Ìgbéyàwó Àti Ìkọ̀sílẹ̀.

<< išaaju

itele >>

  Kristiẹni ije jara.

Ko ri bẹẹ lati atetekọṣe.


William Branham.

Ka iroyin kikun ni...
Ìgbéyàwó Àti Ìkọ̀sílẹ̀.

Matiu 19:8,
8 O wi fun wọn wipe, Nitori lile aya yin ni Mose ṣe jẹ fun yin lati maa kọ aya yin silẹ; ṣugbọn lati igba atetekọṣe wa, ko ri bẹẹ.

Iwe mimọ yii, ibeere yii, dojukọ Jesu ni ibẹrẹ iṣẹ-iriju iwaasu Rẹ, o si dojukọ Mose ni ibẹrẹ iṣẹ-iriju iwaasu rẹ. O jẹ ibeere akọkọ ni ọkan onigbagbọ. Ẹlẹṣẹ ko bikita. Ṣugbọn awọn onigbagbọ ni o wa fun, nitori onigbagbọ n ṣe gbogbo ohun ti o mọ lati ṣe, lati gbe igbe-aye ti o tọ́ niwaju Ọlọrun. Nitorinaa, ti ibeere kankan ba jẹyọ nipa ẹsin, ọrọ lori igbeyawo ati ikọsilẹ maa n jẹyọ. Ki ni idi? Idi ni wipe oun ni o fa ẹṣẹ akọkọ. Ibi ti ẹ̀ṣẹ̀ ti bẹrẹ niyẹn, idi si nìyẹn ti o fi maa n jẹyọ ni gbogbo igba, nitori oun gan-an ni ibẹrẹ ẹṣẹ.

Bayi, n ko ni ni akoko lati ṣalaye gbogbo awọn nkan wọnyi, ṣugbọn inu mi yoo dun lati dahun awọn iwe yin tabi ohunkohun ti mo ba lee ṣe, tabi a ti ni awọn iwe ti a kọ nipa rẹ, ati ọpọlọpọ awọn ibeere, ati awọn iwe iroyin ti a ge, ati awọn nkan miiran nihin lati fi idi eleyi mulẹ. A mọ wipe Eefa ni.... Eso apple ti wọn sọ wipe ó jẹ (ko tilẹ ba iwe mimọ mu), bayi, wọn tun sọ wipe eso apricot ni. Kii ṣe ọkankan ninu awọn mejeeji. Panṣaga ni o ṣe, eyiti o mu ọmọ àkọ́kọ́ wá, ìyẹn ni Kaini, ọmọkunrin Satani. Nitori inu rẹ̀ ni ibi wà. Ko ti ipaṣẹ Abẹli wá. Ọmọ Satani ni Kaini.

----
O da gẹgẹ bi mo ṣe sọ; ti mo ba fẹ lọ si ila oorun ni owurọ yii, eyi ti o dara ju ti mo mọ ni... mo nilati wadi ohun kan pàtó ni pápá, ti o si wà ni ìlà oorun, ti mo si lọ si ila oorun. Ki ẹnikan wa sọ wipe, “Arakunrin Branhan, ila oorun niyi.” O jẹ ila-oorun lọna kan, ṣugbọn ila-oorun ariwa ni. N ó kọja ohun ti mo n wa gan-an; n o si pada wa, n o wa mọ wipe o kuna. Ti ẹnikan ba si sọ wipe, “Arakunrin Branham, gba ọna yii lọ, ni apa ọtun rẹ.” Bayi, ìyẹn naa jẹ ila-oorun ni ọna kan, ṣugbọn ila-oorun gusu ni. N o padanu ohun ti mo n wa lọ, nitori pe mo ti kọja aala ọna ti o lọ taara, ti o sì pé.

