Ngbe ọrọ jara Atọka.

  Ngbe ọrọ jara.

Iran Iyawo.


William Branham.

Ka iroyin kikun ni...
Ìrora Ìbímọ

Bibeli wipe iyawo Rẹ ti múra tán ni òpin ìgbà ijọ yii. Bawo lo ṣe múra silẹ?... lati di iyawo rẹ. Ati irú asọ wo ló wọ̀ sọ́rùn? Ọrọ Rẹ. Ó wọ Ododo Rẹ? Iyẹn ni ohun to jẹ, sé o kíyèsi? Awọn iran.
Kiyesi. A ti n parí bayii. Mo fẹ sọ ohun kan yi, ki a to pari. Iyẹn ni ohun to mu mi sọ eyi. Mo ni “BAYI NI OLUWA WI” Bi ẹnikan yoo ba sọ iyẹn lá ì fi si inu èrò ararẹ̀, yoo jẹ alágàbàgebè o si yẹ ko lọ si ọ̀run àpáádi nitori rẹ̀. Bẹ ni. Ti yoo ba gbiyanju lati ko ọpọ eniyan jọ, awọn eniyan to dara bi eyi, ti yoo si tàn wọn jẹ, nitorinaa, yoo jẹ eṣu ninu ẹran ara eniyan, Ọlọrun ki yoo bu ọla fun un. Sẹ o ro pe Ọlọrun yoo bu ọla fun eṣu kan tabi òpùrọ́ kan? Laelae. Kiyesii, o wọ kọja oye wọn, wọn ko si loye rẹ, O fa awọn ayanfẹ jade.

Wo gbogbo awọn wolii ni gbogbo igba ijọ bi O ṣe gba awọn ayanfẹ. Wo, ki a to wa si igba atunto, gẹgẹ bi ijọ Aguda a Romu ṣe jo Joana ara Arc mọ́ igi fun pe ó jẹ́ àjẹ́. Otitọ ni. Nigba to yá wọn ri wipe kii ṣe bẹẹ; obinrin naa jẹ ẹni mimọ. Wọn wa ṣe atunṣe ifiyajẹ-ara-ẹni, wọn gbẹ iboji awọn alufaa, wọn wu oku wọn jade, wọn si ju wọn sinu odò, ṣe o mọ, ṣugbọn eyi ko yanju rẹ ninu iwe Ọlọrun. Rara!

Wọn pe Patrick mimọ naa ni ọkan pẹlu, sẹ ẹ ri, o si fẹ jẹ bi emi naa gẹgẹ ṣe jẹ ọkan. Nitorina, a sa kiyesi... wo awọn ọmọ rẹ; wo ibiti wọn wa; wo iye awọn ti wọn ti pa; wo ẹ̀kọ́ lori awọn ajẹ́ríkú ki o si wo iye awọn ti wọn pa nibẹ. Kiyesi, ko ri bẹ. Ṣugbọn ohun ti awọn eniyan naa sọ, ko sọ pe o rí bẹẹ, o jẹ ohun ti Ọlọrun sọ to si fi idi rẹ mulẹ pe o jẹ otitọ. “Ẹ wa di ohun gbogbo. Di eyi ti o tọ mu.”

Bayi, a ri nibi ni nkan bi osu diẹ sẹyin, ni owurọ ọjọ kan mo n rìn jade lati inu ile iran kan si wa. Mo pe ẹnikẹni níja nibi to mọ̀ lati gbogbo awọn ọdun yi wa lati sọ pe igbà kí gbà ti Oluwa ba mú mi sọ pe “Bayi ni Oluwa wi” ṣugbọn ti o maa n ṣẹlẹ. Eniyan melo lo mọ pe otitọ ni, ẹ na ọwọ yin soke. Ṣe ẹnikẹni le sọ ohun to lodi? Otitọ ni.

Maṣe kiyesi si ìránsẹ́ naa; wo iṣẹ ti a fi ran an. Iyẹn ni ohun ti ojẹ. Ki i ṣe iyẹn. Maṣe kiyesi apari kekere naa (ṣe o mọ) ẹni nitori o kan jẹ eniyan lasan, ṣe o mọ, bákanná ni gbogbo wa ṣe ri. Ṣugbọn kiyesi ohun to n sẹlẹ. Iyẹn ni ohun to fìdì rẹ̀ múlẹ̀.

