Opin akoko jara.

  Opin akoko jara.

Àwọn Ẹni-Àmì-Òróró Ní Ìgbà Ìkẹyìn.


William Branham.

Ka iroyin kikun ni...
Àwọn Ẹni-Àmì-Òróró Ní Ìgbà Ìkẹyìn.

Matiu 24:23-24,
23 Nígbànáà bi ẹnìkan ba wi fun nyin pe, Wò ó, Krístì ḿbe níhìín, tabi lọ́hù́n; ẹ máse gbà á gbọ́.
24 Nítorí awọn èke Krístì, ati awọn èke wòlíì yoo dìde, wọn o sì fi àmì ati ohun ìyanu nlá hàn; tóbẹ́ẹ̀ bí o lè seé sé wọn o tan àwọn àyaǹfé pàápàá.

Mo fẹ́ ki ẹ se àkíyèsí ní Máttéù orí kẹrìnlélógún, Jesu lo ọ̀rọ̀ awọn Krístì - à-w-ọ-n k-r-í-s-t-ì - awọn krístì, kìí ṣe Krístì kan, ṣùgbọ́n awọn krístì, ọ̀pọ̀lọpọ̀, kii ṣe ẹyọ̀kan - awọn krístì. Nítorínáà ọ̀rọ̀ náà krístì túmọ̀ sí “ẹni- àmì-òroro.” Njẹ́ nítorínáà, ti ó bá jẹ́ ẹni-àmì-òróró, kì yoo jẹ́ ẹnì kansoso, sùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ awọn ẹni-àmìòróró, se ó yé yin. Bíbẹ́ẹ̀kọ́, ti Ó ba fẹ́ fọ́ọ sí wẹ́wẹ́ ki a lè ní òye ti ó dára síi nípa rẹ̀, Òun yóò sọ pe, “Ní àwọn ìkẹyìn ọjọ́ àwọn ẹni-àmì-òroro èke yoo dìde.” Bayi, ìyẹn dàbí wipe kò seé ṣe (wòó) ... ní àwọn ọ̀rọ̀ ti ẹni-àmì-òróró. Ṣùgbọn ẹ ṣe àkíyèsí awọn ọ̀rọ̀ ti o tẹ̀lée, “ati awọn wòlíì èke” - à-w-ọ-n w-ò-l-í-ì - púpọ̀.

Bayi, ẹni-àmì-òroro jẹ́ “ẹnìkan ti o ni isẹ́-ìfiránsẹ́ kan.” Ati pé ọ̀nà kan sọso ti a le gbà mú isẹ́-ìfiránsẹ́ naa jáde ni nípasẹ̀ ẹnìkan ti a fi òróró yàn; ìyẹn yoo si jẹ wòlii - ẹni-àmì-òróró. “Àwọn olùkọ́ni èke ti ó jẹ́ ẹni-àmìòróró yoo dide.” Wòlíì a máa kọ́ni ní ohun tí isẹ́-ìfiránsẹ́ rẹ̀ jẹ́ - àwọn olùkọ́ni ti a fi òróró yàn, ṣùgbọn awọn ènìyàn ti a fi òróró yàn pẹ̀lú ẹ̀kọ́ èké, àwọn ẹni-àmì-òróró: awọn kristi, púpọ̀; awọn wòlíì, púpọ̀. Àti pé bí irú Kristi kan bá wà, ẹyọ̀kan, nígbànáà àwọn wọ̀nyí yoo ni lati jẹ́ ẹni-àmì-òróró tí ó jẹ́ wipe àsọtẹ́lẹ̀ ti ohun tí wọ́n nkọ́ni yoo yàtọ̀, nítorí awọn ẹni-àmì-òróró ni wọ́n, tí a fi òróró yàn.

