Iku. Ohun ti nigbana?

<< išaaju

itele >>

  Ajinde jara.

Nwò kọjá ikélé akókó.


William Branham.

Ka iroyin kikun ni...
Ọba Náà Tí Wọń Kọ̀.

Ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àìkú tí ó kọjá, mo tètè jí, ó jẹ ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, ìràn yìí. Ominú ti ń máa kọ mí, mo ti máa ń ronú ikú. Èmi, tí mo jẹ́ ẹni àádọ́ta ọdún, àkókò mi... N kò rò pé ó gun. Mo ti ń ronú pé báwo ni n o ṣe rí nínú àra òkè-ọ̀run, ara-ọ̀run. Ǹjẹ́ yóò jẹ́ wípé nígbà tí mo bá rí àwọn ọ̀rẹ mi iyebíye n o wá rí kúrukúru funfun tí ń lọ tí n o sì sọ wípé, “Arákùnrin Neville ni ó ń lọ yẹn”. Tí kò sì ní lè sọ pé, “pẹ̀lẹ́ o, Arákùnrin Branbam”? nígbà tí Jesu bá sì dé ni n o wá di eniyan pàdà. Mo ti máa ń ronú èyí.

Mo wá ńlá àlá wípé mo wà ní ìwọ̀-oòrùn mo sì ń sọ kalẹ̀ bọ̀ láti inú igbó kan, ìyàwó mi sì wà pẹ̀lú mi, tí a sì ń pa ẹja òṣùmàrè. Mo dúró mo sì ṣí ilẹ̀kùn tí ilooro, ojú-ọ̀run sì dára púpọ̀. Wọn kò rí bí ó ti ṣe rí ní afonífojì ní ibíyí. Wọn jẹ́ àwọ̀ aró pẹ̀lú àwọ̀sánmà funfun. Mo sì wí fún ìyàwó mi pé, “ó yẹ kí a ti wà ní ibiyí ní ìgbà pípẹ́ ṣẹ́yìn, Oyin”.
O wípé, nítorí tí àwọn ọmọ, kò yẹ kí a ti wà, Billy“,
Mo sọ wípé, “Bẹ́ẹ̀...”

Mo sì jí dìde. Mo wá ronú pé, “Mo ń lá àlá púpọ̀ jù, è é ṣe tí ó fi rí bẹ́ẹ̀?” Mo sì wolẹ̀, ó sì tún wà ní ẹ̀gbẹ́ mi tí ó sùn. Mo gbára lé ìrọ̀rí mi, bí ọpọlọ́pọ̀ yín ti máa ńṣe, mo sì wa gbé orí mi lé ibi òkè ibùsùn àti ọwọ́ mi lẹ́yìn mi. Mo sì na ara síbẹ̀ báyìí. Mo wá sọ wípé; “Mo sì ti lẹ̀ wà nkọminú ohun tí yóò jẹ́, ní òdìkéjì lọ́hún. Mo ti di ẹni àádọ́ta ọdún, n kò sì ti ṣe ohun kan síbẹ̀. Tí mo bá lè ṣe ohun kan láti fi ran Olúwa lọ́wọ́. Nítorí mo mọ̀ pé ń kì yóò jẹ́ eniyan ẹlẹran-ara... idájì ìgbà mi ti lọ, ó kéré tán, tàbí ju ìdajì lọ, tí mo bá lè gbé to iye ọdún àwọn eniyan mi, síbẹ̀ ìdájì ìgbà mi ti lọ, o kéré tán, tàbí ju ìdáji lọ. ”Mo sì wò yíká, mo sì wà lórí ibùsùn tí mo fẹ́ dide. Ó jẹ́ nǹkan bí agogo meje. Mo wípé, “Mo gbagbọ wípe n o lọ sí ilé-ìjọsìn ni òwúrọ̀ yìí, tí ohùn mi bá ti há, N o fẹ́ láti gbọ Arákùnrin Neville kò wàásù.
Mo sì wá wípé, “N jẹ́ o ti jí, Oyin?” O sì nsùn fọnfọn.
N kò si fẹkí ẹ pàdánù eléyìí, o tí yí mi pada. Ǹ kò lè jẹ́ Arákùnrin Branham ti tẹlẹ mọ.

