Yíyan Ìyàwó Kan.

<< išaaju

itele >>

  Kristiẹni ije jara.

Ohun nla ni iyan.


William Branham.

Ka iroyin kikun ni...
Yíyan Ìyàwó Kan.

Bayii, ni ẹsẹ kẹsan, ori kọkanlelogun, iwe Ifihan.
9 Ọkan ninu awọn angẹli meje ni, ti nwọn ni igo meje ni, ti o kun fun iyọnu meje ikẹhin si wa, o si bami sọrọ wi pe, wa nihin, emi o fi iyawo, aya Ọdọ-Aguntan naa han ọ.

Ninu ọpọlọpọ nkan laye yii, a fun wa ni anfaani lati yan ohun ti a fẹ. Ọna ti eniyan fi ngbe igbesi aye ganan jẹ nipa yiyan. A ni ẹtọ lati yan ohun ti a fẹ, ati bi a se fẹ gbe igbe aye wa. Ìyàn ni iwe kika. O lee yan yala o fẹ kawe, tabi o ko fẹ. Anfaani ti a ni niyii. Iyan ni lati se ohun to tọ tabi ohun to kuna. Ọkunrin kọọkan, obinrin kọọkan, ọmọkunrin, ọmọbinrin ni lati yan boya iwọ yoo gbiyanju lati gbe igbe aye to tọ tabi bẹẹ kọ. Iyan ni. Ohun nla ni iyan.

Ibi ti iwọ yoo ti lo ayeraye rẹ, iyan ni. Boya ni alẹ yii, ọpọlọpọ yin ni yoo se ipinnu ibi ti iwọ yoo ti lo ayeraye rẹ, ki isin yii to pari. Bi iwọ ba kọ Ọlọrun silẹ lọpọ igba, igba kan yoo de ti iwọ yoo kọ Ọ silẹ fun igba to gbẹhin. Aala kan wa laarin aanu ati idajọ, ohun to lewu si ni fun ẹnikẹni- ọkunrin, obinrin, ọmọkunrin tabi ọmọbinrin- lati rekọja aala na, nitori pe, ko si atunse mọn, bi iwọ ba ti re aala naa kọja. Nitori naa, ni alẹ yii, o le jẹ akoko ti ọ̀pọ̀ yoo yan ibi ti wọn yoo ti lo ainipẹkun.

Anfaani ati yan miiran tun wa ti a ni, ni aye yii, eyi ni yiyan ọkọ tabi aya. Ọ̀dọ́ ọkunrin kan, tabi ọ̀dọ́bìnrin. Ọ̀dọ́kùnrin yii yoo yan, ọ̀dọ́bìnrin ni ẹ̀tọ́ lati gbà tabi ki o kọ̀. Sugbọn yíyàn ni lọna mejeeji, atọkunrin, atobinrin. Wọn ni ẹtọ lati yan.

Bẹẹ naa ni iwọ ni ẹ̀tọ́ gẹgẹbi Kristẹni. Iwọ ni ẹ̀tọ́ lati yan ijọ ti o wu ọ ni Amẹrika lati maa jọsin pẹlu. Eyi ni anfaani ti o ni gẹgẹbi ẹni ti o ngbe Amẹrika lati yan ijọ to wu ọ lati darapọ mọn. Iyan kan ni. Iwọ ko ni lati jẹ ọmọ eyikeyi ninu wọn bi iwọ ko ba fẹ. Sugbọn bi iwọ ba fẹ kuro ni ijọ Eleto, ki o si di ijọ Onitẹbọmi, tabi ijọ Aguda, tabi ijọ to tako ijọ Aguda ati bẹẹbẹẹ lọ, ko si ẹni to lee fi ipa mu ọ lọ si eyikeyi ninu wọn. Eyi ni ominira wa. Ohun ti ijọba-awọn-eniyan-fun-awọn-eniyan fun wa niyii. Olukuluku eniyan ni o lee yan fun ra rẹ. Ominira ti ẹsin. Ohun nla si ni eleyi. Ki Ọlọrun ran wa lọwọ lati pa eleyi mọn bi o ba se lee pẹ to.

