Iwe Ifihan.


  Iwe Ifihan jara.

Iṣipaya Johanu Mimọ.


William Branham.

Ka iroyin kikun ni...
Ifihan ti Jesu Kristi.

Iwe Ifihan 1:1-3,
1 Ifihan ti Jesu Kristi, ti Ọlọrun fifun Un, lati fihan fun awọn iranṣẹ Rẹ ohun ti ko lee ṣai ṣẹ ni lọọlọ; O si ranṣẹ, O si fi I han lati ọwọ angẹli Rẹ wa fun Johanu, iranṣẹ Rẹ.
2 Ẹni ti o jẹri Ọrọ Ọlọrun, ati ẹri Jesu Kristi, ati ti ohun gbogbo ti o ri.
3 Olubukun ni ẹni ti n ka; ati awọn ti o n gbọ Ọrọ Isọtẹlẹ yii, ti o si n pa nnkan wọnni ti a kọ sinu Rẹ mọ; nitori igba ku si dẹdẹ.

Akọwe (ki i ṣe onkọwe) ti o kọ Iwe yii ni Johanu Mimọ. Awọn onpitan fi ohun ṣọkan wi pe o gbe ipa ti o gbẹyin ni igbesi aye rẹ ni Efesu, bi o tilẹ jẹ wi pe ni erekuṣu Patimọsi ni o wa nigba ti o kọ Iwe yii. Eyi ki I ṣe itan igbesi aye Johanu, ṣugbọn Ifihan Jesu Kristi ninu awọn igba ijọ ti n bọ wa ni. Ni ẹsẹ kẹta a pe Iwe naa ni asọtẹlẹ, ohun ti o si jẹ gẹlẹ ni yii.

A maa n saaba pe Iwe yii ni Iṣipaya Johanu Mimọ, ṣugbọn eyi ko ri bẹẹ. Ohun ti o jẹ ni Iṣipaya Jesu Kristi ti a fi le Johanu lọwọ lati fifun awọn Kristẹni gbogbo iran. Òhun ni Iwe kanṣoṣo ninu gbogbo Bibeli ti Jesu FUNRARARẸ kọ nipa fifi ara Rẹ han fun akọwe kan.

O jẹ Iwe ti o gbẹyin ninu Bibeli, sibẹsibẹ O sọ ibẹrẹ ati opin awọn sáà Ihinrere.

Ọrọ ti o duro fun ifihan ni ede Gririki ni,“apocalypse”, ti o tumọ si, “Ṣiṣi aṣọ ikele kuro.” Ṣiṣi aṣọ ikele kuro yii ni a ṣalaye ni pipe perepere ninu apẹẹrẹ agbẹgilere ti o n ṣi aṣọ kuro lori ere yíyá rẹ, ti o n fi i han olùwòran. Mimu iboju kuro, ani iṣipaya ohun ti o farasin tẹlẹ ri ni. Wayi o, ṣiṣi aṣọ ikele yii ki i ṣe iṣipaya Ẹni Ti Kristi n ṣe nikan ṣugbọn o jẹ IFIHAN IṢẸ RẸ NI ỌJỌ IWAJU NINU AWỌN IGBA IJỌ MEJE TI N BỌ WA. Pataki iṣipaya lati ọwọ Ẹmi Mimọ si onigbagbọ otitọ jẹ ohun ti a ko lee tenumọ ju. Iṣipaya ṣe pataki si ọ ju bi o ti mọ lọ. Ki i ṣe Iwe Ifihan yii ni mo n sọrọ nipa rẹ ni pàtó, bikoṣe nipagbogbo Iṣipaya Ọrọ Ọlọrun. O ṣe pataki jọjọ si Ijọ.

