Ofin ibisi ti Ọlọrun.

<< išaaju

itele >>

  Ngbe ọrọ jara.

Ofin ibisi ti Ọlọrun.

Lati...  Igba Ijọ Pagamu.


William Branham.

“Eyi ni ohun ti Mo n gbiyanju lati sọ fun ọ. Ofin ibisi ni wi pe ki iru kọọkan maa bi irú irú tirẹ ni ibamu pẹlu Jẹnẹsisi 1:11, ”Ọlọrun si wi pe, Ki ilẹ ki o hu oko, eweko ti yoo maa so eso, ati igi eleso ti yoo maa so eso ni iru tirẹ, ti o ni irugbin ninu, lori ilẹ: o si ri bẹẹ.“ Ìyè-kí-yè ti o ba wà ninu iru naa yoo di irugbin yoo si tẹsiwaju lati di eso. Ofin yii kan naa ni o n ṣiṣẹ ninu Ijọ loni. Iru-ki-ru ti a fi ṣẹ̀dálẹ̀ ijọ yoo dagba yoo si dabi iru akọkọ nitori wi pe iru kan naa ni wọn. Ni igbẹyin ọjọ yii, Ijọ Aya Kristi tootọ (Iru Kristi) yoo jẹ Iṣẹ Aṣekagba-Jesu Kristi, yoo si jẹ ijọ alailẹgbe, ẹya ti ko lẹgbẹ, bi o ṣe n dabi Kristi si i. Awọn ti o jẹ Ijọ Aya Kristi naa yoo dabi Kristi to bẹẹ gẹ ti wọn yoo fi di aworan Oun Tikalararẹ gẹlẹ. Eyi yoo ṣẹlẹ ki wọn ba lee parapọ di ọkan pẹlu Rẹ. Wọn o di ọkan. Wọn o jẹ ogidi ifarahan Ọrọ Ọlọrun Alaaye naa gan an. Awọn ijọ-ti-n-fi-ẹkọkẹkọ-rọpo-Ọrọ Ọlọrun (iru eke) ko lee mu eyi jade. Wọn o maa mu ẹkọkẹkọ wọn ati ẹkọ adamọ ti a dapọ mọ Ọrọ Ọlọrun jade. Adalu yii n bi adamọdi.

Ọmọkunrin akọkọ (Adamu) jẹ irú-Ọrọ Ọlọrun ti a sọ jade. A fun un ni iyawo kan lati bí iru ara rẹ. Idi ni yii ti a fi fun un ni iyawo naa,lati bi iru ara rẹ, eyi ni lati bi ọmọ Ọlọrun miiran. Ṣugbọn iyawo naa ṣubu. O ṣubu nipa adamọdi-iru. O ṣe okunfa iku ọkọ rẹ.

Ọmọkunrin Keji (Jesu) Ti i ṣe Iru-Ọrọ Ọlọrun Ti a sọ jade, ni a fun ni iyawo kan gẹgẹ bi ti Adamu. Ṣugbọn ki O to gbe e ni iyawo oun naa ṣubu. Oun naa, bi iyawo Adamu, ni a dan wo boya yoo gba Ọrọ Ọlọrun gbọ ki o ye, tabi ki o ṣe iyemeji si Ọrọ Ọlọrun, ki o ku. O ṣe iyemeji. O fi Ọrọ Ọlọrun silẹ. O ku.

Lati inu ẹgbẹ kekere ti iru-Ọlọrun tootọ, Ọlọrun yoo fun Kristi ni Iyawo ọ̀wọ́n kan. Iyawo yii jẹ wundia si Ọrọ Ọlọrun. O jẹ wundia nitori ti ko gba ẹkọ-kẹkọ ati ẹkọ-adamọ eniyan kankan gbọ. Nipasẹ, ati ninu awọn ti o jẹ Iyawo yii ni a o ti sọ gbogbo ohun ti Ọlọrun ṣe ileri wi pe a o fi han fun araye ri ninu wundia naa di imuṣẹ.

Ọrọ ileri tọ Maria Wundia wa. Ṣugbọn Ọrọ ileri naa ni Kristi Tikalararẹ Ti a ni lati fihan. A sọ Ọlọrun di mímọ̀. Oun Funrararẹ ni O gbe igbese naa ti O si mu Ọrọ ileri Rẹ ṣẹ ninu wundia naa. Bi o tilẹ jẹ wi pe angẹli ni o mu iṣẹ naa tọ ọ wa, ṣugbọn Ọrọ Ọlọrun ni iṣẹ ti angẹli naa jẹ. Aisaya 9:6. O mu ohun gbogbo ti a kọ silẹ nipa Kristi ni akoko naa ṣẹ nitori ti Maria gba gbogbo Ọrọ naa ti a mu tọ ọ wa. Gbogbo awọn ti o jẹ ara Wundia, aya Kristi naa ni yoo ni ifẹ Rẹ, wọn yoo si ni ipá ati agbara Rẹ ti o wa ni ipamọ, nitori Oun ni Ori wọn, gbogbo agbara si jẹ Tirẹ. Wọn wa labẹ iṣakoso Rẹ gẹgẹ bi awọn ẹya ara wa ti wa labẹ iṣakoso ori wa.

