Isọdọmọ apa kẹrin.

<< išaaju

itele >>

  Isọdọmọ jara.

Isọdọmọ.


William Branham.

Ka iroyin ni kikun ni...
Isọdọmọ apa kẹrin.

Bayi o wipe, “Oun ti sọ ijinlẹ naa di mimọ.” Iwọ gba Ẹmi Mimọ laaye nigba kan, ki iwọ bẹrẹ si ka iyẹn, ki o ri bi yoo ṣe kọ ọ. Ni ọsan yii, mo lo nkan bi ọgbọn iṣẹju lati kẹkọ, lati yẹ ẹkọ naa wo. Mo tilẹ lee sọ wipe iṣẹju marundogun ni. Mo si bẹrẹ si I ka a, mo ro nipa “Ijinlẹ naa - bawo ni o ṣe jinlẹ to!” Iwe Mimọ si mu mi lọ sinu Majẹmu laelae, o tun mu mi wa sinu Majẹmu Titun, o si so wọn papọ lati ri ijinlẹ bibọ Rẹ, ijinlẹ ifẹ Rẹ, ati ijinlẹ bi a ṣe joko papọ. Ranti wipe, a ko lee kọ eleyi ninu Ile-ẹkọ ti Ẹsin Kankan. Ijinlẹ ni. Iwọ ko le e mọ ọn nipa iwe kikọ, tabi nipa ẹkọ ẹsin. O jẹ ijinlẹ ti a ti fi pamọ lati ipilẹṣẹ aye, ti o nduro de ifarahan awọn ọmọ Ọlọrun.

Sọ fun mi arakunrin, sọ fun mi arabinrin, akoko wo ni a lee fi awọn ọmọ Ọlọrun han-fayeri yatọ si akoko yii? Nigba wo, ninu gbogbo itan aye, ti a lee gba gbogbo ẹda la? Ẹda funra rẹ nkerora, o nduro de akoko ifarahan naa, ki a to ṣe irubọ etutu naa, ki a to tu Ẹmi Mimọ jade, ṣaaju Majẹmu Laelae. Ko ṣeeṣe ki ifarahan ṣẹlẹ. O nilati duro de akoko yii. Bayi, ohun gbogbo ni a ti muwa, ti o ntẹsiwaju, ti o si nwa si okuta tente-ori ile, titi di ifarahan awọn ọmọ Ọlọrun, ti Ẹmi Ọlọrun si nwa sinu awọn eniyan yii ni pipe, tobẹẹ ti Iṣẹ Iriju iwaasu wọn yoo sunmọ ti Kristi, tobẹẹ ti yoo sọ Oun ati Ijọ Rẹ di ọkan ṣoṣo.

----
Bi a ba yan ọ tẹlẹ si Iye Ainipẹkun, Ọlọrun yoo pe ọ lọna kan tabi omiran. Dajudaju yoo ṣe e. “Gbogbo awọn ti Baba ti fifun Mi, yoo tọ Mi wa.” Ijọ ti o wu ki iwọ lọ, iyẹn ko ni ohun Kankan I ṣe pẹlu rẹ. Ijọ to fẹkọ- kẹkọ-rọpo-Ọrọ-Ọlọrun ko le e ṣe ọ ni ire kan, sugbọn o le e ṣe idiwọ pupọ fun ọ lati tẹsiwaju pẹlu Ọlọrun, sugbọn ko le e ṣe ohun miran. Iwọ n kojọpọ pẹlu adalu onigbagbọ ati alaigbagbọ. Ni tootọ, a nba iyẹn pade nibikibi ti a ba nlọ, wọn tilẹ ni iyẹn ni Ọrun pẹlu. O dara. Sugbọn iwọ nfi igbagbọ sinu Ijọ ẹlẹkọ-adamọ rẹ. Wo Jesu. Oun ni iwọ nilati kọbi ara si, ti o nilati gbagbọ.

----
Bayi, bibọ Jesu Oluwa ti sun mọle to bẹẹ gẹ lati ibẹrẹ ti I ṣe idalare, isọdimimọ, ati baptisimu Ẹmi Mimọ, titi ti a fi wa ni akoko bibọ ti okuta tente-ori yẹn. Ijọ nilati dabi Kristi ni pipe, tobẹẹ ti ijọ ati Kristi yoo di ọkan naa nipa Ẹmi kan naa. Bi Ẹmi Kristi ba si wa ninu rẹ, yoo mu ki iwọ gbe igbe aye Kristi, ki o si ṣe iṣẹ Kristi. Ẹniti o ba gba Mi gbọ, iṣẹ ti Emi ṣe ni oun yoo ṣe pẹlu“ gẹgẹ bi Jesu ti wi. Bayi, a ni iṣẹ Iriju Iwaasu kan ti nbọ wa ti o dabi ti Jesu gẹlẹ. Kin ni iṣẹ Iriju Iwaasu naa n tọka si? Bibọ Oluwa ni.