Iwọ si ni ẹtọ pẹlu, nigba ti o yan ijọ yii, o ni anfaani lati yan ijọ ti yoo tọọ sọna si ile rẹ ainipẹkun. Iwọ lee yan ijọ kan ti o ni ẹkọ adamọn kan, bi o ba se pe, ẹkọ adamọn yẹn ni iwọ fẹ. Tabi ijọ miiran si tun ni ẹkọ adamọn tirẹ. Ọrọ Ọlọrun si wa pẹlu ti iwọ lee yan. O nilati yan ohun ti o fẹ. Ofin kan wa laarin wa ti a ko kọ silẹ, ti o fun wa ni anfaani lati yan.

Mo gbagbọ pe Elijah ni, nigba kan lori oke kamẹli, lẹyin gbangba-dẹkun-kedere-bẹwo naa. Ni wakati wahala kan, iru eyi ti awa naa nbọ ninu rẹ laipẹ bayii. O si lee jẹ wi pe, iwọ tabi emi yoo yan lalẹ yii gẹgẹbi wọn ti se ni oke kamẹli. Nitootọ, mo ro wi pe ipinnu yii nlọ lọwọ bayi ni gbogbo agbaye. Sugbọn, akoko na ti sunmọle, ti iwọ nilati yan ohun kan.

Ẹyin eniyan ti o jẹ ti awọn ijọ tofi-ẹkọkẹkọ-rọpo-Ọrọ-Ọlọrun, saa gba eleyi gbọ pe: wakati naa ti de tan, ti iwọ ni lati yan ohun kan. Yala ki ẹ lọ sinu Igbimọ Ijọ Agbaye, tabi ki o ma jẹ ọmọ ijọ-tofi-ẹkọkẹkọ-rọpo-Ọrọ- Ọlọrun. O di dandan lati se eleyii. Iyan yi si nbọ laipẹ, o si jẹ ohun to lewu lati duro de akoko to gbẹyin yẹn, Nitori pe, o seese ki o ti gba ohun kan ti iwọ ko lee kuro ninu rẹ mọn. O mọn wi pe, akoko kan wa ti a lee kilọ fun ọ, lẹhin naa, bi iwọ ba kọja aala ikilọ naa, nigba naa, a ti sami si ọ ni odikeji, o ti gba ami.

Ranti, nigba ti ọdun idasilẹ ba de, ti Alufaa gun ẹsin la ilu lọ, ti o fun ipe wi pe gbogbo ẹru lee gba idasilẹ, ki wọn maa lọ ni ominira. Sugbọn bi wọn ba kọ lati gba ominira naa, a ni lati mu ẹru yii lọ sibi òpó Tẹmpili, ki a si fi ìlu kan lu u ni eti. Lẹhin naa, yoo sin oluwa rẹ titi lae. A fi amin si eti rẹ gẹgẹbi amin gbigbọ. Igbagbọ n wa nipa gbigbọ. O gbọ ohun ipe naa, sugbọn o kọ̀ lati feti sii.

Lọpọ igba, ọkunrin ati obinrin maa n gbọ otitọ Ọlọrun, ti wọn yoo rii pe, a jẹrigbe e lati fi dani-loju pe, Otitọ ni. Sibẹ, wọn ko fẹ gbọ Ọ. Wọn ni idi miiran, ati ohun miiran ti wọn yan, ju lati dojukọ otitọ. Nitori naa, a lee dí eti wọn si Ihinrere. Wọn ko lee gbagbọ mọn. Imọran mi fun ọ ni pe, nigba ti Ọlọrun ba sọrọ si ọkan rẹ, se ohun ti O sọ lẹsẹkẹsẹ!
Elijah fun wọn ni anfaani lati yan. “Ẹ yan loni, ẹni ti ẹyin yoo sin. Bi Oluwa ba jẹ Ọlọrun, ẹ sin In. Bi o ba si jẹ Baali ni Ọlọrun, ẹ sin in”.