Njẹ o ranti ninu Iwe Matiu 16 nigba ti Jesu beere ibeere yii lọwọ awọn ọmọ ẹyin Rẹ wi pe,
“Tani awọn eniyan n fi Emi Ọmọ-Ẹniyan pe? Wọn si wi fun Un pe, Omiran ni, Johanu Baptisti; omiran wi pe, Elija; awọn ẹlomiran ni, Jeremaya, tabi ọkan ninu awọn wolii. O bi wọn leere, wi pe,Ṣugbọn tani ẹyin n fi Mi pe? Simon Peteru dahun, wi pe, Iwọ ni Kristi naa, Ọmọ Ọlọrun Alaaye ni Iwọ I ṣe. Jesu si dahun O wi fun un pe, Alabukun fun ni iwọ Simoni Ọmọ-jona; ki i ṣe ẹran-ara, ati ẹjẹ ni o ṣaa fi eyi han ọ, ṣugbọn Baba Mi Ti n bẹ ni Ọrun. Emi si wi fun ọ pẹlu pe, Iwọ ni Peteru, lori apata yii ni Emi o kọ ijọ Mi le; ẹnu-ọna ipo-oku ki yoo si lee bori rẹ“.

Awọn ọmọ ijọ aguda sọ wi pe lori Peteru ni a kọ Ijọ le. Eyi jẹ ironu eniyan ti ko ni Ẹmi Ọlọrun. Bawo ni Ọlọrun yoo ṣe kọ Ijọ lori ọkunrin kan ti ko-lẹ́sẹ̀-n-lẹ to bẹẹ gẹgẹ ti o sẹ́ Jesu Oluwa, ti o si n ṣepe bi o ti n ṣe bẹẹ? Ọlọrun ko lee kọ ijọ Rẹ le ori ẹnikẹni ti a bi ninu ẹṣẹ. Ki i si ṣe wi pe okuta kan wa ni ilẹ nibẹ bi ẹni wi pe Ọlọrun ti ya ilẹ ti wọn ti n sọrọ naa si mimọ. Ko si ri bi awọn Alatako-ijọ-Aguda ṣe n sọ wi pe a kọ ijọ lori Jesu. IṢIPAYA Ẹni Ti O jẹ ni a kọ ọ le. Ka A bi a ti kọ Ọ, “Ẹran ara ati ẹjẹ kọ ni o FI I HAN Ọ. ṢUGBỌN BABA MI NI O FI I HAN ati LORI APATA YII (IṢIPAYA) NI EMI YOO KỌ IJỌ MI LE”. A kọ ijọ lori iṣipaya, ani lori, “Bayi ni Oluwa wi.”

Bawo ni Abẹli ṣe mọ ohun ti o yẹ ki o ṣe lati rú ẹbọ ti o tọ si Ọlọrun? Nipa igbagbọ o gba iṣipaya ẹjẹ naa. Kaini ko ri iru iṣipaya bẹẹ gba (bi o tilẹ jẹ wi pe o mọ ofin) nitori naa ko lee rú ẹbọ ti o tọ́. Iṣipaya lati ọdọ Ọlọrun ni iyatọ láàárín wọn, oun kan naa ni o si fun Abẹli ni lye Ainipẹkun. Wayi o, o lee gba ohun ti oluṣọ-agutan wi tabi ohun ti ile-ẹkọ Bibeli wi, bi o tilẹ jẹ wi pe a lee kọ ọ lati ọwọ ẹni ti o ni ẹbun ọrọ sisọ, titi di igba ti Ọlọrun yoo fi han ọ wi pe Jesu ni Kristi ati wi pe Ẹjẹ naa ni O n wẹ ọ mọ, ati wi pe Ọlọrun ni Olugbala rẹ, o ko lee ni Iye Ainipẹkun. Iṣipaya ti Ẹmi Mimọ ni o n ṣe iṣẹ yii.