Njẹ ti o ba ri bẹẹ, a ni awọn erongba ẹkọ meji lori igbeyawo ati ikọsilẹ. Ọkan ninu wọn sọ wipe, ẹẹkansoso ni ọkunrin lee fẹ iyawo ayafi ti iyawo rẹ ba ku. Ọkan ninu awọn ibeere naa nìyẹn. Ṣugbọn ti ẹ ba tẹle ìyẹn, ẹ o kọja ààlà. Ekeji si sọ wipe, “Ah, ti iyawo tabi ọkọ (ọkan ninu wọn) ba ṣe panṣaga, eyikeyi ninu wọn ni a lee kọ silẹ, ki o si tun igbeyawo ṣe.” Iwọ yoo tun kọja aala pẹlu ìyẹn.

Ṣe ẹ rii bayi, kii ṣe ila-oorun gusu tabi ila-oorun ariwa; ila-oorun taara ni a n fẹ. Iwọ yoo kuro ninu iwe mimọ ti o ba lọ ni ọna yii. Iwọ yoo kuro ninu iwe mimọ ti o ba lọ ni ọna yẹn. A fẹ mọ ibi ti iwe mimọ ti pade ara wọn, ki a si mọ otitọ rẹ̀. Olukuluku gba ọna ọtọọtọ, wọn si kuna lati mu idahun ti o tọ́ wá, ṣugbọn idahun sì nilati wà.

O dabi ọjọ oni, awọn ẹkọ nla meji ni o wà ninu ijọ: ọkan ninu wọn ni ti Calvin, ekeji si ni Arminia. Ọkan ninu wọn jẹ olofin, ekeji si jẹ oloore-ọfẹ. A si wa rii wipe awọn eniyan ti o gbagbọ ninu oore-ọfẹ (awọn atẹ̀lé Calvin), wọn ni, “Ẹ fi ibukun Ọlọrun, ko ṣe mi ni nkankan lati mu siga, ko pa mi lara lati mu ọti. Mo lee ṣe awọn nkan wọnyi; mo ti ni aabo ainipẹkun.” A si wa ri ẹni ti o wà ni apa keji (awọn olofin) sọ wipe, “Ah, o wu mi lati bu u gidigidi, o wu mi lati sọrọ sii; ṣugbọn Kristẹni ni mi, mo nilati dakẹ jẹẹ.”
Ṣe ẹ rii, a ba ara wa ni ọna meji ọtọọtọ, kò sì sí eleyi ti o tọ́ ninu wọn. Bayi, ìyẹn le lati sọ, ṣugbọn otitọ ni. A bá ara wa ni ọna meji ọtọọtọ: ọkan lọ ni ọna kan, ekeji si lọ ni ọna miiran. Bayi, ẹ jẹ ki a wo kini otitọ.

----
A ni awọn ero meji nipa igbeyawo ati ikọsilẹ yii. Ni bayi ti Oluwa wa ti ṣi awọn ijinlẹ edidi meje ti Ọrọ Rẹ fun wa ni ikẹyin ọjọ wọnyi... Bayi, fun ọpọlọpọ yin, eyi lee jẹ adiitu fun yin, ṣugbọn ijọ mi loye ohun ti ... nigbati ẹ ti gbọ nipa awọn iran ati awọn nkan ti o ti ṣẹlẹ. Ibeere naa si jẹ ibeere Bibeli. A pe wa sihin yii lati gbagbọ wipe idahun tootọ kan nilati wà si gbogbo aṣiri ti o ti farasin lati ipilẹsẹ aye. Bibeli si sọtẹlẹ wipe ni ọjọ oni, a o fi awọn aṣiri wọnyi han. Ifihan 10: “Ati ni igba didun ti angẹli keje (ojiṣẹ ti Laodikea) a o sọ awọn ijinlẹ Ọlọrun di mímọ̀.” Iran ti o kẹyin si niyii, eyi tii ṣe Laodikea.

