Iransẹ Iwo̩ oorun.

<< išaaju

itele >>

  Opin akoko jara.

Oke Iwo̩ oorun.


William Branham.

Ka iroyin kikun ni...
Ki ni ifanimo̩ra ni ori oke naa?

Laipẹ pupọ sẹyin, mo duro nibi aga iwaasu yii, mo si sọ nipa Ẹmi Mimọ pe, “Ọjọ naa nbọ, nigba ti wọn yoo gbá èèkàn kan mọlẹ niwaju ile rẹ, wọn yoo si wú ẹnu bodè ile rẹ, ki iwọ ki o lee ré eleyi fo, ki iwọ ma si se binu”. Mo si ri ẹnu-bode ile mi, ti wọn si wu u danu ti o si wa ni ilẹ ẹba oke kan. Mo ri oke to wa niwaju ile mi ti wọn wuu, pẹlu awọn pako ati ohun miiran ti wọn wó papọ sibẹ. Mo wo o, mo si ri ọmọ alẹja kan ti o wu ẹnu ibode ile mi naa. Mo wi pe, “Kin ni o de, ti o ko fi sọ fun mi?” O si gbiyanju lati bami ja, mo si nilati luu. Nigba ti eyi si sẹlẹ, mo wi pe, “Emi ko tii se eleyi lẹyin igba ti mo dẹkun fifi-ija-pawo ninu gbagede, sugbọn mo kan fẹ ki o mọn”. Mo si gba a ni ẹ̀sẹ́ kan. Nigba ti mo si gbe e sanlẹ, mo faa dide, mo tun luu bolẹ lẹẹkan si, mo si luu bolẹ ni igba mẹta tabi mẹrin, lẹhin naa, mo taari rẹ si ẹyin oke naa. Nigba naa, ni mo lọ si ibi to wa, mo wi pe, “Iyẹn ko tọ”. Mo si faa dide, mo bọọ lọwọ, mo wi pe, “Inu ko bi mi si ọ, sugbọn mo saa fẹ ki o mọn pe, iwọ ko lee bami sọrọ bẹyẹn”. Nigba ti mo si yiju pada ti mo pada wa, Ẹmi Mimọ duro si ẹnubode mi, O wi pe “Bayii, ré iyẹn kọja. Nigba ti wọn ba kan èèkàn yẹn mọlẹ, lọ si Ìwọ̀ oorun.
Iwe yii, ni ohun gbogbo ti mo nilo
Iwe yii ni olutọsọna rere
(ohun ti o n fihan Ọna lati lọ yipo idamu mi)
Amin. Iwe naa si ni Ọrọ naa, Ọrọ naa si ni Ọlọrun. Re idamu rẹ kọja. Yoo sọ fun ọ ohun ti iwọ yoo se.

Ni ọdun mẹta sẹyin, mo gbọ ti ọrẹ mi kan ti o jẹ wọnlẹ-wọnlẹ, osisẹ ijọba ilu yii, o n gbe isalẹ opopo ile mi, o si kan èèkàn kan mọlẹ. Mo lọ baa, mo wi pe, “Kin ni o sẹlẹ Mud?” Ọmọ Ọgbẹni King ni, ọrẹ mi ni. O wi pe, “Billy, wọn yoo fẹ titi yi sẹyin” Gbogbo yin ranti. Mo wi pe, “O lee jẹ iran yẹn ni”. Mo sọ fun Arakunrin Wood, mo wi pe, “Tọju ilẹ rẹ. O seese ki afara odo yẹn gba ibiyi wa, tabi ohun kan”. Wọn tu titi naa ka, okuta biriki si fọnka si gbogbo ilẹ. Nitori naa, mo sọ fun un pe, “Tọju ilẹ rẹ”. Nigba ti Ọgbẹni King si sọ fun mi pe iyẹn yoo sẹlẹ, mo wọle lọ, mo si wi fun iyawo mi to joko nibẹ yẹn pe, “Oyin, ohun kan wa ti a kọ nipa iyẹn. ‘Bayi ni Oluwa wi’ ni níbìkan.”