Kiyesi ni aye loni, ki o si wo ohun ti Khrushchev nsọ pẹlu ohun gbogbo to nṣẹlẹ wọnyi, ati gbogbo ija nla kaakiri aye. Aye lee di eeru nigba-kii-gba, otitọ niyẹn. A si mọ wipe iyẹn ti sunmọle. Enikẹni ti o ni ori pipe, lee ka ninu iwe iroyin tabi ki o feti si redio, yoo mọ wipe, o ti sunmọle. Ranti wipe Kristi yoo mu Ijọ Rẹ lọ ki iyẹn to ṣẹlẹ. Nitori naa, ni bibọ Oluwa ti sunmọle to? Boya ki isin yii to pari ni. A ti wa ni opin aye. Otitọ ni, dajudaju.

Kiyesi Ijọ bi o ti wa, ati bi o ti ntẹsiwaju. Ẹyin olukọtan, ẹ saa wo o ni ọkan yin. Wo Ijọ ti Luther ni abẹ idalare, ti o jade lati inu ijọ Katoliiki taara. Wo bi o ṣe siṣẹ. Ẹ si wo Wesley bi o ti sunmọ otitọ si, ti o gba isọdimimọ ti o kọ Iwe Mimọ si. Wo aarin Ijọ ti Wesley. Eyi ti o tẹle e ni ijọ Pẹntikọsita - ti iran ti Pẹntikọsita si wọle pelu idapada awọn ẹbun Ẹmi. Si wo iran to nwọle bayi ti o wa si okuta tente ori ile naa. Ṣe ohun ti mo nsọ ye ọ? Eyi nfi bibọ Oluwa han. Ọlọrun ati gbogbo ẹda nduro de Ijọ naa lati duro si Ipo rẹ.

----
Lẹyin ti Ijọ ti mu ipo rẹ, a pe wa si ipo isọdọmọ ti awọn Ọmọ Ọlọrun nipa Ẹmi Mimọ. Nigbati ẹni kọọkan ba si ti mu ipo rẹ (ohun ti Ọlọrun ti pe e si lati ṣe) ti o si duro titi de opin irin-ajo naa, ti o nlọ gba awọn ti o ti ṣako, ti o ti sọnu.

Ṣaaju, Paulu mu gbogbo ibẹru kuro ninu rẹ, o wipe, “Bi a ba ti pe ọ nitootọ - ti ki i ṣe wipe a kan fi ẹkọ ẹsin kan ru ọkan rẹ soke lasan - bi a ba tun ọ bi nipa Ẹmi Mimọ nitootọ, a jẹ wipe Ọlọrun ti yan ọ tẹlẹ ṣaaju ipilẹṣẹ aye, O si ti kọ orukọ rẹ sinu Iwe Iye ti Ọdọ Aguntan, bayi, awa ti wa papọ lati joko ninu awọn Ọrun ninu Jesu Kristi. Awọn eniyan Mimọ, orilẹ-ede Mimọ, awọn eniyan ọ̀tọ̀, Olu alufaa, ti wọn nrubọ ti ẹmi si Ọlọrun, ti I ṣe eso ti ètè wa, ti n fi iyin fun orukọ Rẹ”.
Awọn eniyan wa, wọn si wipe, “Ori awọn eniyan naa ti daru.” Dajudaju, bẹẹ ni. Ọgbọn Ọlọrun jasi iṣiwere loju eniyan, ọgbọn eniyan si jẹ isiwere si Ọlọrun. Awọn mejeeji tako ara wọn.

Sugbọn ijọ kan ti a kun pẹlu Ẹmi, ti o kun fun agbara Ọlọrun, ti njoko ninu awọn Ọrun, ti nrubọ mimọ, nipa iyin si Ọlọrun ti Ẹmi Mimọ nsiṣẹ laarin wọn, ti o ntu aṣiri ẹṣẹ, ti o si npe ikuna wọn jade kuro, ti o nmu wọn tọ, ti O si nmu wọn wa ni isọkan. Nitori kin ni? Irubọ to kun fun ẹjẹ yẹn wa niwaju Ọlọrun ni gbogbo igba.

