O n fi Ijọ Rẹ sipo.
<< išaaju
itele >>
Isọdọmọ apa kẹta.
William Branham.Ka iroyin ni kikun ni...
Isọdọmọ apa kẹta.Idi ti a fi nkọ ẹkọ yii nipe, ki a le fẹsẹ awọn to ti gbagbọ mulẹ ninu ilẹ naa. Idi ti a fi nkọ ekọ yii ninu iwe Efesu ni ki a fi Ijọ si ibiti yoo ti duro patapata si ipo rẹ ninu Kristi, o jẹ apẹẹrẹ iwe Joshua ti majẹmu Laelae nibiti Joshua ti pin ilẹ naa (A gbọ ọ ni ọjọ Aiku ti o kọja) fun olukuluku eniyan, ati iran nipa imisi.
-----
Bayi, o ṣeeṣe ki iwọ ṣe ohun ti o kuna, nigba gbogbo ti iwọ ba si ṣe ohun to kuna, iwọ yoo jẹ iya rẹ! Bẹẹ ni, iwọ yoo ka ohun ti iwọ ba gbin! Sugbọn iyẹn ko ni ohun kan iṣe pẹlu igbala rẹ. Nigbati a bi ọ pẹlu Ẹmi Ọlọrun, iwọ ti ni Iye ainipẹkun, iwọ ko si lee ku, gẹgẹbi Ọlọrun ko ṣe le e ku. Iwọ jẹ ipa kan ninu Ọlọrun, ọmọkunrin Ọlọrun ni iwọ iṣe.A bi mi gẹgẹbi Branham kan, Iwọ le pe mi ni orukọ miran. Orukọ miran ti iwọ pe mi ko yi mi pada - Branham ni mo si jẹ sibẹ. A bi mi gẹgẹbi Branham, emi yoo jẹ Branham titi. Lọjọ kan, ara mi le e di palapala, nipa arun arun-mọ-lee-gun, tabi nipa ijamba ọkọ kan, ki ara mi si wo, tobẹẹ ti yoo ri bi ẹranko kan. Sugbọn, Branham ni emi yoo jẹ sibẹ. Nitori kin ni? Ẹjẹ Branham ni o wa ninu mi.
Ohun ti iwọ jẹ niyẹn. Niwọn igbati Ọlọrun si ti ṣe ọ ni ọmọ Rẹ. Ranti bayi pe, emi ko sọrọ nipa awọn ti ko si ninu Kristi; mo nsọrọ nipa awọn to wa ninu Kristi. Bawo ni a ṣe nwọ inu Kristi? Nipa Ẹmi kan. Eyi jasi. “Nipa Ẹmi Mimọ kan ni a baptisti wa sinu ara kan.” Bawo ni a ṣe nwọle? Ṣe nipa itẹbọmi kan ni? Emi tako ẹyin Baptisti ati Church of Christ, ki i ṣe nipa itẹbọmi rara! Kọrinti kinni, ori kejila wipe, Nipa Ẹmi kan (Ẹmi Mimọ) ni a mu wa bọ sinu ara naa, a si wa ninu aabo, gẹgẹbi ara naa ti wa ni ipamọ. Ọlọrun ṣeleri rẹ.
Bawo ni Ọlọrun ṣe lee da Kristi lẹjọ lẹẹkan si nigba ti O ti lọ si Kalfari? O lọ si Gọlgọta, a lu u, a pa A lara. Oun ko si le e wosan, Oun ko tilẹ lee sọ ọrọ kankan. Nitori kin ni? O gbe gbogbo ẹṣẹ aye le ori Rẹ. Kii ṣe wipe Oun jẹ ẹlẹṣẹ, sugbọn a sọ Ọ di ẹṣẹ nitori iwọ ati emi. Gbogbo ẹṣẹ aye lati Adamu titi di bibọ Rẹ ni o wa lejika Rẹ. Ọlọrun ko si fi iya jẹ Ọmọ Rẹ. Ọlọrun fi iya jẹ ẹṣẹ. Ṣe o ri bi ẹṣẹ ti buru to? Ọlọrun nṣe etutu fun ẹṣẹ. Ọlọrun la ọna abayọ fun gbogbo awọn ti o ti mọ nipa imọtẹlẹ pe yoo wa. A o de inu eyi lẹyin iṣẹju diẹ si.