Bi a se rii wi pe, gbogbo ohun ti a nfojuri nse akawe ohun ti ẹmi, bi a ti lọ ninu rẹ ninu ẹkọ wa ni owurọ yii- gẹgẹbi oorun ati ìse rẹ. Eyi ni Bibeli mi akọkọ. Ki emi to ka ohunkohun ninu Bibeli, mo mọn Ọlọrun. Nitori pe a kọ Bibeli si ibi gbogbo ninu awọn ẹda Ọlọrun, o si ba Ọrọ Ọlọrun mu rẹgi- Gẹgẹbi iku, isinku ati ajinde ti ẹda Ọlọrun, ati yíyọ oòrùn, lila aye kọja, wiwọ rẹ, kiku, jijinde lẹẹkansi- Ọpọlọpọ nkan ni a le fi safiwe Ọlọrun ninu ẹda, ti a nilati fi silẹ fun lwaasu yii.

Bayii, bi ohun ti a fojuri ba nse apẹẹrẹ ti ẹmi, nigba naa, yiyan iyawo kan nipa ti ara jẹ akawe ti lyawo nipa ti ẹmi. Oun ti o lagbara ni nigba ti a ba lọ yan iyawo kan, tabi ọkọ kan. Nitori pe, ẹjẹ igbeyawo yii, “Titi lku yoo fi ya wa ni”. Bi a se nilati pa a mọn niyii. Iwọ si jẹ ẹjẹ yii, niwaju Ọlọrun, pe iku nikan ni yoo ya yin.

Mo si ro pe o yẹ ki a…. Ọkunrin kan ti ọpọlọ rẹ pe, ti o si n seto ọjọ iwaju rẹ, o ni lati sọra ni yiyan iyawo yẹn. Sọra nipa ohun ti iwọ nse yii. Obinrin ti o si n yan ọkọ tabi ti o n gba lati fẹ ọkunrin kan ni ọkọ, gbọdọ sọra pupọ, ki o mọn ohun to nse, paapaa ni ọjọ oni. Ọkunrin ni lati ronu, ki o gbadura, ki o to yan iyawo kan.

Mo ro wi pe, ohun to fa ọpọlọpọ ikọra-ẹni-silẹ loni laarin ọkọ ati iyawo, tobẹẹ ti o jẹ pe, Amẹrika ni o siwaju ni gbogbo aye nipa ikọra-ẹni-silẹ ninu igbeyawo. Orilẹ-ede yi si yẹ ki o jẹ orile-ede kristẹni. Abuku nla ni! Mo gbagbọ pe idi ti o fi ri bẹẹ ni pe, awọn eniyan ti fi Ọlọrun silẹ, atọkunrin, atobinrin ti fi Ọlọrun silẹ. A si ri pe, bi ọkunrin ba gbadura, ti obinrin si gbadura ki wọn to yan-kii se ki wọn kan wo oju to lẹwa, tabi ejika to tobi, to si lagbara tabi ohun kan bẹẹ, tabi ifẹ aye kan-sugbọn ki wọn kọkọ wo Ọlọrun, ki wọn wipe, “Ọlọrun, se eto Rẹ ni eyii?”.

