibẹ.” Nigbati iwọ ba ngbiyanju lati ṣe ohun kan - ṣe iwọ Kristẹni ti ni iriri yẹn ri? - pe, nigbati iwọ ba ngbiyanju lati ṣe ohun kan ti o ṣe Pataki, nigba naa, iwọ yoo rii wipe eṣu wa lọtun losi lati da ọ laamu. Yoo fẹ mu ki ohun gbogbo ti o fẹ ṣe ki o ma ṣeeṣe. Ohun kan ti mo fẹ sọ niyi, ki Kristẹni le mọ: pe nigbati iwọ ba fẹ ṣe ohun kan ti o tọ, ti ohun kan si ngbiyanju lati da ọ lẹkun lati ṣe e, iwọ tẹsiwaju ki o ṣe e lọnakọna. Eṣu ni o wa nibẹ, ti o ngbiyanu lati de ọ lọna lati ṣe ohun ti o tọ.
Bayi, lọpọ igba ni mo ma a npade awọn eniyan ti o ni aibalẹ ara. Nigbati wọn ba ri i wipe, wọn ngbiyanju lati ṣe ohun kan, ti ohun gbogbo si nṣe idena si wọn, wọn yoo wipe, “O le ma jẹ ifẹ Oluwa.” Ma ṣe jẹ ki eṣu parọ fun ọ bẹyẹn. Ohun akọkọ ni ki o wadi bi ohun naa ba jẹ ifẹ Ọlọrun tabi bẹẹ kọ. Bi iwọ ba si fẹ mọ bi o ba jẹ ifẹ Ọlọrun, wo inu Bibeli. Ohun kan ni o le e tọọ sọna, ohun ni Ọrọ Ọlọrun. Bi iwọ ba si rii pe, o wa ninu Ọrọ Ọlọrun lati ṣe e, fun apẹẹrẹ, wiwa ibaptisimu Ẹmi Mimọ.
Ni ọpọ igba ni mo npade awọn eniyan ti wọn wipe, “Mo ti wa Ẹmi Mimọ, emi ko si ri I gba. Nko gbagbọ pe o wa fun mi. Bi mo ba gba aawẹ, emi yoo saisan. Bi mo ba si gbiyanju lati ṣe aisun, orun yoo kun mi tobẹẹ ti emi ko lee gbe ẹsẹ mi nilẹ”. Ranti, eṣu niyẹn, nitori pe Ọlọrun fẹ ki iwọ ni Ẹmi Mimọ. O wa fun ẹnikẹni ti o fẹ.
Ni ọpọ igba, iwọ yoo ri i wipe, bi a ba gbadura fun ọ ninu isin fun imularada, lẹyin naa, ni ọjọ keji, iwọ yoo ri i wipe eṣu yoo mu ki aisan naa buru ni ilọpo meji bi o ti ri tẹlẹ. Ranti pe, eṣu ni o sa ngbiyanju lati mu ki iwọ ya kuro ninu Ibukun ti Ọlọrun ti fifun ọ. Iwọ maṣe feti si ẹda yẹn! Iwọ saa ti tẹsiwaju.
-----
Bayi, a o sọ nipa oungbẹ ti ara ṣaaju. Jẹ ki a mu oungbẹ fun omi, bi Dafidi ti sọ nibi yii. Ara nilo omi. Bi iwọ ko ba si fun ara ni omi, iwọ yoo ku. Iwọ yoo gbẹ, iwọ yoo si ku. Bi iwọ ko ba fi omi fun oungbẹ yẹn ti ara beere fun, iwọ yoo ku. O ko ni wa laaye pẹ.Iwọ le wa laaye lai jẹ onjẹ ju ki o má mu omi lọ. Nitori pe, iwọ lee gbawẹ fun ogoji ọjọ. Jesu ṣe bẹẹ laijẹ ounjẹ kankan, ṣugbọn iwọ ko lee ṣe iyẹn lai mu omi. Iwọ yoo gbẹ, ó si ku. O nilani ni omi. Oungbẹ ti iwọ si ni, o jẹ lati sọ fun ọ ohun ti ara rẹ nilo lati wa laaye. Ara nilati ni omi lati wa laaye. Omi ko ipa to ju ida mẹrin ninu ida marun ara, o si nilati ni ohun yii lati wa laaye. Gẹgẹ bi mo ti sọ, bi iwọ ba kọ lati fun ara ni omi, iwọ yoo ṣegbe.