A mu mi. Bayi, Mo mọ pe awọn eniyan n sọ orisirisi nkan, a si mọ pe ọpọlọpọ rẹ ni ko tọna. Emi ko le dahun fun ohun ti ẹnikẹni básọ. Mo nilati dahun fun ohun ti mo ba sọ. Emi ko si le sọ boya otitọ ni tabi rara, Emi si ni mo ni lati dahun fun un, ki ṣe ohun ti elomiiran basọ. Emi ko le da ẹnikẹni lẹjọ. A ko ran mi lati dajọ, ṣugbọn lati waasu iṣẹ-iranṣẹ naa ni.

Kiyesi, mo ri àkọ́wò bi ìjọ ṣe ri. Ẹnikan ti n ko ri lo n ba mi sọrọ, a sig be mi duro lori akete kan. Mo si gbọ orin to dùn ju ti mo ti i gbọ ri. Mo si wo ohun bọ wa... ati ọpọ awọn obìnrìn kékèké to wa yíká, ti wọn da bi ọmọ ogun ọdun (mejidinlogun, ogun), gbogbo wọn si ni irun gigun wọn si wa ninu asọ orisirisi, orisirisi, awọn asọ, wọn si n yan ni ibamu pẹlu orin yẹn bi wọn ti le ṣe tó. Wọn si n lọ lati apa osi mi wọn n lọ ni ọna kan, Mo si n wo wọn. Mo si wo o nigbana lati ri ẹni to n ba mi sọ̀rọ̀, emi ko si lee ri ẹnikan.

Lẹyin naa mo gbọ orin “tàka n súfé” to n dun. Nigba ti mo si wo apa ọtun mi, to n bọ wa ni ọna kan bi eyi (Óhún padàbọ̀), awọn ijọ aye lo n bọ yi. Ati awọn kan ninu... ọkọọkan wọn gbe asia wọn lati ibi ti wọn ti wa - awọn ohun to dọ̀tí jù ni wíwò ti mo tii rí rí ni aye mi. Nígbàti ijọ Amẹrika goke wa, o jẹ ohun ìríra to buruju ti mo ti i ri! Baba wa ọrun ni onidajọ mi. Wọn wọ yẹ̀rì pénpé aláwọ̀ọ eèrù (bi okan ninu awọn ọmọbinrin ilé-ọtí) ti ko bo ẹ̀yìn rárá, ni bi, ó mu ohun to da bi tákàdá kékeré aláwọ̀ò eérú, ati bi ijo o aye, wọn kun ọ̀dà soju, irun kukuru, wọn n mu sìgá, wọn n lọ́ bi wọn ti n yan si orin tàka n súfé yẹn.
Mo si sọ pe, “Ṣe eyi ni ijọ ti ori lẹ ede Amẹrika?”
Ohun naa si sọ pe, “bẹẹ ni.”

Nigba ti wọn si kọja, wọn ni lati muu lọwọ bi eyi ki wọn si mu tákàdá naa lọwọ lẹyin wọn nigbati wọn kọja lọ. Mo bẹrẹ si ni sọkun. Mo kan ro pe, “Pelu gbogbo ìla kàkà mi ati ohun gbogbo ti Mo ti ṣe ati ohun gbogbo ti àwa iransẹ Ọlọrun ti jọ ṣe papo...” Ẹyin ara, emi ko mọ bi ẹ ti ṣe gbagbọ nipa awọn ìran yi, ṣugbọn ni ti emi, otitọ ni; a ti fi idi rẹ mulẹ pe otitọ ni, ni gbogbo igba. Nigba ti mo ri yẹn ti mo si mo wipe o sẹlẹ lọwọ, mo fẹrẹ lee dákú. “Kini mo ṣe? Bawo ni mo ṣe kuna? Mo ti duro deede pẹlu Ọrọ naa, Oluwa, Bawo ni n ba ṣe ṣe...?” Mo ro “ki lo de ti Iwọ yoo fi fun mi ni iran laipẹ sẹyin ti o si ri mi nibi?” Mo si wipe, “O dara, ṣe a o dawon lẹjo bi?”
O si wipe, “Aẉon eniyan Paulu, pẹlu.”
Mo wipe, “Mo waasu Ọrọ kanna ti Paulu waasu.” (Awọn onisowo Kristẹni gbe iroyin rẹ̀ jade). Mo si wipe “kilode? Kilode ti yoo ri bayi?” Mo si ri ọ̀gọ̀rọ̀ awọn asẹ́wó yẹn ti wọn n lọ bẹ́ ẹ̀, gbogbo won wọṣọ bẹẹ, wọn si pe ijọ omidan Amẹrika. Mo kan n dákúú lọ ni.

