Kini Ẹmi Mimọ?

<< išaaju

itele >>

  Isọdọmọ jara.

Oun ni edidi.


William Branham.

Ka iroyin ni kikun ni...
Kini Ẹmi Mimọ?

Bayi, mo ti bi ile ijọsin kere yi.... Nisisiyi, a ko wọ inu eyi lati lee ṣe ipade fun akoko gigun. Mo fẹẹ wọ inu ẹkọ yi lọ - mo si fẹ, bẹẹ ni mo ti rọ̀ yin lati jo gbogbo afara ti ẹ gba kọja ni ina, ki ẹ si ṣe atunṣe gbogbo ẹṣẹ yin - awa n wọ inu eyi lọ pẹlu ohun gbogbo to wa ninu ọkan ati ayé wa. A gbọdọ wa sihin fun idi kan-ṣoṣo, eyi ni lati pese ọkan ara wa silẹ fun dide Oluwa, ki i ṣe fun idi miran. Bi mo si ti sọrọ ti mo si wi pe boya nigbamiran, mo lee ṣe ikọni tabi ki n sọ ohun kan ti o lee tako ero ẹlomiran.... Tabi ọna ti wọn gba gbaagbọ. Nko wa fun ariyanjiyan, ṣe ẹ rii. Mo wa.... A wa nihin lati lee murasilẹ fun ipadabọ Oluwa.

-----
Lori ibiti a ka yi, a fẹ lati wọ inu akori naa (eyiti mo ro pe o jẹ akori ti o tayọ loni) nipa: Ki Ni Ẹmi Mimọ? Ki ni ohun ti O jẹ? Bayi, idi ti mo fi yàn lati sọrọ lori akori yi, ni ọna yi: Iwọ ko lee wa lati gba Ẹmi Mimọ, ayafi ti o ba mọ ohun ti O jẹ. Iwọ ko si lee gba a (ti o ba mọ ohun ti O jẹ, ayafi ti o ba gbagbọ pe a fifun ọ, O si wa fun ọ. Lẹyin naa, iwọ ko lee mọ boya o ti gba a tabi rara, ayafi ti o ba mọ èso to n mu jade. Nitorina, ti o ba mọ ohun ti O jẹ, ati ẹniti O wa fun un, ati iṣẹ ti O n ṣe nigbati O ba de, nigbana, iwọ yoo mọ ohun ti o gba, nigbati o ba gba a, ṣe ẹ rii. Iyẹn yoo yanju ọrọ naa.

Bayi, iyatọ nla wa laarin Kristẹni lasan ati Kristẹni ti a kun pẹlu Ẹmi Mimọ. Bayi, a o ri eyi ninu Iwe Mimọ, a o si fi sinu Iwe Mimọ. Ni akọkọ, Kristẹni kan wa, ti o n jẹwọ pe oun jẹ Kristẹni. Ṣugbọn ti Kristẹni yi ko ba ti i gba Ẹmi Mimọ, ó kan wa ni abẹ igbesẹ lati di Kristẹni ni, ṣe ẹ rii. O n jẹwọ lati gba a gbọ; o n gbe igbesẹ si i, ṣugbọn Ọlọrun ko tii fun un ni Ẹmi Mimọ yi. Oun ko ti i de ipele yẹn pẹlu Ọlọrun, nibiti Ọlọrun yoo ti da a mọ.

-----
Ikọla naa jẹ afiwe Ẹmi Mimọ. Ọlọrun si fun Abrahamu ni àmi ikọla naa lẹyin ti o ti gba Ọlọrun gbọ lori ileri Rẹ, ti o si lọ si ilẹ ajeeji, ṣe ẹ rii. O jẹ àmi kan. Gbogbo awọn ọmọ rẹ ati awọn iru ọmọ rẹ gbọdọ ni àmi yi ni ara wọn nitori o jẹ àmi pataki ti o tayọ. Ọlọrun fun wọn lati ya wọn sọtọ kuro lọdọ gbogbo eniyan yooku, àmi ikọla yi. Ohun si ni ohun ti Ọlọrun n lo ni oni. O jẹ àmi ikọla ọkàn, Ẹmi Mimọ, eyiti o sọ ijọ Ọlọrun di ijọ ti o yatọ kuro ninu awọn ẹkọkẹkọ, oniruru igbagbọ, ati awọn ijọ ẹlẹkọ adamọ. Wọn wa ni oniruru awọn ijọ ẹlẹkọ adamọ, ṣugbọn sibẹ wọn jẹ eniyan ti a ya sọtọ.