-----
Bi a ba si kiyesi ohun ti a n se nigbati a ba lọ se igbeyawo, nigba ti a ba yan iyawo tabi ọkọ wa, bi a ba lee yẹwo daradara. Ọkunrin kan gbọdọ gbadura gidigidi, nitori pe, o lee ba gbogbo igbe aye rẹ jẹ. Ranti pe, ẹjẹ naa ni “Titi ti iku yoo fi ya wa”. Eyi lee ba gbogbo igbesi aye rẹ jẹ bi o ba sìyàn. Sugbọn bi oun ba mọn pe, oun n yan ẹni ti ko tọ, oun si nfẹ obinrin ti ko yẹ ki o fẹ, ti o si se e lọnakọna, ẹ̀bi rẹ ni. Bi obinrin naa ba gba lati fẹ ọkọ kan, ti o si mọn pe ko yẹ lati jẹ ọkọ fun oun, nigba naa, ẹbi rẹ ni, lẹhin ti o ti mọn ohun to tọ ati ohun to kuna. Nitori naa, o ko gbọdọ see, afi igba ti o ba ti gba adura yanju.

Bakan naa ni o ri, nigba ti o ba n yan ijọ kan. O gbọdọ gbadura lati yan ijọ ti iwọ yoo maa jọsin ninu rẹ. Ranti pe, awọn ijọ ni ẹmi tiwọn. Bayii, emi ko fẹ se atako, sugbọn mo rii wi pe arugbo ni mi, mo si ni lati fi aye silẹ lọjọ kan. Mo ni lati jihin ni ọjọ idajọ fun ohun ti mo ba sọ lalẹ yii tabi ni igbakuugba. Nitori naa, mo ni lati mọn ohun ti mo n se, ki o si da mi loju.

Sugbọn, bi o ba lọ si ile isin kan, bi o ba fẹ mọn iwa ijọ naa, iwọ saa fiyesii olusọ-agutan fun igba diẹ-iwọ yoo ri i pe, ipejọpọ naa n se bi olusọ-agutan wọn. Nigba miiran, mo tilẹ n ro wipe, se kii se pe, a n gba ẹmi ara wa, dipo Ẹmi Mimọ. Bi iwọ ba de ijọ kan ti Olusọ-agutan jẹ eniyan kan ti ko gba igbakugba ti o si mu iduro rẹ gidi-iwọ yoo ri wi pe, ipejọpọ n se bẹẹ gẹgẹ. Emi yoo mu ọ lọ si ipejọpọ kan, nibiti Olusọ-agutan ti ma n fi ori siwa-sẹhin. Kiyesi ipejọpọ naa. Wọn n se bẹẹ gẹgẹ. Bi o ba ri Olusọ-agutan kan ti o jẹ wi pe, ko si ohun ti ko lee gbagbọ, ijọ rẹ naa yoo se bẹẹ gẹgẹ. Nitori naa, bi emi ba fẹ yan ijọ, emi yoo yan ijọ to jẹ ojulowo, to duro lori ẹkọ ipilẹ Bibeli, ti o si gba gbogbo ọrọ Bibeli gbọ, bi emi ba fẹ yan ijọ kan ti n o o fi ẹbi mi si. Yan.

-----
Lẹẹkan si, iru obinrin ti ọkunrin kan ba yan lati fẹ, yoo fi ilepa ọkan rẹ ati iwa rẹ han. Bi ọkunrin kan ba yan obinrin ti ko dara, eyi n fi iwa rẹ han. Ohun tó sì so ara rẹ̀ mọ́n, fi ohun to wa ninu ọkunrin na han, nigba ti o ba yan an ni iyawo. O fi ohun to wa ni isalẹ ọkan rẹ han. Laibikita, ohun ti o fi ẹnu sọ jade, kiyesi ohun ti o fẹ niyawo. Bi mo ba lọ si ile isẹ ẹnikan ti o pe ara rẹ ni kristẹni, o si ni awọn aworan buburu ti a lẹ mọn ara ogiri kaakiri, orin taka nsufe si n dun nibẹ, emi ko bikita fun ohun to fẹnu sọ, n ko gba ẹri rẹ gbọ, nitori pe, ẹmi rẹ nifẹ si ohun aye, o n gba imisi ninu ohun aye.

