Irúgbìn Òdì.

<< išaaju

itele >>

  Opin akoko jara.

Òjò n rọ̀ sórí olódodo ati aláìsòdodo.


William Branham.

Ka iroyin kikun ni...
Irúgbìn Òdì.

Mo ti n gbadura ninu iho kan, nibiti mo ti lọ maa n gbadura. Ara mi kun fun eruku ninu iho naa, ni ọsan ọjọ kan, mo jade, mo gbe Bibeli mi le igi kan, afẹfẹ si si i si Heberu, ori kẹfa. Ti o sọ wipe, ni ikẹyin ọjọ, bi yoo se ri ti a ba subu kuro ninu otitọ, ti a si sọ ara wa di ọtun lòdì si ironupiwada, ko si ẹbọ fun ẹsẹ mọ, ati gẹgẹ bi ẹgun ati osusu, ti o sunmọ kikọ silẹ, opin ẹniti o wa fun ijona; sugbọn ojo n rọ sori ilẹ, leralera, lati bu omi rin-in, lati tun-un se; sugbọn ẹgun oun osusu ni a o kọ̀, sugbọn alikama ni a o ko jọ. Mo si ronu wipe, “O dara, afẹfẹ ni o kan si ibẹyẹn.” O dara, mo tun fi Bibeli yẹn silẹ lẹẹkan sii. Mo wa ronu wipe, “O dara, bayi n o kan....” afẹfẹ si tun wa, o tun si i silẹ. Iyẹn sẹlẹ ni igba mẹta. Mo wa ro o wipe, “O dara, bayi o, iyẹn se ajeji.”

Bi mo si se dide, mo ronu, “Oluwa, eese ti O fi si Bibeli yẹn fun mi lati ka ibẹyẹn, nigbati mo de ibi ẹgun oun osusu, eyi ti o sunmọ kikọ silẹ, opin ẹniti o wà fun ijona?” Mo ro o, “Eese ti O fi si iyẹn fun mi nibẹyẹn?” Mo wa wo ayika.

Bayi, awọn iran wọnyi maa n wa lai jẹ wipe mo se nkankan. Ọlọrun niyẹn. Se ẹ rii? Mo wo, mo si ri aye kan ti o n yi niwaju mi, mo si ri i wipe a ti ro gbogbo oko inu rẹ, a si ti kọ ebe si i. Ọkunrin kan wa ti o wọ asọ funfun, o n lọ kaakiri, o si n gbin alikama. Lẹyin ti o la aye ja; ọkunrin miiran tun wa ti o buru jai, oun si wọ asọ dudu, o si bẹrẹ si ju irugbin epo si inu rẹ. Awọn mejeeji si hu jade. Nigbati wọn se bẹẹ, orungbẹ n gbẹ awọn mejeeji, nitori wọn nilo ojo. O wa dabi ẹni wipe ọkọọkan wọn n gbadura, pẹlu idorikodo, “Oluwa, fi ojo ransẹ, fi ojo ransẹ.” Bẹẹni ikuuku bo ilẹ, ojo si rọ sori awọn mejeeji. Nigbati eleyi sẹlẹ, alikama kekere yẹn fo soke, o bẹrẹ si wipe, “Ẹ yin Oluwa! Ẹ yin Oluwa!” Bẹẹni epo kekere yẹn naa fo soke lẹgbẹ rẹ, o wipe, “Ẹ yin Oluwa! Ẹ yin Oluwa!”

Lẹyinnaa, a tumọ iran naa. Ojo n rọ sori olododo ati alaisododo. Ẹmi kannaa lee sọkalẹ sinu ipade isin, ki gbogbo eniyan si maa yọ ninu rẹ: ati agabagebe, ati Kristẹni, ati gbogbo eniyan. Bẹẹ gan-an ni. Sugbọn kini? Nipa eso wọn ni a fi n mọ wọn. Se ẹ rii? Ọna kansoso ti a le gba mọ ọ niyẹn.

Se ẹ ri iyẹn bayi, niwọn igba ti o jẹ wipe epo, nigbamiran, maa n se afarawe alikama, wọn si jọ ara wọn de ibi wipe wọn yoo tan awọn ayanfẹ gan-an jẹ. Mo ro wipe a n gbe ni igba ti o yẹ, nigbati o yẹ ki a waasu lori awọn nkan wọnyi, ki a si sọrọ nipa wọn.