----
Jesu, ninu ibi kika wa, pe wa lati pada si ibẹrẹ fun idahun tootọ lati inu iwe mimọ. Bayi, nigbati eleyi doju kọ Ọ, awọn nkan meji ni o farahan. Alufaa sọ fun-un wipe, “Ṣe ọkunrin lee kọ iyawo rẹ silẹ, ki o si fẹ ẹlomiran nitori ọrọ gbogbo?”
Jesu si wipe, “Ko ri bẹẹ lati atetekọṣe.”
Nigbanaa wọn wipe, “Mose fi aaye gba wa lati kọ iwe ikọsilẹ,” ki a si kọ ọ silẹ fun ohunkohun ti wọn ba fẹ. O sọ wipe Mose ṣe ìyẹn nitori... (ẹ jẹ ki ìyẹn lọ taara fun igba diẹ)... nitori lile aya yin, ṣugbọn lati, tabi ni atetekọṣe, ko ri bẹẹ.
Ibeere naa,...

----
Ti Jesu ba sọ pe, “Ẹ pada si atetekọṣe,” meji-meji iru ohunkohun ni o wà lori ilẹ aye. Adamu kan ni o wà, ati Eefa kan. Ọlọrun nikan ni o so wọn papọ. Abo ẹsin kan, akọ kan. Abo ayekootọ kan, akọ kan. Ni atetekọṣe, bi Ó ṣe sọ fun wa wipe ki a pada, meji-meji iru ohunkohun ni o wà. Ṣe otitọ nìyẹn? Nigbanaa a rii wipe ohun gbogbo ni atetekọṣe n lọ ni pipe, letoleto, ati ni isọkan pẹlu Ọlọrun; ko si ohun ti o yẹ kuro ni aaye rẹ. Ohun gbogbo ni ọrun ṣì wà leto; gbogbo awọn irawọ, awọn akojọpọ irawọ, ilana òòrùn, ohun gbogbo wà ni pipe ati ni eto. Ti ọkan ninu wọn ba yẹ̀, yoo da gbogbo eto naa ru.

Ẹ feti silẹ bayi! Ṣe ẹ rii? Ti ọkan ba yẹ kuro, yoo da gbogbo eto naa ru! Bayi, nigbati awọn eniyan n lọ letoleto pẹlu Ọlọrun, pẹlu ọkunrin kan ati obinrin kan, obinrin yii dẹṣẹ. O si sọ gbogbo eto aye nu kuro ninu itẹsiwaju pẹlu Ọlọrun! Nitorinaa, ọrọ kan ti a ba fi kun Iwe yii, tabi Ọrọ kan ti a ba mu kuro, yoo sọ Kristẹni nu kuro ninu itẹsiwaju pẹlu Ọlọrun, yoo sọ ijọ nu kuro ninu itẹsiwaju pẹlu Ọlọrun, yoo sọ idile nu kuro ninu itẹsiwaju pẹlu Ọlọrun! Gbogbo onigbagbọ ni a lee sọnu nipa aigba gbogbo Ọrọ Ọlọrun gbọ.

----
Bayi, lẹyinnaa ni a mu ki ọkunrin maa ṣakoso obinrin nipa Ọrọ Ọlọrun. Kii ṣe ẹgbẹ kannaa mọ pẹlu ọkunrin. Wọn jọ jẹ ẹgbẹ tẹlẹ gẹgẹbi ẹda, ṣe ẹ mọ. Ṣugbọn nigbati o ṣẹ́ Ọrọ Ọlọrun, Ọlọrun fi ọkunrin ṣe alakoso lori rẹ. Gẹnẹsisi 3:16, ti ẹ ba fẹ kọ ọ́ silẹ. Kii ṣe ẹgbẹ kannaa pẹlu ọkunrin mọ. Ó jẹ ẹniti o ṣẹ́ Ọrọ Ọlọrun.

Ṣe ẹ kò ri “oun” - “oun”, ijọ ti o wà nibi yii, ẹniti o ṣẹ́ Ọrọ Ọlọrun? Ìyẹn si mu u kuro patapata ni itẹsiwaju, ohun ti ijọ si ti ṣe nìyẹn; ó ti da iku ẹmi sori gbogbo rẹ! Bayi, ẹ o mọ idi ti mo fi maa n tẹnumọ awọn nkan wọnyi bi mo ṣe n ṣe! Otitọ ni! Awọn otitọ Bibeli niyi!