Oungbẹ pẹlu jẹ igbe ikilọ tabi itaniji kan. Ọkan rẹ ninu rẹ yoo ṣe itani-giri kan ninu rẹ, yoo kilọ fun ọ pe, iku ko jina si ọ, pe bi iwọ ko ba ri omi laipẹ, iwọ yoo ku. Igbe naa yoo si maa pọ si, bi iwọ ba si dagunla si igbe ikilọ naa, iwọ yoo ku. Nitoripe, agogo ikilọ ni.
-----
Bayi, ẹkọ nla kan wa nibi yii, ti Dafidi sọ nibi yii pe, “Bi agbọnrin ti nmi hẹlẹ si ipado omi, bẹẹ ni ọkan mi nmi hẹlẹ si Ọ, Ọlọrun.” Agbọnrin yẹn mọ wipe, bi oun ko ba ri omi mu, iku ti de. Ko lee ye. Mo ti tọpasẹ wọn ni ọpọ igba. Lẹyin ti o ti ni ijamba, nigbati o ba ti de odo sisan kan, oun yoo re odo naa kọja si odikeji, yoo si mu omi, yoo si gun oke diẹ, yoo tun pada si odo naa, yoo re e kọja, yoo si mu omi, yoo gun oke. Iwọ ko lee baa lọna mọ, niwọn igbati o ba ti tẹle odo omi sisan yẹn. Ṣugbọn bi o ba fi odo silẹ, laipẹ aja yoo ba a. Agbọnrin naa mọ iyẹn, nitori naa, yoo duro ti omi odo yẹn nibiti oun ti le tete mu omi kiakia. Se o lee ro nipa agbọnrin kan ti o gbe imu rẹ si oke; ti wọn ti ka mọ ibikan ti ko ni omi.O si wipe, “Bi agbọnrin ti nmi hẹlẹ ti o npoungbẹ si ipado omi, ọkan mi npoungbẹ fun Ọ, Ọlọrun. Bi emi ko ba ri Ọ, Oluwa, emi yoo ṣegbe. Emi ko lee lọ bi emi ko ba ri Ọ” Nigbati ọkunrin tabi obinrin kan, ọmọkunrin tabi ọmọbinrin ba si ni iru oungbẹ bẹẹ fun Ọlọrun, Oun yoo ri ohun kan gba. Ṣugbọn nigbati a ba nwa Ọlọrun lai fi gbogbo ọkan wa A, “O dara, emi yoo kunlẹ, n o si wo ohun ti Oluwa yoo ṣe” Woo, oungbẹ ko tii gbẹ ọ gidi. O nilati jẹ oungbẹ ti iwọ wa laarin iye ati iku. Nigba naa ni ohun kan yoo ṣẹlẹ.
Agbọnrin tun ni onmọ ara miran lati gboorun nigba ti ọta rẹ ba sunmọ tosi. A fun ẹda kekere yii ni onmọ lati daabo bo ara rẹ. Oun si ni agogo ikilọ kan ninu rẹ, onmọ kan ti yoo kan imu rẹ nigbati ọta ba sunmọ ọn. Bi iwọ ba sunmọ ọn, bi o ba ti gboorun rẹ, yoo ti mọ pe ewu wa, lọgan ni yoo sa lọ. Nigbamiran, ni ilaji ibusọ jinna sọdọ rẹ yoo ti mọ, yoo si salọ. O le jẹ ikooko tabi ewu miran, oun lee mọ ọn, nitori bi a ṣe daa niyẹn. Agbọnrin ni iwa ẹda yẹn. Onmọ igboorun yii jẹ ọkan ninu awọn onmọ ara, ti Ọlọrun fifun un lati fi wa laaye.