Ẹ kiyesii ni ẹsẹ 41, awọn mejeeji jọ ara wọn, wọn jọ ara wọn ni ikẹyin ọjọ́ de ibi wipe Oun ko se.... Oun ko lee gbẹkẹ le ijọ kan pato lati ya wọn sọtọ, boya, ijọ Eleto tabi ijọ Onitẹbọmi, tabi awọn ijọ Afede-ajeji-sẹri- Ẹmi-Mimọ, lati ya wọn sọtọ. O ni, “O ran awọn angẹli Rẹ lati ya wọn sọtọ.” Angẹli kan n bọ wa lati mu iyasọtọ naa wa, iyasọtọ laarin ohun ti o tọ ati ohun ti kò tọ. Ko si si ẹni ti o lee se iyẹn bikose angẹli Oluwa. Oun ni yoo sọ eyi ti o tọ ati eyi ti kò tọ. Ọlọrun sọ wipe Oun yoo ran awọn angẹli Oun ni igba ikẹyin. Kii se awọn angẹli ni aarin meji, sugbọn awọn angẹli ni igba ikẹyin, wọn yoo si ko o jọ pọ. A mọ wipe akoko ikore ti de tan bayi. Bayi, angẹli tumọ si “ojisẹ.” A si rii wipe awọn angẹli meje ti awọn ijọ meje ni o wà ni awọn igba ijọ.

Ẹ kiyesii ẹniti O sọ wipe awọn afurugbin naa jẹ, ati ohun ti irugbin naa jẹ pẹlu. Lakọkọ, Oun, Ọmọ Ọlọrun, ni afurugbin naa, ẹniti o jade lọ, ti o si n furugbin. Ọta kan si wá lẹyin Rẹ, eyi tii se esu, o si gbin irugbin òdì, lẹyin gbingbin Irugbin ti o tọ. Bayi, ẹyin ọrẹ, iyẹn ti sẹlẹ ni gbogbo igba, lati igba ti aye ti sẹ̀. Bẹẹ ni. Lati ibẹrẹ wa, o bere ohun kannaa.

----
A kiyesii wipe ẹniti o kọkọ gbin irugbin òdì ni a pe ni “esu,” a si mọ wipe o wà ni Gẹnẹsisi 1. Bayi a ti rii, wipe ninu iwe Matteu, ni ori kẹtala, Jesu si pe ohunkohun ti o lòdì si Ọrọ Rẹ ni esu. Ati ni ọdun 1965 yii, ohunkohun ti o ba gbin òdì, lòdì si Ọrọ Ọlọrun ti a kọ, tabi ti o fi itumọ ikọọkọ si i, o jẹ irugbin òdì. Ọlọrun ko ni bu ọla fun-un. Ko lee se e. Ko lee dapọ. Dajudaju, ko lee se e. O dabi irugbin mustadi; ko lee dapọ mọ ohun miiran, e ko lee se alupayida rẹ, o nilati jẹ ojulowo. Irugbin òdì!

Bayi, a rii, nigbati Ọlọrun gbin irugbin Rẹ ni ọgba Edẹni, a rii wipe o mu Abẹli jade wa. Sugbọn nigbati Satani gbin irugbin òdì rẹ, o mu Kaini jade wa. Ọkan mu olododo jade wa; ọkan mu alaisododo jade wa. Nitori Eefa fi eti si ọrọ òdì, ti o lòdì si Ọrọ Ọlọrun, o si mu ki ẹsẹ maa tẹsiwaju lati ibẹyẹn, o si ti n tẹsiwaju lati igba naa wa. A ko si lee mu gbogbo rẹ kuro, ayafi ti awọn angẹli ba wa lati pin wọn niya, ti Ọlọrun si ko awọn ọmọ Rẹ lọ si Ijọba naa, a o si sun awọn epo ninu ina. E kiyesi awọn ajara mejeeji yẹn.

----
Ẹ kiyesii, awọn irugbin wọnyi jọ n dagba papọ gẹgẹbi Ọlọrun se sọ nihin ni ori kẹtala, ti ibi ti a ka ni asalẹ yii, ti Matteu, “Ẹ jẹ ki wọn maa dagba papọ.” Bayi, Kaini lọ si ile Nọdi, o wa iyawo kan fun ara rẹ, o si fẹ ẹ; a si pa Abẹli, Ọlọrun si gbe Seti dide lati rọpo rẹ. Awọn iran naa si n tẹsiwaju, laarin rere ati buburu. Bayi, a kiyesii wipe wọn n pejọ pọ, olukuluku wọn, lati igba de igba, Ọlọrun si nilati.... O buru de ibi wipe Ọlọrun nilati pa wọn run.