-----
Iwọ yoo yatọ, nigbati Ẹmi Mimọ ba wọ inu rẹ, titi ti awọn eniyan aye yi ko fi ni fẹran rẹ mọ, ti wọn yoo si ta ko ọ, ti wọn ko si ni fẹ ohunkohun lati ṣe pẹlu rẹ rara; ati bi ọ si aye miran; iwọ yoo jẹ ajeeji si aye yi, iwọ yoo jẹ ajeeji ni ilọpo mẹwa ju bi iwọ yoo ṣe jẹ lọ ti o ba lọ si ibiti o jinna ju ni ilẹ Afirika lọ. Iwọ yoo yatọ nigbati Ẹmi Mimọ ba wa. O si jẹ àmì kan. O jẹ àmì laarin awọn eniyan.
Bayi, iwọ sọ pe, nigbana, “Arakurin Branham, Abrahamu ni a fun ni àmì ikọla yẹn (otitọ ni) ati fun iru ọmọ rẹ.” Bẹẹ ni. O dara.

-----
Bayi, Iwe Efesu 4:30 ka bayi pe: Ki ẹ maṣe mu Ẹmi Mimọ Ọlọrun binu, nipa eyiti a ṣe edidi yin titi di ọjọ idande yin.
Emi yoo ni lati tẹnu mọ eyi gidigidi, ati ni ọna líle bayi.... Niisisyi, ẹyin ara ti ẹ n tẹle ofin, ẹ dakẹ-jẹ fun igba diẹ. Njẹ ẹ sakiyesi bi edidi naa ṣe pẹ to? Ki i ṣe titi di akoko isọji miran, ki i ṣe titi di igba ti ohun kan yoo ṣe lodi, “O jẹ titi di ọjọ idande yin!” Bi igbati a ṣe edidi yin yoo ṣe pẹ to niyi. Titi di ọjọ idande yin, nigbati a o ṣe idande yin si oke ọrun pẹlu Ọlọrun, bi Ẹmi Mimọ yoo ṣe ṣe edidi yin pẹ to niyi. Ki i ṣe lati isọji kan de ikeji, ṣugbọn lati ainipẹkun de ainipẹkun ni a ṣe edidi yin nipasẹ Ẹmi Mimọ. Ohun ti Ẹmi Mimọ jẹ niyi; O jẹ edidi Ọlọrun.... O ti ri ore ọfẹ ni oju Rẹ, O si fẹran yin, O si gbagbọ ninu yin, O si ti fi àmì edidi Rẹ si ori rẹ. Ki ni edidi?.... Eeṣe, edidi n ṣe àmì tabi otumọsi “iṣẹ ti a ti ̣se pari.” Amin! Ọlọrun ti gba ọ la, O ti sọ ọ di mimọ, O ti fọ yin mọ, O ti ri oju rere pẹlu rẹ, O si ti ṣe edidi rẹ! O ti ̣se e pari! Iwọ jẹ iṣẹ aṣejade Rẹ titi di ọjọ idande rẹ. Ohun ti a ṣe edidi rẹ jẹ iṣẹ aṣe-pari.
Ki ni Ẹmi Mimọ? O jẹ àmì kan. A o de ori iyẹn to ba ya ninu iwaasu miran, àmì ti Paulu sọ nipa rẹ; ifedefọ jẹ àmi si awọn onigbagbọ.... Tabi, si awọn alaigbagbọ.

