Tani Iwọ Fi Eyi Pe?
<< išaaju
Tani Iwọ Fi Eyi Pe?
William Branham.Ka iroyin ni kikun ni...
Tani Iwọ Fi Eyi Pe?Matteu 21:10-11,
10 Nigbati o si de Jerusalẹmu, gbogbo ilu mì, wipe, Tani eyi?
11 Ọpọ ijọ eniyan si wipe, Eyi li Jesu wolii ti Nasareti ti Galili.Nisisinyi a ti mọ akoko ti o jẹ, ati pe ọpọlọpọ ninu nyin ti mọ ori kan pato ti iwe mimọ yii. O jẹ lori... nitootọ ni ọjọ ti Kristi wa si Jerusalẹmu, o gun kẹtẹkẹtẹ kekere yii. Ati awa.... Àlàyé kan wa ti o sọ pe “kẹtẹkẹtẹ funfun kan ni.” Emi yoo foju inu wo, gẹgẹbi apẹrẹ bibọ Rẹ lẹẹkeji lori ẹsin kan. Ní àkókò yẹn, wòlíì náà sọ pé, “Yóò gùn... Ọba rẹ ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ lórí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, Ó sì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ti O tẹnu.” Bẹ́ẹ̀ ni Ó ṣe wá... lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kékeré kan, tí ó ru o maa nru ẹrù díẹ̀. Ṣugbọn nigbamiran ti O ba wa lati inu ogo (ni ori Ikọkandinlogun ti Ifihan), O wa bi aṣẹgun nla kan. Aṣọ Rẹ̀ ni a ri sinu ẹ̀jẹ̀, O joko lori ẹṣin funfun, gbogbo ogun ọrun si tẹle e lori ẹṣin funfun. Ati arosọ naa (kii ṣe iwe-mimọ tabi itan).... Ṣugbọn arosọ naa gbagbọ pe o gun kẹtẹkẹtẹ funfun kekere kan bi O ti ṣe wa si Jerusalẹmu.
Nisisinyi ti mo ti yan eyi... o jẹ pe... nitori pe a wa ninu awọn ojiji ti awọn... ni akoko ti Ajọdun ti keresimesi, ati ọdun titun; òpin ọdún àtijọ́, àti ìmúṣẹ tuntun wá. Awọn ọjọ diẹ lati isisinyi, ọpọlọpọ awọn eniyan yoo yi awọn oju-iwe tuntun pada ati ṣe awọn ohun titun ati ṣiṣe awọn ẹjẹ titun; ati ti ibẹrẹ ti ọdun titun. Ati pe ko dabi keresimesi si mi. Emi ko mọ idi, mo fẹ lati pe ni Ọjọ Santa Claus nigbagbogbo.“ Wo? Nitoripe ko si ohun kan nipato gan....
Kò lè jẹ́ ọjọ́ ìbí Kristi. Ko le ṣeeṣe lati jẹ bẹẹ. O ni lati jẹ pe ni Oṣu Kẹta tabi Kẹrin ni a bi I, nitori pe oun ni Ọdọ-Agutan naa. Oun si jẹ akọ agutan ti a bi ni abẹ ami àgbo, (Aries). O ni lati jẹ bẹẹ, ṣe o rii. Ati pe awọn agutan kii bi ọmọ ni Oṣu Kejila botiwukori. A bi agutan ni akoko àkọ́rọ̀ ọjọ. Ohun miiran si tun ni pe, awọn òke Judea bayi, ni iwọ̀n ogun ẹsẹ bata ojo-didi lori wọn. Báwo làwọn olùṣọ́ àgùntàn ṣe lè wà níbẹ̀?
Nitorináà, ó wá láti inú ìtàn àròsọ àwọn ará Róòmù, ìyẹn si jẹ ọjọ́ ìbí ọlọ́run oòrùn. Gẹgẹbi Oorun ti n kọja, awọn ọjọ n gun sii lati igba de igba, ati awọn oru nkuru sii. Ati laarin ogunjọ ati ọjọ mẹẹdọgbọn ti oṣu kejila ni ọjọ ibi ọlọrun oorun, labẹ awọn itan aye atijọ ti Romu. Ati lẹyin naa awọn oriṣa wọn.... Nigbanaa Ni wọn nṣe ayẹyẹ ọjọ-ibi ọlọrun-oorun. Constantine ni igbẹkale ofin ti ijọ ati ipinlẹ ati bẹẹbẹẹ lọ. Ó sọ pé: “Àwa yóò pààrọ̀ rẹ̀ [láìmọ̀ ohun tí ọjọ́ náà jẹ́], a ó sì fi í síbi ọjọ́ ìbí ọlọ́run oòrùn, a ó sì ṣe é ni: ọjọ́ ìbí Ọmọ Ọlọ́run,” wò ó.... ṣugbọn a ko mọ ọjọ wo ni o jẹ.