Ranti bayi (a kọ nipa rẹ lowurọ yii), ẹjẹ naa kọ ni o gba ọ la. Sugbọn a pa ọ mọ sinu igbala nipa ẹjẹ naa. Sugbọn a fi Oore-ọfẹ gba ọ la nipa igbagbọ. Iwọ gba a gbọ. Ọlọrun kan ilẹkun ọkan rẹ nitoripe o ti yan ọ tẹlẹ. Iwọ boju woke, o si gba A gbọ. Bayi, ẹjẹ naa ṣe etutu fun ẹṣẹ rẹ. Ranti pe, mo sọ wipe Ọlọrun ko da ẹlẹṣẹ lẹbi fun ẹṣẹ rẹ. Ẹlẹṣẹ ni oun lati ibẹrẹ. Ọlọrun nda Kristẹni lẹbi fun ẹṣẹ rẹ. Nitori pe o si ti da a lẹbi. Kristi gba idalẹbi wa. Nitori naa, “Ko si idalẹbi mọ bayi fun awọn to wa ninu Kristi Jesu, ti wọn ko rin nipa ti ara, sugbọn ti wọn nrin nipa ti Ẹmi”.

Bi iwọ ba si ṣe ohunkohun ti o kuna, iwọ ko mọnmọ ṣe e. Iwọ ko le mọnmọ dẹṣẹ. Ẹnikan to jade lọ, to lọ mọnmọ dẹṣẹ, ko ti I wa sinu ara yẹn rara. Sugbọn ẹnikan to ti wa ninu ara Kristi ti ku, a si ti fi iye rẹ pamọ sinu Ọlọrun nipasẹ Kristi, ti a fi edidi ti Ẹmi Mimọ di I, eṣu ko tilẹ lee ri i, oun ti jina pupọ ninu ara naa. Oun nilati jade wa kuro nibẹ ki eṣu to le e ri I mu. Nitori ti iwọ ti ku.

----
Ranti wipe, a ṣẹṣẹ kaa tan ni ninu Efesu ori kinni, ẹsẹ kẹwa.
Fun iṣẹ iriju ti kikun akoko naa....
Bayi, a ti kọ wipe, ẹkunrẹrẹ akoko nduro de kin ni? Ekunrẹrẹ gbogbo akoko, nigbati ẹṣẹ yoo ti pari, ti iku yoo ti pari, ti aisan yoo ti pari, ẹṣẹ yoo ti pari, akoko ti gbogbo idibajẹ ati awọn ohun to ti dibajẹ, ti eṣu ti bajẹ yoo dopin - nigbati akoko funra rẹ yoo dopin. Kiyesi.

Eyi ti yoo jẹ jade ni kikun akoko, lati ṣe akọjọpọ awọn ohun ti Ọrun ati ti aye labẹ or ikan, ani Kristi. “Ko ohun gbogbo papọ ninu Kristi” Gẹgẹbi mo ti sọ lowurọ yii, gbogbo awọn ohun iyebiye ti a lee ri wọnyi, a le e mu wọn jade ni Jẹnẹsisi, Eksodu, Lefitiku, titi de ifihan, gbogbo wọn yoo si fi Jesu han. Bi iwọ ba mu Josefu, ati Abrahamu, Isaaki, Jakobu, Dafidi, gbogbo awọn ẹkọ iyebiye nipa awọn ọkunrin Ọlọrun wọnyẹn - iwọ yoo rii ti I ti wọn yoo fi Jesu Kristi han fayeri. “Ki Oun lee ko ohun gbogbo sọkan ninu Jesu Kristi”.

Jẹ ki a tẹsiwaju diẹ bayi. Ẹsẹ ikọkanla wipe:
Ninu Ẹniti awa ti gba ogun ini kan....
Ah, ogun ini kan. Ẹnikan nilati fi ohun kan silẹ fun ọ lati jogun rẹ. Ṣe bẹẹ ni? Ogun ini wo ni a ni? Ogun ini wo ni mo ni? Emi ko ni ohun kan. Sugbọn Ọlọrun fi ogun ini kan silẹ fun mi, nigbati o fi orukọ mi sinu Iwe Iye ti Ọdọ-Aguntan ṣaaju ipilẹṣẹ aye.

Ah, iwọ wipe, “Wo o, Jesu ni o ṣe Iyẹn nigbati o ku fun ọ” Rara. Kọ ṣe bẹẹ. Jesu wa lati sanwo fun ogun ini yẹn fun mi. Iwọ ka ẹsẹ ti o kan:
Ninu Ẹniti awa ti gba ogun-ini kan, gẹgẹbi ipinnu Ẹniti nsiṣẹ ohun gbogbo gẹgẹbi imọ ifẹ Rẹ.