Bayi, kiyesii, ṣugbọn ninu eyi, Ẹmi Mimọ jẹ àmì kan.... Ohun ti mo n sọ nipe, Ẹmi Mimọ jẹ edidi. O jẹ àmì ti Ọlọrun fifun awọn ọmọ Rẹ ti O yanfẹ. Lati kọ Ọ ni lati di ẹniti a kọ silẹ laarin awọn eniyan, lati gba a si ni lati kọ aye silẹ ati ohun gbogbo ti o wa ninu aye, ati lati di iṣẹ ti Ọlọrun ti fi edidi ifọwọ si Rẹ si. Mo maa n siṣẹ ni ọna ọkọ oju irin nihin pẹlu ile iṣẹ Harry Waterberry. A si maa n lọ lati ko ẹru sinu ọkọ̀. Arakunrin mi, “Doc” to n duro si ẹyin lọhun, o maa n ran mi lọwọ lati ko awọn ẹru naa sinu ọkọ. Nigbati a ba ti ko ẹru kun inu ọkọ kan tan, wọn maa n yẹ ọkọ̀ naa wo daradara, (iyẹn olùbẹ̀wò); ti o ba si ri ohun kan ti ko tọna, nibiti o ṣe e ṣe ki ẹru naa ti dànu tabi ki o fọ, tabi ohunkohun ti yoo bajẹ.... Ki yoo ṣe edidi ọkọ̀ naa titi ti a o fi di ẹru ọkọ naa daradara, titi ti yoo fi wa bi o ti yẹ, ti awọn ẹru naa si wa ni títò daradara, ti mímì ọkọ naa ko fi ni pa awọn ẹru ti o wa ninu ọkọ naa lara.

Ohun ti o n ṣẹlẹ niyi, a ko ki n ṣe edidi wa to bẹẹ gẹẹ; a ni ọpọlọpọ aiṣedede nipa awọn nkan. Nigbati Olùbẹ̀wò ba lọ yika lati ṣe ayẹwo aye rẹ, lati mọ boya ko si aiṣedede diẹ nipa awọn nkan, o ni aiṣedede diẹ nipa igbe-aye adura rẹ, o ni kudiẹ-kudiẹ nipa ibinu yẹn, ti o ni aiṣedede diẹ nipa ọrọ ẹyin; Oun ki yoo ṣe edidi ọkọ naa. Awọn iwa eeri yẹn, awọn ohun to buru, awọn èrò ti ko dara, Oun ko lee ṣe edidi ọkọ naa. Ṣugbọn nigbati O ba ri ohun gbogbo bi o ti yẹ ki o wa (Olubẹwo naa), nigbana, yoo ṣe edidi rẹ̀. Ko si ẹnikẹni ti yoo lee ṣi edidi yẹn titi ti ọkọ naa yoo fi de ibiti o n lọ, si ibi ti a ṣe edidi rẹ fun niyi. “Maṣe fi ọwọ kan ẹni-ami ororo Mi, ki o ma si ṣe awọn wolii Mi ni ibi. Nitori mo sọ fun yin, yoo sàn ki a so ọlọ-ata mọ ọ lọrun, ki iwọ si ri si iṣalẹ òkun, ju ki o tilẹ gbiyanju lati ṣẹ ọ̀kan tabi ki o kọsẹ diẹ lara eyiti o kere ju ninu awọn eniyan wọnyi ti a ti ṣe edidi wọn.” Ṣe o ri ohun ti o tumọsi?

Ohun ti Ẹmi Mimọ jẹ niyi. Oun ni idaniloju rẹ; Oun ni aabo rẹ; Oun ni ẹlẹri rẹ; Oun ni edidi rẹ; Oun ni àmì rẹ pe “Mo ti di ti ijọba Ọlọrun!” Ohun to wu ki eṣu sọ ko ni itumọ si ọ, ijọba ọrun ni ile mi. Eeṣe? Ọlọrun ti ̣se edidi mi; O ti fifun mi. O ti ṣe edidi mi sinu ijọba Rẹ, mo si di ti ogo! Jẹki iji naa ja; jẹki Satani ṣe ohun ti o ba fẹ ṣe; Ọlọrun ti ̣se edidi mi titi di ọjọ idande mi. Amin! Ohun ti Ẹmi Mimọ jẹ niyi. Ah, o yẹ ki iwọ maa fẹ ẹ; emi ko lee tẹsiwaju laisi Ẹmi Mimọ. A lee sọ ọpọlọpọ nipa Rẹ nihin, ṣugbọn o damiloju pe ẹ mọ ohun ti mo n sọ.