Nigbana ní tàràtà ni Mo gbọ ojúlówó orin didun yẹn to padàwá, awọn Iyawo kekere kan naa yẹn lo sì tún n bọ̀ lẹẹkan si. Ó wipe, “Eyi ni ohun tó n jade nítòtọ́ ọ́”. Nigba to si kọja lọ, o jẹ bi iru eyi to ti wà lakọkọ, o n rin ni ìbámu si orin Ọrọ Ọlọrun naa, o n yan-án lọ. Nigbati mo si ri, mo duro sibẹ pẹlu ọwọ mejeeji loke ti mo n sọkun bẹ́ yẹn. Nigbati mo jade koru ninu iran naa, mo n duro ni ita ile mi, mo si n wò ìsọda a pápá.

Kini? Ò ni lati jẹ Iyawo kanna, iru kanna, ti a mu jáde lati inu irú èrojà kanna ti Ó jẹ́ ni ibẹrẹ. Bayi, ka iwe Malaki ori kẹrin ki a si ri ti kò bá yẹ kí á ní iṣẹ-iranṣẹ kan ni opin ọjọ ti yoo yi ọkan awọn ọmọ pada si ti awọn baba, pada si ojúlówó iṣẹ-iranṣẹ pentikosti ni Ọ̀rọ̀ sí Ọ̀rọ́. Ẹyin arakunrin, ibí ni a wà! Nisinsinyi, o yẹ ki ijọ yii ni ami kan. Ati ami igbẹyin rẹ̀, a ri ni ibi ninu iwe Mimọ... kiyesi, nisinsinyi. Kiyesi awọn irora ibimọ to ga julọ to tii wa ni igba ijọ Laodekia yi. A ti bí í si inu n... Ijọ ti di atunbi.

Ki yoo si agbekalẹ miiran. Ẹnikẹni lo mọ pe ni gbogbo igba ti isẹ iransẹ kan ba jade... Ẹ bi awọn o ni ìmọ̀ nípa ìtàn. Lẹyin ti isẹ iransẹ kan ba ti jade lọ, agbekalẹ kan ma n jade lati inu rẹ. Ho, Alexander Campbell, o hun miiran lèyin rẹ, Martin Luther ati ohun gbogbo, wọn maa n di ẹgbẹ-to-fi-eniyan-ṣe-adari ni. Bi ó sì ṣe ma n jẹ isẹ iranṣẹ kan ma n lọ fun bi ọdun mẹta - isọji kan. Eyi si ti n lọ fun bi ọdun mẹẹdogun, kò sì tii si ẹgbẹ- to-fi-eniyan-ṣe-adari kankan to ti ìnu rẹ jade. Kí lò fáá? Iyangbo naa lo gbẹ yin. A wà ní òpin. Ṣe o rí awọn irora ibimọ? Ṣe o kiyesi ohun to sẹlẹ? Awọn diẹ to sẹ ku lasan la o mu jade. Idi ni yẹn ti mo fi n pariwo, ti mo n ti ra ka, mo n gbiyanju ti mo si n fi gbogbo oju rere eniyan lori ilẹ aye silẹ lati ri oju rere pẹlu Ọlọrun ti mo si n rin ninu Ọrọ Rẹ. O wa ninu ìrora. Iyẹn ni ohun to sẹlẹ. Yoo bi ọmọ. O gbọdọ yan ohun to fẹ. A ti kọ idajọ si ara ogiri. A ri pe aye ti fẹ parẹ́. Bẹẹ lori. A si ri ijọ; o ti jẹra, o ti fẹ parẹ́. Irora ìbímọ si wa lori gbogbo rẹ - lori aye ati ijọ naa. Aye tuntun kan si wà ti a gbọdọ bi ati Ijọ tuntun lati lọ si bẹ fun ijọba ẹgbẹrun ọdun. A mọ iyẹn.