Ọlọrun, ṣaaju ipilẹṣẹ aye, gẹgẹ bi a ti mu Un wa ninu ẹkọ fun yin. Bi a ṣe ri I wipe, Ọlọrun dawa ni Oun nikan; Bi o ṣe jẹ wipe ninu Rẹ ni ifẹ wa, ninu Rẹ ni agbara lati jẹ Ọlọrun, agbara lati jẹ Olugbala (ko si ti si ohun kan ti o sọnu) Inu rẹ ni ipa lati jẹ Oluwosan. Eyi ni awọn iwa ati ipa Rẹ. Ko si ti si ohun kan nibẹ, Nitori naa, oun funrarẹ mu awọn nkan wọnyi jade, ki o lee fi gbogbo nkan wọnyi han nipasẹ ọkunrin kan yii, ti I ṣe Jesu Kristi. Ah, oju ko ti I riri, eti ko tii gbọ ri.... Ko yani lẹnu ti o fi jẹ ijinlẹ kan.

Wo o, o ti yan wa tẹlẹ si ogun ini kan. Bi mo ba jẹ ajogun si ohun kan. Bi Ọlọrun ba nkanlẹkun ọkan mi wipe, “William Branham. Emi ti pe ọ ṣaaju ipilẹṣẹ aye, lati waasu ihinrere”. Mo ni ogun inikan - ogun ini ti iye ainipẹkun. Lẹyin naa, Ọlọrun ran Jesu lati mu ki ogun ini naa di arigbamu fun mi, nitori pe, ko si ohun kan ti mo lee ṣe lati jogun rẹ. Ko jẹ okodoro si mi tẹlẹ. O wa nibẹ. Ko si ohun ti mo lee ṣe nipa rẹ. Sugbọn, ni ẹkunrẹrẹ akoko, nigbati o wu u, Ọlọrun ran Jesu - Odo Aguntan naa, ti a ti pa ṣaaju ipilẹṣẹ aye. A ta ẹjẹ Rẹ silẹ, ki emi lee lọ si ogun ini mi. Lati jẹ kin ni? Kin ni ogun-ini naa? Ti ọmọ, lati jẹ ọmọ Ọlọrun.

Bayi, eleyi yoo ya ọ lẹnu pupọ. Njẹ iwọ mọ wipe awọn ọmọ Ọlọrun tootọ jẹ Ọlọrun kekeke? Ẹni melo ni o mọ iyẹn? Tani o mọ pe Jesu sọ bẹẹ? Jesu wipe, “Njẹ ofin yin, ninu Bibeli ko ti sọ wipe, Ọlọrun ni ẹyin iṣe?” Ti o si jẹ wipe, ninu Jẹnẹsisi 2, Ọlọrun pe wọn ni Ọlọrun kekeke, nitori pe wọn ni isakoso lori gbogbo aye. O fun Adamu ni isakoso lori ohun gbogbo. Oun si sọ ipo rẹ nu gẹgẹbi Ọlọrun, o sọ ipo rẹ nu gẹgẹbi Ọmọ Ọlọrun. O sọ ipo rẹ nu gẹgẹbi alakoso aye, satani si gba a.

Sugbọn arakunrin, awa nduro de ifarahan awọn ọmọ Ọlọrun, ti yoo pada wa, ti yoo si gba isakoso aye lẹẹkansi. A nduro de ẹkunrẹrẹ akoko, nigbati ile nla alaramọnda yẹn yoo gba ade-tente-ori rẹ, ti a si ri ifarahan-fayeri ti awọn ojulowo ọmọkunrin Ọlọrun, nigbati agbara Ọlọrun yoo di mímọ̀ (Halleluyah!) ti a o si gba gbogbo agbara ti satani ni kuro lọwọ rẹ. Bẹẹ ni sa, gbogbo agbara jẹ ti Jesu.