Mo wọle lọ, mo si mu iwe mi, mo wo inu rẹ, o si wi pe, “Yoo si sẹlẹ pe...” Lẹyin ọdun mẹjọ! Nigba ti mo si wo o, mo wi pe, “Asiko ti to bayi, oyin, a gbọdọ lọ si Iwọ oorun”.
Ọjọ meji lẹyin eleyi, mo duro ninu iyara ni nkan bi agogo mẹwa owurọ, mo wọ inu Ẹmi Ọlọrun, mo si ri awọn ẹyẹ adaba diẹ ti wọn nfo papọ yẹn, mo wo awọn ẹyẹ kekere naa. Ẹ ranti rẹ. Mo ri awọn Angẹli Meje ti wọn to bi ile alaramọnda to kere loke to si fẹ ni isalẹ, wọn sare wa si ọdọ mi, wọn wi pe, “Lọ si Iwọ oorun, lọ si Tucson, ki o si wa ni ogoji ibusọ si iha ariwa mọ ila oorun Tucson. Iwọ yoo si maa yọ èèmọ́ (ẹmimọ) kuro lara asọ rẹ”.

Arakunrin Fred Sothman, ti o joko nibẹ yẹn, ti o n wo mi bayii, wa nibẹ ni owurọ ọjọ naa. Emi si ti gbagbe nipa rẹ.
Mo wi pe, “Ìró nla kan dun bi ìsẹ́lẹ̀ ti o mi gbogbo agbegbe naa. Emi ko ri bi eniyan kan se lee rú là”. Ẹru ba mi. Mo duro ni Phoenix; gbogbo ẹyin ti o ngbọ mi lalẹ yii, ẹ jẹri mi. Mo waasu, “Ẹyin Alagba, Akoko Wo Niyii?” Nibo ni a wa? Mo lọ si Iwọ oorun orilẹ ede yii. Ọpọlọpọ yin lo ni ohùn ta gba silẹ naa. Pupọ yin ni ẹ gbọ ti a sọ ọ bi ọdun kan tabi ju bẹẹ lọ ki o to sẹlẹ.

Mo lọ si Iwọ oorun, mo n fọkan daniyan nipa ohun ti yoo sẹlẹ. Lọjọ kan, mo gba ipe kan lati ọdọ Oluwa. Mo sọ fun iyawo mi pe, “Oyin, boya isẹ mi ti pari”. Emi ko mọn. Mo wi pe, “O seese ki o jẹ wi pe, Ọlọrun ti pari pẹlu mi, boya emi yoo ma lọ si Ile mi Ọrun. Lọ duro pẹlu Billy, pẹlu awọn ọmọ, Ọlọrun yoo la ọna fun ọ, lọnakọna. Gbe igbe aye ti o tọ pẹlu Ọlọrun. Ki o rii pe awọn ọmọ pari ile iwe wọn, tọ wọn dagba ninu imọn Ọlọrun”.
O wi pe, “Billy, iwọ ko mọn boya eyi ri bẹẹ”.
Mo wi pe, “Rara. Sugbọn, ko si eniyan ti o lee la ninu ohun to sẹlẹ yẹn”.
Ni owurọ ọjọ kan, Oluwa ji mi dide. O wi pe, “jade lọ si oke Sabino Canyon”. Mo mu iwe kekere kan ati Bibeli mi.
Iyawo mi wi pe, “Nibo ni o n lọ?”
Mo wi pe, “Emi ko mọn. Emi yoo sọ fun ọ bi mo ba de”.

Mo goke lọ sori apata lọ si ibi ti awọn idi ti nfo kaakiri. Mo n wo agbọnrin kan to duro sibẹ. Mo kunlẹ lati gbadura, mo si gbe ọwọ mi mejeeji soke, ida kan si bọ si ọwọ mi. Mo wò kaakiri, mo ro o wi pe, “Kin ni iyẹn? Kii se pe, emi ko mọn ohun ti mo nse. Ida yẹn niyii lọwọ mi, o mọn, o ndan, o nkọ yinrin ninu oorun”. Mo wi pe, “Bayii, ko si awọn eniyan ni ọpọlọpọ ibusọ ni ibi yii ni ori oke yii. Nibo ni eleyi ti wa?”
Mo gbọ ti Ohùn kan wi pe, “Ida Ọba Naa ni Iyẹn”.
Mo wi pe, “Ọba kan a maa fi eniyan kan jẹ balogun nipa ida”.
Ohùn naa tun pada wi pe, “Kii se Ida ọba kan, Sugbọn Ida Ọba Naa ni, Ọrọ Oluwa”. O wi pe, “Ma bẹru, onfa kẹta saa ni. O jẹ ijẹrigbe isẹ iransẹ rẹ”.