Nitori naa bayi, “Nipa Ẹmi kan ni a baptisti wa sinu ara yẹn, ara kan, tii ṣe ”Kristi“ a si wa ni ipamọ titi lae. Bayi, ibi yii ni o dabi ẹnipe o le diẹ; paa paa, fun awọn ara ijọ Arminia, ti wọn ro wipe, wọn nilati ṣe ohun kan lati lee yẹ funra wọn, tabi ohun akayẹ kan. Bawo ni o ṣe lee jẹ nipa ohun meji papọ nigba kan naa? O nilati jẹ nipa oore-ọfẹ tabi nipa iṣẹ, ọkan ni ninu meji yii. Ko le jẹ nipa mejeeji, wọn lodi si ara wọn, O nilati jẹ ọkan ṣoṣo ninu wọn.
Ni temi, emi ko ri ohun miran yatọ si oore-ọfẹ Ọlọrun. Ohun ti a fi dami niyẹn. Nigba gbogbo ni emi ngbagbọ ninu oore-ọfẹ. Oore-ọfẹ nimi patapata. Kii ṣe emi, nigbati mo jẹ ọmọkunrin paapaa. Emi ko le e ri ohun miran bikoṣe Oore-ọfẹ. Wọn ma a wipe, “Bi iwọ ba ranmilọwọ, emi naa yoo ran ọ lọwọ. Ọrọ ti ko dara ni. Emi ko fẹ mọ bi iwọ ranmilọwọ tabi iwọ ko ranmilọwọ, bi iwọ ba nilo iranlọwọ mi, emi yoo ṣe e lọnakọna. Ṣe o ri oore-ọfẹ. Bẹẹ ni, sa. Wo o, oore-ọfẹ nsiṣẹ nipa ifẹ. Bi iwọ ba nilo rẹ! Bi iwọ ko tilẹ ṣe ohun kan fun mi ri, ti emi ko ni nkankan ṣe pẹlu rẹ ri, bi iwọ ba nilo ohun kan, emi yoo ṣee. Oore-ọfẹ! Nitoripe iwọ nilo rẹ!
Mo nilo igbala. Ko si ohun kan ti o le gba mi la. Ko si ohun kan ti emi lee ṣe nipa rẹ funra mi, emi ko lee gba ara mi la. Sugbọn mo nilo igbala nitori mo gba Ọlọrun gbọ. Ọlọrun si ran Ọmọ Rẹ, ti a ṣe ni ifarahan ara ẹlẹṣẹ lati jiya ni ipo mi, a si gba mi la nipa oore-ọfẹ nikan. Ko si ohun kan ti mo lee ṣe, tabi ti iwọ lee ṣe, lati gba ara rẹ la. Awọn ti O si ti mọtẹlẹ, ṣaaju ipilẹṣẹ aye....
-----
Ninu Rẹ, Oun ni Iwa ẹda ati ipa lati jẹ Olugbala. Bawo ni ọkan ninu awọn ẹda yẹn ṣe lee ṣubu nigbati ko si ẹṣẹ tabi ero lati dẹṣẹ? Ko le e ri bẹẹ. Nitori naa a nilati da ohun kan ti o le ṣubu sinu ẹṣẹ, ki Oun ba le jẹ Olugbala. Ninu Rẹ ni agbara lati jẹ Oluwosan. Ṣe iwọ gbagbọ pe Olugbala ni Oun iṣe? Ṣe iwọ gbagbọ wipe, Oluwosan ni? Bi o ba ṣe wipe ko si ẹnikẹni lati gbala ati lati wosan nkọ? Wo o, ohun kan ni lati wa ti o nilo iwosan tabi igbala. Nitori naa, Oun ko da eniyan lati ṣubu, sugbọn O fi eniyan si ipo lati yan ohun ti o wu u. “Bi iwọ ba jẹ eleyi, iwọ yoo ye; Bi iwọ ba jẹ omiran, iwọ yoo ku”. Gbogbo eniyan to nwa sinu aye ni a si fun ni anfani kan naa. Ọlọrun, nipa imọtẹlẹ Rẹ mọ ẹniti yoo ṣee, ati ẹniti ki yoo ṣee.-----