Wo o, mo sọ wi pe Iwe lfihan jẹ Iṣipaya Jesu ati ohun ti O n ṣe ninu awọn ijọ fun awọn igba ijọ mejeeje. O jẹ iṣipaya Ọrọ Ọlọrun nitori awọn ọmọ ẹyin paapaa ko mọ awọn Otitọ ti a kọ silẹ wọnyi. A ko ṣí awọn Ọtitọ wọnyi payá ṣaaju akoko yii. Ṣe o ranti wi pe ninu Iwe Iṣe Awọn Apọsteli wọn tọ Jesu wa, wọn si beere lọwọ Rẹ wi pe, “Njẹ nisisinyi ni Iwọ yoo da ijọba pada fun Israẹli bi?” O si dahun wi pe, “Ki i ṣe fun yin lati mọ igba tabi akoko.” Awọn eniyan wọnyi ṣi n ro wi pe Jesu yoo ni ijọba aye kan, ṣugbọn ijọba Ẹmi ni Jesu yoo gbe kalẹ. Ni gba naa lọhun Oun paapaa ko lee sọ ipa ti Oun yoo ko ninu rẹ nitori Baba ko i ti fi I han An. Ṣugbọn nisisinyi lẹyin iku ati ajinde Rẹ, paapaa ni asiko yii ninu iṣẹ agbawi Rẹ, O wa lee sọ ọ di mímọ̀ ninu Iṣipaya Ara Rẹ fun Johanu ohun ti Ogo Rẹ ati Ifarahan-isọkalẹ Rẹ si inu Ijọ yoo jẹ, ti yoo si ṣe.

Ninu iṣipaya yii O n sọ fun wa ohun ti opin eṣu yoo jẹ, O n sọ bi Oun yoo ṣe fi ìyà jẹ eṣu ati bi Oun yoo ṣe ju u si inu adagun ina. O n fi opin awọn ẹni buburuti n tẹlẹ Satani han. Eṣu si korira eleyi.

Njẹ o ti fi igba kan ri kiyesi bi eṣu ṣe korira meji ninu awọn iwe Bibeli ju awọn iyoku lọ? Ni gbogbo igba ni eṣu n gbogun ti Iwe Jẹnẹsisi ati Iwe Ifihan nipasẹ awọn ẹlẹkọ-ijinlẹ-ẹsin ti igbalode ati awọn eke onimọ-ijinlẹ sayẹnsi. Ninu awọn Iwe mejeeji wọnyi ni a ti ri ipilẹṣẹ eṣu, awọn ọna buburu rẹ ati iparun rẹ. Idi ni yii ti eṣu fi n gbogun ti awọn Iwe mejeeji wọnyi. Eṣu ko fẹ ki a tu aṣiri oun, ṣugbọn ninu awọn iwe mejeeji wọnyi, a fi ohun ti o jẹ gẹlẹ han. Jesu sọ nipa Satani wi pe, “ko ni ipa-kí-pa ninu Mi, bẹẹni Emi ko si ni ipa-ki-pa ninu rẹ”. Bi o tilẹ jẹ wi pe eṣu fẹ sọ gbolohun yii di irọ, ko lee ṣe bẹẹ. Nitori naa o n sa gbogbo ipa ti o lee sa lati pa igbẹkẹle ninu Ọrọ Ọlọrun run. Ṣugbọn nigba ti ijọ ba kọ̀ lati gba eṣu gbọ, ti o si gba iṣipaya Ọrọ Ọlọrun lati ọwọ Ẹmi Mimọ gbọ, ogun ọrun-apaadi ko lee bori rẹ.

Ti o ba gba mi laaye, mo fẹ sọ ọrọ kan nihin lati inu iṣẹ-iriju-iwaasu mi. Gbogbo yin ni ẹ mọ wi pe ẹbun ti n bẹ ninu mi yii ga ju ti agbara ẹda lọ. O jẹ ẹbun nipasẹ eyi ti Ẹmi Mimọ n mọ awọn aisan ati awọn ero ọkan eniyan, ati awọn ohun ikọkọ ti o jẹ wi pe Ọlọrun nikan ni O lee mọ ọn, ti yoo si ṣi wọn paya fun mi. Ìbá wu mi ki o lee duro ti mi, ki o si ri oju awọn eniyan naa nigba ti eṣu ba mọ wi pe a fẹ tu aṣiri oun. Bayi o, a ko sọrọ nipa eniyan naa. Ohun ti n ṣẹlẹ ni wi pe eṣu ti fi ẹsẹ mulẹ ninu igbesi-aye wọn nipa ẹṣẹ, aibikita ati aisan. Ṣugbọn i ba dara ki o ri oju wọn. Eṣu mọ wi pe a fẹ tu aṣiri oun, nitori naa awọn iyipada ti o yatọ patapata yoo wa han loju awọn eniyan naa. Ẹru n ba Satani ni. O mọ wi pe Ọlọrun ṣetan lati jẹ ki awọn eniyan naa mọ iṣẹ ọwọ oun. Idi ni yii ti o fi korira irufẹ awọn ipade bawọnyi gidigidi. Nigba ti a ba pe orukọ awọn eniyan, ti a si sọ aisan ti n ṣe wọn, Satani a maa korira rẹ. Ṣugbọn kin ni ohun ti n ṣẹlẹ? Ki i ṣe afọṣẹ eniyan lasan, kii ṣe ifi-agbara-eṣu mọ ero-ọkan-eniyan ti o wa lokerere, ki i si i ṣe oṣo. IṢIPAYA lati ọwọ Ẹmi Mimọ ni. Ọna kan ṣoṣo yii ni mo fi lee mọ awọn nnkan wọnyi. Nitootọ, eniyan lasan ti ko ni Ẹmi Ọlọrun yoo pe e ni ohun gbogbo ti o yatọ si Ẹmi Mimọ.