Mo lọ se ọdẹ pẹlu ọrẹ mi kan, lai mọ ohun ti yoo sẹlẹ. Ẹnikan si pe mi, ẹni ti o tako mi nipa aworan Angẹli Oluwa yẹn, ti o ya aworan naa. Mo ni lati lọ si Houston nipa ọmọ rẹ, nitori wọn ti dajọ iku fun un, wọn yoo si paa lẹyin ọjọ diẹ si. O si pade mi nibẹ, o fọwọ mejeeji gba mi mu mọra, o wi pe, “Tilẹ roo wo pe, ọkunrin ti mo tako gan an, ni o wa lati gba ọmọkunrin mi kan soso!” Ẹgbẹ to nse aanu ọmọniyan fun mi ni ohun kan ti wọn pe ni Oscar, eyi si fun mi laaye lati gba eniyan kan lọwọ iku, bi a ba ti dajọ iku fun un.

Lẹhin naa, a pada. Mo lọ si ori oke lati lọ sọdẹ. Nibẹ, Arakunrin Fred ati emi jade lọ ni owurọ ọjọ kan - emi ti pa ẹlẹdẹ igbo temi - Mo si woo, mo ri ibiti awọn ẹranko naa lọ. Mo wi pe, Arakunrin Fred, lọ si ori oke yẹn ni kutukutu owurọ, emi yoo si bọ si ori oke keji. Emi ko ni ta awọn ẹranko naa nibọn, Sugbọn emi yoo ta ibọn siwaju wọn lati le wọn pada si ọ bi wọn ba wa si ọdọ mi.

Arakunrin Fred lọ si ibẹ, ko si si awọn ẹlẹdẹ kankan nibẹ. O juwọ simi, mo si rii. Mo so̩kale̩ si koto inu canyon naa, afonifoji nla kan. Oorun se̩se̩ be̩re̩ sii yo̩ ni. Mo yipo gba odikeji oke naa, emi ko si ronu nipa iso̩te̩le̩ naa. Mo joko, mo n simi, Mo si roo pe, “kin ni o se̩le̩ si awo̩n ẹlẹdẹ igbo ye̩n?”
Mo joko bi awo̩n India se maa n joko, se e̩ mo̩n, mo dabu e̩se̩ mi; mo si wo ara sokoto mi, mo ri èmìmó̩ kan. Mo mu u kuro, mo si wi pe, “Iye̩n sajeji; Ibi yii ni mo wa, ni ogoji ibuso̩, ni ila oorun, ariwa Tucson. O̩mo̩kunrin mi kekere Joseph niye̩n to joko demi” Bi mo se dide lati wo o, mo ri ò̩wó̩ awo̩n e̩le̩de̩ ye̩n jade ni nkan bii e̩gbe̩run yaadi si ibi ti mo wa. Mo ju èmìmó̩ naa sile̩. Mo wi pe “Emi yoo da awo̩n ẹranko yii. Emi yoo lo̩ pe Arakunrin Fred, emi yoo si so iwe kekere kan lati je̩ ki o mọn ibi ti yoo gba lati lee ri awo̩n e̩ranko naa. A o si pe Arakunrin Fred.”
Mo si be̩re̩ si sare ni ori-oke naa, bi mo se lee sare to ni odi keji. Lojiji; mo ro wi pe e̩ni kan ti ta mi ni ibo̩n ni. Emi ko tii gbo̩ iro ti o to yẹn ri. O mi gbogbo adugbo naa. Nigba ti mo si gbọ iro naa, Awo̩n Angẹli meje duro niwaju mi, Awo̩n mejeeje duro papo̩.