Kiyesi irẹpọ Baba ati Ọmọ. Jesu ko ṣe ohunkohun ayaafi ti Baba ba kọkọ fi i han An. Johanu 5:19 Irẹpọ yii ni yoo wa nisisinyi láàárín Ọkọ-iyawo ati Iyawo Rẹ. O n fun un ni Ọrọ Iye Rẹ.Iyawo yii gba A. Ki i fi igba kan ṣiyemeji si I. Nitori naa ohunkohun ko lee pa a lara,iku paapaa ko to bẹẹ. Nitori bi a ba gbin irugbin,omi yoo sọ ọ di aaye lẹẹkan sii.Aṣiri ọrọ naa ni yii.Ọrọ Ọlọrun wa ninu Iyawo Kristi (gẹgẹ bi O ti ṣe wa ninu Maria wundia). Iyawo Kristi nì ọkàn Kristi nitori wi pe o mọn ohun ti O fẹ ki a ṣe pẹlu Ọrọ Ọlọrun.O n mu aṣẹ Ọrọ Ọlọrun ṣẹ ni Orukọ Rẹ nitori o mọn, “Bayi ni Oluwa wi.” Nigba naa ni Ẹmi n sọ Ọrọ Ọlọrun di aaye O si n wa si imuṣẹ.Gẹgẹ bi iru ti a gbin,ti a bomi rin,o n dagba de ibi ẹkunrẹrẹ ikore rẹ,ati nipa ṣiṣe bẹẹ o n mu idi ti a fi gbin in ṣẹ.

Ifẹ Rẹ nikan ni awọn ti o jẹ Iyawo Kristi n ṣe. Ko si ẹnikẹni ti o lee mu wọn ṣe lodi si Ọrọ Rẹ. Wọn ki i gbe igbeṣe kan ayaafi bi wọn ba mọn, “Bayi ni Oluwa wi” nipa rẹ. Wọn mọn wi pe o gbọdọ jẹ Ọlọrun ninu wọn ni O n ṣe awọn iṣẹ naa, ti O si n mu Ọrọ Oun Tikalararẹ ṣẹ. Ko pari gbogbo iṣẹ Rẹ ni igba ti O wa ninu iṣẹ-iriju Rẹ lori ilẹ-aye, nitori naa, nisisinyi O n ṣiṣẹ ninu, ati nipasẹ Iyawo Rẹ. Iyawo-Kristi mọn eyi, nitori akoko ko i ti i to fun Un nigba naa lati ṣe awọn nnkan kan ti O ni lati se bayi. Ṣugbọn nisisinyi Yoo ṣe awọn iṣẹ ti O fi silẹ fun igba yii ni pato, nipasẹ Iyawo Rẹ.

Wayi o, ẹ jẹ ki a duro bi i Joṣua ati Kalẹbu. Gẹgẹ bii Joṣua ati Kalẹbu, a ti n kófirí Ilẹ Ileri wa gẹgẹ bi wọn ṣe ri ti wọn. Joṣua tumọ si “Jeofa Olugbala”, o si ṣe apẹẹrẹ olori ti igba ikẹyin ti yoo wa si inu ijọ gẹgẹ bi Pọọlu ti wà bi olori ijọ akọkọ. Kalẹbu jẹ apẹẹrẹ awọn ti o jẹ olootọ si Ọrọ Ọlọrun loni gẹgẹ bi Kalẹbu ti ṣe si iwaasu Joṣua...”

Lati...  Igba Ijọ Pagamu.


  Iwe-mimọ sọ...

Dìde, tan ìmọ́lẹ̀; nítorí ìmọ́lẹ̀ rẹ ti dé, ògo OLUWA sì ti tàn sára rẹ.

Nítorí òkùnkùn yóo bo ayé mọ́lẹ̀, òkùnkùn biribiri yóo sì bo àwọn orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀, ṣugbọn ìmọ́lẹ̀ OLUWA yóo tàn sára rẹ, ògo OLUWA yóo sì hàn lára rẹ.

Aisaya 60:1-2


Tẹ aworan kan lati ṣe igbasilẹ aworan iwọn ni kikun tabi PDF.


Acts of the Prophet.

(PDFs Gẹẹsi)
 

Christ is the Mystery
of God Revealed.

(PDF Gẹẹsi)

Ṣaaju...

Lẹhin...

William Branham
Life Story.

(PDF Gẹẹsi)

How the Angel came
to me.
(PDF Gẹẹsi)


Ifiranṣẹ ibudo...Yan ede rẹ ki o gba awọn ifiranṣẹ ọfẹ lati ọdọ Arákùnrin Branham.


Ohun ijinlẹ Kristi.

Wẹẹbu iwe iroyin Gẹẹsi.

Iwe Ifihan jara.

 

Ọlọrun ati Imọ Atọka.
- Archaeology.

Igbasoke n bọ.

 

Awọn ẹkọ akọkọ
ti ifiranṣẹ naa.

Awọn ti o dara iroyin.
Jesu ku fun ese re.

Iribomi Omi.

 

Awọsanma eleri nla.

Ọwọn ti ina.

Ogo Shekinah ti Ọlọrun.

Ibojì ti ṣofo.
O ti jinde.

Ọlọrun salaye.

Awọn ìgbà ijọ meje.

Awọn edidi meje.

Ọlọrun ati Itan.
jara Atọka - Dáníẹ́lì.

Kristiẹni ije jara.
Ìgbéyàwó Àti Ìkọ̀sílẹ̀.
Akojọ Ifiranṣẹ.

Opin akoko jara.

Ngbe ọrọ jara.

Keresimesi jara.

Iku. Ohun ti nigbana?

Orúkọ Ọlọrun.

Ọkọ Noa.

 

Ẹṣẹ Atilẹba.
Je o ẹya apulu?

Adaparọ.
Awọn orisun - Babeli.

Ọlọrun ati Imọ.
Dainoso Adaparọ.

Archaeology.
Sodomu ati Gomorra.