Bayi, pẹlu, ẹ jẹki a ṣi Bibeli wa sinu Iwe Johanu ori kẹrinla fun iṣẹju kanṣoṣo. Mo fẹran Ọrọ Ọlọrun. Oun ni otitọ. Bayi, Ẹmi Ọlọrun, Ẹmi Mimọ.... Ki ni Ẹmi Mimọ? Oun ni Ẹmi Kristi ninu rẹ.
Bayi, ki a to ka a, n o ni lati ṣe awọn alaye diẹ nihin. Ki ni Ẹmi Mimọ? Oun ni edidi. Ki ni Ẹmi Mimọ? Majẹmu ni. Ki ni Ẹmi Mimọ? Àmì ni. Kini Ẹmi Mimọ nigbanaa? Oun ni Ẹmi Jesu Kristi ninu yin. Nigba diẹ si ni Jesu sọ, “aye ki yoo ri mi mọ, sibẹ ẹyin yoo ri Mi; nitori Emi yoo wa pẹlu yin, paapa ninu yin titi de opin aye.”

Ẹmi Ọlọrun ninu ijọ Rẹ, Ki ni O wà fun? Ki ni idi ti O fi mu Un wa? Eyi jẹ diẹ ninu ohun ti akori aṣalẹ ọla, ṣugbọn ki ni idi ti O fifun wa ni Ẹmi Mimọ? Kilode ti.... Kilode ti Ẹmi Mimọ.... Ki lo wa fun? Ki ni O wọ inu rẹ fun? Ki ni idi ti O fi wọ inu mi? O jẹ lati maa siṣẹ Ọlọrun siwaju si i.
“Mo maa n ṣe eyiti o tẹ Baba lọrun. Nko wa lati ṣe ifẹ ti ara mi, bikoṣe ti Baba ti o ran Mi; Baba ti o ran mi si wa pẹlu Mi. Bi Baba Mi ṣe ti ran Mi, bẹẹ ni Emi pẹlu ran yin.” Ah, akiika! Baba ran an, O wọ inu Rẹ lọ. Baba ti O ran Jesu wọ inu Rẹ lọ, O siṣẹ nipasẹ Rẹ. Jesu ti O ran iwọ pẹlu n lọ pẹlu rẹ, O si wa ninu rẹ. Ti Ẹmi naa to n gbe ninu Jesu Kristi ba mu ki O maa ṣe ki O si maa hu wa ni ọna ti O gba hu wa, iwọ yoo ni awọn ero kan nipa bi yoo ṣe maa ṣe nigbati O ba wa ninu rẹ; nitori igbe aye yẹn ko lee yipada. Yoo maa lọ lati inu ara kan si ikeji, ṣugbọn ko lee yi iwa ẹda Rẹ pada, ti Ọlọrun ni.

-----
Bayi, a o beere bayi.... Ileri ti O ṣe fun wa fun igba ikẹyin.... Alagbawi yi, edidi, ileri, ohun gbogbo ti a ti sọ nipa Rẹ ni aṣalẹ yi - pẹlu ẹgbẹrun ni ọna mẹwa ọna siwaju si i - O ṣe jẹ ileri ti a ṣe fun wa ni opin ọjọ. Wọn ko ni i nigbana; wọn kan ni edidi naa ninu ẹran ara wọn ni, gẹgẹ bi edidi ati àmì, wọn si gbagbọ pe O n bọ wa. Wọn si rin nipa ojiji ofin, ninu eyiti a kọ wọn ni ila nipa ti ara.