Mo pade Arakunrin Fred ati awo̩n to ku nigba ti o se die̩ si, Wo̩n wi pe, “kin ni ye̩n”?
Mo wi pe, “Oun ni ye̩n”.
“Kin ni iwo̩ yoo se?”
“Emi yoo pada sile. Nitori pe, ‘Bayii ni Oluwa wi’, awo̩n ohun ijinle̩ meje ti a ti fi pamo̩ sinu Bibeli ni gbogbo ọdun wo̩nyi, awo̩n ijo̩-tofi-e̩ko̩ke̩ko̩-ro̩po-Ọrọ-O̩ro̩run wọnyi ati ohun gbogbo be̩e̩, O̩lo̩run yoo si awọn ijinlẹ meje naa fun wa ninu awo̩n edidi meje”. Obiripo ye̩n si dide lati ile̩ bii ikuuku ti o dijo̩. Nigba ti O si se be̩e̩ tan, O goke lọ titi ti O fi ga kọja awo̩n oke ye̩n. O bẹrẹ sii lọ si iha iwo̩ oorun lati ibi ti O ti wa. Awo̩n onimo̩n-ijinlẹ, ri I nigba ti o se, O ga si ile̩ ni iwo̩n o̩gbo̩n ibuso̩, O si fe̩ ni iwo̩n ibuso̩ marun-do̩gbo̩n, O si wa ni obiripo ti ile alara-mo̩da to fẹ ni isalẹ, ti o si kere ni oke.

Ni ijelo, mo duro nibe̩, mo yi aworan naa si o̩wo̩ o̩tun, mo si ri I pe, Jesu ge̩ge̩bi O se wa ninu awo̩n igba Ijo̩ Meje, ti O ni ibori funfun ti o fihan wi pe, Oun ni O̩lo̩run Olodumare, Alasẹ-ti-O-ga-julọ. Oun ni Alfa ati Omega, Oun ni Ẹni ibe̩re̩ ati E̩ni opin; Oun ni Onidajo̩-Alase̩-Togajulo̩ ni gbogbo ainipẹkun, ti O duro nibẹ, ti O si nfi e̩se̩ lse̩ iransẹ wakati yi mulẹ. Imo̩le̩ yoo si wa ni igba asale̩; kin ni gbogbo rẹ tumọn si? Kin ni o jẹ?

Mo lo̩ si Iwo̩ oorun. Lori oke yi kan naa pẹlu Banks Wood nibẹ. O wi pe, “Ju okuta kan soke. Sọ fun o̩gbẹni Wood pe, ‘Bayii ni Oluwa wi, iwo̩ yoo ri ogo O̩lo̩run.’”
Ni o̩jo̩ keji, mo duro nibẹ, Iji kan so̩kale̩ wa, o si fọ́ oke naa ka. Awọn okuta si ge ori gbogbo igi to wa nibe̩ kuro bii e̩se̩ bata me̩ta si me̩rin ni ikọja ori mi soke. O si se iro nla me̩ta, awọn ará naa sare wa si o̩do̩ mi. Awo̩n ọkunrin bi marun-dogun ti o wa nibẹ , ti o̩po̩ wo̩n si je̩ oniwaasu ati be̩e̩be̩e̩ lo̩. “Kin ni iye̩n?” O wi pe, “kin ni eleyi”?
Mo wi pe, “Idajo̩ nko̩lu bebe okun Iwọ Oorun”.

Ni nkan bi o̩jo̩ meji lẹyin eleyi, ìsé̩lè̩ kan fe̩re̩e̩ ri Alaska, kin ni Imọlẹ ye̩n ni ori oke Sunset ni igbo colorado ni Arizona? Kin ni ohun ajeji to se̩le̩ nibe̩ ti o mu ki awọn eniyan maa wako̩ lo̩ sibẹ lati ila oorun, ati iwo̩ oorun, ki wo̩n maa sa okuta to tuka naa nitori ti iji ye̩n kọlu, ti olukuluku awo̩n okuta naa si ni igun me̩ta mẹta. (o̩kan ni awo̩n apele me̩ta na). Awo̩n okuta wo̩nyi si wa lori tabili ati osuwo̩n ti o n wo̩n bi nkan se wuwo si kaakiri orile̩-ede yii bayii - kin ni ohun ajeji yii to se̩le̩ lori oke sunset ni igbo Coronado.