Ki a wa sọ pe, oun lọ fẹ alajota kan, tabi o fẹ obinrin asẹwo oniwa-ibajẹ kan, tabi ọmọ alẹjà igbalode oni kan? O nfi inu ọkan rẹ han, nipa ohun ti ile rẹ yoo jẹ lọjọ iwaju, nitoripe, o fẹ ẹ lati tọ awọn ọmọ rẹ. Ohunkohun ti ohun ba si jẹ, bẹ ẹ gẹlẹ ni yoo se tọ awọn ọmọ naa. Nitori naa, o fi ifẹ ọkan ọkunrin naa han. Ọkunrin ti o ba fẹ iru obinrin bẹẹ nfi ohun ti ọkunrin yii lero fun ọjọ iwaju. Njẹ iwọ ro pe, kristẹni tootọ kan yoo se ohun yii? Rara, alagba, Emi ko ro bẹẹ. Kristẹni tootọ, ki yoo wa awọn obinrin, a-fi-ẹwa-ara-pawo, a-fijojẹun ati awọn oniwa-ibajẹ afifẹkufẹ-ara-pawo wọnyii. Yoo wa iwa rere ti kristẹni tootọ.

Bayii, a o yipada nisisinyi si ipa ti e̟mi. Nigba ti iwo̟ ba si ri ijo̟ kan ti o wa ninu aye, ti o nse awọn ohun taye, to nba aye s̟e ohun gbogbo, to n se alabapin ohun aye, ti ko si ka awo̟n ofin O̟lo̟run si, bi ẹni pe Ọlọrun ko ko̟ wo̟n, nigba naa, o ye̟ ki o mo̟n daju pe, Kristi ko ni fe̟ iru ijo̟ be̟e̟ ni iyawo. Nje̟ o lee ro o wi pe, Kristi yoo fe̟ iru ijo̟ to̟jo̟ oni ni Iyawo? Ki i s̟e Oluwa mi? Emi ko ro be̟e̟. Rara!
Ranti, ọkunrin kan ati iyawo re̟, o̟kan ni wo̟n. Nje̟ iwo̟ yoo da ara re̟ po̟ mo̟n iru eniyan bi eleyi? Bi iwo̟ ba see, dajudaju eyi yoo ja igbagbọ mi ninu kule̟.

Nigba naa, melomelo ni ki O̟lo̟run da Ara re̟ po̟ mo̟n ohun kan be̟e̟? Ase̟wo, ijo̟-ti-o-fi e̟ko̟ke̟ko̟-ro̟po-O̟ro̟-O̟lo̟run pọnbele! Nje̟ iwo̟ ro wipe ohun yoo see? Ti o ni afarawe iwa-bi-O̟lo̟run, sugbo̟n ti o s̟e̟ agbara rẹ̀ - Oun ko le s̟e laelae. O gbo̟do̟ ni iwa ti Ọlọrun ninu rè̟. Ijo̟ ti o di atunbi nitooto̟, gbo̟do̟ ni iwa Kristi ninu rè̟, nitori pe, ọkọ ati iyawo je̟ o̟kan naa. Bi Jesu ba si se kiki ohun to wu Ọlọrun, to pa Ọrọ Rẹ mọn, ti o si fi Ọrọ-Rẹ-han-faye-ri, Iyawo Rẹ ni lati ni iru iwa kan naa. Ko lee je̟ Ijo̟-tofi-ẹkọkẹkọ-rọpo-Ọrọ-Ọlọrun, lọnakọna. Nitori pe, bi o ti wu ki iwọ fẹ sọ pe rara, a n dari ijọ bẹẹ lati ọwọ igbimọ kan nibikan, ti yoo sọ ohun to gbọdọ se- ti o si jẹ pe, lọpọ ìgbà, o lodi nigba ẹgbẹgbẹrun ọna si otitọ Ọrọ Ọlọrun.