Ṣugbọn nisisiyi, nibẹ wọn ti mu Kristi kuro pupọpupọ, titi ti o jẹ ohun gbogbo... diẹ ninu wọn mu awọn itan diẹ ti aye atijọ nipa awọn ẹda ti o gbé ri pada, awọn olorukọ bi ti St Nicholas tabi Kriss Kringle, diẹ ninu awọn itan aye atijọ ti Germani. Ati pe gbogbo rẹ jẹ arosọ, Kristi ko si ninu rẹ rara. Ati awọn eniyan ti yipada sinu ki a ra ọti oyinbo, ati ayo, ati asakasa. Ati ọkunrin kan ti o... a oniṣowo le ta ọjà rẹ de akoko Keresimesi ti yoo si le gbe fun awọn akoko iyokù ninu odun, o ṣeeṣe, woo. O jẹ iru isinmi nla kan, iṣowo. Ati awọn talaka ọmọde lori pópó; awọn obi wọn ko ni anfaani lati bẹ wọn wo pẹlu ẹbun kan, bii lati ọdọ Santa Claus, wọn rin ni opopona, ati awọn ọwọ kekere wọn pẹlu idọti ati awọn oju wọn pupa. Mo kan korira lati rii pe o wa ṣẹlẹ bẹẹ. Ó yẹ kí ó jẹ́ ọjọ́ ìsìn ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run, dípò ìrora ọkàn àti ẹ̀fọ́rí àti àwọn ohun tí a ti ṣe. Ko si nkankan fun Kristi nipa iyẹn. Ṣugbọn a wa laarin gbogbo eyi ni bayi.
A ri ara wa, nkan bi wọn wà ṣe nigba yẹn. Wo, o n wọle ni bayi si ajọdun nla kan. Jésù ń bọ̀ wá síbi àse Ìrékọjá. O si ti wọ Jerusalemu... tabi O nwọ Jerusalẹmu. Isọtẹlẹ gbogbo gbọdọ di mimu ṣẹ. Ohun gbogbo ti o wa ninu Bibeli ni itumọ. Orukọ kọọkan ni itumọ kan. Ko si ohun ti a kọ sinu Iwe Mimọ ṣugbọn ti ko ni itumọ ti o jinlẹ.
Mo sọ ni alẹ kan ni Tucson, lori “Kilode ti O Ni Lati Jẹ Awọn Oluṣọ-agutan Dipo Ẹlẹsin?” A bi I l'oju ijọ. Ẹ̀mí mímọ́ sì ń jáde lọ sínú aginju, ó sì gbé ẹniti kì í ṣe àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀sìn, bíkòṣe àwọn olùṣọ́ àgùntàn. O ni lati jẹ bẹẹ. Awọn onimọ-jinlẹ kii yoo gba iru iṣẹ-iranṣẹ bẹẹ gbọ. Nitorina wọn... o ni lati jẹ oluṣọ-agutan. Mo wàásù níbí, ní ọdún bíi mélòó kan sẹ́yìn (ọdún méjì sẹ́yìn), “Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù Kekere?” Bí Olúwa ba fẹ́, ni ọdún Kérésìmesì tí ń bọ̀, mo fẹ́ kí a wàásù lórí, “Èéṣe Tí Ó Fi Ní Láti Jẹ́ Amòye?” Àwọn “Kí nìdí” wọ̀nyí rí ìdáhùn sí wọn, wọ́n sì wà nínú Bíbélì nibi. Ati pe a n gbe ni akoko iyalẹnu, akoko nla julọ ti gbogbo ọjọ. A n gbe nigba ti, nigbakugba ni... akoko le dẹkun ati pe ainipẹkun si le dapọ pẹlu rẹ ninu itẹsiwaju. Awọn ọjọ ti gbogbo awọn wolii ati awọn ọjọgbọn fojusọna fun.... O yẹ ki a wa nipo ẹṣọ ni gbogbo wakati wa, ki a maa ṣọna fun wiwa Rẹ.