Junior Jackson ti o ngbo̩ mi bayii, se ẹ ranti ala ti o la, ti mo tumo̩n, “nibi ti mo ti nlo̩ si apa iwo̩ oorun”. Ìsè̩lè̩ yii si se̩le̩ ni ori oke sunset (oke Iwo̩ oorun). Akoko iro̩le̩ ni. Ise̩ iransẹ ti iro̩le̩ ni akoko ti oorun n wo̩, ti igbekalẹ iso̩te̩le̩ si ndi mimuse̩. Imo̩le̩ yoo si wa ni akoko iro̩le̩, lori oke iwo̩ oorun, ninu igbo Coronado, ni ogoji ibuso̩ lapa ariwa si Tucson. Iwọ gbe iwe aworan ti nfi ipo gbogbo ilu ati ile̩ han lori ile̩ aye, ki o si wo ibi ti o ga julo̩ lori oke Sunset. Ibe̩ gan ni o ti se̩le̩. N ko mo̩ te̩le̩, titi di ijelo.

Ni o̩na gbogbo, iye̩n ko lee ku. O sa tunbo̩ nsi ara Re̩ paya ni. Be̩re̩ lati ise̩le̩ na gan ti o se̩le̩, si awo̩n aworan Re̩ ti wo̩n ya, tii se Jesu ti O nwo wa, titi mo̩n bi o se je̩ pe oke Sunset ni o ti se̩le̩, ni Imo̩le̩ asaale̩ ti tan. Imo̩le̩ asaale̩ ti de. Ọlọrun n jẹrigbe Ara Re̩. Kin ni? Otito̩ ni pe Ọlọrun ati Kristi je̩ o̩kan soso. Awọn melo lo ri Ibori funfun naa ni ori Re̩ bi a ti so̩ o̩ ni Iwe ifihan:1? Se o rii, Ọlọrun Olodumare, Ẹni ti o ni gbogbo Ase̩ ati Agbara; ko si ohun miiran, ko si Ọlọrun miiran, ko si ohun kankan mo̩n. “Ninu Re̩, ni ẹkunre̩re̩ Ọlọrun ngbe ni iduro” Awo̩n Angẹli funrawo̩n ni ibori Re̩. Aamin.

Kin ni o se̩le̩ ni ori oke sunset? Ọlọrun n fe̩se̩ O̩ro̩ Re̩ mule, pe otito̩ ni. Ohun ti o fa gbogbo ariwo wo̩nyi niye̩n. Kiyesii, Ọlọrun ni O n mu O̩ro̩ Ileri Re̩ se̩ le̩e̩kansi, ti Iwe Ifihan 10:1-7. “Ati ni o̩jo̩ ohun ise̩ iranse̩ ti Angẹli keje, a o pari gbogbo ijinle̩ Ọlọrun.” Awọn ohun ijinlẹ ti Iwe Ifihan 10:1-7, isẹ iransẹ to kẹyin si ijọ to kẹyin. Eyi mu Iwe Luku 17:30 sẹ ni iran yi “Ni ọjọ naa ti a o fi Ọmọ Eniyan Naa han”.
“Awo̩n eke wolii ati eke Kristi yoo si dide, wo̩n yoo se ise̩ amin ati isẹ ara nla, nla to be̩e̩ ge̩ ti yoo fi tan awo̩n ayanfe̩ je̩, kani o seese”. Awo̩n eniyan si wa ni iyemeji sibe̩. Ati bi o se maa n se̩le̩, o n se ijo̩ pẹlu ni kayeefi.

Awo̩n onimo̩n ijinle̩ sibe̩, ni gbogbo Tucson, wo̩n n kọwe nipa rè̩ sinu iwe iroyin. Titi pada lo̩ de ori oke Lemmon, awo̩n e̩ro̩ ayaworan nla ye̩ ko rii bi O se dide lati ibi ti a duro si, ti O si nlọ ninu ofurufu si apa iwo̩ oorun, ti o n fihan pe, akoko ti dopin. Ko lee lo̩ pupo̩ si mọ́ nibe̩, o ti de bebe okun ti Iwo̩ Oorun. Idajọ kọlu aye ni apa ibi ti o gbalo̩. O kọja lo̩ lori Phoenix ati lori Prescott, O si kọja lori awo̩n oke lo̩ si bebe okun Iwo̩ Oorun. Wo̩n si lo̩ soke si... Nibo ni wo̩n lo̩? Taara lọ si Alaska, ìsẹ́lè̩ si n san bi àra, o nlo̩ ni apa ibi ti O gba lo̩.