Loni, a ko rin mọ nipa ojiji ofin; a n rin nipa agbara ajinde. A n rin nipa agbara Ẹmi, eyitiṣe edidi wa tootọ, Alagbawi wa tootọ, Olutunu wa tootọ, àmì wa tootọ pe a bi wa lati ọrun wa, ti a jẹ eniyan ọ̀tọ̀, ajeeji laarin aye, ti a n hu wa ni ọna to n ṣe aye ni kàyéfì, ti a n gba Ọlọrun mu ninu Ọrọ Rẹ, ti a n pe ohun gbogbo miran ni ikuna. Ọrọ Ọlọrun tọna. Ah, akiika! Ohun ti Ẹmi Mimọ jẹ niyi.

-----
Bayi, nisisiyi, a o ri pe, lẹyin ti a ti kun wọn pẹlu Ẹmi Mimọ, a ṣe edidi wọn di igbawo, eniyan melo lo wa nihin to ni Ẹmi Mimọ, ẹ jẹki a ri ọwọ yin loke. Iye awọn to ni Ẹmi Mimọ ju iye awọn ti ko nii lọ. A fẹ ki ẹ di ọkan ninu wa, Arakunrin, Arabinrin. Nigbati ẹ ba loye ohun ti O jẹ, O jẹ Ẹmi Ọlọrun to n gbe inu yin lati ṣe iṣẹ Ọlọrun. Nigbati Ọlọrun ba ran eyikeyi Ẹmi Rẹ sinu eyikeyi iranṣẹ Rẹ, eyikeyi wolii Rẹ, eyikeyi olukọ Rẹ, eyikeyi apọsteli Rẹ, nigba-gbogbo ni aye maa n kọ wọn. Wọn maa n pe wọn ni aṣiwere, ninu ikọọkan igba ijọ ti o ti wa. Nigbati Paulu duro niwaju Agrippa paapa, o wipe, “Ni ọna ti wọn n pe ni ẹkọkẹkọ.... ”Kini ẹkọkẹkọ? “Iṣiwere.” Ni ọna ti wọn n pe ni ẹkọkẹkọ....“Ni ọna ti wọn n pe ni Iṣiwere, agbarijọ kókó ẹ̀rọ, ọna ti mo gba jọsin si Ọlọrun awọn baba wa niyi.” Inu mi dun pe mo lee sọ pe mo jẹ ọ̀kan ninu wọn. Mo layọ pe mo lee sọ pe mo jẹ kan ninu wọn.

Bayi, lẹyin ti Ẹmi Mimọ yi ba le wọn, wọn di ololufẹ to bẹẹ gẹẹ ti wọn fi ni ohun gbogbo sọkan. Ṣe bẹẹ ni? Akiika, akiika, iru ijọsin wo niyi! A maa n kọ orin yẹn nigbamiran: “Ah, iru ijọsin wo, ah, iru ayọ pipe wo....” Bẹẹ ni. Wọn ko bikita boya oorun ràn tabi rara. Wọn ko beere fun àketè-irọrun. “Bayi, n o gba Ẹmi Mimọ,” ni ohun ti awọn kan n sọ fun mi, “Ọgbẹni Branham, ti iwọ yoo ba fi damiloju pe n o di olowo tabua, ti iwọ yoo ba sọ fun mi pe n o ni kanga to n sun epo-rọ̀bì jade, tabi ti n o ba ni ilẹ ti wọn ti n wa wura jade, ati....” Ṣe ẹ rii, awọn eniyan maa nkọ iyẹn, wọn si n kọ ẹkọ eke. Ọlọrun ko ṣe ileri awọn nkan wọnyẹn.