Mo sì wò, tí mo sì gbọ́ ohun kan tí ó ń sọ wípé, “Ó ṣẹṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni. Máa tẹ̀síwájú nínú ògùn náà. Sá máa tẹ̀síwájú”. Mo mi orí mi fún ìṣẹ́jú kan. Mo ronú, “Bóyá mo kan ń rònú lọ́nà báyìí ni, ṣe ẹ mọ̀pé eniyan lè ní ìwòòye”, mo sì wípé, “Bóya mo kan n wòye èyí nnì ni”.
Ó wípé, “Tẹ̀síwájú ní ogun náà! máa lọ! Máa lọ!”
Mo sọ wípé, “Bóya èmi ló ń sọ èyí”,
Mo sì wá fi eyín mi di ètè mi mú, mo sì fi ọwọ́ mi bo ẹnu mi, bẹ́ẹ̀ni ohùn náà sì tún ni wípé, “sá máa tẹ̀síwájú, ti ó bá tilẹ̀ mọ ohun tí o wá lòpin ọ̀nà náà”. O sì dàbí ẹnipé mo lè gbọ́ Graham Snelling tàbí ẹnìkan tí ó ń kọ orin nnì báyìí; wọn máa ńkọ nibiyí - Anna Mac àti gbogbo yín:
Àárò ilé sọ mi, mo sì ń pòǹgbẹ mo sì fẹ́ rí Jesu;
N o fẹ́ kí àwọn agogo ebúté dídùn náà rò;
Yóò ṣe ìmọ́lẹ̀ sí ipa ọnà mi, tí yóò sì mú gbogbo ẹ̀rù lọ;
Olúwà, jẹ́ kí nwò kọjá ikélé akókó,
Ẹ ti gbọ ti wọn kọ ni ilé-ìjọsin yìí,
Mo sì gbọ ohun kan ti ó wípé,
“Njẹ́ ìwọ yóò fẹ láti wo kọja ìkélé àkókò náà bíi?
Mo sọ wípé, “yóò rànmí lọ́wọ́ púpọ̀”. Mo sì wo, ní iṣẹ́jú díẹ̀, èémí kan, mo tí dé ibikan tí ó tẹ́; mo sì wo ẹ̀yìn, níbẹ̀ ní mo sì wa lórí ibùsùn mi. Mo sì wí pé; “Èyí ṣe àjèjì”.

Nisisiyi, n kò ní fẹ́ kí ẹ tún èyí wí, níwájú ìjọ mi ni mo ti ń sọ èyí, tàbí àwọn àgùntàn tí mo ń ṣe olùṣọ́ fún. Bóyá mo ti jáde kúró nínú ara yi tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, bóyá ó jẹ́ ìpaláradà... kò da bí ọ̀kan nínú àwọn ìran tí mo ti máa ń rí tẹ́lẹ̀. Mo lè wò lọ́hùn, mo sì tún le wo ibi yi nígbà kanna. Nígbàtí mo sì dé ibi kékeré náà, n kò ti ri ọ̀pọ̀ eniyan bẹ́ẹ̀ rí, tí wọn ń sáré wá, tí wọ́n sì ń kígbe, “oh, arákùnrin wa ọ̀wọ́n!” mo si wo, àwọn ọ̀dọ́mọbìnri bóyá bíi ẹni ogún ọdún, ẹni ọdún méjìdínlógún si ogún ọdún, wọn fi ọwọ́ wọn di mọ mi ti wọn sì ń kígbe pé, “arákùnrin wa iyebíye”.
Níbiyi ni àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin náà dé tí wọ́n si ń dán bi ìgbà-èwe wọn, tí ojú wọn si n tàn, tí wọ́n dàbí ìràwọ̀ nínú òkùnkùn òru, ẹyín wọn funfun bíi peali, wọ́n sì ń kígbe tí wọ́n di mọmi pẹ̀lú igbe, “oh, arákùnrin wa ọ̀wọ́n!” Mo sì dúrò, mo sì tún wo, mo sì ti di ọ̀dọ́. Mo sì n wo ara mi àtijọ́ mi lórí ìbùsùn pẹ̀lú ọwọ́ mi lábẹ́ orí mi, mo wá sọ wí pé, “Èyí kò yé mi.”
Àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin wọ̀nyí pẹ̀lú ń fi ọwọ́ wọn kọ́mi lọ́rùn.