Ẹ kiyesii, ki ni idi ti o fi ṣe iru nkan bi eleyi? Bawo ni obinrin ti o ni ifẹ, ti o rẹwa, ti o si pe yẹn...? Mo ri aworan kan nigba kan (mo gbagbọ wipe ni Greece ni) ti ayaworan kan ti o ya aworan Eefa, o jẹ ohun ti o burẹ́wà julọ ti a tii ri ri. Ìyẹn fihan, ohun ti ọkan ẹlẹran ara lee maa wo. Ṣugbọn ko burẹwa. O rẹwa, nitori o jẹ obinrin ti o pe, lati oke de ilẹ.

Ẹ kiyesii, eeṣe ti o fi ṣe iru nkan bẹẹ, bi o ṣe wà ni ipo ti o ga to iyẹn? O wà pẹlu ọkunrin, o jẹ ẹlẹgbẹ rẹ. Ṣugbọn gbogbo wa la mọ bayi wipe o ti sọ jijẹ ẹlẹgbẹ pẹlu ọkunrin nu nigbati o dẹ́ṣẹ̀, Ọlọrun si wipe, “Ọkunrin ni yoo maa se olori rẹ lati isisiyi lọ.” Bayi, Iwe Mimo nìyẹn. Ti ẹ ba fẹ, a lee ka a. Mo n fun yin ni ẹsẹ Iwe Mimọ (ki a lee ge akoko kuru fun awọn ti o wà lori tẹlifoonu kaakiri orilẹ-ede yii) ki ẹ lee ka a funra yin.

Ẹ kiyesi idi ti o fi ṣe ìyẹn. Bawo ni Satani ṣe de ọdọ rẹ?
Njẹ ẹ mọ wipe Satani jẹ ẹgbẹ pẹlu Ọlọrun nigba kan ri? Dajudaju o ri bẹẹ. O jẹ ohun gbogbo yatọ si ẹlẹda. O jẹ ohun gbogbo, o n duro ni ọwọ ọtun Ọlọrun ni ọrun, kerubu nla ti o tayọ. Ẹ kiyesii, idi ti o fi ṣe eleyi, ni wipe ko si ninu ojulowo iṣẹda. Ko si ninu ojulowo iṣẹda Ọlọrun. O jẹ àmújáde. Nitorinaa, ni atetekọṣe (bi Jesu ṣe tọka sii), kii ṣe ojulowo iṣẹda ti Ọlọrun! O jẹ ẹniti a mu jade lati ara ọkunrin, nigbati Jesu tọka si atetekọṣe.

-----
Bayi, lori igbeyawo ati ikọsilẹ, ṣe ẹ rii, a ni lati fi i han. Ti a ko ba tii fi i han, ẹ ko mọ ọ. Ṣugbọn O ṣe ileri wipe ni ikẹyin ọjọ wọnyi, ni iran yii, wipe gbogbo ijinlẹ ti o farasin ninu Bibeli ni a o fi han. Ẹni melo lo mọ ìyẹn? (Ifihan ori kẹwa.) Jesu ṣe ileri rẹ, wipe gbogbo awọn ijinlẹ ti o farasin lori igbeyawo ati ikọsilẹ, gbogbo awọn ijinlẹ ti o farasin yii ti o ti wà, ni a o fi han ni akoko ikẹyin.

Bayi, ṣe ẹ ranti wipe, ohùn naa sọ pe, “Lọ si Tucson?” Ṣe ẹ ranti imọle adiitu kan ni oju ọrun, ati awọn angẹli meje ti wọn duro sibẹ? Mo pada wa, a si ṣi awọn edidi mejeeje? Ẹ kiyesi ohun ti o ti ṣẹlẹ. Otitọ nìyẹn.

-----
Ohun ti o le gidigidi ni eleyi. N ko mọ bi mo ṣe lee sọ ọ! Ki ni n o ṣe nigbati mo ni awọn ọkunrin ati awọn obinrin ti wọn joko ninu ijọ mi, awọn miiran ti ṣe igbeyawo ni igba meji tabi igba mẹta? Awọn ọkunrin rere, awọn obinrin rere, ti nkan ti daru fun! Ki lo fa a? Ẹkọ eke. Bẹẹ ni. Wọn kò duro de Oluwa. “Ohun ti Ọlọrun ti so papọ, ki ẹnikẹni maṣe ya wọn...” Kii ṣe ohun ti eniyan so papọ, ṣugbọn ohun ti Ọlọrun so papọ.