Nitorina, Ọlọrun duro. O si ti sọ ara Rẹ di mímọ̀ gẹgẹbi Ọlọrun. O ti fi ara Rẹ han ni Olugbala, eniyan sọnu, O si gba wọn la. O ti fi ara Rẹ han ni Oluwosan. Ko ṣe Pataki ohunkohun ti eniyan le e pe E, O jẹ Oun to jẹ, sibẹ. Oluwosan ni, Olugbala ni, Ọlọrun ni, Ainipẹkun si ni. Oun si ni afojusun kan. Afojusun Rẹ lati ipilẹ si ni wipe, ki O da awọn ẹda kan, ti yoo fẹ Ẹ, ti yoo si ma a sin In.Oun si da awọn ẹda, awọn ẹda naa si ṣubu. Nigba naa, Ọlọrun, nipa Imọ ailopin Rẹ, bojuwo gbogbo akoko, O si ri gbogbo awọn ti a o gbala. O mọ gbogbo eniyan nipa imọtẹlẹ. Nitori naa, niwọnbi Oun, nipa imọtẹlẹ mọ gbogbo awọn ti a o gbala, ati awọn ti a ko ni gbala, Oun le e yantẹlẹ. Nitori naa, Ọrọ yii kii ṣe Ọrọ to buru pupọ, abi? Oun lee yantẹlẹ, nitoripe o mọ ẹniti yoo gba a ati awọn ti ko ni gba a. Nitori naa, ki Oun lee gba awọn ti a o gbala, O nilati ṣe etutu fun ẹṣẹ wọn. Ah, bi o ba ṣeeṣe a o debẹ laipẹ ni ẹsẹ diẹ siwaju si. O yan wa tẹlẹ si Iye ainipẹkun, nitori O mọ eniyan ti yoo pa ohun gbogbo ti si apa kan. Bi o si ti ki o ri loju awọn eniyan aye, ko ni ni itumọ kankan si wọn, nitoripe wọn jẹ ọmọ Ọlọrun.
O si ti pe wọn. O si ran Jesu, ki ẹjẹ Rẹ lee ṣe ilaja, nipa etutu tabi ifọnumọ. O si jẹ ifọnumọ ti nlọ lọwọ, ki ikan ṣe iṣẹlẹ ti isọji kan, sugbọn “O wa laaye titi lati maa ṣe ilaja.” Ki Kristẹni naa lee wa ni ipamọ mimọ tọsan toru. Ẹjẹ Jesu Kristi si wa niwaju Ọlọrun lati ma a fọ wa mọ nigbogbo igba, tọsan-toru kuro ninu ẹṣẹ gbogbo. A si wa ni ipamọ titi. Ipamọ ni ọna wo? Nipasẹ Ẹmi Mimọ, ninu Ara ti Jesu Oluwa. O wipe, “Ẹniti o ba gbọ Ọrọ Mi, ti o si gbagbọ ninu ẹniti O ran Mi, ni Iye ainipẹkun, oun ki yoo si wa sinu idajọ, sugbọn o ti rekọja iku bọ si Iye. Ko si idajọ fun un mọ! Kristẹni ki yoo lọ si idajọ. Kristi ti lọ si idajọ fun un. Agbẹjọro mi ti duro funmi. O ti gba ẹjọ mi ro, wipe mo jẹ alaimọkan. O sọ fun Baba wipe, emi ko yẹ, ati pe emi ko mọ nkankan. Sugbọn o fẹmi, o si gba ipo mi, o gba ẹjọ mi ro, loni, mo ti wa ni ominira! Bẹẹ ni sa. O ta ẹjẹ Rẹ silẹ, lati fi rubọ ẹṣẹ wa.
-----
Nigba naa, isọdọmọ, ifini-sipo. Bayi, Ọlọrun nṣe iṣẹ yii. Bi mo ba si lee fi eyi yee yin, nitori naa, a o bẹrẹ bayi ni ẹsẹ karun. Mo fẹ ka a:
Ẹniti o ti yan wa tẹlẹ si isọdọmọ nipa Jesu Kristi fun ara Rẹ, gẹgẹ bi idunnu ifẹ Rẹ.