Jẹ ki n fi idi miiran ti eṣu fi korira Iwe Ifihan Jesu Kristi láàárín Ijọ yii han ọ. Idi naa ni wi pe eṣu mọ wi pe Jesu jẹ ọkan naa lana, loni ati titi ayeraye, ati wi pe Ki I yipada. Eṣu mọ eleyi ju idamẹsan ninu mẹwa awọn ẹlẹkọ-ijinlẹ-awọn-ẹsin-aye lasan lọ. O mọ wi pe ni iwọn igba ti Ọlọrun ko lee yipada ninu Iwa-ẹda Rẹ, bẹẹ gẹgẹ ni ko lee yipada ninu awọn ọna Rẹ. Nitori eyi, eṣu mọ dajudaju wi pe Ijọ akọkọ, ti ọjọ Pẹntikọsti, ti o ni agbara Ọlọrun (ti n fi Maaku 16 han ni arigbamu) ni Ijọ Otitọ ti Jesu pe ni Ijọ TIRẸ. Gbogbo awọn iyoku lẹyin eleyi jẹ eke. Wọn ni lati jẹ bẹẹ.

Nisisinyi ranti eleyi. Kristi ninu Ijo Otitọ jẹ itẹsiwaju Iwe Iṣe Awọn Apọsteli. Ṣugbọn Iwe Ifihan fi i han bi ẹmi aṣodi-si-Kristi yoo ṣe wọ inu ijọ, ti yoo si ṣọ ọ di alaimọ, nipa sísọ ijọ di ko-gbona-ko-tutu, alasa lasan, ati alai-lagbara. O tu aṣiri eṣu, o n fi awọn iṣẹ rẹ han (ilepa lati pa awọn eniyan Ọlọrun run) ati lati sọ Ọrọ Ọlọrun di otubantẹ) titi di igba ti a o fi ju u si inu adagun ina. O n gbogun ti eyi. Ara rẹ ko gba a. O mọ wi pe bi awọn eniyan naa ba ni IFIHAN OTITỌ ti IJỌ OTITỌ ati ohun ti o jẹ, awọn Otitọ ti o gbagbọ ati wi pe o LEE ṢE AWỌN IṢE TI O PỌ SII NAA, yoo jẹ ọmọ ogun ti-a-ko-lee-ṣẹgun. Ti awọn eniyan ba ni iṣipaya Otitọ nipa awọn ẹmi mejeeji ti n ṣiṣẹ láàárín ijọ onigbagbọ, ti wọn ba fi Ẹmi Ọlọrun da ẹmi aṣodisi- Kristi-mọ, ti wọn si fi agbara Rẹ kọju ija si i, eṣu yoo jẹ alailagbara niwaju wọn. A o ṣẹgun eṣu dajudaju loni gẹgẹ bi a ti ṣẹgun rẹ nigba ti Kristi bori gbogbo ilepa rẹ lati gba agbara lori Oun ninu aginju. Bẹẹ ni, eṣu korira iṣipaya Ọrọ Ọlọrun. Ṣugbọn awa fẹran rẹ. Pẹlu iṣipaya Otitọ ni igbesi aye wa, awọn ogun ọrunapaadi ko lee bori wa, awa ni yoo bori wọn.