A rii ara wa, ni Keresimesi yii, gẹgẹ bi wọn ti ṣe ni Keresimesi akọkọ. Aye ti mura tan lati ṣubu. Bi mo ti waasu ni ẹẹkan, nibikan, nipa iṣẹ-iranṣẹ Keresimesi kan, Aye To Nṣubu. Ati aye ti fẹrẹẹ ya pẹrẹpẹrẹ lẹẹkansi. Kiyesi awọn iwariri-ilẹ lori ibi ni California. Mo sọtẹlẹ, ṣaaju wiwa Jesu Oluwa, pe Ọlọrun yoo rìi ibẹ. Mo gbagbọ wipe Hollywood ati Los Angeles, ati awọn ibi ẹlẹgbin gbogbo nibẹ, wipe Ọlọrun Olodumare yoo rì wọn. Wọn yoo lọ si isalẹ okun. Ati pe o jẹ ẹṣẹ pupọ, o rii, o jẹ agbatẹru.
Ọlaju ti rin pẹlu oorun, lati... o si bẹrẹ ni ila-oorun to nlọ si iwọ-oorun. Ati nisisiyi o wa ni Iwọ-oorun Iwọ- oorun. Ti o ba lọ siwaju sii, yoo pada si Ila-oorun lẹẹkansi. Bẹẹni ẹniti o ru ẹsẹ niyẹn. Ati ẹṣẹ pẹlu ti rin pẹlu ọlaju, o si ti di ẹgbin ti gbogbo awọn igba. Awọn ohun ti wọn ṣe ti eniyan ni eyikeyi igba miiran kii yoo ronu iru nkan bẹẹ. Obirin ti ju ara wọn si iru eeri, ti ko si obinrin ni eyikeyi awọn igba ti yoo ro ti iru ohun ti a nṣe loni. Ati pe a si tun pe ara wa kristẹni. Ẹ wo ẹ̀gàn!
-----
Abajọ ti wolii nla naa fi dide, ti o si wipe, “Emi kii ṣe wolii tabi ọmọ wolii, ṣugbọn....” Wipe: Kiniun ti ke ramuramu, tani ki yoo bẹru? Ọlọrun si ti sọ̀rọ, tani le ṣe aisọtẹlẹ? (Wo, ohun kan wa ti o ni lati pe jade.) A wa ni wakati to lagbara; aye wa nibẹ̀. Ṣùgbọ́n ìjọ, ìjọ gidi (kii ṣe ijọ-adamọ); ṣugbọn ijọ, funraarẹ, ti ṣetan fun iṣẹgun nla julọ ti o ti wa ri: wiwa ọkọ-iyawo fun iyawo.A n wa ni apakan, a n wo fun Messia kan, ohun kan lati wa gba wa, ti yoo yọ wa kuro ninu gbogbo rẹ. A n wo... awọn wahala ni isalẹ ni ila-oorun. A ri ni Afrika awọn rogbodiyan, ati awọn iṣoro ẹya, ati awọn ajọṣepọ, ati iyapa. Ti ede-aiyede si wa laarin gbogbo wa ti a npariwo nibi laipẹ yii (awọn ọrẹ wa alawọ dudu) nipa, “A gbọdọ ni, a gbọdọ ni ajọṣepọ. Ohun ti a nilo niyẹn. A gbọdọ ni iṣọkan; olukuluku eniyan, dọgba; gbogbo eniyan tẹriba....” Iyẹn tọ́ o si pe. Iyẹn tọ́ o si pe. Nko gbagbọ ninu ẹru. Awọn eniyan wọnyẹn kii ṣe ẹrú lati bẹrẹ pẹlu. Wọn kii ṣe ẹrú.