Ti o ba ti ni ifihan taara lati ọdọ Ọlọrun wipe iyawo rẹ nìyẹn, ati nkan kannaa, tirẹ nìyẹn titi ọjọ aye rẹ. Ṣe ẹ rii? Ṣugbọn ohun ti eniyan so papọ, ẹnikẹni ni o lee ya a. Ṣugbọn ohun ti Ọlọrun so papọ, eniyan kankan ko gbọdọ fi ọwọ kan-an. “Ohunkohun ti Ọlọrun ba ti so papọ,” O ni, “ki ẹnikẹni maṣe pin wọn niya.” Kii ṣe ohun ti ọmuti adajọ kan tabi ohun miiran so papọ, tabi oniwaasu kan ti o ti pada sẹyin pẹlu ọpọlọpọ ẹkọ adamọ ninu iwe ti o n gba wọn laaye lati ṣe ohun ti o wu wọn laye yii, ti Ọrọ Ọlọrun si wa nibẹ. Ṣe ẹ rii? Mo n sọrọ nipa ohun ti Ọlọrun ti so papọ.

-----
Ni ijelo, gẹgẹbi mo ṣe mọ wipe ti mo ba sọ ohunkohun fun yin, o nilati jẹ “Bayi ni Oluwa wi,” nigbanaa mo ni awọn Iwe Mimọ gẹgẹbi Ó ṣe fi han fun mi, ṣugbọn, “Oluwa Ọlọrun, ki ni mo lee sọ fun ijọ yẹn? N ó ní awọn ipinya. Awọn ọkunrin yoo joko si ẹnu ọna wọn, ati ni ayika ile wọn ati ibi gbogbo wipe: 'Ṣe ki n fi i silẹ ni?' Awọn obinrin naa: 'Ṣe ki n fi ọkọ mi silẹ ni?' 'Ki ni ki n ṣe?'” Mo ni, “Oluwa, ki ni mo lee ṣe?”

Nkankan sọ fun mi wipe, “Lọ si ori oke yẹn, n o si ba ọ sọrọ.”
Nigbati mo si wà lori oke yẹn.... Laimọ wipe ni isalẹ ni Tucson, wọn n ri i, bẹẹni awọn olukọ tilẹ pe awọn ọmọ lati - (ọmọbinrin mi kekere ati awọn ti o kù) - jade kuro ni yara ikawe, wọn si wipe, “Ẹ wo ori oke yẹn. Ikuuku kan ti o dabi ina ni o n lọ soke ninu afẹfẹ, ti o si n pada sọkalẹ, o n lọ soke ninu afẹfẹ, o si n pada sọkalẹ!”

Iyaafin Evans, ṣe o wa nibi? Ronnie, ṣe o wa nibi? Mo pada sọkalẹ wa si ile-epo, ọdọmọkunrin yii (ni ileepo, ile-epo ti Evans nibẹyẹn, ki n si to mọ ohun ti ọmọkunrin yii fẹ sọ), o ba mi lojiji, o ni, “Arakunrin Branham, o wà lori oke yẹn nibẹyẹn, abi o kò si nibẹ?”
Mo ni, “Ki ni ò ń sọ, Ronnie? Rara.” (Ṣe ẹ rii? Mo fẹ wo ohun ti yoo ṣe.) Ọpọ igba ni awọn nkan maa n ṣẹlẹ ti n kò... n kò sọ ọ fun awọn eniyan. Yoo di.... Ohun ti o wa nibẹ ni wipe, ẹ ti ri ọpọlọpọ ti o ṣẹlẹ, ko jọ yin loju mọ. Ṣe ẹ rii? Emi kii kan sọ fun awọn eniyan ni. Mo ni, “Ronnie, kini iwọ...?”