Lẹyin naa, mo roo, bi mo ṣe nfi agbọnrin we eniyan kan ti oungbẹ ngbẹ fun Ọlọrun. Ki ọta to de, ohun kan wa nipa ọmọ Ọlọrun kan ti a ti tunbi nipa Ẹmi Ọlọrun; ti o si ti gba Ẹmi Mimọ, ohun kan wa nipa rẹ ti o lee mọ pe ọta ti sunmọ tosi. O le mu ẹnikan, bi o ti n ka Iwe Mimọ, ti o si ngbiyanju lati fi oun kan ti o lodi si Iwe Mimọ sinu rẹ. Ẹnikan ti a ti kun fun Ẹmi Mimọ le mọ iyẹn lọgan. Ohun kan ti lodi. A fun ọ ni onmọ yẹn lati daabo bo ẹmi rẹ. Iwọ ko gbọdọ gba ohunkohun ti o ba yatọ diẹ si Ọrọ Ọlọrun. O nilati duro patapata pẹlu Ọrọ yẹn. A si ni ipamọ nipa onmọ yẹn, niwọn igbati a ba wa ninu Ẹmi Mimọ.
-----
Iwa ẹda miran wa ninu ọkan ti o ma a nni oungbẹ. Iwọ le wipe, “Arakunrin Branham, ṣe oungbẹ ọkan yẹn wọpọ, ṣe gbogbo eniyan ni o ni in?' Bẹẹni, ohun to ba ẹda mu ni fun ọkan lati ni oungbẹ. Ọlọrun da ọ ni ọna yẹn, ki iwọ le ni oungbẹ fun Ọlọrun. O fẹ ki o safẹri Oun.Bayi, Ọlọrun da ọ bẹẹ. Oun ko nilati da ọ bẹẹ, ṣugbọn O da ọ bẹẹ. Bi o ba ṣe wipe, Oun ko da ọ ni ọna yii ni, iwọ iba ni awawi nibi itẹ idajọ wipe, “Emi ko poungbẹ fun Ọlọrun ri.” Ṣugbọn ko si awawi. Iwọ poungbẹ. Iwọ yoo tẹ oungbẹ yẹn lọrun ni ọna kan tabi ekeji. Iwọ le wa itẹlọrun ninu Iyawo rẹ, o le jẹ ọkọ̀ ayọkẹlẹ rẹ, o le fi ṣe ohunkohun, o le fi ṣe lilọ sile isin rẹ. Emi ko si ni ohunkohun lodi si lilọ si ile-isin, ṣugbọn iyẹn kọ ni itẹlọrun naa. O jẹ pe, ki o wa Ọlọrun ri, Ọlọrun alaaye, Ọlọrun Ọrun sinu Ọkan rẹ ti yoo fun ọkan rẹ ni itẹlọrun ohun gbogbo ti iwọ npoungbẹ fun. Nitori O da ọ pe, ki iwọ ni oungbẹ fun Un, ati idapọ pẹlu Rẹ.
Bayi, oungbẹ tootọ fun idapọ pẹlu wà. A nifẹ lati ni ipade pẹlu ara wa. A n ṣe iyẹn lalẹ yii. A pade papọ lalẹ yii nitoripe a nifẹ si idapọ, lati ṣe ipade pẹlu ara wa. Kin ni idi eleyi? Nitoripe ohun kan wa ninu wa ti o fẹ ṣe ipade pẹlu ẹnikẹji. Iyẹn ba iwa- ẹda mu. A si wa pade ara wa nibi nipa ohun kan ti a ni papọ. Eyi jẹ nitoripe gbogbo wa ni o n poungbẹ fun Ọlọrun.
Nigba naa, a pade nibi nitori idapọ ti a ni papọ. Nile isin lalẹ yii, ọpọ orisirisi igbagbọ ijọ ni o le wa, ṣugbọn, bi o ba ṣe ti oungbẹ yẹn, a le pade lori koko kan naa ti gbogbo wa ni, wipe gbogbo wa ni o ni oungbẹ. Awọn diẹ lo gbagbọ ninu bibu omi wọn ni, awọn miran le gbagbọ ninu itẹbọmi, awọn kan dida omi le eniyan lori, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ṣugbọn nigbati o ba di ti oungbẹ fun Ọlọrun, a ni iyẹn papọ sọkan. Ọlọrun si da wa ki a lee ṣe iyẹn, ki a poungbẹ fun Un ati idapọ pẹlu Rẹ.
Ka iroyin kikun ni... Òùngbẹ.