Mo kọminu, loni, ti adura wa ba.... Ẹ gbọ ti wọn nwi pe, “Gbadura fun isọji nla. Gbadura fun eyi. Gbadura fun bibu jade. Gbàdúrà fún ìṣọ̀kan.” Mo woye pe, ti Ọlọrun yoo ba ran iru eto yii, ti a o ba gba a. Mo kan kọminu boya a o gba ohun ti O fi ranṣẹ si wa. Woo, Oun.... Idi ti a fi gbadura fun nkan wọnyi... nitori a mọ pe a nilo rẹ ni. Ṣugbọn nigbati Ọlọrun ba fi ranṣẹ ni ọna ti o fẹ, nigbanaa kii ṣe gẹgẹ bi itọwo wa, nitorina a ko ni gba a. Bẹ́ẹ̀ sì ni ó rí ní ọjọ́ yẹn. Bi ko ba ba adun igbagbọ wọn mu, ati ti wọn.... Wọn ko ni gba A, loni. Ìdí nìyí tí wọ́n fi bèèrè ìbéèrè yìí pé, “Tani èyí? Tani ẹni tí ń bọ̀ yìí?” Wo, o jẹ akoko nla kan. Oh, gbogbo eniyan ni... aya ko balẹ. Nkankan n ṣetan lati ṣẹlẹ.
Ki o si wo aye loni, iru wahala ti gbogbo agbaye n wa ninu rẹ. Ti o ba lọ si ita l'oju popo... O jẹ ewu lati wakọ. Ewu ni lati wa ni oju opopona mẹrin. Gbogbo eniyan wa ninu wahala, imọlara ati.... Kini o ṣẹlẹ? Dakẹjẹẹ. Nibo ni iwọ nlọ? Iyẹn ni o jẹ ki awọn ile-itọju aṣiwere kun fọ́fọ́. Ohun ti o mu ki ijọ wa ninu iru rudurudu niyẹn. Wọn ti di olori-kunkun lori ohun kan. Wọn ko ni duro ati ro Ọrọ Ọlọrun, ati wakati ti a n gbe; gbogbo eniyan wa labẹ inira, aibalẹ aya.
Ati nisisiyi, a mọ. O ye wa. Ilẹ̀ ayé ṣẹ̀ṣẹ̀ la ìrora ìbímọ ńlá kan kọjá. Ati pe ijọ ti nla awọn irora ibi kọja. Ó ní láti la ìrora ìbímọ ja kí ó tó lè fúnni.... Olúkúlùkù àwọn wòlíì, nígbà tí wọ́n wá sí ayé, ìrora ìbímọ ni fún ìjọ. Aye ti kọja Ogun Agbaye akọkọ, Ogun Agbaye Keji, ati ni bayi o ti ṣetan fun Ogun Agbaye Kẹta. Ati pe o tun wa ninu irora ibimọ lẹẹkansi. Ṣugbọn ohun kan ṣoṣo ni o wa ti o le mu alaafia wá, iyẹn ni Kristi.
Gbogbo awọn eto wa, ati awọn ero wa, ati awọn ile ijọsin wa, ati gbogbo iṣelu wa, ati gbogbo imọ-jinlẹ wa ati gbogbo nkan, a ti fi idi rẹ mulẹ pe isọkusọ ni. Ati lẹyin naa a gbadura fun Ọlọrun lati ran wa lọwọ, lati dasii, “Wọle wa ki o ṣe ohun kan fun wa.” Ati lẹyin naa nigbati O ba ṣe, Mo kọminu boya a o ni anfaani lati loye rẹ; bí a bá lè gbà á; tabi paapaa awa yoo ronu nipa rẹ?
Bayi, ohun ti wọn ṣe nigba atijọ niyẹn. Wọn ti ngbadura, wọn ni oniruuru awọn adari nla, wọn ti wa labẹ ijọba, wọn wa labẹ ọba, wọn ti wa labẹ ohun gbogbo, awọn onidajọ. Ṣùgbọ́n wọ́n mọ̀ pé ohun kan ṣoṣo ló wà tó lè gbà wọ́n là, ìyẹn ni Mèsáyà tó ń bọ̀. Mèsáyà náà sì túmọ̀ sí “ẹni àmì òróró náà.” Èniyàn kan tí a fi àmì òróró yàn. Nigbana ẹda eniyan naa, ni àmì òróró Ọrọ yàn. Ọrọ naa di ara laarin wa. Ati nigbati O si de, ko wa ninu adun ti wọn le fi fẹ Ẹ; Kì í ṣe adùn tí wọ́n ní... pé kí ó wọlé. Nítorí náà wọ́n kígbe pé, “Ta nìyí? Kini gbogbo racket yii nipa?” Àwọn ẹgbẹ talaka lasan kan wa lẹ́nu ibodè, wọ́n ń ja ọpẹ́ àti....