Ile ise̩ ti-nfi-imo̩n-ijinle̩ wo ofurufu ti o wa ni Tucson ati gbogbo awo̩n to wa nilu naa si n beere sibe̩, awo̩n oluwadi-nipa-imo̩n-Ijinle̩ si nse iwadi, wo̩n n gbiyanju lati mo̩n ohun to jẹ gan an. O ga de ibi ti ikuukuu ojo ko lee de. “Kin ni o se e? Ohun na da?” O si nse wo̩n ni kayeefi bi Imo̩le̩ nipa agbara nla Ọlọrun ni ofurufu naa se farahan, ge̩ge̩bi awo̩n amoye se wa si Jerusalẹmu nipa irawo̩ ti wo̩n te̩le, ti wo̩n si n so̩ wi pe,“E̩ni naa ti a bi ni O̩ba awo̩n Juu da?”. Kin ni o se̩le̩? Ọlọrun ni O n mu O̩ro̩ Re̩ se̩. “Irawo̩ kan yoo si dide lati inu Jako̩bu wa”.

Ọlọrun O̩run si seleri pe, akoko asaale̩ yoo ni Imo̩le̩ asaalẹ. Ni o̩dun me̩ta se̩yin, ijinle̩ yii je̩ iso̩te̩le̩, “Akoko wo ni yii, Alagba?” Sugbo̩n bayii, o ti di itan, o ti ko̩ja. A ti mu ileri naa se̩. Akoko wo niyii, alagba ati kin ni Ifamo̩ra naa? Ọlọrun ni o n mu O̩ro̩ Re̩ se̩: O̩kan naa ni Oun, lana, loni ati titi lae.

Ka iroyin kikun ni...
Ki ni ifanimo̩ra ni ori oke naa?


Ohun ijinlẹ Kristi.

Wẹẹbu iwe iroyin Gẹẹsi.

Iwe Ifihan jara.

 

Ọlọrun ati Imọ Atọka.
- Archaeology.

Igbasoke n bọ.

 

Awọn ẹkọ akọkọ
ti ifiranṣẹ naa.

Awọn ti o dara iroyin.
Jesu ku fun ese re.

Iribomi Omi.

 

Awọsanma eleri nla.

Ọwọn ti ina.

Ogo Shekinah ti Ọlọrun.

Ibojì ti ṣofo.
O ti jinde.

Ọlọrun salaye.

Awọn ìgbà ijọ meje.

Awọn edidi meje.

Ọlọrun ati Itan.
jara Atọka - Dáníẹ́lì.

Kristiẹni ije jara.
Ìgbéyàwó Àti Ìkọ̀sílẹ̀.
Akojọ Ifiranṣẹ.

Opin akoko jara.

Ngbe ọrọ jara.

Keresimesi jara.

Iku. Ohun ti nigbana?

Orúkọ Ọlọrun.

Ọkọ Noa.

 

Ẹṣẹ Atilẹba.
Je o ẹya apulu?

Adaparọ.
Awọn orisun - Babeli.

Ọlọrun ati Imọ.
Dainoso Adaparọ.

Archaeology.
Sodomu ati Gomorra.

  Iwe-mimọ sọ...

Tó bá di ìgbà náà, kò ní sí òtútù tabi òjò dídì mọ́,

kò ní sí òkùnkùn, kò ní sí ọ̀sán, kò ní sí òru bíkòṣe ìmọ́lẹ̀ nígbà gbogbo. Ṣugbọn OLUWA nìkan ló mọ ìgbà tí nǹkan wọnyi yóo ṣẹlẹ̀.

Sakaraya 14:6-7


Tẹ aworan kan lati ṣe igbasilẹ aworan iwọn ni kikun tabi PDF.


Acts of the Prophet

(PDFs Gẹẹsi)
 

God, Hidden and
Revealed in simplicity.

(PDF Gẹẹsi)

William Branham
Life Story.

(PDF Gẹẹsi)

How the Angel came
to me.

(PDF Gẹẹsi)


 


Ifiranṣẹ ibudo...Yan ede rẹ ki o gba awọn ifiranṣẹ ọfẹ lati ọdọ Arákùnrin Branham.