O ni, “Mo le fi ibi ti o wa gan-an han ọ.” O ni, “Mo pe Mama mi, a si duro nihin yii, a si n wo ikuuku yẹn ti o duro si ofuurufu ni oke yẹn, ti o n lọ soke-sodo. Mo ni, 'O nilati jẹ wipe Arakunrin Branham ni o joko si ibi kan ni oke ibẹyẹn. Ọlọrun ni o n ba a sọrọ yẹn!'”
Gbogbo awọn ara ilu ni o si wo o. Ni ọsan gangan, ti kò si ikuuku nibikibi rara, pẹlu ikuuku alawọ ina yii ti o duro sibẹ, ti o n sọkalẹ bi àrọ, ti o si n pada soke, ti o n gbilẹ.

-----
Bayi, a ba ara wa ninu ibajẹ yii nitori ẹkọ ẹsin ti wọn ṣi tumọ. Ṣe bẹẹ ni? Idi nìyẹn ti ẹyin obinrin fi fẹ ọkọ keji, ati ẹyin ọkunrin, nitori ẹkọ ẹsin ti wọn ṣi tumọ. Bayi, mo fẹ fi nkankan ti ó sọ fun mi han yin. Ti Ọlọrun, Ẹlẹda wa, ti a ba bi I ni ibeere naa nigbati Ó wà lori ilẹ aye (Jesu Kristi), ati nigbati wolii oludande rẹ jade wa (Mose) si Egipti lati mu awọn ọmọ jade kuro ni Egipti, lati fi wọn sinu ilẹ-ileri; Jesu si sọ nibi yii wipe Mose ri awọn eniyan naa ni ipo yii, o si fun wọn ni iwe ikọsilẹ nitori nkan ri bi o ṣe ri, Mose ri iru nkan.... “Jẹ ki o fi aaye gba wọn....” Ọlọrun fi aaye gba Mose, wolii nni ti a ran si awọn eniyan naa, lati fun wọn ni iwe ikọsilẹ yii.

Ni Kọrinti kinni, ori keje, ẹsẹ kejila ati ẹsẹ kẹẹdogun, wolii Majemu Titun, Pọọlu, ẹni ti o ba nkan kannaa ninu ijọ, o si sọ eleyi: “Emi niyi, kii ṣe Oluwa.” Ṣe bẹẹ ni? Nitori ipo ikọsilẹ.
Ko ri bẹẹ ni atetekọṣe. Ṣugbọn a fi aaye gba Mose, Ọlọrun si ka a si ododo! Pọọlu naa pẹlu si ni ẹtọ nigbati o ri ijọ rẹ ni ipọ yẹn.

Bayi, ẹyin gba eleyi gbọ wipe o jẹ otitọ, ati wipe o ti ọdọ Ọlọrun wa. Ati nipa ifidimulẹ ikuuku Rẹ ati iṣẹ-iranṣẹ ti o mu mi de ibi ti mo wa bayi, njẹ Ọlọrun ki yoo gba mi laaye, ni ori oke yẹn, lati ṣe iru nkan kannaa, lati fi aaye gba yin wipe ki ẹ tẹsiwaju ni ipo ti ẹ wà ki ẹ ma si ṣe e mọ? Ẹ maa lọ pẹlu awọn aya yin ki ẹ si maa gbe ni alaafia, nitori ọjọ ti lọ. Bibọ Oluwa ti sunmọ tosi! A ko ni akoko to lati fọ awọn nkan wọnyi si wẹwẹ! Ẹ mase dẹja lati dan iru rẹ wo mọ! Ijọ temi nikan ni mo n ba sọrọ. Ṣugbọn ti ẹ ba ti ṣe igbeyawo - Ọlọrun si jẹ mi lẹri si ìyẹn ni ori oke naa, wipe mo lee sọ eleyi (ifihan atọrunwa nitori ṣiṣi awọn edidi mejeeje, eleyi si jẹ ibeere ninu Ọrọ Ọlọrun): jẹ ki wọn maa lọ bi wọn ṣe wà, ki wọn ma si ṣe dẹṣẹ mọ!