Ní bayi, ó jẹ́ ẹ̀kọ́ ilé-ẹ̀kó ọjọ́ ìsinmi, a fẹ́ gbìyànjú lati mú èyí wá sí ìsàfihàn gidi nípasẹ̀ Ìwe Mímọ́, kìí se nípa ohun ti ẹlòmíràn ti sọ nípa rẹ̀, ṣugbọn ki a sáà ka Ìwé-Mímọ́.
Ẹ lè sọ wipe, “Báwo ni èyí ṣe lè rí béè? Se àwọn ẹni-àmì-òróró.... Kini wọ́n jé?” Awọn krístì - à-w-o-n k-rí- s-t-ì, awọn krístì eni-àmì-òróró ati àwọn wòlíì èke. Awọn ẹni-àmì-òróró, ṣùgbọ́n àwọn wòlii èke. Jesu sọ pe òjò n rọ̀ sórí olódodo ati aláìsòdodo. Ni bayi, ẹnìkan lè sọ fún mi pe, “Ṣe o gbàgbọ́ pe àmìòróró lórí àwọn ènìyàn wọ̀nyẹn túmọ̀ sí pe òróró Ẹ̀mí-Mímọ́ ni?” Bẹ́ẹ̀ni, sà, ojúlówó Ẹ̀mí-Mímọ́ Ọlọ́run lórí ẹnìkan, síbẹ̀ wọ́n jẹ́ èke! Bayi, ẹ fetí sílẹ̀ dáradára kí ẹ sì wo ohun ti Ó sọ: “Wọn yoo sì fi àwọn isẹ́-àmì ati isẹ́- ìyanu hàn, tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ ti yoo tan àwọn àyànfẹ́ jẹ ti o bá seése.” A sì ta àmì-òróró sí won pèlú Ẹ̀mí-Mímọ́ tòótọ́. Mo mọ̀ pe eléyi dabi ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ púpọ̀, sugbọn a ó gba àkókò lati sàlàyé rẹ̀ nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ naa pe ìyẹn jẹ́ “bayi ni Olúwa wí,” nítòótọ́.

-----
Matiu 5:45,
Kí ẹ̀yin kí o lè máa jẹ́ ọmọ Baba nyín tí ḿbẹ ní ọ̀run: nítorí Ó nmú òòrùn Rẹ ràn sára ènìyàn búburú ati... ènìyàn rere, o si nrọ̀jò sórí olódodo ati... áláìsòdodo.
(Òjò nrọ̀ sórí ẹni búburú ati ẹni rere.)

Heberu 6:7-8,
7 Nítorí ilẹ̀ (Ẹ gbọ!)... nmu nínú òjò ti ó rọ̀ sórí rẹ̀ lati ìgbà dé ìgbà, lati mú ewébẹ̀ wá fun awọn ti ó ntọ́jú rẹ̀, n gba àwọn ìbùkún lati ọ̀dọ̀ Ọlọ́run:
8 Sùgbọ́n èyítí ó n hu ẹ̀gún... òsùsú ni a kọ̀, o sì súnmọ́ ẹ̀gún; opin ẹnití yóò jẹ́ ìfijóná.

-----
Bayi, ẹ se àfiwé ìyẹn pẹ̀lú Matteu orí karùn-ún, ẹsẹ kẹrìnlélógún lẹ́ẹ̀kansíi. Kiyesii, Jesu sọ pe òjò ǹrọ̀, òòrùn sì n ràn sórí ilẹ̀, pe Ọlọ́run fi ránṣẹ́ lati sètò oúnjẹ ati awọn nkan mìíràn fun awọn ènìyàn ayé. A sì fi òjò ránsé fun oúnjẹ, àwọn ewébẹ̀. Ṣùgbọ́n awọn èpò - koríko - ti wọn wà ninu pápá, ngba ohun kannáà. Òjò kannáà ti o n mú kí àlìkámà dàgbà ni òjò kannáà ti o n mú kí àwọn èpò dàgbà.

-----
Nítorínáà, òjò ti n rọ̀ sórí koríko ilẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ òjò ti Ẹ̀mí ti ó n fún ni ní ìyè àìnípẹ̀kun, ti o n sọ̀kalẹ̀ só́rí ìjo; nítorí a n pèé ni òjò àkọ́rọ̀ ati òjò àrọ̀kúrọ̀. Òjò sì ni, tí o n tú Ẹ̀mí Ọlọ́run jáde sórí Ìjọ Rẹ̀.