Iwọ yoo ranti wi pe mo ti sọ ṣaaju ni ibẹrẹ iwaasu yii wi pe, Iwe ti a n kẹkọ ninu rẹ yii jẹ iṣipaya Jesu, Funrarare, gan an ninu ijọ ati iṣẹ Rẹ ni awọn igba ti yoo hu wa lẹyin ọla. Bẹẹ naa ni mo tun sọ wi pe bi Ẹmi Mimọ ko ba fun ni ni iṣipaya a ko lee ri iṣipaya. Bi a ba mu awọn ero mejeeji wọnyi papọ a o ri i wi pe ki i ṣe kikẹkọ lasan ati ṣiṣe aṣaro ni yoo lee sọ Iwe Ifihan yii di okodoro. Agbara Ẹmi Mimọ ni o gba lati ṣe eyi. Eyi tumọ si wi pe a ko lee ṣi Iwe yii paya fun ẹnikẹni lasan bikoṣe ẹgbẹ awọn akanda eniyan kan. Ẹnikan ti o jẹ wolii ariran ni yoo lee ṣe eyi. Yoo gba ẹbun lati lee gbọ Ohun Ọlọrun. Yoo gba ikọni ti o ga ju ti eniyan lọ, ki i ṣe wi pe ki akẹkọ kan lasan maa fi ẹsẹ Bibeli kan wé omiran, bi o tilẹ jẹ wi pe eyi dara. Ayaafi bi Ẹmi Mimọ ba fi ijinlẹ Ọrọ Ọlọrun kọni Ko lee ye ni laelae. Bawo ni o ṣe ṣe pataki fun wa to lati gbọ Ohun Ọlọrun ati lati ṣí ọkan wa paya silẹ, ki a si wá jọwọ ara wa silẹ fun Ẹmi Mimọ lati gbọ ati lati ni imọ.

Gẹgẹ bi mo ti ṣe sọ ṣaaju, Iwe yii (Ifihan) ni o pari Iwe Mimọ. Ibi ti o yẹ Ẹ gẹlẹ ninu Iwe Mimọ ni a fi I si; ni ipari. Wayi o, o wa lee ri idi naa ti O fi sọ wi pe, ẹnikẹni ti o ba ka A tabi ti o gbọ Ọ paapaa jẹ alabukun. Iṣipaya Ọlọrun ni yoo fun ọ ni aṣẹ lori eṣu. O wa lee ri idi rẹ ti o fi jẹ wi pe ẹni ti o ba ṣe afikun tabi ayọkuro ninu Ọrọ Ọlọrun yoo di ẹni ifibu. Yoo ri bẹẹ, nitori wi pe tani lee fi kun tabi ki o yọ kuro ninu iṣipaya pipe ti Ọlọrun ki o si lee ṣẹgun ọta. Bi o ti ṣe rọrun to ni yii. Ko si ohunkohun ti o ni agbara ti n ṣẹgun bi iṣipaya Ọrọ Ọlọrun. Wo o, ninu ẹsẹ kẹta, a paṣẹ ibukun si ori ẹnikẹni ti o ba gbọ Ọrọ Iwe yii. Mo ro wi pe eyi n tọka si aṣa Majẹmu Laelae ninu eyi ti awọn alufaa maa n ka Ọrọ Ọlọrun ni owurọ si etigbọ awọn eniyan. Ṣe o ri i, ọpọlọpọ awọn eniyan naa ni ko lee kawe, nitori naa, alufaa ni lati ka Ọrọ Ọlọrun si etigbọ wọn. Niwọn igba ti o jẹ Ọro Ọlọrun, ibukun Ọlọrun wa lori Rẹ. Ko ṣe pataki boya a ka Ọrọ naa ni,tabi boya a gbọ Ọ.