Eniyan ti o ba gba Ẹmi Mimọ ki i bikita boya oun n bẹbẹ fun ounjẹ tabi rara; iyẹn ko ni itumọ sii, o ti di ẹda ọrun. Ko ni ajọṣepọ pẹlu aye ẹṣẹ yi rara! Bẹẹ ni. Kì í bikita; boya ó wa ni, tabi ó lọ, ohun to wu ki o ṣẹlẹ. Jẹki wọn ṣe atako rẹ̀, tabi ki wọn fi ọ ṣe ẹlẹ́yà, tabi ki o ju ọlá rẹ nu, kilo ṣe pataki si ọ nibẹ? O wa ni oju ọna si Ilu Ogo. Hallelujah! Iwọ n wo Kristi, o si wa ni oju ọna rẹ si ọrun. Iwọ ko bikita nipa ohun to wu ki aye sọ. Ohun ti Ẹmi Mimọ wa fun niyi. O jẹ agbara; O jẹ edidi; O jẹ Olutunu; O jẹ alagbawi; O jẹ àmị. Ah, akiika! Oun ni idaniloju pe Ọlọrun ti tẹwọgba ọ.

Bayi, lẹyin ti a ba ti kun eniyan kan pẹlu Ẹmi Mimọ, ṣe o ṣe e ṣe ki inunibini ati awọn nkan miran mu ki o pada sẹyin.... Bayi, oun ko lee padanu mọ; o si jẹ ọmọ Ọlọrun sibẹ; yoo maa jẹ bẹẹ titi laelae, nitoripe titi di igbawo ni a ṣe edidi rẹ? [Apejọpọ dahun pe, “Titi di ọjọ idande.”] Bẹẹ ni. Ohun ti Bibeli sọ niyi.

Ka iroyin ni kikun ni... Kini Ẹmi Mimọ?


Ohun ijinlẹ Kristi.

Wẹẹbu iwe iroyin Gẹẹsi.

Iwe Ifihan jara.

 

Ọlọrun ati Imọ Atọka.
- Archaeology.

Igbasoke n bọ.

 

Awọn ẹkọ akọkọ
ti ifiranṣẹ naa.

Awọn ti o dara iroyin.
Jesu ku fun ese re.

Iribomi Omi.

 

Awọsanma eleri nla.

Ọwọn ti ina.

Ogo Shekinah ti Ọlọrun.

Ibojì ti ṣofo.
O ti jinde.

Ọlọrun salaye.

Awọn ìgbà ijọ meje.

Awọn edidi meje.

Ọlọrun ati Itan.
jara Atọka - Dáníẹ́lì.

Kristiẹni ije jara.
Ìgbéyàwó Àti Ìkọ̀sílẹ̀.
Akojọ Ifiranṣẹ.

Opin akoko jara.

Ngbe ọrọ jara.

Keresimesi jara.

Iku. Ohun ti nigbana?

Orúkọ Ọlọrun.

Ọkọ Noa.

 

Ẹṣẹ Atilẹba.
Je o ẹya apulu?

Adaparọ.
Awọn orisun - Babeli.

Ọlọrun ati Imọ.
Dainoso Adaparọ.

Archaeology.
Sodomu ati Gomorra.

  Iwe-mimọ sọ...

N óo bèèrè lọ́wọ́ Baba, yóo wá fun yín ní Alátìlẹ́yìn mìíràn tí yóo wà pẹlu yín títí lae.

Òun ni Ẹ̀mí tí ń fi òtítọ́ Ọlọrun hàn. Ayé kò lè gbà á nítorí ayé kò rí i, bẹ́ẹ̀ ni kò mọ̀ ọ́n. Ṣugbọn ẹ̀yin mọ̀ ọ́n, nítorí ó ń ba yín gbé, ó sì wà ninu yín.

Èmi kò ní fi yín sílẹ̀ bí aláìlárá. Mò ń pada bọ̀ wá sọ́dọ̀ yín.

Johanu 14:16-18


Tẹ aworan kan lati ṣe igbasilẹ aworan iwọn ni kikun tabi PDF.


Acts of the Prophet.

(PDFs Gẹẹsi)

Chapter 11
- The Cloud

(PDF Gẹẹsi)

Ọwọn ti ina.

Awọsanma eleri nla.




Ifiranṣẹ ibudo...Yan ede rẹ ki o gba awọn ifiranṣẹ ọfẹ lati ọdọ Arákùnrin Branham.