Kíyèsíi, ohun àjèjì níhin. Nígbàtí awọn irúgbìn wọnnì wọ inú ilẹ̀, ọ̀nà yóowù ti wọn gbà dé ibẹ̀, wọn jẹ́ ẹ̀gún lati ìbẹ̀rẹ̀ wá. Sùgbọ́n àlìkámà ti o wọ inú ilẹ̀.... Awọn ewébẹ̀ jẹ́ ewébẹ̀ lati ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú. Ewébẹ̀ kọ̀ọ̀kan ti o n bí irú ara rẹ̀ léèkansíi sàfihàn wipe o jẹ́ ojúlówó lati ìbèrè wá.

“Ati pe wọn yóò tan awọn àyànfẹ́ jẹ ti o ba seeṣe,” nítorí wọn n gba òjò kannáà, ìbùkún kannáà, wọ́n n fi àwọn àmì kannáà hàn, awọn isẹ́-ìyanu kannaa. “Wọn yoo tàn jẹ, tabi wọn yoo tan àwọn àyànfẹ́ jẹ ti o ba seéṣe.” Bayi, ẹ̀gún kò lè ṣe aláìse ẹ̀gún, bẹ́ẹ̀ni àlìkáma kò lè se ki ó má jẹ́ àlìkáma; ó jẹ́ ohun ti Ẹlẹ́dàá ọ̀kọ̀ọ̀kan ti pinnu rẹ̀ lati ìbẹ̀rẹ̀. Ìyàntẹ́lẹ̀ nìyẹn.
Òjò kannáà....

-----
Bayi, òòrùn n tàn o sì n mú kí ọkà pọn. Bayi, kò lè mú gbogbo rẹ̀ pọn lẹ́ẹ̀kannáà. Bí o se ntẹ̀síwáju lati gbo síi, o npọ́n léraléra títí ti yoo fi gbó pátápátá. Bẹ́ẹ̀ lo ri pẹlu ìjọ lónìí. Ó bẹ̀rẹ̀ ni kékeré ni ìgbà òkùnkùn biribiri níbi tí o ti wà labẹ ilẹ̀. O ti wá dàgbà, o ti gbó. A sì leè rii dáradára, gégébí Ọlọ́run nípasẹ̀ ìsẹ̀dá nígbàgbogbo....

Ẹ ko lè dí ìsẹ̀dá lọ́wọ́. Ohun ti o n sẹlẹ̀ loni nìyẹn. A n gbé àwọn àdó-ikú fò jáde sinu òkun, a n fọ́ọ si wẹ́wẹ́, a si n fọ́n-ọn ká pelu àdó-ikú. Ẹ kàn n fọ́ ilẹ̀ yẹn kúrò ni nígbàgbogbo, bi ẹ se n jùú sinu rẹ̀. Bi ẹ bá gé awon igi lulẹ̀, ìjì afẹ́fẹ́ yoo kọlù yín. Bi ẹ bá sọ omi ti n sàn di adágún, yóò ya. Ẹ níláti wá ọ̀nà ti Ọlọ́run n gbà se nǹkan kí ẹ sì dúró ninu rẹ̀. A ti sọ àwọn ènìyàn di ẹlẹ́yà-mẹ̀yà ninu awọn ìjọ ati àkójọpọ̀; ẹ wá wo ohun ti a ní! Ẹ duró ni ọ̀nà ti Ọlọ́run ti pèsè sílẹ̀.

Ṣugbọn ẹ woo, Ó fi òjò ránsẹ́ (kí á padà si kókó-ọ̀rọ̀ wa) sórí olódodo ati aláisododo. Jesu sọ fún ọ níbí ni Máttéù ori kerìnlélógún wipe yoo jẹ́ àmì ni ìgbà ìkẹyìn. Bayi, ti ó bá jẹ́ pe ìgbà ìkẹyìn ni á o mọ àmì yii, nígbànaa yoo jẹ́ lẹ́yìn ti a bá ti sí awọn edídí wọnnì tán. O jẹ́ àmì òpin. Ìyẹn yoo jẹ́, nígbàti awọn nkan wọnyi bá nṣẹlẹ̀ yoo jẹ́ ìgbà ìkẹyìn. Yoo si jẹ́ àmì kan, ni bayi, ki awọn àyànfé ma baà ni ìpòrúùru ninu àwọn nnkan wọ̀nyì. Se ẹ rii? Nítorínáà, a gbọ́dọ̀ fii hàn, ki à síi payà.