“Akoko ku si dẹdẹ”. Ki o tó tó igba yii akoko kò i ti ku si dedẹ.Ninu ọgbọn ati ijọba Ọlọrun, Ifihan nla yii (bi o tilẹ jẹ wi pe Ọlọrun mọ Ọn ni ẹkunrẹrẹ) ko lee di mímọ̀ ṣaaju igba yii. Bayi, ni oju ẹsẹ, a kọ ilana kan -iṣipaya Ọlọrun fun igba kọọkan yoo wa ni igba ijọ naa nikan ati ni asiko kan pato. Wo itan orilẹ-ede Israẹli. Iṣipaya ti Ọlọrun fifun Moṣe wa ni igba kan pato ni asiko igbe-aye awọn ọmọ Israẹli, ati paapaa, o wa nigba ti awọn eniyan naa sọkun ni ohun rara si Ọlọrun. Jesu, Tikalararẹ, wa ni ẹkunrẹrẹ igba, ni iwọn igba ti Oun paapaa jẹ ẹkunrẹrẹ Ifihan Ọlọrun Kanṣoṣo. Ati ninu igba ijọ yii (Laodekia) Iṣipaya Ọlọrun yoo wa ni akoko Tirẹ ti o wọ. Ko ni pẹ́ de,bẹẹ si ni ko ni de ṣaaju igba Tirẹ. Ṣe aṣaro lori eleyi ki o si ṣe igbọran si i de oju ami, nitori a wa ni opin igba loni.

Ka iroyin kikun ni...
Ifihan ti Jesu Kristi.



Iwe Ifihan jara.
Tẹsiwaju lori oju-iwe atẹle.
(Awọn Ọlọhun, Jesu Kristi.)


Ohun ijinlẹ Kristi.

Wẹẹbu iwe iroyin Gẹẹsi.

Iwe Ifihan jara.

 

Ọlọrun ati Imọ Atọka.
- Archaeology.

Igbasoke n bọ.

 

Awọn ẹkọ akọkọ
ti ifiranṣẹ naa.

Awọn ti o dara iroyin.
Jesu ku fun ese re.

Iribomi Omi.

 

Awọsanma eleri nla.

Ọwọn ti ina.

Ogo Shekinah ti Ọlọrun.

Ibojì ti ṣofo.
O ti jinde.

Ọlọrun salaye.

Awọn ìgbà ijọ meje.

Awọn edidi meje.

Ọlọrun ati Itan.
jara Atọka - Dáníẹ́lì.

Kristiẹni ije jara.
Ìgbéyàwó Àti Ìkọ̀sílẹ̀.
Akojọ Ifiranṣẹ.

Opin akoko jara.

Ngbe ọrọ jara.

Keresimesi jara.

Iku. Ohun ti nigbana?

Orúkọ Ọlọrun.

Ọkọ Noa.

 

Ẹṣẹ Atilẹba.
Je o ẹya apulu?

Adaparọ.
Awọn orisun - Babeli.

Ọlọrun ati Imọ.
Dainoso Adaparọ.

Archaeology.
Sodomu ati Gomorra.

  Iwe-mimọ sọ...

Nítorí nígbà tí ilẹ̀ bá ń mu omi òjò tí ń rọ̀ sórí rẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà, tí ó sì ń mú kí ohun ọ̀gbìn hù fún àwọn àgbẹ̀ tí ń roko níbẹ̀, ilẹ̀ náà ń gba ibukun Ọlọrun ni.

Ṣugbọn bí ó bá ń hu ẹ̀gún ati igikígi, kò wúlò, kò sì ní pẹ́ tí Ọlọrun yóo fi fi í gégùn-ún. Ní ìkẹyìn, iná ni a óo dá sun ún.

Heberu 6:7-8


Tẹ aworan kan lati ṣe igbasilẹ aworan iwọn ni kikun tabi PDF.


Acts of the Prophet

(PDFs Gẹẹsi)
 

Ìgbéyàwó Àti Ìkọ̀sílẹ̀.

(PDF)

William Branham
Life Story.

(PDF Gẹẹsi)

How the Angel came
to me.
(PDF Gẹẹsi)



 


Ifiranṣẹ ibudo...Yan ede rẹ ki o gba awọn ifiranṣẹ ọfẹ lati ọdọ Arákùnrin Branham.