O jẹ inu didun Ọlọrun lati ṣe ifẹ Rẹ - isọdọmọ, ifini-sipo. Kin ni O nṣe bayi? O n fi Ijọ Rẹ sipo. Ṣaaju, O pe ijọ Rẹ - lati Methodisti, Presibiteria, Lutheria, Baptisti - O pe wọn. Lẹyin naa kin ni O ṣe? O ran Ẹmi Mimọ, O fun wọn ni ibaptisimu Ẹmi Mimọ.Mo fẹ ki ẹyin Pẹntikọsita mu eleyi kuro ni ọkan yin. Pẹntikọsti kii ṣe ẹgbẹ ẹsin kan, Pẹntikọsti jẹ iriri kan. Ẹmi Mimọ ni. Kii ṣe ẹgbẹ ẹlẹsin-to-feniyan-sadari-rọpo-Ẹmi Mimọ, Iwọ ko lee fi Ẹmi Mimọ sabẹ isakoso eniyan. Ko ni gba fun ọ. Ẹyin ti ni ẹgbẹ kan, ijọ ẹgbẹ ẹlẹsin kan ti ẹ npe ni Pẹntikọsita, sugbọn Ẹmi Mimọ jade lọ kuro, o si fi yin silẹ sibi ti ẹ joko si, Oun si tẹsiwaju. Pẹntikọsti kii ṣe ẹgbẹ ijọ ẹlẹsin kan. Pẹntikọsti jẹ iriri ti Ẹmi Mimọ.
-----
Fifi ọmọ sipo. Ohun kin-ni, ni wipe, a bi ọmọkunrin kan sinu ẹbi kan, sugbọn a rii wipe, iwa rẹ ni o mu ki o yẹ fun isọdọmọ - yala o huwa to tọ tabi ko ṣe bẹ ẹ. O si jẹ awọn Pẹntikọsita.... Sa jẹ ki nfihan ọ pe, Pẹntikosti kii ṣe ẹgbẹ-ijọ-ẹlẹsin kan. Baptisti melo lo wa nibi ti o ti gba Ẹmi Mimọ? Ẹ na ọwọ soke? Mẹtọdisti melo lo wa nibi ti o ti gba Ẹmi Mimọ? Ẹ na ọwọ soke. Awọn ọmọ Ijọ Nasarinni melo lo wa nibi ti o si ti gba Ẹmi Mimọ? Na ọwọ rẹ soke. Pirẹsibiteria, to ti gba Ẹmi Mimọ? Lutheria, awọn ijọ miran ti kii ṣe Pẹntikosita rara, ti wọn si ti gba Ẹmi Mimọ? Ẹ nawọ yin. Ṣe o rii. Nitori naa, Pẹntikọsti kii ṣe ijọ-ẹlẹkọ-adamọ kan, iriri kan ni.Bayi, Ọlọrun mu ọ wa sinu ara Kristi. Kin ni oun si ṣe? Lẹyin igbati iwọ ti mu ara rẹ yanju ti o yara rẹ si mimọ pẹlu iwa rere ni igbọran si Ẹmi Mimọ, lai bikita fun ohun ti aye sọ.