Kiyesi. Àwọn àlìkáma ati àwọn èpò ngbé nípasẹ̀ àmì-òróró kannáà lati ọ̀run wá. Awọn mèjèèjì nyọ̀ lori rẹ̀. Mo rántí èyí, nígbàtí mo ntọ́ka si àpẹẹrẹ yii níbẹ̀ ni ọjọ́ yẹn ní Ilé-èrò ti Green. Mo rì ìran yii bí o se si, ilé-ayé nlá kan wà, a sì ti kọ ọ́ ni ebè. Afúrúgbìn kan si kọ́kọ́ saájú lọ. Mo fẹ́ fi ìyẹn si iwájú yin. Ẹ wo èyí tí o kọ́kọ́ lọ, léyìnnáà ohun ti o tẹ̀lé e. Bi ọkùnrin alásọ funfun yii se wá sínú ayé ti o sì nfúrúgbìn… Lẹ́yìn Rẹ̀ ni ọkùnrin kan wá, pẹ̀lú aṣọ dúdú, o jé alárékérekè, o nyọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lẹ́yìn Rẹ̀ ó sì n gbin èpò. Bi eléyìí se nsẹlẹ̀… nígbànáà mo rí ọ̀gbìn méjèèjì hù jáde. Bi wọ́n se hù jáde, ọ̀kan jẹ́ àlìkámà, èkejì sì jẹ́ èpò. Ìyàn kan sì mú, pé nígbàtí… ó dàbí ẹni pe àwọn méjèèjì sọrí kọ́, wọn npè fún òjò. Lẹ́yìnnáà ní ìkúùku òjò nlá bo ilẹ̀, òjò si rọ̀. Àlìkáma gbé orí sókè ó wipe, “Ẹ yin Olúwa! Ẹ yin Olúwa!” Awọn èpò naa gbé orí sókè wọn sì kígbe, “Ẹ yin Olúwa! Ẹ yin Olúwa!” Àbájáde kannáà, awọn méjèèjì nsègbé, awọn méjèejì nlọ. Lẹ́yìnnáà òrùngbẹ n gbẹ àlìkámà. Àti nítorí pe ó wà ni inu oko kannáà, inu ọgbà kannáà, ibi kannáà, lábẹ́ ọ̀wàrà-òjò kannaà, àlìkámà ati èpò hù jáde nípasè ohun kannaà.
Kiyesii. Omi àmì-òróró kannaa ti ó mú àlìkámà jáde, òun naa ni o mú èpò jáde.

Ẹ̀mí Mímọ́ kannaà ti o ta àmì-òróró si ìjọ, ti ó fun wọn ni ìfẹ́ lati gba àwọn ọkàn là, ti ó fun wọn ni agbára lati se awọn isẹ́ ìyanu, o bà lé orí awọn aláìsòdodo bi ó se se si awọn olódodo - Ẹ̀mí kannaà. Bayi, ẹ kò lè seé ni ọ̀nà miiràn ki ẹ sì lóye Matteu ori kẹrìnlélógún, ẹsẹ kerìnlélógún. Ó sọ pé, “Awọn èké Kristi yoo dìde,” awọn ẹni-àmì-òróró èké, ti a fi ojúlówó àmì-òróró yàn, sugbọn wọn jẹ́ awọn wóliì èke, èke olùkọ́ rẹ̀. Kini ó lè mú kí ẹnìkan fẹ́ lati jẹ́ olùkọ èké ohun ti o jẹ́ òtítọ́? Bayi, a ó lọ sórí àmì ti ẹranko naà ní ìsẹ́jú díẹ̀, ẹ o si ri ìjọ ẹ̀yàmẹ̀yà rẹ̀. Awọn olùkọ́ni èké, awọn eni-àmì-òróró èké, awọn kristi tí a ta àmì-òróró sí, sugbọn ti wọn jẹ́ olùkọ́ni èké. Ọ̀nà kan ti a lè gba rii nìyẹn.