O si wipe, “Eeṣe, mu ki wọn pa ẹnu wọn mọ́. Wọ́n ń kó jìnnìjìnnì bá wa, bí wọ́n ṣe ń pariwo, tí wọ́n sì ń kigbe, ati bẹẹbẹẹ lọ.”
Ó ní, “Bí wọ́n bá pa ẹnu wọn mọ́, àwọn àpáta wọ̀nyí yóò kígbe lẹsẹkẹsẹ.”Oh, akoko ti n ṣii silẹ! Àsọtẹ́lẹ̀ ti ń di ìmúṣẹ. Abajọ! “Kìnnìún ké ramúramù.” Ó ní, “Tani kì yóò bẹ̀rù? Ọlọ́run sì ti sọ̀rọ̀, tani si lè ṣe aisọtẹ́lẹ̀?”
“Rara, ti ko ba jẹ ninu adun itọwo tiwa.... Ti ko ba jẹ ọna ti a fẹ Ẹ nikan, ọna ti a ro pe o yẹ ki Ó wá, àwa kò ní gbà Á.” Nigba naa awọn igbagbọ wọn ni o mu wọn kuro ninu Ọrọ ti a ti kọ. Wọ́n jìnnà rere, wọ́n kùnà láti mọ ẹni tí wọ́n ti gbàdúrà fun pé kí ó wá. Àwọn ìjọ wọn ti mu wọn jìnnà réré sí, títí di ìgbà tí ohun tí wọ́n ti gbàdúrà fún, fi tọ̀ wọ́n wa, kò sì sí nínú adun wọn, nítorí náà wọn kò lè gbà á gbọ́. Wọn ni lati lọ kuro ninu rẹ. Wọ́n lé E kúrò. Ohun kan ṣoṣo ni o le ṣe nigbati o ba pade Kristi. Boya ki o gba A tabi kọ Ọ. O ko le rin kuro lasan. O ko le ṣe bẹ. Kii ṣe fun ọ lati ṣee. Bi o ṣe jẹ yẹn.Ṣe akiyesi, bi awọn diẹ ṣe mọ pe Oun ni Ọrọ tii ṣe ẹni-ami-ororo naa, ti ọjọ yẹn. Kiyesi i, Ọlọrun li atetekọṣe, ti o jẹ ailopin, ti O si mọ ohun gbogbo lati ipilẹṣẹ.... Ati ohun kan ti nkan wọnyi jẹ ni ifihan awọn iwa ẹda Rẹ. Iwa kan.... O ni iwa ẹda kan. O jẹ ero rẹ. O ronu nkan kan, lẹyin naa o sọ, lẹyin naa o mu. Ọlọrun niyẹn. Oun, ni ibẹrẹ.... Ti o ba.... Ti o ba wa tabi iwọ yoo ba wa ni ọrun, o wa ni ọrun lati bẹrẹ pẹlu. O jẹ apakan ti Ọlọrun. O jẹ ero Rẹ̀. O mọ orukọ rẹ. O mọ ẹni ti o jẹ ṣaaju ki moleku to wa, ṣaaju ki imọlẹ to wa. Ṣaaju ki ohunkohun to wa, O mọ ọ ati orukọ rẹ. O sì fi i sinu ìwé ìyè Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, kí a tó dá ayé. Kiyesi i, iwọ ni ero Rẹ. Ati lẹyin naa o di ọrọ kan. Ati pe ọrọ jẹ ero ti a sọ. Lẹhin eyi ni o farahan.
Bi o ti ri niyẹn. Òun wà ní ìbẹ̀rẹ̀ fúnrarẹ̀. Ọlọrun n gbe pẹlu ero Rẹ fúnrarẹ̀. Oun ki yoo tun ṣe bẹẹ mo nitori a nfi ero Rẹ han. Ìdí nìyí tí a fi wà níhìn-ín, lónìí... Ọlọrun nba ero Rẹ ti a fi han ni idapọ. Woo? Nibẹ ni a wa. Nítorí náà, ìwọ, nípa ríronú, kò lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún gigun rẹ. O ko le ṣe eyi, iyẹn, tabi omiran. Ọlọrun lo n ṣe aanu. Ọlọrun ni. “Gbogbo awọn ti Baba ti fifun mi ni yoo wa si ọdọ mi, ko si si ẹnikan ti o le wa ayafi bi Baba mi ba fa a.” Iyẹn yanju rẹ.
Ka iroyin ni kikun ni...
Tani Iwọ Fi Eyi Pe?