Sugbọn nikẹyin, wọn jade wa titi ti awọn irugbin mejeeji, irugbin òdì ati irugbin Ọlọrun, fi so ojulowo eso wọn, iyẹn si yọri si Judasi Iskariọti ati Jesu Kristi. Nitori, Oun ni irugbin Ọlọrun, Oun ni ibẹrẹ isẹda Ọlọrun, ko yatọ si Ọlọrun. A si bi Judasi Iskariọti ni ọmọ ègbé, o ti ọrun apaadi wá, o si pada si ọrun apaadi. Jesu Kristi jẹ Ọmọ Ọlọrun, Ọrọ Ọlọrun ti a fihan. Judasi Iskariọti, ninu òdì rẹ, jẹ irugbin esu, o wa si aye fun ẹtan; gẹgẹbi o se ri ni ibẹrẹ, Kaini, baba rẹ atijọ.

Judasi kan n fi ijọ boju ni. Ko jẹ olootọ rara, ko ni igbagbọ nitootọ (ki ba ti da Jesu). Sugbọn, se ẹ rii, o gbin irugbin òdì yẹn. O ro wipe oun lee ba aye se ọrẹ, mamoni, ki oun si tun jẹ ọrẹ pẹlu Jesu, sugbọn o ti pẹ ju fun-un lati se ohunkohun nipa rẹ. Nigbati wakati naa de, nigbati o se ohun buburu yii, o ti re aala kọja laarin lilọ siwaju ati pipada sẹyin. O nilati tẹsiwaju ni ọna ti o rin, gẹgẹbi ẹlẹtan. O gbin irugbin òdì, o gbiyanju lati ri ojurere awọn ijọ ti a fi ọgbọn eniyan gbe kalẹ ni igba yẹn, pẹlu awọn Farisi ati Sadusi. O ro wipe oun yoo pa owo diẹ, ati wipe oun yoo jẹ olokiki laarin awọn eniyan. Njẹ iyẹn kọ́ ni o n jẹ ki ọpọlọpọ eniyan bọ sinu òdì yen, wọn n gbiyanju lati wa ojurere eniyan! Ẹ jẹ ki a wa ojurere Ọlọrun, kii se ti eniyan. Sugbọn ohun ti Judasi se niyẹn nigbati awọn òdì wọnyi so eso jade ninu rẹ.

A si mọ wipe Jesu ni Ọrọ naa, Johannu Mimọ 1, sọ pe, “Ni atetekọse ni Ọrọ wa, Ọrọ wa pẹlu Ọlọrun, Ọlọrun si ni Ọrọ naa... Ọrọ naa si di ara, O si n ba wa gbe ihin.” Nigbanaa, Ọrọ naa jẹ Irugbin, Irugbin naa si di ara, o si n ba wa gbe.

Ti Judasi ba jẹ irugbin ti ọta ati ti òdì, oun naa di ara o si n gbe aarin wa ninu ẹni ti Judasi Iskariọti jẹ. Ko fi igba kan ni igbagbọ tootọ. O ni ohun ti o ro wipe o jẹ igbagbọ. Ohun kan ni ki eniyan ni igbagbọ; ọtọ si ni afarawe igbagbọ.
Igbagbọ Ọlọrun tootọ yoo gbagbọ ninu Ọlọrun, Ọlọrun si ni Ọrọ naa, ki yoo fi ohunkohun kun-un laelae. Bibeli sọ fun wa wipe ti a ba fi ọrọ kan kun-un, tabi a mu ọrọ kan kuro, a o mu ipin wa kuro ninu iwe iye, Ifihan 22:18, ori ti o gbẹyin.

Ni atetekọse, iwe akọkọ ninu Bibeli, Ọlọrun sọ fun wọn wipe wọn ko gbọdọ sẹ ẹyọ kan ninu ọrọ yẹn. Wọn gbọdọ pa gbogbo ọrọ naa mọ. Wọn gbọdọ maa gbe nipa Ọrọ yẹn. Jesu, ni aarin Iwe naa, wa, O si sọ wipe... ni iran Tirẹ, O ni, “Eniyan ki yoo wa laaye nipa akara nikan, sugbọn nipa gbogbo Ọrọ ti o ti ẹnu Ọlọrun jade.” Ati ni ipari iran Ifihan, o sọtẹlẹ fun wa, wipe “Ẹnikẹni ti o ba mu ọrọ kan kuro ninu Iwe naa, tabi ti o fi ọrọ kan kun-un, a o mu ipin rẹ kuro ninu iwe iye.”