O buru pupo̟ pe a kuro lo̟do̟ Oludari tooto̟ ti O̟lo̟run fi fun wa, lati dari Ijo̟. O̟lo̟run ko ran Alagba Ipinlẹ kan, ko ran biso̟bu, olori awo̟n biso̟bu, Alufaa, tabi Poopu. O ran E̟mi Mimo̟ lati dari Ijo̟. “Nigba ti Oun, E̟mi Mimo̟ naa ba de, yoo to̟ ọ si gbogbo Otito̟, yoo fun ọ ni isipaya nkan wo̟nyii, ti Mo ti so̟ fun un yin, yoo mu wọn wa si iranti yin, yoo si fi awo̟n ohun ti o nbo̟ han yin”. E̟mi Mimo̟ yoo s̟e iye̟n.

Bayii, ijo̟ ode oni korira eleyi. Wo̟n ko si nife̟ rẹ̀. Nitori naa, bawo ló s̟e lee je̟ Iyawo Kristi? Awọn eniyan loni nyan ijo̟ ode oni to fi ẹko̟ke̟ko̟-rọpo-O̟ro̟ O̟lo̟run - ohun ti eyi n se ni pe, o fi ailoye wo̟n han ninu O̟ro̟ naa. Emi ko fe̟ mu inu bii yin, sugbo̟n mo fe̟ ki o jinle̟ to, tobe̟e̟ ti iwọ yoo fi ye̟ e̟ wo gidigidi.

Ka iroyin kikun ni...
Yíyan Ìyàwó Kan.


Ohun ijinlẹ Kristi.

Wẹẹbu iwe iroyin Gẹẹsi.

Iwe Ifihan jara.

 

Ọlọrun ati Imọ Atọka.
- Archaeology.

Igbasoke n bọ.

 

Awọn ẹkọ akọkọ
ti ifiranṣẹ naa.

Awọn ti o dara iroyin.
Jesu ku fun ese re.

Iribomi Omi.

 

Awọsanma eleri nla.

Ọwọn ti ina.

Ogo Shekinah ti Ọlọrun.

Ibojì ti ṣofo.
O ti jinde.

Ọlọrun salaye.

Awọn ìgbà ijọ meje.

Awọn edidi meje.

Ọlọrun ati Itan.
jara Atọka - Dáníẹ́lì.

Kristiẹni ije jara.
Ìgbéyàwó Àti Ìkọ̀sílẹ̀.
Akojọ Ifiranṣẹ.

Opin akoko jara.

Ngbe ọrọ jara.

Keresimesi jara.

Iku. Ohun ti nigbana?

Orúkọ Ọlọrun.

Ọkọ Noa.

 

Ẹṣẹ Atilẹba.
Je o ẹya apulu?

Adaparọ.
Awọn orisun - Babeli.

Ọlọrun ati Imọ.
Dainoso Adaparọ.

Archaeology.
Sodomu ati Gomorra.

  Iwe-mimọ sọ...

Mo fi ilẹ̀ ati ọ̀run ṣe ẹlẹ́rìí níwájú yín lónìí, pé mo fun yín ní anfaani láti yan ikú tabi ìyè, ati láti yan ibukun tabi ègún. Nítorí náà, ẹ yan ìyè kí ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín lè wà láàyè.

Diutaronomi 30:19


Tẹ aworan kan lati ṣe igbasilẹ aworan iwọn ni kikun tabi PDF.


Acts of the Prophet.

(PDFs Gẹẹsi)

Ìgbéyàwó Àti Ìkọ̀sílẹ̀.

(PDF)

William Branham
Life Story.

(PDF Gẹẹsi)

How the Angel came
to me.
(PDF Gẹẹsi)

As the Eagle
Stireth her nest.

(PDF Gẹẹsi)
 

Chapter 14
- Sabino Canyon

(PDF Gẹẹsi)
Ibi ti idà farahan.


Ifiranṣẹ ibudo...Yan ede rẹ ki o gba awọn ifiranṣẹ ọfẹ lati ọdọ Arákùnrin Branham.