Nisisiyi, mo mọ̀ wípé tọkùnrin-tobìnrin ni ó wà ni ibíyi, mo sì sọ èyí pẹ̀lú adùn àti ìdákẹ́rọ́rọ́ ti Ẹ̀mí. Àwọn ọkùnrin kò le fi ọwọ́ kọ́ àwọn obìnrin lọ́rùn kí ara eniyan ma mọ́ yàtọ̀. Ṣùgbọ́n kò sí níbẹ̀, kò sí àná tàbí ọ̀la, àárẹ̀ kò mú wọn. wọn kan..... n kò tii rí irú àwọn obìnrin tóní ẹwà bẹ́ẹ̀ rí láyé mi. Irun orí wọn gùn dé ìbàdí wọn, tòbí wọn gun de ẹsẹ̀ wọn, wọn sì ń di mọ́mi. Kò dàbí ìgbàtí arábìnrin mi tí ó jókòó níbẹ̀yẹn bá di mọ́mi. Wọ́n kò fi ẹnu kò mí ni ẹnu, èmí náà kò fi ẹnu kò wọ́n ní ẹnu. Ó jẹ́ ohun tí n kò ni ọ̀rọ̀-ńlá fun; N kò ni àwọn ọ̀rọ̀ láti sọ, pípé, kò le ṣàlàyé rẹ̀. Ó tayọ, kò le ṣàlàyé rẹ̀ lọ́nà kankan. Ó jẹ́ ohun tí n kò.... O ní láti wà níbẹ̀.

Wọ́n sì wo ìhín àti ọ̀hún, wọ́n sì ń wá ni ẹgbẹẹgbẹrun. Mo sì wípé, “Èyí kò yé mi.” Mo sọ pé, “Èéṣe, àwọn... nígbànáà ni Hope si de - ẹnití i ṣe ìyàwó mi àkọ́kọ́. Ó sáré, kò sí wí pé “ọkọ mi”. ó wípé, “Arákùnrin mi ọwọn.” Nígbàtí ó sì di mọ mi, obìnrin mìíràn sì wa níbẹ̀ láti di mọ mi, Nígbànáà ni Hope si dì mọ́ obìnrin yìí àti mọ ara wọn... mo rò wípé, “èyí ni láti jẹ́ ohun tí ó yàtọ̀, kò gbọdọ̀ ri bẹ́ẹ̀. Ohun kan wa...” Ǹ jẹ́ n o ha fẹ́ padà si ogbologbo ara kíkú nni mọ bí? Mo wò káàkiri mo sì ronú pé, “kínni èyí?” Mo sì dùn wò púpọ̀, mo sì wípé, “èyí kò yé mi“ ṣùgbọ́n Hope dàbí ẹni pàtàkì. Kò yàtọ̀ rárá, ṣùgbọ́n ó dàbí ẹni pàtàkì kan.