Ko ri bẹẹ lati atetekọṣe. Bẹẹ ni. Ko ri bẹẹ, ko si nii ri bẹẹ ni opin! Ṣugbọn labẹ ipo ti ode oni wa, gẹgẹbi iranṣẹ Ọlọrun - n ko ni pe ara mi ni wolii Rẹ, ṣugbọn mo gbagbọ wipe ti a ko ba ran mi fun ìyẹn, mo n fi ipilẹ lelẹ fun-un nigbati o ba de - nitorinaa, labẹ ipo ti ode oni wa, mo paṣẹ fun yin wipe ki ẹ maa lọ si ile yin pẹlu iyawo yin bayi. Ti inu rẹ ba dun pẹlu rẹ, maa baa gbe, ẹ tọ awọn ọmọ yin ni ilana Ọlọrun; ṣugbọn ki Ọlọrun ṣaanu fun yin ti ẹ ba tun pada ṣe ìyẹn! Ẹ kọ awọn ọmọ yin ki wọn maṣe ṣe iru nkan bẹyẹn. Ẹ tọ́ wọn dagba ninu ilana Ọlọrun! Bayi ti ẹ ti wà bi ẹ se wà, ẹ jẹ ki a lọ bayi si... akoko wakati aṣalẹ yii ti a n gbe inu rẹ, ki a si tẹ siwaju si ami ipe giga ninu Kristi, nibi ti ohun gbogbo yoo ti ṣee ṣe.

Ka iroyin kikun ni... Ìgbéyàwó Àti Ìkọ̀sílẹ̀.


Ohun ijinlẹ Kristi.

Wẹẹbu iwe iroyin Gẹẹsi.

Iwe Ifihan jara.

 

Ọlọrun ati Imọ Atọka.
- Archaeology.

Igbasoke n bọ.

 

Awọn ẹkọ akọkọ
ti ifiranṣẹ naa.

Awọn ti o dara iroyin.
Jesu ku fun ese re.

Iribomi Omi.

 

Awọsanma eleri nla.

Ọwọn ti ina.

Ogo Shekinah ti Ọlọrun.

Ibojì ti ṣofo.
O ti jinde.

Ọlọrun salaye.

Awọn ìgbà ijọ meje.

Awọn edidi meje.

Ọlọrun ati Itan.
jara Atọka - Dáníẹ́lì.
Ìgbéyàwó Àti Ìkọ̀sílẹ̀.

Opin akoko jara.

Ngbe ọrọ jara.

Orúkọ Ọlọrun.

Ọkọ Noa.

 

Ẹṣẹ Atilẹba.
Je o ẹya apulu?

Adaparọ.
Awọn orisun - Babeli.

Ọlọrun ati Imọ.
Dainoso Adaparọ.

Archaeology.
Sodomu ati Gomorra.

  Iwe-mimọ sọ...

tí ó sì wí pé, ‘Ìdí nìyí tí ọkunrin yóo fi fi baba ati ìyá rẹ́ sílẹ̀ tí yóo fara mọ́ iyawo rẹ̀. Àwọn mejeeji yóo wá di ara kan?’

Èyí ni pé wọn kì í tún ṣe ẹni meji mọ́, bíkòṣe ọ̀kan. Nítorí náà ohun tí Ọlọrun bá ti so pọ̀, eniyan kò gbọdọ̀ yà á.

Matiu 19:5-6Ifiranṣẹ ibudo...Yan ede rẹ ki o gba awọn ifiranṣẹ ọfẹ lati ọdọ Arákùnrin Branham.


Tẹ aworan kan lati ṣe igbasilẹ aworan iwọn ni kikun tabi PDF.


Acts of the Prophet

(PDF Gẹẹsi)
 

Sirs, is this the time?

(PDF Gẹẹsi)
Òke Iwọoorun.
Nibiti awọsanma ti han.

Chapter 14
- Sabino Canyon

(PDF Gẹẹsi)

Chapter 11
- The Cloud

(PDF Gẹẹsi)

William Branham
Life Story.

(PDF Gẹẹsi)

How the Angel came
to me.

(PDF Gẹẹsi)