Nitorinaa, ko lee si bojuboju kan nibẹ, bikose ojulowo Ọrọ Ọlọrun ti ko ni abula! Awọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin Ọlọrun niyẹn, awọn ti a ko bi nipa ifẹ eniyan, tabi nipa bibọ ọwọ, tabi nipa ilana iribọmi kan; sugbọn ti a bi ninu Ẹmi Ọlọrun, nipa Ẹmi Mimọ, ti Ọrọ naa si n fi ara Rẹ han ninu wọn. Awọn irugbin Ọlọrun tootọ niyẹn!

Ọta n darapọ mọ ijọ, yoo si jẹ olootọ ninu ẹkọ adamọ tabi nkan miiran. Sugbọn iyẹn kọ ni.... Òdì niyẹn, ohunkohun ti o ba tako ojulowo otitọ Ọrọ Ọlọrun taara yẹn. Bawo ni a si se mọ? A sọ pe, “O dara, se o ni ẹtọ lati tumọ rẹ?” Rara, sa! Ko si ẹni ti o ni ẹtọ lati tumọ Ọrọ Ọlọrun. Oun ni olutumọ ara Rẹ. O se ileri rẹ, lẹyinnaa O si se e, itumọ rẹ niyẹn. Nigbati O se ileri rẹ, lẹyinnaa ti O mu u sẹ, itumọ rẹ niyẹn. Ohunkohun ti o ba lòdì si Ọrọ Ọlọrun, jẹ òdì! Dajudaju!

Bayi, gẹgẹbi mo se sọ, Judasi ko ni igbagbọ tootọ. O ni ohun ti o jẹ afarawe igbagbọ. Ó ni igbagbọ kan ti o fi ro wipe Ọmọ Ọlọrun niyẹn, sugbọn ko mọ wipe Ọmọ Ọlọrun niyẹn. Ki ba ti se e. Ẹni ti o ba si gba ibọde wipe Ọrọ Ọlọrun yii kii se otitọ, o ni igbagbọ afarawe. Ojulowo iransẹ Ọlọrun so mọ Ọrọ yẹn.

Ka iroyin kikun ni... Irúgbìn Òdì.



Ohun ijinlẹ Kristi.

Wẹẹbu iwe iroyin Gẹẹsi.

Iwe Ifihan jara.

 

Ọlọrun ati Imọ Atọka.
- Archaeology.

Igbasoke n bọ.

 

Awọn ẹkọ akọkọ
ti ifiranṣẹ naa.

Awọn ti o dara iroyin.
Jesu ku fun ese re.

Iribomi Omi.

 

Awọsanma eleri nla.

Ọwọn ti ina.

Ogo Shekinah ti Ọlọrun.

Ibojì ti ṣofo.
O ti jinde.

Ọlọrun salaye.

Awọn ìgbà ijọ meje.

Awọn edidi meje.

Ọlọrun ati Itan.
jara Atọka - Dáníẹ́lì.

Kristiẹni ije jara.
Ìgbéyàwó Àti Ìkọ̀sílẹ̀.
Akojọ Ifiranṣẹ.

Opin akoko jara.

Ngbe ọrọ jara.

Keresimesi jara.

Iku. Ohun ti nigbana?

Orúkọ Ọlọrun.

Ọkọ Noa.

 

Ẹṣẹ Atilẹba.
Je o ẹya apulu?

Adaparọ.
Awọn orisun - Babeli.

Ọlọrun ati Imọ.
Dainoso Adaparọ.

Archaeology.
Sodomu ati Gomorra.

  Iwe-mimọ sọ...

Nítorí nígbà tí ilẹ̀ bá ń mu omi òjò tí ń rọ̀ sórí rẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà, tí ó sì ń mú kí ohun ọ̀gbìn hù fún àwọn àgbẹ̀ tí ń roko níbẹ̀, ilẹ̀ náà ń gba ibukun Ọlọrun ni.

Ṣugbọn bí ó bá ń hu ẹ̀gún ati igikígi, kò wúlò, kò sì ní pẹ́ tí Ọlọrun yóo fi fi í gégùn-ún. Ní ìkẹyìn, iná ni a óo dá sun ún.

Heberu 6:7-8


Tẹ aworan kan lati ṣe igbasilẹ aworan iwọn ni kikun tabi PDF.


Acts of the Prophet

(PDFs Gẹẹsi)
 

Ìgbéyàwó Àti Ìkọ̀sílẹ̀.

(PDF)

William Branham
Life Story.

(PDF Gẹẹsi)

How the Angel came
to me.

(PDF Gẹẹsi)


Ifiranṣẹ ibudo...Yan ede rẹ ki o gba awọn ifiranṣẹ ọfẹ lati ọdọ Arákùnrin Branham.