Mo sì gbọ́ ohùn kan tí o bámí sọ̀rọ̀ láti inú iyàrá náà, tí ó wípé; “Èyí ni ohun tí ó ti wàásù tí i ṣe Ẹ̀mí Mímọ́. Èyí ni ìfẹ́ pípé, kò sì sí ohun kan tí ó le wọ ibíyi láìsí eyi.
Mo wa pinnu ju ti àtẹ̀yìnwá lọ nínú ayé mi wípé ó gba ìfẹ́ pípé láti wọ ibẹ̀. Kò sí owú jíjẹ. Kò sí àárẹ̀, kò sí ikú, àìsàn kò le wọ ibẹ̀ láyéláyé. Ẹ̀dá eniyan kò le jẹ́ kí ó di arúgbó, wọn kò si le sunkún. Ó jẹ́ ayọ̀ kan - “Oh, arákùnrin mi ọwọn.”
Nwọn sì gbé mi jòkóò ni ibi ńlá gíga kan. Mo sì wa ronú pé, “N kò lá àlá, ara mi ni mo sì ń wò tí ó dùbúlẹ̀ ní orí ibùsùn ni ibẹ̀ yẹn.” Nwọn sì gbé mi jókòó níbẹ̀ yẹn, mo sì wípé, “Oh, kò yẹ kí n jókòó nibiyi.”
Àwọn ọkùnrin àtobìnrin si ń wá láti ẹgbẹ́ méjèèjì, tí wọ́n wa ndán bi ọ̀dọ́, wọ́n ń kígbe. Obìnrin kan si dúró níbẹ̀ tí ó kígbe, “Oh arákùnrin mi ọ̀wọ́n. Oh, inú wá dùn púpọ̀ láti rí ọ ni ibíyi.”
Mo sọ wípé, “Eléyìí kò yé mi.”
Nígbànáà ohùn tí ó ń bámi sọ̀rọ̀ láti òkè wa sọ wípé; “Ṣèbí o mọ̀ wípé a ti kọ́ nínú Bíbélì wípé a kó àwọn wolii jọ pẹ̀lú àwọn eniyan wọn.”
Mo sì sọ wípé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo rántí nínú ìwé mímọ́.”
Ó sì wípé, “Èyí ni ìgbà tí a ó ko ọ jọ pẹ̀lú àwọn eniyan rẹ̀.”
Mo sì wí pé, “Nígbànáà wọn yóò wa nínú ara gidi, mo lè mọ wọn nínú ara mi.”
“Bẹ́ẹ̀ni o”
Mo wípé, “Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ni àwọn wọ̀nyí. Ìdílé Branham kò pọ̀ tó báyìí.”
Ohùn náà si sọ wípé, “Àwọn ìdílé Branham kọ nìyí, àwọn tí ó jèrè fún Krístì nìyí. Àwọn tí ó darí sí ọ̀dọ̀ Olúwa ni.” O sì wípé, “Díẹ̀ nínú àwọn obìnrin tí ó rò wípé ó lẹ́wà púpọ̀ wọ̀nyí tilẹ̀ ju ẹni àádọ́run ọdún lọ nígbàtí ó darí wọn sí ọ̀dọ̀ Olúwa. Kò yanilẹ́nu tí wọ́n fi n kígbe pé, 'Arákùnrin wa ọ̀wọ́n.'”
Gbogbo wọn si kígbe lẹẹkanaa, “Tí o kò bá ti lọ, àwa ki bá ti wa níbíyí.”

Mo wò yíká, mo sì rò wípé, “Èyí kò yé mi,” mo wa sọ wípé “oh, níbo ni Jésù wa? Mo fẹ ́ láti rí I kánkán.
Wọ́n sì sọ wípé, “Nísisiyi, Ó wá lókè díẹ̀ sí ní ibẹ̀ yẹn”, wọ́n wípé, “Yóò tọ̀ ọ́ wá lọ́jọ́ kan”, wọ́n wípé, “A rán ọ jáde gẹgẹ́bí olórí kan, Ọlọ́run yóò sì wá, nígbà tí ó bá sì dé, yóò dá ọ lẹjọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó ti fi kọ́ wọn, lákọ́kọ́ náà, bóyá wọn yóò wọlé tàbí bẹ́ẹ̀kọ́. A o wọlé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀kọ́ tí ó ti kọ́ wa”.
Mo sọ wípé, “Oh, inú mi dùndùn púp! Ṣe Paulu... n o ní láti dúró báyìí? Ṣe Peteru ni láti dúró báyí?”
“Bẹ́ẹ̀ni”.
Mo wípé “Nígbà náà, mo ti wàásù ohun gbogbo tí wọ́n wàásù”. Èmi kò yẹsẹ̀ kúrò níbẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ kan tàbí òmíràn. Níbi tí wọ́n ti ṣe Ìtèbọmi ní Orúkọ Jesu Kristi, mo ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. Níbití wọ́n ti kọ mi ní Ìtẹbọmi Ẹ̀mí Mímọ́, mo ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú, ohunkóhun tí wọn fi kọní, mo ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú“.
Àwọn eniyan wọnnì sì kígbe wípé, “Awa mọ èyí, a sì mọ wípé awa yóò padà sínú ayé pẹ̀lú rẹ̀ ní ọjọ́ kan”, wọ́n wípé, nígbà tí Jesu yóò dé, a ó sì dá ọ lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ náà ti ó ti wàásù fún wa. Nígbà náà, tí a bá ṣe itẹ́wọ́gbà, èyí tí yóò rí bẹ́“, wọn sì wípé, ”Nigbà náà, ni ìwọ yóò fi wá fún-un gẹ́gẹ́ bí àwọn èrè iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀“. Wọ́n sì wípé, “ìwọ yóò darí wá sọ́dọ̀ Rẹ̀ àti ní apapọ̀ a o padà sínú ayé láti máa gbé títí láé”.
Mo wípé; “Ǹjẹ́ mo ní láti padà báyìí?”
“Bẹ́ẹ̀ni, ṣùgbọ́n máa tẹ̀síwájú”.