-----
Kiyesii. Ṣugbọn ohun ti wọn so jade ni o nsọ iyatọ fun ọ. “Nipa eso wọn,” Jesu sọ pe, “ẹyin yoo mọ̀ wọ́n.” A ko lee ka eso ajara lara ẹ̀gún bi o tilẹ wa ninu igi ajara. Iyẹn le ṣee ṣe, ṣugbọn eso ni yoo fi I han. Kini eso naa? Ọ̀rọ̀ naa fun... eso fun àkókò naa; ohun ti o jẹ niyẹn: ẹ̀kọ́ wọn. Ẹ̀kọ́ ti kini? Ẹ̀kọ́ ti àkókò, àkókò ti o jẹ́: ẹ̀kọ́ eniyan, ẹ̀kọ́ àdámọ̀, tabi Ọrọ Ọlọrun fun àkókò naa.
Bayi, àkókò nsare lo tobeẹ.... A le duro lori iyen fun ìgbà pipẹ, ṣugbọn mo ni idaniloju pe ẹ̀yin ti ẹ wà nibi, ati ẹ̀yin ti ẹ wa káàkiri orile-ede, ẹ lee ri ohun ti mo ngbiyanju lati sọ fun yin, nitori a ko ni akoko pupọ lati duro lori rẹ̀.

Ṣugbọn ẹ lè rii pe ami-ororo naa wa lori awọn alaiṣododo, awọn olukọ èké, o si n mu ki wọn ṣe ohun ti Ọlọrun sọ fun wọn pe ki wọn má ṣe gan-an; ṣugbọn wọn ó ṣe bakannaa. Kini idi? Wọn ko le saláì se bẹẹ! Bawo ni ẹ̀gún se le jẹ ohun miiran yàtọ̀ si ẹ̀gún? Bi o ti wu ki òjò rọ sii to, o nilati jẹ ẹ̀gún. Idi niyen ti Jesu fi sọ pe wọn yoo sunmọ tobẹẹ gẹe ti wọn yoo tan awọn ayanfẹ jẹ (ti o wa ninu awọn gbòngbò), ti o ba ṣeeṣe. Ṣugbọn ko ṣee ṣe. Alikama ko le ṣe ki o ma so eso alikama; gbogbo ohun ti o lee so niyẹn.

Ka iroyin kikun ni...
Àwọn Ẹni-Àmì-Òróró Ní Ìgbà Ìkẹyìn.


Ohun ijinlẹ Kristi.

Wẹẹbu iwe iroyin Gẹẹsi.

Iwe Ifihan jara.

 

Ọlọrun ati Imọ Atọka.
- Archaeology.

Igbasoke n bọ.

 

Awọn ẹkọ akọkọ
ti ifiranṣẹ naa.

Awọn ti o dara iroyin.
Jesu ku fun ese re.

Iribomi Omi.

 

Awọsanma eleri nla.

Ọwọn ti ina.

Ogo Shekinah ti Ọlọrun.

Ibojì ti ṣofo.
O ti jinde.

Ọlọrun salaye.

Awọn ìgbà ijọ meje.

Awọn edidi meje.

Ọlọrun ati Itan.
jara Atọka - Dáníẹ́lì.

Kristiẹni ije jara.
Ìgbéyàwó Àti Ìkọ̀sílẹ̀.
Akojọ Ifiranṣẹ.

Opin akoko jara.

Ngbe ọrọ jara.

Keresimesi jara.

Iku. Ohun ti nigbana?

Orúkọ Ọlọrun.

Ọkọ Noa.

 

Ẹṣẹ Atilẹba.
Je o ẹya apulu?

Adaparọ.
Awọn orisun - Babeli.

Ọlọrun ati Imọ.
Dainoso Adaparọ.

Archaeology.
Sodomu ati Gomorra.

  Iwe-mimọ sọ...

Angẹli keje fun kàkàkí rẹ̀, àwọn ohùn líle kan ní ọ̀run bá sọ pé, “Ìjọba ayé di ti Oluwa wa, ati ti Kristi rẹ̀. Yóo jọba lae ati laelae.”

Ìfihàn 11:15


Tẹ aworan kan lati ṣe igbasilẹ aworan iwọn ni kikun tabi PDF.


Acts of the Prophet.

(PDFs Gẹẹsi)

Àwọn Ẹni-Àmì-Òróró
Ní Ìgbà Ìkẹyìn.
(PDF)

William Branham
Life Story.

(PDF Gẹẹsi)

How the Angel came
to me.

(PDF Gẹẹsi)


Ifiranṣẹ ibudo...Yan ede rẹ ki o gba awọn ifiranṣẹ ọfẹ lati ọdọ Arákùnrin Branham.