Oun ni Ọrọ (Logọsi) ti o jade lọ kuro ninu Ọlọrun. Otitọ niyẹn. Iyẹn ni Ọmọ Ọlọrun. Lẹyin naa o da ọkunrin, ti I ṣe Ọlọrun kekere yẹn. Jesu wipe “Bi wọn ba pe awọn ti Ọrọ Ọlọrun tọ wa (awọn wolii) ni Ọlọrun kekeke” Ọlọrun si sọ ọ funra Rẹ, wipe Ọlọrun kekeke niwọn. O sọ fun Mose pe, “Mo ti fi ọ ṣe Ọlọrun, mo si fi Aroni ṣe wolii rẹ” Amin. Ah, ah, Mo le jọ bi aṣiwere-ẹlẹsin kan, sugbọn emi kii ṣe were. Ah bi oju rẹ ba lee ṣi lati ri awọn nkan wọnyẹn! O dara.

O da eniyan ni Ọlọrun kekere kan, alakoso kan ninu ilẹ ijọba rẹ. Ilẹ ijọba rẹ si kaakiri gbogbo ilẹ aye. O ni isakoso lori rẹ. Nigbati Jesu si de, ti o jẹ Ọlọrun kanṣoṣo, ti ko ni ẹṣẹ, o fi eleyi daniloju. Nigbati iji nja, O wipe, “Alaafia, dakẹ jẹ!” Amin. Nigba ti O si sọ fun igi ọpọtọ pe, “Ki ẹnikẹni maṣe jẹ eso lori rẹ mọ” o ri bẹẹ. Lootọ, lootọ ni mo wi fun yin (Ẹyin Ọlọrun kekeke) bi iwọ ba wi fun oke yii wipe, 'ṣidi' ti iwọ ko si ṣe iyemeji ni ọkan rẹ, sugbọn ti o gbagbọ wipe, ohun ti iwọ sọ, yoo ṣẹlẹ bẹẹ, iwọ lee ri ohun ti o sọ gba.

Ka iroyin ni kikun ni...
Isọdọmọ apa kẹrin.


Ohun ijinlẹ Kristi.

Wẹẹbu iwe iroyin Gẹẹsi.

Iwe Ifihan jara.

 

Ọlọrun ati Imọ Atọka.
- Archaeology.

Igbasoke n bọ.

 

Awọn ẹkọ akọkọ
ti ifiranṣẹ naa.

Awọn ti o dara iroyin.
Jesu ku fun ese re.

Iribomi Omi.

 

Awọsanma eleri nla.

Ọwọn ti ina.

Ogo Shekinah ti Ọlọrun.

Ibojì ti ṣofo.
O ti jinde.

Ọlọrun salaye.

Awọn ìgbà ijọ meje.

Awọn edidi meje.

Ọlọrun ati Itan.
jara Atọka - Dáníẹ́lì.

Kristiẹni ije jara.
Ìgbéyàwó Àti Ìkọ̀sílẹ̀.
Akojọ Ifiranṣẹ.

Opin akoko jara.

Ngbe ọrọ jara.

Keresimesi jara.

Iku. Ohun ti nigbana?

Orúkọ Ọlọrun.

Ọkọ Noa.

 

Ẹṣẹ Atilẹba.
Je o ẹya apulu?

Adaparọ.
Awọn orisun - Babeli.

Ọlọrun ati Imọ.
Dainoso Adaparọ.

Archaeology.
Sodomu ati Gomorra.

  Iwe-mimọ sọ...

Ẹ̀mí tí Ọlọrun fun yín kì í ṣe èyí tí yóo tún sọ yín di ẹrú, tí yóo sì máa mu yín bẹ̀rù. Ṣugbọn Ẹ̀mí tí ó sọ yín di ọmọ ni ẹ gbà. Ẹ̀mí yìí náà ni ó jẹ́ kí á lè máa ké pe Ọlọrun pé, “Baba! Baba wa!”

Ẹ̀mí kan náà ní ń sọ sí wa lọ́kàn pé ọmọ Ọlọrun ni wá.

Wàyí ò, tí a bá jẹ́ ọmọ, ajogún ni wá. Tí a bá sì jẹ́ ajogún, a jẹ́ pé àwa pẹlu Kristi ni a óo jọ jogún pọ̀, bí a bá bá Kristi jìyà, a óo bá a gba iyì pẹlu.

Romu 8:15-17


Tẹ aworan kan lati ṣe igbasilẹ aworan iwọn ni kikun tabi PDF.


Acts of the Prophet.

(PDFs Gẹẹsi)

Chapter 9
- The Third Pull

(PDF Gẹẹsi)

Ṣaaju...

Lẹhin...

William Branham
Life Story.

(PDF Gẹẹsi)

How the Angel came
to me.

(PDF Gẹẹsi)




Ifiranṣẹ ibudo...Yan ede rẹ ki o gba awọn ifiranṣẹ ọfẹ lati ọdọ Arákùnrin Branham.