Mo wo. Mo sì rí àwọn eniyan tí wọn sì ń bọ̀ wá láti ọ̀nà jínjìn réré ní bí mo ti ṣe lè rí mọ, tí wọ́n fẹ́ dì mọ́ mi, tí wọ́n ńkígbe, “arákùnrin wa ọ̀wọ́n”.
Nígbà náà, ohun kan sọ wípé, “gbogbo ẹnití ó nifẹ́ àti gbogbo ẹnití ó nifẹ rẹ, ni Ọlọ́run ti fún ọ níbíyìí”. Mo sì wò, níbẹ̀ ni mo ti rí ajá mi àtijọ́ tí ó ń rìn bọ̀ wá. Bẹ́ẹ̀ni mo rí ẹṣin mi tí ó rìn wá tí ó sì gbé orí rẹ̀ lé mi ní èjìká tí ó sì ń kígbe, wọ́n sì wípé, “gbogbo ohun tí ó nifẹ́, àti gbogbo ohun tí ó nifẹ́ rẹ ni Ọlọ́run ti fi lé ọ lọ́wọ́ nípasẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀”.
Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí níí mọ wípé a ti ń gbàmí kúrò ní ibi dídára náà. Mo sì wo yíká, mo ní “ṣe o ti jí, Oyin?” O sì tún sùn, mo wá rò wípé, “Ọlọ́run o! Oh, ran mí lọ́wọ́, Ọlọ́run o, má ṣe jẹ́ kí n gba àbọ̀de pẹ̀lú ọ̀rọ̀ kan. Jẹ́ kí ń dúró ṣánṣán pẹ̀lú ọ̀rọ̀ náà kí n sì wàásù rẹ̀. N kò bìkítà ohunkóhun tí ó wù kí ó ṣẹlẹ̀, ohun tí ẹnikan lè ṣe, iye àwọn Saulu, àwọn ọmọ Kiiṣi, tí ó dìde, iye àwọn èyí, ìyẹn tàbí òmíràn, Olúwa! Jẹ́ kí n lè tẹ̀síwájú síi ibẹ yẹn”.

Gbogbo ẹ̀rù ikú... mo sọ èyí pẹ̀lú Bíbélì mi níwájú mi ní òwúrọ̀ yìí. Mo ní ọmọkùnrin kékeré kan níbẹ̀ yẹ, ẹni ọdún mẹ́rin, láti tọ dágbà. Mo ní ọmọbìnrin ẹni ọdún mẹ́sàn-án àti ọ̀dún kan tí mo dúpẹ́ fún, tí ó ti yípadà si ọnà Olúwa. Ọlọ́run! Jẹ́ kí ń lè wá láàyè láti tọ wọn ní ìlànà Ọlọ́run. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó dàbí ẹni pé gbogbo ayé ń kígbe sí mi. Awọn ẹni àádọ́rún-un ọdún lọ́kùnrin àti lóbìnrin àti onírúurú, “Tí o kò bá tí lọ ni, a kò bá ti wà níbíyìí”. Ọlọ́run jẹ́ kí n lè tẹsiwaju ninu ogun náà. Sùgbọ́n tí ikú bá dé, tí ń kò sì mọ̀... yóò jẹ́ ayọ kan, yóò jẹ́ ìdunnú láti wọlé kúrò ní ibi ìdíbàjẹ́ àti ìtìjú yìí.