Wo Ọlọrun fun un (Ẹ feti silẹ daradara si eyi nisinsinyi. Mo n wá si ìparí) àmì rẹ to gbẹyin, isẹ iransẹ rẹ to kẹyin, àmí rẹ to gbẹyin. Ami rẹ to gbẹyin nipe o ni lati pada si ipo to wa ni ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀. Aye, ijọ naa... wo bi ó ti ri ni ibẹrẹ, gbogbo ọdun sẹyin - lati igba Malaki titi di igba Jesu. Wo lati awọn ọdun yi wa, wo gbogbo rẹ látẹ̀yìn wá, pẹlu ìdibàjẹ́ to wọ inu rẹ. Wo ile aye, bi o ti ri ni igba kọkan - bi igba ọjọ Noah, ati síwájú. O ni lati jẹ irú à fi wé kanna, a si ri iyẹn. “Gẹgẹ bi o ti ri nigba a aye Noah” ari awọn nkan wọnyi ti wọn n sarajọ ni ọna kan naa.

Ka iroyin kikun ni... Ìrora Ìbímọ



Ifiranṣẹ ibudo...Yan ede rẹ ki o gba awọn ifiranṣẹ ọfẹ lati ọdọ Arákùnrin Branham.


Ohun ijinlẹ Kristi.

Wẹẹbu iwe iroyin Gẹẹsi.

Iwe Ifihan jara.

 

Ọlọrun ati Imọ Atọka.
- Archaeology.

Igbasoke n bọ.

 

Awọn ẹkọ akọkọ
ti ifiranṣẹ naa.

Awọn ti o dara iroyin.
Jesu ku fun ese re.

Iribomi Omi.

 

Awọsanma eleri nla.

Ọwọn ti ina.

Ogo Shekinah ti Ọlọrun.

Ibojì ti ṣofo.
O ti jinde.

Ọlọrun salaye.

Awọn ìgbà ijọ meje.

Awọn edidi meje.

Ọlọrun ati Itan.
jara Atọka - Dáníẹ́lì.

Kristiẹni ije jara.
Ìgbéyàwó Àti Ìkọ̀sílẹ̀.
Akojọ Ifiranṣẹ.

Opin akoko jara.

Ngbe ọrọ jara.

Keresimesi jara.

Iku. Ohun ti nigbana?

Orúkọ Ọlọrun.

Ọkọ Noa.

 

Ẹṣẹ Atilẹba.
Je o ẹya apulu?

Adaparọ.
Awọn orisun - Babeli.

Ọlọrun ati Imọ.
Dainoso Adaparọ.

Archaeology.
Sodomu ati Gomorra.

  Iwe-mimọ sọ...

Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹ óo sunkún, ẹ óo ṣọ̀fọ̀, ṣugbọn inú aráyé yóo dùn. Ẹ óo dààmú ṣugbọn ìdààmú yín yóo di ayọ̀.

Nígbà tí aboyún bá ń rọbí, ó gbọdọ̀ jẹ ìrora, nítorí àkókò ìkúnlẹ̀ rẹ̀ tó. Ṣugbọn nígbà tí ó bà bímọ tán, kò ní ranti gbogbo ìrora rẹ̀ mọ́, nítorí ayọ̀ pé ó bí ọmọ kan sinu ayé.

Johanu 16:20-21


Tẹ aworan kan lati ṣe igbasilẹ aworan iwọn ni kikun tabi PDF.


Acts of the Prophet

(PDFs Gẹẹsi)

Ìgbéyàwó Àti Ìkọ̀sílẹ̀.

(PDF)

William Branham
Life Story.

(PDF Gẹẹsi)

How the Angel came
to me.

(PDF Gẹẹsi)