-----
Ẹ si nfi apele Baba, Ọmọ ati Ẹmi Mimọ ṣe itẹbọmi nigbati ko si Iwe mimọ kankan fun un ninu Bibeli. Mo fẹ ki olori awọn bisọbu tabi ẹlomiran wa fihan mi ninu Bibeli bi o ba ri ibiti a ti ṣe itẹbọmi ni orukọ Baba, Ọmọ, ati Ẹmi Mimọ. Mo fẹ ki ẹnikan wa fihan mi bi a ba ri ẹnikẹni ti a ṣe itẹbọmi fun yatọ si orukọ Jesu. Awọn ti Johanu ti ṣe itẹbọmi fun, se ijẹwọ igbagbọ wipe Olugbala nbọ, sugbọn wọn ko mọ Ẹniti o jẹ. Sugbọn lọgan ti wọn mọ iyẹn, wọn nilati ṣe itẹbọmi miran fun wọn ni orukọ Jesu Kristi. Mo fẹ ki ẹnikan wa fihan mi. Mo ti beere lọwọ Ijọ Akọjọpọ ti Ọlọrun (Assemblies of God) Mo ti beere lọwọ awọn oniwaasu miran, awọn Baptisti, Presibiteria, ati gbogbo wọn. Ah, wọn ko ni sọrọ nipa rẹ. Mo fẹ ri Iwe Mimọ naa. Mo si ti di agba-were-mẹsin, abi? Nigba naa, o ro wipe mo siwin, ori mi daru, mo ya were, nitori pe mo ngbiyanju lati sọ otitọ fun yin. Otitọ niyẹn, ẹyin ara. Bi eniyan ba fi ara rẹ fun Ọlọrun, O fi ara rẹ fun Un patapata. A ti ya ọ sọtọ. Ẹda ọtọ ni ọ.Ọpọ ni a pe, diẹ ni a yan. Ọpọ eniyan ni a pe. Bi iwọ ba ni ipe kan ni ọkan rẹ, Iwọ wipe, “Bẹẹni, mo gba pe Ọlọrun fẹran mi.” Mo gba bẹẹ. Sugbọn, arakunrin, iwọ yoo ṣegbe gẹgẹbi awọn ti o ku, nitori wọn yoo wa lọjọ naa, ti wọn yoo wipe, “Oluwa, emi ti le ẹmi eṣu jade ni orukọ rẹ. Mo ti ṣe ohun pupọ ni orukọ Rẹ. Mo ti ṣe isin iwosan. Mo ti waasu ihinrere. Mo ti le ẹmi eṣu jade”. Jesu yoo wipe, “Kuro lọdọ mi. Emi ko tilẹ mọ ọ ri, iwọ agabagebe. Ẹniti o ba ṣe ifẹ Baba Mi nikan ni”. Kin ni idi ti awọn eniyan ko fi ri otitọ wọnyi? Mo mọ pe, iyẹn jẹ inira. Emi ko ni in lọkan lati sẹ yin. Emi ko fẹ ki o jọ bẹẹ,
O jọ loju mi wipe, a ti wa ni opin ọjọ, Ọlọrun si nsọ awọn eniyan di ọmọ. O nfi Ijọ Rẹ si ipo wọn, ninu ara Kristi. Awọn ti Oun yoo fi sibẹ ko ni pọ rara. Mo kọkọ sọ iyẹn fun ọ ni ibẹrẹ. Iwọ lee sọ wipe, awọn to pọ niye ni yoo wa nibẹ“. Sugbọn Oun ti ni ẹgbẹrun ọdun mẹfa lati sa wọn jade pẹlu. Ranti pe, ajinde yoo de, a o si gba wa soke pẹlu wọn. Awọn perete ni. Iwọ tete wadi igbala rẹ yanju. Iwọ funra rẹ wo yika, ki o si wadi ohun ti o kuna. Wadi ohun to ṣẹlẹ. Mo mọ pe iyẹn le, arakunrin, sugbọn otitọ ni. Otitọ Ọlọrun ni. Isọdọmọ!
-----
Isọdọmọ, fifi si ipo ti o yẹ! Awọn da? Fi ibiti wọn wa han mi? Ọlọrun npe ijọ Rẹ sọtọ nipa ifihan-fayeri. Wọn ko nilati sọ ohun kan nipa rẹ, ẹ o ri ohun to nṣẹlẹ. Fifi ọmọ Rẹ si ipo to tọ, mimu ọmọ Rẹ wa ni ilana pẹlu ohun kan naa ti Oun jẹ. Ọmọ naa ni aṣẹ kan naa, ọrọ rẹ ni ipa kan naa pẹlu olori angẹli tabi jubẹẹ lọ pẹlu. A ti fi ọmọkunrin yii si ipo, a gbe e ga si ibi kan, a paarọ aṣọ rẹ ati awọ rẹ. Baba rẹ si ṣe aṣeyẹ kan, o wipe, “Eyi ni ayanfẹ ọmọ mi. Lati oni lọ oun ni alakoso. O ti di alasẹ. Oun ni o wa nipo akoso lori gbogbo ogún Mi. Ohun gbogbo ti mo ni, di tirẹ”. Otitọ niyẹn.Ka iroyin ni kikun ni...
Isọdọmọ apa kẹta.