Tí ó bá lè ṣééṣe fún mi lókè lọ́hún láti ní ibùsọ ọgọ́rùn-ún bílliọ́nù kan, tí ògiri tí a kọ́, tí ó jẹ́ ìfẹ́ pípé. Gbogbo ìṣísẹ̀ ni ibiyí ni ó sì ńhá sí, títí a o fi dé ibi tí a wà nísisiyi. Yóò sì jẹ́ òjìjì ìdíbàjẹ́ lásán ni. Ohun kékeré nnì tí a lè mọ̀ nínú wa àti lára wípé ohun kan wà ní ibìkan, a kò mọ ohun tíí ṣe. Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi iyebíye, ẹ̀yin olùfẹ́ mi, ẹ̀yin olólùfẹ́ mi nínú ìhìnrere, ẹ̀yin ọmọ tí mo bí fún Ọlọ́run, ẹ gbọ́ tèmi Olùṣọ́-àgùntàn yín. Ìbá wùmí kí ọ̀nà kan wà fún mi láti ṣàlàyé rẹ̀ fún yín. Kò sí àwọn ọ̀rọ̀ kankan. Ǹ kò lè ríi, a kò lè ríí níbi kan, ṣùgbọ́n lẹ́yìn èémí ìkẹyìn yìí ni ohun tí ó lógo jùlọ tí ó ti lè.... Kò sí ọ̀nà láti ṣàlàyé rẹ̀. Kò sí ọ̀nà kan; N kò tilẹ̀ lè ṣe é. Ṣùgbọ́n ohunkóhun tí ẹ bá ń ṣe, ẹ̀yin ọ̀rẹ́, ẹ pa ohun gbogbo tì sí apákan títí ẹ o fi ní ìfẹ́ pípé. Dé ibi tí ẹ ó fi lè fẹ́ gbogbo eniyan, gbogbo ọtá, ohun gbogbo. Abẹ̀wò kan tímo ní síbẹ̀ tí sọ mí di ọkùnrin ọ̀tọ̀. Ǹkò lè jẹ́ irú Arákùnrin Branham tí mo ti jẹ́ tẹ́lẹ̀ mọ́ láé láé.

W. Branham.

Ka iroyin kikun ni...
Ọba Náà Tí Wọń Kọ̀.

(PDF Gẹẹsi)...  Beyond the curtain of time.


  Iwe-mimọ sọ...

Dandan ni pé kí gbogbo eniyan kú lẹ́ẹ̀kan, lẹ́yìn ikú ìdájọ́ ló kàn.

Bákan náà ni Kristi, nígbà tí a ti fi rúbọ lẹ́ẹ̀kan láti kó ẹ̀ṣẹ̀ ọpọlọpọ lọ, yóo tún pada lẹẹkeji, kì í ṣe láti tún ru ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, ṣugbọn láti gba àwọn tí ó ń fi ìtara retí rẹ̀ là.

Heberu 9:27,28


Ohun ijinlẹ Kristi.

Wẹẹbu iwe iroyin Gẹẹsi.

Iwe Ifihan jara.

 

Ọlọrun ati Imọ Atọka.
- Archaeology.

Igbasoke n bọ.

 

Awọn ẹkọ akọkọ
ti ifiranṣẹ naa.

Awọn ti o dara iroyin.
Jesu ku fun ese re.

Iribomi Omi.

 

Awọsanma eleri nla.

Ọwọn ti ina.

Ogo Shekinah ti Ọlọrun.

Ibojì ti ṣofo.
O ti jinde.

Ọlọrun salaye.

Awọn ìgbà ijọ meje.

Awọn edidi meje.

Ọlọrun ati Itan.
jara Atọka - Dáníẹ́lì.

Kristiẹni ije jara.
Ìgbéyàwó Àti Ìkọ̀sílẹ̀.
Akojọ Ifiranṣẹ.

Opin akoko jara.

Ngbe ọrọ jara.

Keresimesi jara.

Iku. Ohun ti nigbana?

Orúkọ Ọlọrun.

Ọkọ Noa.

 

Ẹṣẹ Atilẹba.
Je o ẹya apulu?

Adaparọ.
Awọn orisun - Babeli.

Ọlọrun ati Imọ.
Dainoso Adaparọ.

Archaeology.
Sodomu ati Gomorra.

Tẹ aworan kan lati ṣe igbasilẹ aworan iwọn ni kikun tabi PDF.


Acts of the Prophet.

(PDFs Gẹẹsi)

The Two Babylons

by Rev Alexander Hislop.
(PDF Gẹẹsi)

Oke ati dide igbo
ni egbon ni Ṣaina.

Awọn Lili ti Ina.

William Branham
Life Story.

(PDF Gẹẹsi)

How the Angel came
to me.

(PDF Gẹẹsi)

Ọwọn ti Ina.
- Houston 1950

Imọlẹ lori apata
jibiti.


 


Ifiranṣẹ ibudo...Yan ede rẹ ki o gba awọn ifiranṣẹ ọfẹ lati ọdọ Arákùnrin Branham.